< 1 Corinthians 16 >

1 Ǹjẹ́ ní ti ìdáwó fún àwọn ènìyàn mímọ́, bí mo tí wí fún àwọn ìjọ Galatia, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní kí ẹ ṣe.
Now concerning the collection for the saints: as I commanded the assemblies of Galatia, you do likewise.
2 Ní ọjọ́ kìn-ín-ní ọ̀sẹ̀, kí olúkúlùkù yín fi sínú ìṣúra lọ́dọ̀ ara rẹ̀ ni apá kan, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti ṣe rere fún ún, ki ó má ṣe si ìkójọ nígbà tí mo bá dé.
On the first day of every week, let each one of you save as he may prosper, that no collections are made when I come.
3 Àti nígbà ti mo bá dé, àwọn ẹni tí ẹ bá yàn, àwọn ni èmi ó rán láti mú ẹ̀bùn yín gòkè lọ si Jerusalẹmu.
When I arrive, I will send whoever you approve with letters to carry your gracious gift to Jerusalem.
4 Bí ó bá sì yẹ kí èmí lọ pẹ̀lú, wọn ó sì bá mi lọ.
If it is appropriate for me to go also, they will go with me.
5 Ṣùgbọ́n èmi yóò tọ̀ yin wá, nígbà tí èmí bá ti kọjá láàrín Makedonia: nítorí èmi yóò kọjá láàrín Makedonia.
I will come to you when I have passed through Macedonia, for I am passing through Macedonia.
6 Bóyá èmi ó sì dúró pẹ̀lú yín, tàbí kí n tilẹ̀ lo àkókò òtútù, ki ẹ̀yin lé sìn mí ni ọ̀nà àjò mí, níbikíbi tí mo bá ń lọ.
But with you it may be that I will stay with you, or even winter with you, that you may send me on my journey wherever I go.
7 Nítorí èmi kò fẹ́ kan ri yín kí èmi sì ṣe bẹ́ẹ̀ kọjá lọ; nítorí èmi ń retí àti dúró lọ́dọ̀ yín díẹ̀, bí Olúwa bá fẹ́.
For I do not wish to see you now in passing, but I hope to stay a while with you, if the Lord permits.
8 Ṣùgbọ́n èmi yóò dúró ni Efesu títí dí Pentikosti.
But I will stay at Ephesus until Pentecost,
9 Nítorí pé ìlẹ̀kùn ńlá láti ṣe iṣẹ́ gidi ṣí sílẹ̀ fún mí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ni àwọn ọ̀tá tí ń bẹ.
for a great and effective door has opened to me, and there are many adversaries.
10 Ǹjẹ́ bí Timotiu bá dé, ẹ jẹ́ kí ó wà lọ́dọ̀ yín láìbẹ̀rù, nítorí òun ń ṣé iṣẹ́ Olúwa, bí èmi pẹ̀lú ti ń ṣe.
Now if Timothy comes, see that he is with you without fear, for he does the work of the Lord, as I also do.
11 Nítorí náà kí ẹnikẹ́ni má ṣe kẹ́gàn rẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹ sín ín jáde lọ́nà àjò ni àlàáfíà, kí òun lè tọ̀ mí wá; nítorí tí èmí ń fi ojú sí ọ̀nà fún wíwá rẹ̀ pẹ̀lú àwọn arákùnrin.
Therefore let no one despise him. But set him forward on his journey in peace, that he may come to me; for I expect him with the brothers.
12 Ṣùgbọ́n ní ti Apollo arákùnrin wa, mo bẹ̀ ẹ́ púpọ̀ láti tọ̀ yín wá pẹ̀lú àwọn arákùnrin, ṣùgbọ́n kì í ṣe ìfẹ́ rẹ̀ rárá láti wà nísinsin yìí, ṣùgbọ́n òun yóò wá nígbà tí ààyè bá ṣí sílẹ̀ fún un.
Now concerning Apollos the brother, I strongly urged him to come to you with the brothers, but it was not at all his desire to come now; but he will come when he has an opportunity.
13 Ẹ máa ṣọ́ra, ẹ dúró ṣinṣin nínú ìgbàgbọ́, ẹ ṣe bi ọkùnrin tí ó ní ìgboyà, ẹ jẹ́ alágbára.
Watch! Stand firm in the faith! Be courageous! Be strong!
14 Ẹ máa ṣe ohun gbogbo nínú ìfẹ́.
Let all that you do be done in love.
15 Ǹjẹ́ mo bẹ̀ yín ará, ẹ ṣá mọ ilé Stefana pé, àwọn ni ẹni àkọ́kọ́ tó gba Jesu ní Akaia, àti pé, wọn sì tí fi ará wọn fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ àwọn ènìyàn mímọ́.
Now I beg you, brothers—you know the house of Stephanas, that it is the first fruits of Achaia, and that they have set themselves to serve the saints—
16 Kí ẹ̀yin tẹríba fún irú àwọn báwọ̀nyí, àti fún olúkúlùkù olùbáṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú wa tí ó sì ń ṣe làálàá.
that you also be in subjection to such, and to everyone who helps in the work and labors.
17 Mo láyọ̀ fún wíwá Stefana àti Fortunatu àti Akaiku, nítorí èyí tí ó kù nípá tí yín wọ́n ti fi kún un.
I rejoice at the coming of Stephanas, Fortunatus, and Achaicus; for that which was lacking on your part, they supplied.
18 Nítorí tí wọ́n tu ẹ̀mí mí lára àti tiyín: nítorí náà, ẹ máa gba irú àwọn ti ó rí bẹ́ẹ̀.
For they refreshed my spirit and yours. Therefore acknowledge those who are like that.
19 Àwọn ìjọ ni Asia kí í yín. Akuila àti Priskilla kí í yín púpọ̀ nínú Olúwa, pẹ̀lú ìjọ tí ó wà ni ilé wọn.
The assemblies of Asia greet you. Aquila and Priscilla greet you warmly in the Lord, together with the assembly that is in their house.
20 Gbogbo àwọn arákùnrin kí í yín. Ẹ fi ìfẹnukonu mímọ́ kí ara yín.
All the brothers greet you. Greet one another with a holy kiss.
21 Ìkíni ti èmi Paulu, láti ọwọ́ èmi tìkára mi wá.
This greeting is by me, Paul, with my own hand.
22 Bí ẹnikẹ́ni kò bá ní ìfẹ́ Jesu Kristi Olúwa, jẹ́ kí ó dì ẹni ìfibú. Máa bọ Olúwa wa!
If any man doesn’t love the Lord Jesus Christ, let him be cursed. Come, Lord!
23 Oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa kí ó wà pẹ̀lú yín!
The grace of the Lord Jesus Christ be with you.
24 Ìfẹ́ mi wá pẹ̀lú gbogbo yín nínú Kristi Jesu. Àmín.
My love to all of you in Christ Jesus. Amen.

< 1 Corinthians 16 >