< 1 Chronicles 8 >

1 Benjamini jẹ́ baba: Bela àkọ́bí rẹ̀, Aṣbeli ọmọkùnrin ni ẹ̀ẹ̀kejì, Ahara ẹ̀ẹ̀kẹ́ta,
베냐민의 낳은 자는 맏아들 벨라와 둘째 아스벨과 셋째 아하라와
2 Noha ẹ̀ẹ̀kẹrin àti Rafa ẹ̀karùnún.
넷째 노하와 다섯째 라바며
3 Àwọn ọmọ Bela ni, Adari, Gera, Abihudi,
벨라에게 아들들이 있으니 곧 앗달과 게라와 아비훗과
4 Abiṣua, Naamani, Ahoa,
아비수아와 나아만과 아호아와
5 Gera, Ṣefufani àti Huramu.
게라와 스부반과 후람이며
6 Wọ̀nyí ni àwọn ìran ọmọ Ehudu, tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn ìdílé tí ó ń gbé ní Geba tí a sì lé kúrò lọ sí Manahati:
에훗의 아들들은 이러하니라 저희는 게바 거민의 족장으로서 사로잡아 마나핫으로 가되
7 Naamani Ahijah àti Gera, tí ó lé wọn kúrò ní ìlú, àti tí ó sì jẹ́ baba Ussa àti Ahihudu.
곧 나아만과 아히야와 게라를 사로잡아 갔고 그가 또 웃사와 아히훗을 낳았으며
8 A bí àwọn ọmọkùnrin fún Ṣaharaimu ní Moabu lẹ́yìn tí ó ti kọ àwọn ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀, Huṣimu àti Baara.
사하라임은 두 아내 후심과 바아라를 내어보낸 후에 모압 땅에서 자녀를 낳았으니
9 Nípasẹ̀ ìyàwó rẹ̀ Hodeṣi ó ní Jobabu Sibia, Meṣa, Malkamu,
그 아내 호데스에게서 낳은 자는 요밥과 시비야와 메사와 말감과
10 Jeusi, Sakia àti Mirma. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, olórí àwọn ìdílé.
여우스와 사갸와 미르마라 이 아들들은 족장이며
11 Nípasẹ̀ Huṣimu ó ní Abitubu àti Elipali.
또 그 아내 후심에게서 아비둡과 엘바알을 낳았으며
12 Àwọn ọmọ Elipali: Eberi, Miṣamu, Ṣemedu (ẹni tí ó kọ́ Ono àti Lodi pẹ̀lú àwọn ìletò àyíká rẹ̀.)
엘바알의 아들들은 에벨과 미삼과 세멧이니 저는 오노와 롯과 그 향리를 세웠고
13 Pẹ̀lú Beriah àti Ṣema, tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn ìdílé ti àwọn tí ó ń gbé ní Aijaloni àti àwọn tí ó lé àwọn olùgbé Gati kúrò.
또 브리아와 세마니 저희는 아얄론 거민의 족장이 되어 가드 거민을 쫓아내었더라
14 Ahio, Ṣasaki, Jeremoti,
아히요와 사삭과 여레못과
15 Sebadiah, Aradi, Ederi
스바댜와 아랏과 에델과
16 Mikaeli, Iṣifa àti Joha jẹ́ àwọn ọmọ Beriah.
미가엘과 이스바와 요하는 다 브리아의 아들들이요
17 Sebadiah, Meṣullamu, Hiski, Heberi
스바댜와 므술람과 히스기와 헤벨과
18 Iṣimerai, Isiliahi àti Jobabu jẹ́ àwọn ọmọ Elipali.
이스므래와 이슬리아와 요밥은 다 엘바알의 아들들이요
19 Jakimu, Sikri, Sabdi,
야김과 시그리와 삽디와
20 Elienai, Siletai, Elieli,
엘리에내와 실르대와 엘리엘과
21 Adaiah, Beraiah àti Ṣimrati jẹ́ àwọn ọmọ, Ṣimei.
아다야와 브라야와 시므랏은 다 시므이의 아들들이요
22 Iṣipani Eberi, Elieli,
이스반과 에벨과 엘리엘과
23 Abdoni, Sikri, Hanani,
압돈과 시그리와 하난과
24 Hananiah, Elamu, Anitotijah,
하나냐와 엘람과 안도디야와
25 Ifediah àti Penueli jẹ́ àwọn ọmọ Ṣasaki.
이브드야와 브누엘은 다 사삭의 아들들이요
26 Ṣamṣerai, Ṣeharaiah, Ataliah
삼스래와 스하랴와 아달랴와
27 Jareṣiah, Elijah àti Sikri jẹ́ àwọn ọmọ Jerohamu.
야아레시야와 엘리야와 시그리는 다 여로함의 아들들이니
28 Gbogbo àwọn wọ̀nyí jẹ́ olórí àwọn ìdílé, olóyè gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ lẹ́sẹẹsẹ nínú ìtàn ìran wọn, wọ́n sì ń gbé ní Jerusalẹmu.
