< 1 Chronicles 6 >

1 Àwọn ọmọ Lefi: Gerṣoni, Kohati àti Merari.
利未的儿子是革顺、哥辖、米拉利。
2 Àwọn ọmọ Kohati: Amramu, Isari, Hebroni, àti Usieli.
哥辖的儿子是暗兰、以斯哈、希伯伦、乌薛。
3 Àwọn ọmọ Amramu: Aaroni, Mose àti Miriamu. Àwọn ọmọkùnrin Aaroni: Nadabu, Abihu, Eleasari àti Itamari.
暗兰的儿子是亚伦、摩西,还有女儿米利暗。亚伦的儿子是拿答、亚比户、以利亚撒、以他玛。
4 Eleasari jẹ́ baba Finehasi, Finehasi baba Abiṣua
以利亚撒生非尼哈;非尼哈生亚比书;
5 Abiṣua baba Bukki, Bukki baba Ussi,
亚比书生布基;布基生乌西;
6 Ussi baba Serahiah, Serahiah baba Meraioti,
乌西生西拉希雅;西拉希雅生米拉约;
7 Meraioti baba Amariah, Amariah baba Ahitubu
米拉约生亚玛利雅;亚玛利雅生亚希突;
8 Ahitubu baba Sadoku, Sadoku baba Ahimasi,
亚希突生撒督;撒督生亚希玛斯;
9 Ahimasi baba Asariah, Asariah baba Johanani,
亚希玛斯生亚撒利雅;亚撒利雅生约哈难;
10 Johanani baba Asariah. (Òhun ni ó sìn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà nínú ilé Olúwa tí Solomoni kọ́ sí Jerusalẹmu).
约哈难生亚撒利雅(这亚撒利雅在所罗门于耶路撒冷所建造的殿中,供祭司的职分);
11 Asariah baba Amariah Amariah baba Ahitubu
亚撒利雅生亚玛利雅;亚玛利雅生亚希突;
12 Ahitubu baba Sadoku. Sadoku baba Ṣallumu,
亚希突生撒督;撒督生沙龙;
13 Ṣallumu baba Hilkiah, Hilkiah baba Asariah,
沙龙生希勒家;希勒家生亚撒利雅;
14 Asariah baba Seraiah, pẹ̀lú Seraiah baba Josadaki.
亚撒利雅生西莱雅;西莱雅生约萨答。
15 A kó Josadaki lẹ́rú nígbà tí Olúwa lé Juda àti Jerusalẹmu kúrò ní ìlú nípasẹ̀ Nebukadnessari.
当耶和华借尼布甲尼撒的手掳掠犹大和耶路撒冷人的时候,这约萨答也被掳去。
16 Àwọn ọmọ Lefi: Gerṣoni, Kohati àti Merari.
利未的儿子是革顺、哥辖、米拉利。
17 Wọ̀nyí ni àwọn orúkọ àwọn ọmọ Gerṣoni: Libni àti Ṣimei.
革顺的儿子名叫立尼、示每。
18 Àwọn ọmọ Kohati: Amramu, Isari, Hebroni àti Usieli.
哥辖的儿子是暗兰、以斯哈、希伯伦、乌薛。
19 Àwọn ọmọ Merari: Mahili àti Muṣi. Wọ̀nyí ni àwọn ìdílé ará Lefi tí a kọ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé gẹ́gẹ́ bí baba wọn.
米拉利的儿子是抹利、母示。这是按着利未人宗族分的各家。
20 Ti Gerṣoni: Libni ọmọkùnrin rẹ̀, Jahati. Ọmọkùnrin rẹ̀, Simma ọmọkùnrin rẹ̀,
革顺的儿子是立尼;立尼的儿子是雅哈;雅哈的儿子是薪玛;
21 Joah ọmọkùnrin rẹ̀, Iddo ọmọkùnrin rẹ̀, Sera ọmọkùnrin rẹ̀ àti Jeaterai ọmọkùnrin rẹ̀.
薪玛的儿子是约亚;约亚的儿子是易多;易多的儿子是谢拉;谢拉的儿子是耶特赖。
22 Àwọn ìran ọmọ Kohati: Amminadabu ọmọkùnrin rẹ̀, Kora ọmọkùnrin rẹ̀, Asiri ọmọkùnrin rẹ̀.
