< 1 John 5 >
1 Olúkúlùkù ẹni tí ó bá gbàgbọ́ pé Jesu ni Kristi, a bí i nípa ti Ọlọ́run: àti olúkúlùkù ẹni tí ó fẹ́ràn. Ẹni tí ó bi nì, ó fẹ́ràn ẹni tí a bí nípasẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú.
Everyone who believes that Jesus is the Christ has been born of God, and everyone who loves the Father also loves those born of Him.
2 Nípa èyí ni àwa mọ̀ pé àwa fẹ́ràn àwọn ọmọ Ọlọ́run, nígbà tí a bá fẹ́ràn Ọlọ́run, tí a sì ń pa òfin rẹ̀ mọ́.
By this we know that we love the children of God: when we love God and keep His commandments.
3 Nítorí èyí ni ìfẹ́ Ọlọ́run, pé kí àwa pa òfin rẹ̀ mọ́: òfin rẹ̀ kò sì nira,
For this is the love of God, that we keep His commandments. And His commandments are not burdensome,
4 nítorí olúkúlùkù ẹni tí a bí nípa tí Ọlọ́run, ó ṣẹ́gun ayé. Èyí sì ni ìṣẹ́gun tí ó ṣẹ́gun ayé, àní ìgbàgbọ́ wa.
because everyone born of God overcomes the world. And this is the victory that has overcome the world: our faith.
5 Ta ni ẹni tí ó ṣẹ́gun ayé, bí kò ṣe ẹni tí ó gbàgbọ́ pé Ọmọ Ọlọ́run ni Jesu jẹ́?
Who then overcomes the world? Only he who believes that Jesus is the Son of God.
6 Èyí ni ẹni tí ó wá nípa omi àti ẹ̀jẹ̀, Jesu Kristi, kì í ṣe nípa omi nìkan, bí kò ṣe nípa omi àti ẹ̀jẹ̀. Àti pé Ẹ̀mí ni ó sì ń jẹ́rìí, nítorí pé òtítọ́ ni Ẹ̀mí.
This is the One who came by water and blood, Jesus Christ—not by water alone, but by water and blood. And it is the Spirit who testifies to this, because the Spirit is the truth.
7 Nítorí pé àwọn mẹ́ta ni ó ń jẹ́rìí.
For there are three that testify:
8 Ẹ̀mí, omi, àti ẹ̀jẹ̀: àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sì wà ni ìṣọ̀kan.
the Spirit, the water, and the blood—and these three are in agreement.
9 Bí àwa ba ń gba ẹ̀rí ènìyàn, ẹ̀rí Ọlọ́run tóbi jù: nítorí ẹ̀rí Ọlọ́run ni èyí pé, Ó tí jẹ́rìí ní ti Ọmọ rẹ̀.
Even if we accept human testimony, the testimony of God is greater. For this is the testimony that God has given about His Son.
10 Ẹni tí ó bá gba Ọmọ Ọlọ́run gbọ́, ó ni ẹ̀rí nínú ara rẹ̀; ẹni tí kò bá gba Ọlọ́run gbọ́, ó ti mú un ni èké; nítorí kò gba ẹ̀rí náà gbọ́ tí Ọlọ́run jẹ́ ní ti Ọmọ rẹ̀.
Whoever believes in the Son of God has this testimony within him; whoever does not believe God has made Him out to be a liar, because he has not believed in the testimony that God has given about His Son.
11 Ẹ̀rí náà sì ni èyí pé Ọlọ́run fún wa ní ìyè àìnípẹ̀kun, ìyè yìí sì ń bẹ nínú Ọmọ rẹ̀. (aiōnios )
And this is that testimony: God has given us eternal life, and this life is in His Son. (aiōnios )
12 Ẹni tí ó bá ni Ọmọ, ó ni ìyè; ẹni tí kò bá sì ni Ọmọ Ọlọ́run, kò ní ìyè.
Whoever has the Son has life; whoever does not have the Son of God does not have life.
13 Nǹkan wọ̀nyí ni mo kọ̀wé rẹ̀ sí yín, àní sí ẹ̀yin tí ó gba orúkọ Ọmọ Ọlọ́run gbọ́; kí ẹ̀yin lè mọ̀ pé ẹ̀yin ní ìyè àìnípẹ̀kun, àní fún ẹ̀yin tí ó gba orúkọ Ọmọ Ọlọ́run gbọ́. (aiōnios )
I have written these things to you who believe in the name of the Son of God, so that you may know that you have eternal life. (aiōnios )
14 Èyí sì ni ìgboyà tí àwa ní níwájú rẹ̀, pé bí àwa bá béèrè ohunkóhun gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀, ó ń gbọ́ tí wa.
And this is the confidence that we have before Him: If we ask anything according to His will, He hears us.
15 Bí àwa bá sì mọ̀ pé ó ń gbọ́ tí wa, ohunkóhun tí àwa bá béèrè, àwa mọ̀ pé àwa rí ìbéèrè tí àwa ti béèrè lọ́dọ̀ rẹ̀ gbà.
And if we know that He hears us in whatever we ask, we know that we already possess what we have asked of Him.
16 Bí ẹnikẹ́ni bá rí arákùnrin rẹ̀ tí ń dẹ́ṣẹ̀ tí kì í ṣe sí ikú, òun yóò béèrè, Ọlọ́run yóò sì fún un ni ìyè, àní, fún àwọn tí ń dẹ́ṣẹ̀ tí kì í ṣe sí ikú. Ẹ̀ṣẹ̀ kan ń bẹ sì ikú, èmi kò wí pé ki òun gbàdúrà fún èyí.
If anyone sees his brother committing a sin not leading to death, he should ask God, who will give life to those who commit this kind of sin. There is a sin that leads to death; I am not saying he should ask regarding that sin.
17 Gbogbo àìṣòdodo ni ẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀ṣẹ̀ kan ń bẹ tí kì í ṣe sí ikú.
All unrighteousness is sin, yet there is sin that does not lead to death.
18 Àwa mọ̀ pé ẹnikẹ́ni tí a bí nípa ti Ọlọ́run kì í dẹ́ṣẹ̀: ṣùgbọ́n ẹni tí a bí nípa tí Ọlọ́run a pa ara rẹ̀ mọ́, ẹni búburú kò ní lè fọwọ́ kàn án.
We know that anyone born of God does not keep on sinning; the One who was born of God protects him, and the evil one cannot touch him.
19 Àwa mọ̀ pé tí Ọlọ́run ni wá, àti gbogbo ayé ni ó wà lábẹ́ agbára ẹni búburú náà.
We know that we are of God, and that the whole world is under the power of the evil one.
20 Àwa sì mọ̀ pé Ọmọ Ọlọ́run dé, ó sì tí fi òye fún wa, kí àwa lè mọ ẹni tí í ṣe òtítọ́, àwa sì ń bẹ nínú ẹni tí í ṣe òtítọ́, àní, nínú Ọmọ rẹ̀, Jesu Kristi. Èyí ni Ọlọ́run òtítọ́, àti ìyè àìnípẹ̀kun. (aiōnios )
And we know that the Son of God has come and has given us understanding, so that we may know Him who is true; and we are in Him who is true—in His Son Jesus Christ. He is the true God and eternal life. (aiōnios )
21 Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ pa ara yín mọ́ kúrò nínú òrìṣà.
Little children, keep yourselves from idols.