< 1 Chronicles 5 >

1 Ǹjẹ́ àwọn ọmọ Reubeni, àkọ́bí Israẹli. (Nítorí òun ni àkọ́bí; ṣùgbọ́n, bí ó ti ṣe pé ó ba ibùsùn baba rẹ̀ jẹ́, a fi ogún ìbí rẹ̀ fún àwọn ọmọ Josẹfu ọmọ Israẹli: a kì yóò sì ka ìtàn ìdílé náà gẹ́gẹ́ bí ipò ìbí.
The sonnes also of Reuben the eldest sonne of Israel (for he was the eldest, but had defiled his fathers bed, therefore his birthright was giuen vnto the sonnes of Ioseph the sonne of Israel, so that the genealogie is not rekoned after his birthright.
2 Nítorí Juda borí àwọn arákùnrin rẹ̀, àti lọ́dọ̀ rẹ̀ ni aláṣẹ ti ń jáde wá; ṣùgbọ́n ogún ìbí jẹ́ ti Josẹfu),
For Iudah preuailed aboue his brethren, and of him came the prince, but the birthright was Iosephs)
3 àwọn ọmọ Reubeni àkọ́bí Israẹli ni: Hanoku àti Pallu, Hesroni àti Karmi.
The sonnes of Reuben the eldest sonne of Israel, were Hanoch and Pallu, Hezron and Carmi.
4 Àwọn ọmọ Joẹli: Ṣemaiah ọmọ rẹ̀, Gogu ọmọ rẹ̀, Ṣimei ọmọ rẹ̀.
The sonnes of Ioel, Shemaiah his sonne, Gog his sonne, and Shimei his sonne,
5 Mika ọmọ rẹ̀, Reaiah ọmọ rẹ̀, Baali ọmọ rẹ̀.
Michah his sonne, Reaiah his sonne, and Baal his sonne,
6 Beera ọmọ rẹ̀, tí Tiglat-Pileseri ọba Asiria kó ní ìgbèkùn lọ. Ìjòyè àwọn ọmọ Reubeni ni Beera jẹ́.
Beerah his sonne: whom Tilgath Pilneeser King of Asshur caryed away: he was a prince of the Reubenites.
7 Àti àwọn arákùnrin rẹ̀ nípa ìdílé wọn, nígbà tí a ń ka ìtàn ìdílé ìran wọn: Jeieli àti Sekariah ni olórí,
And when his brethren in their families rekoned the genealogie of their generations, Ieiel and Zechariah were the chiefe,
8 àti Bela ọmọ Asasi ọmọ Ṣema, ọmọ Joẹli. Wọ́n tí ń gbé Aroeri àní títí dé Nebo àti Baali-Meoni.
And Bela the sonne of Azaz, the sonne of Shema, the sonne of Ioel, which dwelt in Aroer, euen vnto Nebo and Baal meon.
9 Àti níhà àríwá, o tẹ̀dó lọ títí dé àtiwọ aginjù láti odò Eufurate; nítorí tí ẹran ọ̀sìn wọn pọ̀ sí i ní ilẹ̀ Gileadi.
Also Eastwarde he inhabited vnto the entring in of the wildernes from the riuer Perath for they had much cattel in the land of Gilead.
10 Àti ní ọjọ́ Saulu, wọ́n bá àwọn ọmọ Hagari jagun, ẹni tí ó ṣubú nípa ọwọ́ wọn; wọ́n sì ń gbé inú àgọ́ wọn ní gbogbo ilẹ̀ àríwá Gileadi.
And in the dayes of Saul they warred with the Hagarims, which fell by their hands: and they dwelt in their tentes in all the East partes of Gilead.
11 Àti àwọn ọmọ Gadi ń gbé lékè wọn, ní ilẹ̀ Baṣani títí dé Saleka:
And the children of Gad dwelt ouer against them in the land of Bashan, vnto Salchah.
12 Joẹli jẹ́ olórí, Ṣafamu ìran ọmọ Janai, àti Ṣafati ni Baṣani.
Ioel was the chiefest, and Shapham the second, but Iaanai and Shaphat were in Bashan.
13 Àti àwọn arákùnrin wọn ti ilẹ̀ àwọn baba wọn ní: Mikaeli, Meṣullamu Ṣeba, Jorai, Jaka, Sia àti Eberi méje.
And their brethren of the house of their fathers were Michael, and Meshullam, and Sheba, and Sorai, and Iacan, and Zia and Eber, seuen.
14 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Abihaili, ọmọ Huri, ọmọ Jeroa, ọmọ Gileadi, ọmọ Mikaeli, ọmọ Jeṣiṣai, ọmọ Jado, ọmọ Busi.
These are the childre of Abihail, the sonne of Huri, the sonne of Iaroah, the sonne of Gilead, the sonne of Michael, the sonne of Ieshishai, the sonne of Iahdo, the sonne of Buz.
15 Ahi, ọmọ Adbeeli, ọmọ Guni, olórí ilé àwọn baba wọn.
Ahi the sonne of Abdiel, the sonne of Guni was chiefe of the houshold of their fathers.
