< 1 Chronicles 3 >
1 Àwọn wọ̀nyí sì ni ọmọ Dafidi tí a bí fún un ní Hebroni. Àkọ́bí sì ni Amnoni ọmọ Ahinoamu ti Jesreeli; èkejì sì ni Daniẹli ọmọ Abigaili ará Karmeli;
2 ẹ̀kẹta sì ni Absalomu ọmọ Maaka ọmọbìnrin Talmai ọba Geṣuri bí fún un; ẹ̀kẹrin sì ni Adonijah ọmọ Haggiti;
3 ẹ̀karùnún ni Ṣefatia láti ọ̀dọ̀ Abitali; àti ẹ̀kẹfà, Itreamu, láti ọ̀dọ̀ Egla aya rẹ̀.
4 Àwọn mẹ́fà wọ̀nyí ni a bí fún Dafidi ni Hebroni, níbi tí ó ti jẹ ọba fún ọdún méje àti oṣù mẹ́fà. Dafidi sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n.
5 Wọ̀nyí ni ọmọ wẹ́wẹ́ tí a bí fún un ní Jerusalẹmu: Ṣimea, Ṣobabu, Natani àti Solomoni. Àwọn mẹ́rin wọ̀nyí sì ni a bí láti ọ̀dọ̀ Bati-Ṣua ọmọbìnrin Ammieli.
6 Ibhari sì wà pẹ̀lú, Eliṣama, Elifeleti,
7 Noga, Nefegi, Jafia,
8 Eliṣama, Eliada àti Elifeleti mẹ́sàn-án ni wọ́n.
9 Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Dafidi yàtọ̀ sí àwọn ọmọ tí àlè bí fún un. Tamari sì ni arábìnrin wọn.
10 Ọmọ Solomoni ni Rehoboamu, Abijah ọmọ rẹ̀, Asa ọmọ rẹ̀, Jehoṣafati ọmọ rẹ̀,
11 Jehoramu ọmọ rẹ̀, Ahasiah ọmọ rẹ̀, Joaṣi ọmọ rẹ̀,
12 Amasiah ọmọ rẹ̀, Asariah ọmọ rẹ̀, Jotamu ọmọ rẹ̀,
13 Ahasi ọmọ rẹ̀, Hesekiah ọmọ rẹ̀, Manase ọmọ rẹ̀,
14 Amoni ọmọ rẹ̀, Josiah ọmọ rẹ̀.
15 Àwọn ọmọ Josiah: àkọ́bí ọmọ rẹ̀ ni Johanani, èkejì ọmọ rẹ̀ ni Jehoiakimu, ẹ̀kẹta ọmọ rẹ̀ ni Sedekiah, ẹ̀kẹrin ọmọ rẹ̀ ni Ṣallumu.
16 Àwọn ìran ọmọ Jehoiakimu: Jekoniah ọmọ rẹ̀, àti Sedekiah.
17 Àwọn ọmọ Jekoniah tí a mú ní ìgbèkùn: Ṣealitieli ọmọ rẹ̀ ọkùnrin,
18 Malkiramu, Pedaiah, Ṣenasari, Jekamiah, Hoṣama àti Nedabiah.
19 Àwọn ọmọ Pedaiah: Serubbabeli àti Ṣimei. Àwọn ọmọ Serubbabeli: Meṣullamu àti Hananiah. Ṣelomiti ni arábìnrin wọn.
20 Àwọn márùn-ún mìíràn sì tún wà: Haṣuba, Oheli, Berekiah, Hasadiah àti Jusabhesedi.
21 Àwọn ọmọ Hananiah: Pelatiah àti Jeṣaiah, àti àwọn ọmọ Refaiah, ti Arnani, ti Obadiah àti ti Ṣekaniah.
22 Àwọn ọmọ Ṣekaniah: Ṣemaiah àti àwọn ọmọ rẹ̀: Hattusi, Igali, Bariah, Neariah àti Ṣafati, mẹ́fà ni gbogbo wọn.
23 Àwọn ọmọ Neariah: Elioenai; Hesekiah, àti Asrikamu, mẹ́ta ni gbogbo wọn.
24 Àwọn ọmọ Elioenai: Hodafiah, Eliaṣibu, Pelaiah, Akkubu, Johanani, Delaiah àti Anani, méje sì ni gbogbo wọn.