< 1 Chronicles 7 >

1 Àwọn ọmọ Isakari: Tola, Pua, Jaṣubu àti Ṣimroni, mẹ́rin ni gbogbo rẹ̀.
以萨迦的儿子是陀拉、普瓦、雅述、伸 ,共四人。
2 Àwọn ọmọ Tola: Ussi, Refaiah, Jehieli, Jamai, Ibsamu àti Samuẹli olórí àwọn ìdílé wọn. Ní àkókò ìjọba, Dafidi, àwọn ìran ọmọ Tola tò lẹ́sẹẹsẹ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọkùnrin alágbára ní ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìlélógún ó lé ẹgbẹ̀ta.
陀拉的儿子是乌西、利法雅、耶勒、雅买、易伯散、示母利,都是陀拉的族长,是大能的勇士。到大卫年间,他们的人数共有二万二千六百名。
3 Àwọn ọmọ, Ussi: Israhiah. Àwọn ọmọ Israhiah: Mikaeli, Obadiah, Joẹli àti Iṣiah. Gbogbo àwọn márààrún sì jẹ́ olóyè.
乌西的儿子是伊斯拉希;伊斯拉希的儿子是米迦勒、俄巴底亚、约珥、伊示雅,共五人,都是族长。
4 Gẹ́gẹ́ bí ìtàn ìdílé wọn láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, wọ́n ní ọkùnrin ẹgbàá mẹ́rìndínlógójì tí ó ti ṣe tan fún ogun, nítorí wọ́n ní ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ àti ìyàwó.
他们所率领的,按着宗族出战的军队,共有三万六千人,因为他们的妻和子众多。
5 Àwọn ìbátan tí ó jẹ́ alágbára akọni àwọn ọkùnrin tí ó jẹ́ ti àwọn ìdílé Isakari, bí a ti tò ó lẹ́sẹẹsẹ nínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàdínláàádọ́rin ni gbogbo rẹ̀.
他们的族弟兄在以萨迦各族中都是大能的勇士,按着家谱计算共有八万七千人。
6 Àwọn ọmọ mẹ́ta Benjamini: Bela, Bekeri àti Jediaeli.
便雅悯的儿子是比拉、比结、耶叠,共三人。
7 Àwọn ọmọ Bela: Esboni, Ussi, Usieli, Jerimoti àti Iri, àwọn márààrún. Àwọn ni olórí ilé baba ńlá wọn, akọni alágbára ènìyàn. A sì ka iye wọn nípa ìran wọn sí ẹgbẹ̀rún méjìlélógún ó lé mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n ènìyàn.
比拉的儿子是以斯本、乌西、乌薛、耶利摩、以利,共五人,都是族长,是大能的勇士。按着家谱计算,他们的子孙共有二万二千零三十四人。
8 Àwọn ọmọ Bekeri: Semirahi, Joaṣi, Elieseri, Elioenai, Omri, Jeremoti, Abijah, Anatoti àti Alemeti. Gbogbo wọ̀nyí jẹ́ ọmọ Bekeri.
比结的儿子是细米拉、约阿施、以利以谢、以利约乃、暗利、耶利摩、亚比雅、亚拿突、亚拉篾。这都是比结的儿子。
9 Ìtàn ìdílé wọn láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn tí a kọ lẹ́sẹẹsẹ jẹ́ ti àwọn olórí ìdílé àti ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà ogún ó lé nígba ọkùnrin alágbára.
他们都是族长,是大能的勇士。按着家谱计算,他们的子孙共有二万零二百人。
10 Ọmọ Jediaeli: Bilhani. Àwọn ọmọ Bilhani: Jeuṣi Benjamini, Ehudu, Kenaana, Setamu, Tarṣiṣi àti Ahiṣahari.
耶叠的儿子是比勒罕;比勒罕的儿子是耶乌施、便雅悯、以忽、基拿拿、细坦、他施、亚希沙哈。
11 Gbogbo àwọn ọmọ Jediaeli jẹ́ olórí. Àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlógún ó lé nígba akọni ọkùnrin ni ó ti ṣetán láti jáde lọ sí ogun.
这都是耶叠的儿子,都是族长,是大能的勇士;他们的子孙能上阵打仗的,共有一万七千二百人。
12 Àti Ṣuppimu, àti Huppimu, àwọn ọmọ Iri, àti Huṣimu, àwọn ọmọ Aheri.