哥辖的儿子是亚米拿达;亚米拿达的儿子是可拉;可拉的儿子是亚惜;
23 Elkana ọmọkùnrin rẹ̀, Ebiasafi ọmọkùnrin rẹ̀, Asiri ọmọkùnrin rẹ̀.
亚惜的儿子是以利加拿;以利加拿的儿子是以比雅撒;以比雅撒的儿子是亚惜;
24 Tahati ọmọkùnrin rẹ̀, Urieli ọmọkùnrin rẹ̀, Ussiah ọmọkùnrin rẹ̀ àti Saulu ọmọkùnrin rẹ̀.
亚惜的儿子是他哈;他哈的儿子是乌列;乌列的儿子是乌西雅;乌西雅的儿子是少罗。
25 Àwọn ìran ọmọ Elkana: Amasai, Ahimoti
以利加拿的儿子是亚玛赛和亚希摩。
26 Elkana ọmọ rẹ̀, Sofai ọmọ rẹ̀ Nahati ọmọ rẹ̀,
亚希摩的儿子是以利加拿;以利加拿的儿子是琐菲;琐菲的儿子是拿哈;
27 Eliabu ọmọ rẹ̀, Jerohamu ọmọ rẹ̀, Elkana ọmọ rẹ̀ àti Samuẹli ọmọ rẹ̀.
拿哈的儿子是以利押;以利押的儿子是耶罗罕;耶罗罕的儿子是以利加拿;以利加拿的儿子是撒母耳。
28 Àwọn ọmọ Samuẹli: Joẹli àkọ́bí àti Abijah ọmọ ẹlẹ́ẹ̀kejì.
撒母耳的长子是约珥,次子是亚比亚。
29 Àwọn ìran ọmọ Merari: Mahili, Libni ọmọ rẹ̀. Ṣimei ọmọ rẹ̀, Ussa ọmọ rẹ̀.
米拉利的儿子是抹利;抹利的儿子是立尼;立尼的儿子是示每;示每的儿子是乌撒;
30 Ṣimea ọmọ rẹ̀, Haggiah ọmọ rẹ̀ àti Asaiah ọmọ rẹ̀.
乌撒的儿子是示米亚;示米亚的儿子是哈基雅;哈基雅的儿子是亚帅雅。
31 Èyí ní àwọn ọkùnrin Dafidi tí a fi sí ìdí orin nínú ilé Olúwa lẹ́yìn tí àpótí ẹ̀rí ti wá láti sinmi níbẹ̀.
约柜安设之后,大卫派人在耶和华殿中管理歌唱的事。
32 Wọ́n jíṣẹ́ pẹ̀lú orin níwájú àgọ́ ìpàdé títí tí Solomoni fi kọ́ ilé Olúwa ní Jerusalẹmu. Wọ́n ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà tí a fi lélẹ̀ fún wọn.
