< 1 Corinthians 13 >
1 Bí èmi tilẹ̀ lè sọ oríṣìíríṣìí èdè tí ènìyàn àti ti angẹli, tí n kò bá sì ní ìfẹ́, mo kàn ń pariwo bí ago lásán ni tàbí bí i kimbali olóhùn gooro.
If I speak in the tongues of men and of angels, but have not love, I am only a ringing gong or a clanging cymbal.
2 Bí mo bá ní ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀, tí mo sì ní òye gbogbo ohun ìjìnlẹ̀, àti gbogbo ìmọ̀, bí mo sì ni gbogbo ìgbàgbọ́ tó bẹ́ẹ̀ tí mo lè ṣí àwọn òkè ńlá nídìí, tí èmi kò sì ní ìfẹ́, èmi kò jẹ nǹkan kan.
If I have the gift of prophecy and can fathom all mysteries and all knowledge, and if I have absolute faith so as to move mountains, but have not love, I am nothing.
3 Bí mo bá fi gbogbo nǹkan tí mo ní tọrẹ fún àwọn aláìní, tí mo sì fi ara mi fún ni láti sùn ṣùgbọ́n tí n kò ní ìfẹ́, kò ní èrè kan fún mi.
If I give all I possess to the poor and exult in the surrender of my body, but have not love, I gain nothing.
4 Ìfẹ́ a máa mú sùúrù, ìfẹ́ a máa ṣeun, ìfẹ́ kì í ṣe ìlara, ìfẹ́ kì í fẹ̀, ìfẹ́ kì í sọ̀rọ̀ ìgbéraga.
Love is patient, love is kind. It does not envy, it does not boast, it is not proud.
5 Ìfẹ́ kì í hùwà àìtọ́, kì í wá ohun ara rẹ̀ nìkan. Ìfẹ́ kì í bínú fùfù, ìfẹ́ kì í fi búburú ọmọ ẹnìkejì sínú.
It is not rude, it is not self-seeking, it is not easily angered, it keeps no account of wrongs.
6 Inú ìfẹ́ kì í dùn sí àìṣòótọ́. Ṣùgbọ́n inú rẹ̀ a máa dùn nígbà gbogbo.
Love takes no pleasure in evil, but rejoices in the truth.
7 A máa faradà ohun gbogbo sí òtítọ́, a máa gba ohun gbogbo gbọ́, a máa retí ohun gbogbo, a máa fàyàrán ohun gbogbo.
It bears all things, believes all things, hopes all things, endures all things.
8 Ìfẹ́ kì í kùnà láé, kì í sì í yẹ̀ ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe ìsọtẹ́lẹ̀ ni, wọn yóò dópin, bí ó bá ṣe ẹ̀bùn ahọ́n ni, wọn yóò dákẹ́, bí ó bá ṣe pé ìmọ̀ ni yóò di asán.
Love never fails. But where there are prophecies, they will cease; where there are tongues, they will be restrained; where there is knowledge, it will be dismissed.
9 Nítorí àwa mọ̀ ní apá kan, àwa sì sọtẹ́lẹ̀ ní apá kan.
For we know in part and we prophesy in part,
10 Ṣùgbọ́n nígbà tí èyí ti o pé bá dé, èyí tí í ṣe tí apá kan yóò dópin.
but when the perfect comes, the partial passes away.
11 Nígbà tí mó wà ni èwe, èmi á máa sọ̀rọ̀ bi èwe, èmi a máa mòye bí èwe, èmi a máa gbèrò bí èwe. Ṣùgbọ́n nígbà tí mó di ọkùnrin tán, mo fi ìwà èwe sílẹ̀.
When I was a child, I talked like a child, I thought like a child, I reasoned like a child. When I became a man, I set aside childish ways.
12 Nítorí pé nísinsin yìí àwa ń ríran bàìbàì nínú dígí; nígbà náà a ó rí í lójúkojú. Nísinsin yìí mò mọ̀ pé ní apá kan; nígbà náà èmi o mọ̀ lẹ́kùnrẹ́rẹ́, kódà bí mo ti dí mí mọ̀ pẹ̀lú.
Now we see but a dim reflection as in a mirror; then we shall see face to face. Now I know in part; then I shall know fully, even as I am fully known.
13 Ǹjẹ́ nísinsin yìí àwọn nǹkan mẹ́ta wọ̀nyí dúró: ìgbàgbọ́, ìrètí, àti ìfẹ́. Ṣùgbọ́n èyí tí o tóbi jù nínú wọn ni ìfẹ́.
And now these three remain: faith, hope, and love; but the greatest of these is love.