이는 다 족장이요 대대로 두목이라 예루살렘에 거하였더라
29 Jeieli, baba Gibeoni ń gbé ní Gibeoni. Ìyàwó o rẹ̀ a má jẹ́ Maaka,
기브온의 조상 여이엘은 기브온에 거하였으니 그 아내의 이름은 마아가며
30 àkọ́bí rẹ̀ a sì máa jẹ́ Abdoni wọ̀nyí sì ń tẹ̀lé Suri, Kiṣi, Baali, Neri, Nadabu,
장자는 압돈이요 다음은 술과 기스와 바알과 나답과
31 Gedori Ahio, Sekeri
그돌과 아히오와 세겔이며
32 pẹ̀lú Mikiloti, tí ó jẹ́ baba Ṣimea. Wọ́n ń gbé ní ẹ̀bá ìbátan wọn ní Jerusalẹmu.
미글롯은 시므아를 낳았으며 이 무리가 그 형제로 더불어 서로 대하여 예루살렘에 거하였더라
33 Neri jẹ́ baba Kiṣi, Kiṣi baba Saulu àti Saulu baba Jonatani, Malikiṣua, Abinadabu àti Eṣi-Baali.
넬은 기스를 낳았고 기스는 사울을 낳았고 사울은 요나단과 말기수아와 아비나답과 에스바알을 낳았으며
34 Ọmọ Jonatani: Meribu-Baali tí ó jẹ́ baba Mika.
요나단의 아들은 므립바알이라 므립바알이 미가를 낳았고
35 Àwọn ọmọ Mika: Pitoni, Meleki, Tarea, àti Ahasi.
미가의 아들들은 비돈과 멜렉과 다레아와 아하스며
36 Ahasi jẹ́ baba a Jeheada, Jeheada jẹ́ baba a Alemeti, Asmafeti àti Simri, Simri sì jẹ́ baba Mosa.
아하스는 여호앗다를 낳았고 여호앗다는 알레멧과 아스마웹과 시므리를 낳았고 시므리는 모사를 낳았고
37 Mosa jẹ́ baba Binea; Rafa sì jẹ́ ọmọ rẹ̀, Eleasa ọmọ rẹ̀ àti Aseli ọmọ rẹ̀.
모사는 비느아를 낳았으며 비느아의 아들은 라바요 그 아들은 엘르아사요 그 아들은 아셀이며
38 Aseli ní ọmọ mẹ́fà pẹ̀lú wọ̀nyí ni orúkọ wọn: Asrikamu, Bokeru, Iṣmaeli, Ṣeariah, Obadiah àti Hanani. Gbogbo wọ̀nyí ni ọmọ Aseli.
아셀에게 여섯 아들이 있어 그 이름이 이러하니 아스리감과 보그루와 이스마엘과 스아랴와 오바댜와 하난이라 아셀의 모든 아들이 이러하며
39 Àwọn ọmọ arákùnrin rẹ̀ Eseki: Ulamu àkọ́bí rẹ̀, Jeuṣi ọmọkùnrin ẹ̀ẹ̀kejì àti Elifeleti ẹ̀ẹ̀kẹ́ta.
그 아우 에섹의 아들은 이러하니 그 장자는 울람이요 둘째는 여우스요 셋째는 엘리벨렛이며
40 Àwọn ọmọ Ulamu jẹ́ ògboyà jagunjagun tí ó lè gbá orin mú. Wọ́n ní ọ̀pọ̀ ọmọkùnrin àti ọmọ ọmọkùnrin áàdọ́jọ ní gbogbo rẹ̀. Gbogbo wọ̀nyí ni àwọn ìdílé ìran ọmọ Benjamini.
울람의 아들은 다 큰 용사요 활을 잘 쏘는 자라 아들과 손자가 많아 모두 일백오십 인이었더라 베냐민의 자손들은 이러하였더라

< 1 Chronicles 8 >