< 1 Chronicles 1 >

1 Adamu, Seti, Enoṣi,
Adam, Seth, Énosh;
2 Kenani, Mahalaleli, Jaredi,
Kénan, Mahalaléel, Jéred;
3 Enoku, Metusela, Lameki, Noa.
Hénoc, Métushélah, Lémec;
4 Àwọn ọmọ Noa: Ṣemu, Hamu àti Jafeti.
Noé, Sem, Cham et Japhet.
5 Àwọn ọmọ Jafeti ni: Gomeri, Magogu, Madai; Jafani, Tubali, Meṣeki àti Tirasi.
Fils de Japhet: Gomer, Magog, Madaï, Javan, Tubal, Méshec et Tiras.
6 Àwọn ọmọ Gomeri ni: Aṣkenasi, Rifati àti Togarma.
Fils de Gomer: Ashkénaz, Diphath et Togarma.
7 Àwọn ọmọ Jafani ni: Eliṣa, Tarṣiṣi, Kittimu, àti Dodanimu.
Fils de Javan: Élisham, Tharshisha, Kittim et Rodanim.
8 Àwọn ọmọ Hamu ni: Kuṣi, Ejibiti, Puti, àti Kenaani.
Fils de Cham: Cush, Mitsraïm, Put et Canaan.
9 Àwọn ọmọ Kuṣi ni: Seba, Hafila, Sabta, Raama, àti Sabteka. Àwọn ọmọ Raama: Ṣeba àti Dedani.
Fils de Cush: Séba, Havila, Sabta, Raema et Sabtéca. Fils de Raema: Shéba et Dédan.
10 Kuṣi sì bí Nimrodu ẹni tí ó di alágbára jagunjagun ní ayé.
Cush engendra Nimrod, qui commença à être puissant sur la terre.
11 Ejibiti sì bí Ludimu, Anamimu, Lehabimu, Naftuhimu,
Mitsraïm engendra les Ludim, les Anamin, les Léhabim, les Naphtuhim,
12 Patrusimu, Kasluhimu (láti ọ̀dọ̀ ẹni tí àwọn ará Filistini ti wá) àti àwọn ará Kaftorimu.
Les Pathrusim, les Casluhim, d'où sont sortis les Philistins, et les Caphtorim.
13 Kenaani sì bí Sidoni àkọ́bí rẹ̀, àti Heti,
Canaan engendra Sidon, son premier-né, et Heth,
14 àti àwọn ará Jebusi, àti àwọn ará Amori, àti àwọn ará Girgaṣi,
Les Jébusiens, les Amoréens, les Guirgasiens,
15 àti àwọn ará Hifi, àti àwọn ará Arki, àti àwọn ará Sini,
Les Héviens, les Arkiens, les Siniens,
16 àti àwọn ará Arfadi, àti àwọn ará Semari, àti àwọn ará Hamati.
Les Arvadiens, les Tsémariens et les Hamathiens.
17 Àwọn ọmọ Ṣemu ni: Elamu, Aṣuri, Arfakṣadi, Ludi àti Aramu. Àwọn ọmọ Aramu: Usi, Huli, Geteri, àti Meṣeki.
Fils de Sem: Élam, Assur, Arpacshad, Lud, Aram, Uts, Hul, Guéther et Méshec.
18 Arfakṣadi sì bí Ṣela, Ṣela sì bí Eberi.
Arpacshad engendra Shélach; et Shélach engendra Héber.
19 Eberi sì bí ọmọ méjì: ọ̀kan ń jẹ́ Pelegi, nítorí ní ìgbà ọjọ́ rẹ̀ ni ilẹ̀ ya; orúkọ arákùnrin rẹ̀ ni Joktani.
Deux fils naquirent à Héber: l'un s'appelait Péleg (partage), parce que de son temps la terre fut partagée; et le nom de son frère était Jockthan.
20 Joktani sì bí Almodadi, Ṣelefi, Hasarmafeti, Jera.
Jockthan engendra Almodad, Shéleph, Hatsarmaveth, Jérach,
21 Hadoramu, Usali, Dikla,
Hadoram, Uzal, Dikla,
22 Ebali, Abimaeli, Ṣeba.
Ébal, Abimaël, Shéba,
23 Ofiri, Hafila, àti Jobabu. Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Joktani.
Ophir, Havila et Jobab; tous ceux-là furent fils de Jockthan.
24 Ṣemu, Arfakṣadi, Ṣela,
Sem, Arpacshad, Shélach,
25 Eberi, Pelegi. Reu,
Héber, Péleg, Réhu,
26 Serugu, Nahori, Tẹra,
Sérug, Nachor, Tharé,
27 àti Abramu (tí ń ṣe Abrahamu).
Abram, qui est Abraham.
28 Àwọn ọmọ Abrahamu: Isaaki àti Iṣmaeli.
Fils d'Abraham: Isaac et Ismaël.
29 Èyí ni àwọn ọmọ náà: Nebaioti àkọ́bí Iṣmaeli: Kedari, Adbeeli, Mibsamu,
Voici leur postérité: le premier-né d'Ismaël, Nébajoth; puis Kédar, Adbéel, Mibsam,
30 Miṣima, Duma, Massa, Hadadi, Tema,
Mishma, Duma, Massa, Hadan, Théma,
31 Jeturi, Nafiṣi, àti Kedema. Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Iṣmaeli.
Jéthur, Naphish et Kedma; ce sont là les fils d'Ismaël.
32 Àwọn ọmọ Ketura, obìnrin Abrahamu: Simrani, Jokṣani Medani, Midiani Iṣbaki àti Ṣua. Àwọn ọmọ Jokṣani: Ṣeba àti Dedani.