还有以珥的儿子书品、户品,并亚黑的儿子户伸。
13 Àwọn ọmọ Naftali: Jasieli, Guni, Jeseri àti Ṣallumu—ọmọ rẹ̀ nípa Biliha.
拿弗他利的儿子是雅薛、沽尼、耶色、沙龙。这都是辟拉的子孙。
14 Àwọn ìran ọmọ Manase: Asrieli jẹ́ ìran ọmọ rẹ̀ ní ipasẹ̀ àlè rẹ̀ ará Aramu ó bí Makiri baba Gileadi.
玛拿西的儿子亚斯列是他妾亚兰人所生的,又生了基列之父玛吉。
15 Makiri sì mú ìyàwó láti àárín àwọn ará Huppimu àti Ṣuppimu. Orúkọ arábìnrin rẹ̀ a máa jẹ́ Maaka. Orúkọ ìran ọmọ mìíràn a máa jẹ́ Selofehadi, tí ó ní àwọn ọmọbìnrin nìkan ṣoṣo.
玛吉娶的妻是户品、书品的妹子,名叫玛迦。玛拿西的次子名叫西罗非哈;西罗非哈但有几个女儿。
16 Maaka, ìyàwó Makiri bí ọmọkùnrin kan. Ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Peresi. Ó sì pe arákùnrin rẹ̀ ní Ṣereṣi, àwọn ọmọ rẹ̀ sì ní Ulamu àti Rakemu.
玛吉的妻玛迦生了一个儿子,起名叫毗利施。毗利施的兄弟名叫示利施;示利施的儿子是乌兰和利金。
17 Ọmọ Ulamu: Bedani. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Gileadi ọmọ Makiri, ọmọ Manase.
乌兰的儿子是比但。这都是基列的子孙。基列是玛吉的儿子,玛吉是玛拿西的儿子。
18 Arábìnrin rẹ̀. Hamoleketi bí Iṣhodi, Abieseri àti Mahila.
基列的妹子哈摩利吉生了伊施荷、亚比以谢、玛拉。(
19 Àwọn ọmọ Ṣemida sì jẹ́: Ahiani, Ṣekemu, Likki àti Aniamu.
示米大的儿子是亚现、示剑、利克希、阿尼安。)
20 Àwọn ìran ọmọ Efraimu: Ṣutelahi, Beredi ọmọkùnrin rẹ̀, Tahati ọmọ rẹ̀, Eleadah ọmọ rẹ̀. Tahati ọmọ rẹ̀
以法莲的儿子是书提拉;书提拉的儿子是比列;比列的儿子是他哈;他哈的儿子是以拉大;以拉大的儿子是他哈;
21 Sabadi ọmọ, rẹ̀, àti Ṣutelahi ọmọ rẹ̀. Eseri àti Eleadi ni a pa nípasẹ̀ àwọn ọkùnrin bíbí ìbílẹ̀ Gati nígbà tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ láti lọ fi agbára mú ohun ọ̀sìn wọn
他哈的儿子是撒拔;撒拔的儿子是书提拉。以法莲又生以谢、以列;这二人因为下去夺取迦特人的牲畜,被本地的迦特人杀了。
22 Efraimu baba wọn ṣọ̀fọ̀ fún wọn ní ọjọ́ púpọ̀, àwọn ìbátan rẹ̀ wá láti tù ú nínú.
他们的父亲以法莲为他们悲哀了多日,他的弟兄都来安慰他。
23 Nígbà náà, ó sùn pẹ̀lú, ìyàwó rẹ̀, ó sì lóyún ó sì bí ọmọkùnrin kan. Ó sì sọ ọ́ ní Beriah nítorí òfò ti wà nínú ìdílé náà.
以法莲与妻同房,他妻就怀孕生了一子,以法莲因为家里遭祸,就给这儿子起名叫比利亚。
24 Ọmọbìnrin rẹ̀ sì jẹ́ Ṣerah, ẹni tí ó kọ́ ìsàlẹ̀ àti òkè Beti-Horoni àti Useni-Ṣerah pẹ̀lú.