16 Wọ́n sì ń gbé Gileadi ní Baṣani àti nínú àwọn ìlú rẹ̀, àti nínú gbogbo ìgbèríko Ṣaroni, ní agbègbè wọn.
And they dwelt in Gilead in Bashan, and in the townes thereof, and in all the suburbes of Sharon by their borders.
17 Gbogbo wọ̀nyí ni a kà nípa ìtàn ìdílé, ní ọjọ́ Jotamu ọba Juda, àti ní ọjọ́ Jeroboamu ọba Israẹli.
All these were rekoned by genealogies in the dayes of Iotham King of Iudah, and in the dayes of Ieroboam King of Israel.
18 Àwọn ọmọ Reubeni, àti àwọn ọmọ Gadi, àti ààbọ̀ ẹ̀yà Manase, nínú àwọn ọkùnrin alágbára tí wọ́n ń gbé asà àti idà, tí wọ́n sì ń fi ọrun tafà, tí wọ́n sì mòye ogun, jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó lé ẹgbẹ̀rìnlélógún dín ogójì ènìyàn, tí ó jáde lọ sí ogún náà.
The sonnes of Reuben and of Gad, and of halfe the tribe of Manasseh of those that were viliant men, able to beare shield, and sworde, and to draw a bowe, exercised in warre, were foure and fourtie thousand, seuen hundreth and three score, that went out to the warre.
19 Wọ́n sì bá àwọn ọmọ Hagari jagun, pẹ̀lú Jeturi, àti Nafiṣi àti Nadabu.
And they made warre with the Hagarims, with Ietur, and Naphish, and Nodab.
20 Nígbà tí wọ́n sì rí ìrànlọ́wọ́ gbà si, a sì fi àwọn ọmọ Hagari lé wọn lọ́wọ́, àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú wọn; nítorí tiwọn ké pe Ọlọ́run ní ogun náà, òun sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn; nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ wọn lé e.
And they were holpen against them, and the Hagarims were deliuered into their hande, and all that were with them: for they cryed to God in the battel, and he heard them, because they trusted in him.
21 Wọ́n sì kó ẹran ọ̀sìn wọn lọ; ìbákasẹ ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n àti àgùntàn ọ̀kẹ́ méjìlá ó lé ẹgbàárùn-ún, àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì, àti ènìyàn ọ̀kẹ́ márùn-ún.
And they led away their cattel, euen their camels fiftie thousand, and two hundreth, and fiftie thousand sheepe, and two thousand asses, and of persons an hundreth thousand.
22 Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó ṣubú tí a pa, nítorí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ogun náà, wọ́n sì jókòó ní ipò wọn títí di ìgbà ìkólọ sí ìgbèkùn.
For many fel downe wounded, because the warre was of God. And they dwelt in their steads vntill the captiuitie.
23 Àwọn ọmọkùnrin ààbọ̀ ẹ̀yà Manase ń gbé ní ilẹ̀ náà: wọ́n bí sí i láti Baṣani títí dé Baali-Hermoni, àti Seniri àti títí dé òkè Hermoni.
And the children of the halfe tribe of Manasseh dwelt in the land, from Baashan vnto Baal Hermon, and Senir, and vnto mount Hermon: for they increased.
24 Wọ̀nyí sì ni àwọn olórí ilé àwọn baba wọn. Eferi, Iṣi, Elieli, Asrieli, Jeremiah, Hodafiah àti Jahdieli àwọn alágbára akọni ọkùnrin, ọkùnrin olókìkí, àti olórí ilé àwọn baba wọn.
And these were the heads of the housholds of their fathers, euen Epher and Ishi, and Eliel and Azriel, and Ieremiah, and Hodauiah, and Iahdiel, strong men, valiant and famous, heades of the housholdes of their fathers.
25 Wọ́n sì ṣẹ̀ sí Ọlọ́run àwọn baba wọn, wọ́n sì ṣe àgbèrè tọ àwọn ọlọ́run ènìyàn ilẹ̀ náà lẹ́yìn, tí Ọlọ́run ti parun ní iwájú wọn.
But they transgressed against the God of their fathers, and went a whoring after the gods of the people of the lande, whome God had destroyed before them.
26 Nítorí náà Ọlọ́run Israẹli ru ẹ̀mí Pulu ọba Asiria sókè (èyí ni Tiglat-Pileseri ọba Asiria), ó si kó wọn lọ, àní àwọn ọmọ Reubeni àti àwọn ọmọ Gadi, àti ààbọ̀ ẹ̀yà Manase lọ sí ìgbèkùn. Ó sì kó wọn wá sí Hala, àti Habori, àti Harani, àti sí etí odò Gosani; títí dí òní yìí.
And the God of Israel stirred vp the spirit of Pul king of Asshur, and the spirite of Tilgath Pilneeser king of Asshur, and he caryed them away: euen the Reubenites and the Gadites, and the halfe tribe of Manasseh, and brought them vnto Halah and Habor, and Hara, and to the riuer Gozan, vnto this day.

< 1 Chronicles 5 >