他们就在会幕前当歌唱的差,及至所罗门在耶路撒冷建造了耶和华的殿,他们便按着班次供职。
33 Wọ̀nyí ni àwọn ọkùnrin tí ó sìn pẹ̀lú ọmọ wọn. Láti ọ̀dọ̀ àwọn ará Kohati: Hemani olùkọrin, ọmọ Joẹli, ọmọ Samuẹli,
供职的人和他们的子孙记在下面: 哥辖的子孙中有歌唱的希幔。希幔是约珥的儿子;约珥是撒母耳的儿子;
34 ọmọ Elkana, ọmọ Jerohamu, ọmọ Elieli, ọmọ Toha,
撒母耳是以利加拿的儿子;以利加拿是耶罗罕的儿子;耶罗罕是以列的儿子;以列是陀亚的儿子;
35 ọmọ Sufu, ọmọ Elkana, ọmọ Mahati, ọmọ Amasai,
陀亚是苏弗的儿子;苏弗是以利加拿的儿子;以利加拿是玛哈的儿子;玛哈是亚玛赛的儿子;
36 ọmọ Elkana, ọmọ Joẹli, ọmọ Asariah, ọmọ Sefaniah,
亚玛赛是以利加拿的儿子;以利加拿是约珥的儿子;约珥是亚撒利雅的儿子;亚撒利雅是西番雅的儿子;
37 ọmọ Tahati, ọmọ Asiri, ọmọ Ebiasafi, ọmọ Kora,
西番雅是他哈的儿子;他哈是亚惜的儿子;亚惜是以比雅撒的儿子;以比雅撒是可拉的儿子;
38 ọmọ Isari, ọmọ Kohati, ọmọ Lefi, ọmọ Israẹli;
可拉是以斯哈的儿子;以斯哈是哥辖的儿子;哥辖是利未的儿子;利未是以色列的儿子。
39 Hemani sì darapọ̀ mọ́ Asafu, ẹni tí o sìn ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀: Asafu ọmọ Berekiah, ọmọ Ṣimea,
希幔的族兄亚萨是比利家的儿子,亚萨在希幔右边供职。比利家是示米亚的儿子;
40 ọmọ Mikaeli, ọmọ Baaseiah, ọmọ Malkiah
示米亚是米迦勒的儿子;米迦勒是巴西雅的儿子;巴西雅是玛基雅的儿子;
41 ọmọ Etini, ọmọ Sera, ọmọ Adaiah,
玛基雅是伊特尼的儿子;伊特尼是谢拉的儿子;谢拉是亚大雅的儿子;
42 ọmọ Etani, ọmọ Simma, ọmọ Ṣimei,
亚大雅是以探的儿子;以探是薪玛的儿子;薪玛是示每的儿子;
43 ọmọ Jahati, ọmọ Gerṣoni, ọmọ Lefi;
示每是雅哈的儿子;雅哈是革顺的儿子。革顺是利未的儿子。
44 láti ìbákẹ́gbẹ́ wọn, àwọn ará Merari wà ní ọwọ́ òsì rẹ̀: Etani ọmọ Kiṣi, ọmọ Abdi, ọmọ Malluki,
他们的族弟兄米拉利的子孙,在他们左边供职的有以探。以探是基示的儿子;基示是亚伯底的儿子;亚伯底是玛鹿的儿子;
45 ọmọ Haṣabiah, ọmọ Amasiah, ọmọ Hilkiah,
玛鹿是哈沙比雅的儿子;哈沙比雅是亚玛谢的儿子;亚玛谢是希勒家的儿子;
46 ọmọ Amisi, ọmọ Bani, ọmọ Ṣemeri,
希勒家是暗西的儿子;暗西是巴尼的儿子;巴尼是沙麦的儿子;
47 ọmọ Mahili, ọmọ Muṣi, ọmọ Merari, ọmọ Lefi.
沙麦是末力的儿子;末力是母示的儿子;母示是米拉利的儿子;米拉利是利未的儿子。
48 Àwọn Lefi ẹgbẹ́ wọn ni wọn yan àwọn iṣẹ́ yòókù ti àgọ́ fún, èyí tí í ṣe ilé Ọlọ́run.
他们的族弟兄利未人也被派办 神殿中的一切事。
49 Ṣùgbọ́n Aaroni àti àwọn ìran ọmọ rẹ̀ jẹ́ àwọn tí ó gbé ọrẹ kalẹ̀ lórí pẹpẹ ẹbọ sísun àti lórí pẹpẹ tùràrí ní ìbátan pẹ̀lú gbogbo ohun tí a ṣe ní Ibi Mímọ́ Jùlọ. Ṣíṣe ètùtù fún Israẹli, ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí Mose ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti pàṣẹ.
