< 1 John 1 >
1 Èyí tí ó wà láti àtètèkọ́ṣe, tí àwa ti gbọ́, tí àwa ti fi ojú wa rí, tí àwa sì ti tẹjúmọ́, tí ọwọ́ wa sì ti dì mú; èyí tí a kéde; ní ti ọ̀rọ̀ ìyè;
論到那從起初就有的生命的聖言,就是我們聽見過,我們親眼看見過,瞻仰過,以及我們親手摸過的生命的聖言--
2 iyè náà sì ti farahàn, àwa sì ti rí i, àwa sì ń jẹ́rìí, àwa sì ń sọ ti ìyè àìnípẹ̀kun náà fún yín, tí ó ti ń bẹ lọ́dọ̀ Baba, tí ó sì farahàn fún wa. (aiōnios )
這生命已顯示出來,我們看見了,也為他作證,且把這原與父同在,且已顯示給我們的永遠的生命,傳報給你們-- (aiōnios )
3 Àwa ń sọ fún yín, èyí tí àwa ti rí, tí àwa sì ti gbọ́, kí ẹ̀yin pẹ̀lú kí ó lè ní ìdàpọ̀ pẹ̀lú wa. Nítòótọ́ ìdàpọ̀ wa sì ń bẹ pẹ̀lú Baba àti pẹ̀lú ọmọ rẹ̀, Jesu Kristi.
我們將所見所聞的傳報給你們,為使你們也同我們相通;原來我們是同父和他的子耶穌基督相通的。
4 Àwa sì kọ̀wé nǹkan wọ̀nyí sí yín, kí ayọ̀ yín kí ó lè di kíkún.
我們給你們寫這些事,是為叫我們的喜樂得以圓滿。
5 Èyí sì ni iṣẹ́ tí àwa ti gbọ́ lẹ́nu rẹ̀, tí àwa sì ń jẹ́ fún yín pé, ìmọ́lẹ̀ ni Ọlọ́run; ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ kò sì òkùnkùn rárá.
我們由他所聽見,而傳報給你們的,就是這個信息:天主是光,在他內沒有一點黑暗。
6 Bí àwa bá wí pé àwa ní ìdàpọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, tí àwa sì ń rìn nínú òkùnkùn, àwa ń ṣèké, àwa kò sì gbé nínú òtítọ́.
如果我們說我們與他相通,但仍在黑暗中行走,我們就是說謊,不履行真理。
7 Ṣùgbọ́n bí àwa bá ń rìn nínú ìmọ́lẹ̀, gẹ́gẹ́ bí òun ti ń wà nínú ìmọ́lẹ̀, àwa ní ìdàpọ̀ pẹ̀lú ara wa, àti pé ẹ̀jẹ̀ Jesu Kristi, Ọmọ rẹ̀, wẹ̀ wá nù kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo.
但如果我們在光中行走,如同他在光中一樣,我們就彼此相通,他聖子耶穌的血就會洗淨我們的各種罪過。
8 Bí àwa bá wí pé àwa kò ní ẹ̀ṣẹ̀, àwa ń tan ara wa jẹ, òtítọ́ kan kò sì ṣí nínú wa.
如果我們說我們沒有罪過,就是欺騙自己,真理也不在我們內。
9 Bí àwa bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa, olóòtítọ́ àti olódodo ni òun láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, àti láti wẹ̀ wá nù kúrò nínú àìṣòdodo gbogbo.
但若我們明認我們的罪過,天主既是忠信正義的,必赦免我們的罪過,並洗淨我們的各種不義。
10 Bí àwa bá wí pé àwa kò dẹ́ṣẹ̀, àwa mú un ní èké, ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò sì ṣí nínú wa.
如果我們說我們沒有犯過罪,我們就是拿他當說謊者,他的話就不在我們內。