他的女儿名叫舍伊拉,就是建筑上伯·和 、下伯·和 与乌羡·舍伊拉的。
25 Refa jẹ́ ọmọ rẹ̀, Resefi ọmọ rẹ̀, Tela ọmọ rẹ̀, Tahani ọmọ rẹ̀,
比利阿的儿子是利法和利悉。利悉的儿子是他拉;他拉的儿子是他罕;
26 Laadani ọmọ rẹ̀ Ammihudu ọmọ rẹ̀, Eliṣama ọmọ rẹ̀,
他罕的儿子是拉但;拉但的儿子是亚米忽;亚米忽的儿子是以利沙玛;
27 Nuni ọmọ rẹ̀ àti Joṣua ọmọ rẹ̀.
以利沙玛的儿子是嫩;嫩的儿子是约书亚。
28 Ilẹ̀ wọn àti ìfìdíkalẹ̀ wọn ni Beteli àti àwọn ìletò tí ó yíká, Narani lọ sí ìhà ìlà-oòrùn, Geseri àti àwọn ìletò rẹ̀ lọ sí ìhà ìwọ̀-oòrùn àti Ṣekemu àti àwọn ìletò rẹ̀ ní ọ̀nà lọ sí Ayahi àti àwọn ìletò.
以法莲人的地业和住处是伯特利与其村庄;东边拿兰,西边基色与其村庄;示剑与其村庄,直到迦萨与其村庄;
29 Lẹ́gbẹ̀ ìpínlẹ̀ ti Manase ni Beti-Ṣeani, Taanaki, Megido àti Dori lápapọ̀ pẹ̀lú àwọn ìletò rẹ̀. Àwọn ìran ọmọ Josẹfu ọmọ Israẹli ń gbé nínú ìlú wọ̀nyí.
还有靠近玛拿西人的境界,伯·善与其村庄;他纳与其村庄;米吉多与其村庄;多珥与其村庄。以色列儿子约瑟的子孙住在这些地方。
30 Àwọn ọmọ Aṣeri: Imina, Iṣifa, Iṣfi àti Beriah. Arábìnrin wọn sì jẹ́ Sera.
亚设的儿子是音拿、亦施瓦、亦施韦、比利亚,还有他们的妹子西 拉。
31 Àwọn ọmọ Beriah: Heberi àti Malkieli, tí ó jẹ́ baba Barsafiti.
比利亚的儿子是希别、玛结;玛结是比撒威的父亲。
32 Heberi jẹ́ baba Jafileti, Ṣomeri àti Hotami àti ti arábìnrin wọn Ṣua.
希别生雅弗勒、朔默、何坦,和他们的妹子书雅。
33 Àwọn ọmọ Jafileti: Pasaki, Bimhali àti Asifati. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Jafileti.
雅弗勒的儿子是巴萨、宾哈、亚施法。这都是雅弗勒的儿子。
34 Àwọn ọmọ Ṣomeri: Ahi, Roga, Jahuba àti Aramu.
朔默的儿子是亚希、罗迦、耶户巴、亚兰。
35 Àwọn ọmọ arákùnrin rẹ̀ Helemu Sofahi, Imina, Ṣeleṣi àti Amali.
朔默兄弟希连的儿子是琐法、音那、示利斯、亚抹。
36 Àwọn ọmọ Sofahi: Sua, Haniferi, Ṣuali, Beri, Imra.
琐法的儿子是书亚、哈尼弗、书阿勒、比利、音拉、
37 Beseri, Hodi, Ṣamma, Ṣilisa, Itrani àti Bera.
比悉、河得、珊玛、施沙、益兰、比拉。
38 Àwọn ọmọ Jeteri: Jefunne, Pisifa àti Ara.
益帖的儿子是耶孚尼、毗斯巴、亚拉。
39 Àwọn ọmọ Ulla: Arah, Hannieli àti Resia.
乌拉的儿子是亚拉、汉尼业、利写。
40 Gbogbo wọ̀nyí jẹ́ ìran ọmọ Aṣeri—olórí ìdílé, àṣàyàn ọkùnrin, alágbára jagunjagun àti olórí nínú àwọn ìjòyè. Iye àwọn tí a kà yẹ fún ogun, gẹ́gẹ́ bí à ti ṣe kọ ọ́ lẹ́sẹẹsẹ nínú ìtàn ìdílé wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàlá ọkùnrin.
这都是亚设的子孙,都是族长,是精壮大能的勇士,也是首领中的头目,按着家谱计算,他们的子孙能出战的共有二万六千人。

< 1 Chronicles 7 >