亚伦和他的子孙在燔祭坛和香坛上献祭烧香,又在至圣所办理一切的事,为以色列人赎罪,是照 神仆人摩西所吩咐的。
50 Wọ̀nyí ni àwọn ìránṣẹ́ Aaroni: Eleasari ọmọ rẹ̀, Finehasi ọmọ rẹ̀, Abiṣua ọmọ rẹ̀,
亚伦的儿子是以利亚撒;以利亚撒的儿子是非尼哈;非尼哈的儿子是亚比书;
51 Bukki ọmọ rẹ̀, Ussi ọmọ rẹ̀, Serahiah ọmọ rẹ̀,
亚比书的儿子是布基;布基的儿子是乌西;乌西的儿子是西拉希雅;
52 Meraioti ọmọ rẹ̀, Amariah ọmọ rẹ̀, Ahitubu ọmọ rẹ̀,
西拉希雅的儿子是米拉约;米拉约的儿子是亚玛利雅;亚玛利雅的儿子是亚希突;
53 Sadoku ọmọ rẹ̀ àti Ahimasi ọmọ rẹ̀.
亚希突的儿子是撒督;撒督的儿子是亚希玛斯。
54 Wọ̀nyí ni ibùgbé wọn tí a pín fún wọn gẹ́gẹ́ bí agbègbè wọn (tí a fi lé àwọn ìran ọmọ Aaroni lọ́wọ́ tí ó wá láti ẹ̀yà Kohati, nítorí kèké alákọ́kọ́ jẹ́ tiwọn).
他们的住处按着境内的营寨,记在下面:哥辖族亚伦的子孙先拈阄得地,
55 A fún wọn ní Hebroni ní Juda pẹ̀lú àyíká pápá oko tútù ilẹ̀ rẹ̀.
在犹大地中得了希伯 和四围的郊野;
56 Ṣùgbọ́n àwọn pápá àti ìletò tí ó yí ìlú ńlá náà ká ni a fi fún Kalebu ọmọ Jefunne.
只是属城的田地和村庄都为耶孚尼的儿子迦勒所得。
57 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìran ọmọ Aaroni ni a fún ní Hebroni (ìlú ti ààbò), àti Libina, Jattiri, Eṣitemoa,
亚伦的子孙得了逃城希伯 ,又得了立拿与其郊野,雅提珥、以实提莫与其郊野;
58 Hileni, Debiri,
希 与其郊野,底璧与其郊野,
59 Aṣani, Jutta àti Beti-Ṣemeṣi lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ rẹ̀.
亚珊与其郊野,伯·示麦与其郊野。
60 Àti láti inú ẹ̀yà Benjamini, a fún wọn ní Gibeoni, Geba, Alemeti àti Anatoti lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn. Àwọn ìlú wọ̀nyí, tí a pín láàrín àwọn ẹ̀yà Kohati jẹ́ mẹ́tàlá ní gbogbo rẹ̀.
在便雅悯支派的地中,得了迦巴与其郊野,阿勒篾与其郊野,亚拿突与其郊野。他们诸家所得的城共十三座。
61 Ìyókù àwọn ìran ọmọ Kohati ní a pín ìlú mẹ́wàá fún láti àwọn ìdílé ní ti ààbọ̀ ẹ̀yà Manase.
哥辖族其余的人又拈阄,在玛拿西半支派的地中得了十座城。
62 Àwọn ìran ọmọ Gerṣoni, sí ìdílé ni a pín ìlú mẹ́tàlá fún láti ẹ̀yà àwọn ẹ̀yà Isakari, Aṣeri àti Naftali, àti láti apá ẹ̀yà Manase tí ó wà ní Baṣani.
革顺族按着宗族,在以萨迦支派的地中,亚设支派的地中,拿弗他利支派的地中,巴珊内玛拿西支派的地中,得了十三座城。
63 Sebuluni àwọn ìran ọmọ Merari, ìdílé sí ìdílé, ní a pín ìlú méjìlá fún láti ẹ̀yà Reubeni, Gadi àti Sebuluni.
米拉利族按着宗族拈阄,在吕便支派的地中,迦得支派的地中,西布伦支派的地中,得了十二座城。
64 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli fún àwọn ará Lefi ní ìlú wọ̀nyí pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.