Fils de Kétura, concubine d'Abraham: Elle enfanta Zimran, Jokshan, Médan, Madian, Jishbak et Shuach. Fils de Jokshan: Shéba et Dédan.
33 Àwọn ọmọ Midiani: Efani, Eferi, Hanoku, Abida àti Eldaa. Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ìran Ketura.
Fils de Madian: Épha, Épher, Hanoc, Abida et Eldaa; tous ceux-là sont fils de Kétura.
34 Abrahamu sì jẹ́ baba Isaaki. Àwọn ọmọ Isaaki: Esau àti Israẹli.
Abraham engendra Isaac. Fils d'Isaac: Ésaü et Israël.
35 Àwọn ọmọ Esau: Elifasi, Reueli, Jeuṣi, Jalamu, àti Kora.
Fils d'Ésaü: Éliphaz, Réuël, Jéush, Jaelam et Korah.
36 Àwọn ọmọ Elifasi: Temani, Omari, Sefi, Gatamu àti Kenasi; láti Timna: Amaleki.
Fils d'Éliphaz: Théman, Omar, Tséphi, Gaetham, Kénaz, Thimna et Amalek.
37 Àwọn ọmọ Reueli: Nahati, Sera, Ṣamma àti Missa.
Fils de Réuël: Nahath, Zérach, Shamma et Mizza.
38 Àwọn ọmọ Seiri: Lotani, Ṣobali, Sibeoni, Ana, Diṣoni, Eseri àti Diṣani.
Fils de Séir: Lothan, Shobal, Tsibeon, Ana, Dishon, Etser et Dishan;
39 Àwọn ọmọ Lotani: Hori àti Homamu: Timna sì ni arábìnrin Lotani.
Fils de Lothan: Hori et Homam. Sœur de Lothan: Thimna.
40 Àwọn ọmọ Ṣobali: Afiani, Manahati, Ebali, Ṣefo àti Onamu. Àwọn ọmọ Sibeoni: Aiah àti Ana.
Fils de Shobal: Aljan, Manahath, Ébal, Shéphi et Onam. Fils de Tsibeon: Ajja et Ana.
41 Àwọn ọmọ Ana: Diṣoni. Àwọn ọmọ Diṣoni: Hemdani, Eṣbani, Itrani, àti Kerani.
Fils d'Ana: Dishon. Fils de Dishon: Hamran, Eshban, Jithran et Kéran.
42 Àwọn ọmọ Eseri: Bilhani, Saafani àti Akani. Àwọn ọmọ Diṣani: Usi àti Arani.
Fils d'Etser: Bilhan, Zaavan et Jaakan. Fils de Dishan: Uts et Aran.
43 Àwọn wọ̀nyí ni ọba tí ó jẹ ní Edomu, kí ó tó di pé ọba kankan jẹ lórí Israẹli: Bela ọmọ Beori, orúkọ ìlú rẹ̀ ni Dinhaba.
Voici les rois qui ont régné au pays d'Édom, avant qu'un roi régnât sur les enfants d'Israël: Béla, fils de Béor; et le nom de sa ville était Dinhaba.
44 Nígbà tí Bela kú, Jobabu ọmọ Sera ti Bosra sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
Béla mourut, et Jobab, fils de Zérach, de Botsra, régna à sa place.
45 Nígbà tí Jobabu kú, Huṣamu láti ilẹ̀ Temani sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
Jobab mourut, et Husham, du pays des Thémanites, régna à sa place.
46 Nígbà tí Huṣamu kú, Hadadi ọmọ Bedadi tí ó kọlu Midiani ní ìgbẹ́ Moabu, ó sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Afiti.
Husham mourut, et Hadad, fils de Bédad, régna à sa place; il défit Madian au territoire de Moab. Le nom de sa ville était Avith.
47 Nígbà tí Hadadi sì kú, Samla láti Masreka, ó sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
Hadad mourut, et Samla de Masréka régna à sa place.
48 Samla sì kú, Saulu ti Rehoboti létí odò sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
Samla mourut, et Saül de Réhoboth, sur le fleuve, régna à sa place.
49 Nígbà tí Saulu kú, Baali-Hanani, ọmọ Akbori jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
Saül mourut, et Baal-Hanan, fils d'Acbor, régna à sa place.
50 Nígbà tí Baali-Hanani kú, Hadadi ni ó jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Pau; orúkọ ìyàwó sì ni Mehetabeeli ọmọbìnrin Matiredi, ọmọbìnrin Mesahabu.
Baal-Hanan mourut, et Hadad régna à sa place. Le nom de sa ville était Paï, et le nom de sa femme Méhétabéel, fille de Matred, fille de Mézahab.
51 Hadadi sì kú pẹ̀lú. Àwọn baálẹ̀ Edomu ni: baálẹ̀ Timna, baálẹ̀ Alfa, baálẹ̀ Jeteti
Et Hadad mourut. Les chefs d'Édom furent: le chef Thimna, le chef Alja, le chef Jétheth,
52 baálẹ̀ Oholibama, baálẹ̀ Ela, baálẹ̀ Pinoni.
Le chef Oholibama, le chef Éla, le chef Pinon,
53 Baálẹ̀ Kenasi, baálẹ̀ Temani, baálẹ̀ Mibsari,
Le chef Kénaz, le chef Théman, le chef Mibtsar,
54 Magdieli àti Iramu. Àwọn wọ̀nyí ni baálẹ̀ Edomu.
Le chef Magdiel et le chef Iram. Ce sont là les chefs d'Édom.

< 1 Chronicles 1 >