以色列人将这些城与其郊野给了利未人。
65 Láti ẹ̀yà Juda, Simeoni àti Benjamini ni a pín ìlú tí a ti dárúkọ wọn sẹ́yìn fún.
这以上录名的城,在犹大、西缅、便雅悯三支派的地中,以色列人拈阄给了他们。
66 Lára àwọn ìdílé Kohati ni a fún ní ìlú láti ẹ̀yà Efraimu gẹ́gẹ́ bí ìlú agbègbè wọn.
哥辖族中有几家在以法莲支派的地中也得了城邑,
67 Ní òkè orílẹ̀-èdè Efraimu, a fún wọn ní Ṣekemu (ìlú ńlá ti ààbò), àti Geseri
在以法莲山地得了逃城示剑与其郊野,又得了基色与其郊野,
68 Jokimeamu, Beti-Horoni.
约缅与其郊野,伯·和 与其郊野,
69 Aijaloni àti Gati-Rimoni lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.
亚雅 与其郊野,迦特·临门与其郊野。
70 Pẹ̀lú láti apá ààbọ̀ ẹ̀yà Manase àwọn ọmọ Israẹli fún Aneri àti Bileamu lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn, fún ìyókù àwọn ìdílé Kohati.
哥辖族其余的人在玛拿西半支派的地中得了亚乃与其郊野,比连与其郊野。
71 Àwọn ará Gerṣoni gbà nǹkan wọ̀nyí. Láti ààbọ̀ ẹ̀yà ti Manase wọ́n gba Golani ní Baṣani àti pẹ̀lú Aṣtarotu, lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù wọn.
革顺族在玛拿西半支派的地中得了巴珊的哥兰与其郊野,亚斯他录与其郊野;
72 Láti ẹ̀yà Isakari wọ́n gba Kedeṣi, Daberati
又在以萨迦支派的地中得了基低斯与其郊野,大比拉与其郊野,
73 Ramoti àti Anenu, lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.
拉末与其郊野,亚年与其郊野;
74 Láti ẹ̀yà Aṣeri wọ́n gba Maṣali, Abdoni,
在亚设支派的地中得了玛沙与其郊野,押顿与其郊野,
75 Hukoki àti Rehobu lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.
户割与其郊野,利合与其郊野;
76 Pẹ̀lú láti ẹ̀yà Naftali wọ́n gba Kedeṣi ní Galili, Hammoni àti Kiriataimu, lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.
在拿弗他利支派的地中得了加利利的基低斯与其郊野,哈们与其郊野,基列亭与其郊野。
77 Àwọn ará Merari (ìyókù àwọn ará Lefi) gbà nǹkan wọ̀nyí. Láti ẹ̀yà Sebuluni wọ́n gba Jokneamu, Karta, Rimoni àti Tabori, lápapọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù wọn.
还有米拉利族的人在西布伦支派的地中得了临摩挪与其郊野,他泊与其郊野;
78 Láti ẹ̀yà Reubeni rékọjá Jordani ìlà-oòrùn Jeriko wọ́n gba Beseri nínú aginjù Jahisa,
又在耶利哥的约旦河东,在吕便支派的地中得了旷野的比悉与其郊野,雅哈撒与其郊野,
79 Kedemoti àti Mefaati, lápapọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù wọn.
基底莫与其郊野,米法押与其郊野;
80 Pẹ̀lú láti ẹ̀yà Gadi wọ́n gba Ramoti ní Gileadi Mahanaimu,
又在迦得支派的地中得了基列的拉末与其郊野,玛哈念与其郊野,
81 Heṣboni àti Jaseri lápapọ̀ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ pápá oko tútù wọn.
希实本与其郊野,雅谢与其郊野。

< 1 Chronicles 6 >