< 1 Chronicles 27 >

1 Wọ̀nyí ni ìwé àkójọ orúkọ àwọn ọmọ Israẹli, àwọn olórí àwọn ìdílé, àwọn balógun ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti àwọn balógun ọ̀rọ̀ọ̀rún àti àwọn ìjòyè wọn. Tí ó n sin ọba nínú gbogbo ohun tí ó kan ìpín àwọn ọmọ-ogun tí ó wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ní oṣooṣù ní gbogbo ọdún. Ìpín kọ̀ọ̀kan jẹ́ ẹgbàá méjìlá ọkùnrin.
以色列人的族长、千夫长、百夫长,和官长都分定班次,每班是二万四千人,周年按月轮流,替换出入服事王。
2 Ní ti alákòóso lórí ìpín kìn-ín-ní fún oṣù kìn-ín-ní jẹ́ Jaṣobeamu ọmọ Sabdieli àwọn ọkùnrin ẹgbàá méjìlá ní ó wà ní abẹ́ ìpín tirẹ̀.
正月第一班的班长是撒巴第业的儿子雅朔班;他班内有二万四千人。
3 Ó jẹ́ ìran ọmọ Peresi àti olóyè fún gbogbo àwọn ìjòyè ológun fún oṣù kìn-ín-ní.
他是法勒斯的子孙,统管正月班的一切军长。
4 Alákòóso fún ìpín àwọn ọmọ-ogun fún oṣù kejì jẹ́ Dodai ará Ahohi; Mikloti jẹ́ olórí ìpín tirẹ̀. Ọkùnrin ẹgbàá méjìlá ni ó wà ní ìpín tirẹ̀.
二月的班长是亚哈希人朵代,还有副官密基罗;他班内有二万四千人。
5 Olórí àwọn ọmọ-ogun ẹlẹ́ẹ̀kẹta fún oṣù kẹta jẹ́ Benaiah ọmọ Jehoiada àlùfáà. Ó jẹ́ olóyè, àwọn ọkùnrin ẹgbàá méjìlá ní ó wà ní ìpín tirẹ̀.
三月第三班的班长是祭司耶何耶大的儿子比拿雅;他班内有二万四千人。
6 Èyí ni Benaiah náà tí ó jẹ́ ọkùnrin ńlá láàrín àwọn ọgbọ̀n àti lórí àwọn ọgbọ̀n. Ọmọ rẹ̀ Amisabadi jẹ́ alákòóso lórí ìpín tirẹ̀.
这比拿雅是那三十人中的勇士,管理那三十人;他班内又有他儿子暗米萨拔。
7 Ẹlẹ́ẹ̀kẹrin fún oṣù kẹrin, jẹ́ Asaheli arákùnrin Joabu: ọmọ rẹ̀ Sebadiah jẹ́ arọ́pò rẹ̀. Ẹgbàá méjìlá ọkùnrin ni ó wà ní ìpín rẹ̀.
四月第四班的班长是约押的兄弟亚撒黑。接续他的是他儿子西巴第雅;他班内有二万四千人。
8 Ẹ̀karùnún fún oṣù karùn-ún, jẹ́ olórí Ṣamhuti ará Israhi. Ẹgbàá méjìlá ọkùnrin ní ó wà ní ìpín tirẹ̀.
五月第五班的班长是伊斯拉人珊合;他班内有二万四千人。
9 Ẹ̀kẹfà fún oṣù kẹfà jẹ́ Ira ọmọ Ikẹsi, ará Tekoi. Ọkùnrin ẹgbàá méjìlá ni ó wà ní ìpín rẹ̀.
六月第六班的班长是提哥亚人益吉的儿子以拉;他班内有二万四千人。
10 Èkeje fún oṣù keje jẹ́ Helesi ará Peloni, ará Efraimu. Ọkùnrin ẹgbàá méjìlá ni o wà ní ìpín rẹ̀.
七月第七班的班长是以法莲族比伦人希利斯;他班内有二万四千人。
11 Ẹ̀kẹjọ fún oṣù kẹjọ jẹ́ Sibekai ará Huṣati, ará Sera ọkùnrin ẹgbàá méjìlá ni ó wà ní ìpín rẹ̀.
八月第八班的班长是谢拉族户沙人西比该;他班内有二万四千人。
12 Ẹ̀kẹsànán fún oṣù kẹsànán jẹ́. Abieseri ará Anatoti, ará Benjamini ọkùnrin ẹgbàá méjìlá ni ó wà ní ìpín rẹ̀.
九月第九班的班长是便雅悯族亚拿突人亚比以谢;他班内有二万四千人。
13 Ẹ̀kẹwàá fún oṣù kẹwàá jẹ́ Maharai ará Netofa, ará Sera ọkùnrin ẹgbàá méjìlá ni ó wà ní ìpín rẹ̀.
十月第十班的班长是谢拉族尼陀法人玛哈莱;他班内有二万四千人。
14 Ìkọkànlá fún oṣù kọkànlá jẹ́ Benaiah ará Piratoni ará Efraimu ọkùnrin ẹgbàá méjìlá ni ó wà ní ìpín tirẹ̀.
十一月第十一班的班长是以法莲族比拉顿人比拿雅;他班内有二万四千人。
15 Èkejìlá fún oṣù kejìlá jẹ́ Heldai ará Netofa láti ìdílé Otnieli. Ẹgbàá méjìlá ọkùnrin ni ó wà ní ìpín tirẹ̀.
十二月第十二班的班长是俄陀聂族尼陀法人黑玳;他班内有二万四千人。
16 Àwọn ìjòyè lórí àwọn ẹ̀yà tí Israẹli: lórí àwọn ará Reubeni: Elieseri ọmọ Sikri; lórí àwọn ọmọ Simeoni: Ṣefatia ọmọ Maaka;
管理以色列众支派的记在下面:管吕便人的是细基利的儿子以利以谢;管西缅人的是玛迦的儿子示法提雅;
17 lórí Lefi: Haṣabiah ọmọ Kemueli; lórí Aaroni: Sadoku;
管利未人的是基母利的儿子哈沙比雅;管亚伦子孙的是撒督;
18 lórí Juda: Elihu arákùnrin Dafidi; lórí Isakari: Omri ọmọ Mikaeli;
管犹大人的是大卫的一个哥哥以利户;管以萨迦人的是米迦勒的儿子暗利;
19 lórí Sebuluni: Iṣmaiah ọmọ Obadiah; lórí Naftali: Jerimoti ọmọ Asrieli;
管西布伦人的是俄巴第雅的儿子伊施玛雅;管拿弗他利人的是亚斯列的儿子耶利摩;
20 lórí àwọn ará Efraimu: Hosea ọmọ Asasiah; lórí ààbọ̀ ẹ̀yà Manase: Joẹli ọmọ Pedaiah;
管以法莲人的是阿撒细雅的儿子何细亚;管玛拿西半支派的是毗大雅的儿子约珥;
21 lórí ààbọ̀ ẹ̀yà Manase ní Gileadi: Iddo ọmọ Sekariah; lórí Benjamini: Jaasieli ọmọ Abneri;
管基列地玛拿西那半支派的是撒迦利亚的儿子易多;管便雅悯人的是押尼珥的儿子雅西业;
22 lórí Dani: Asareeli ọmọ Jerohamu. Wọ̀nyí ni àwọn ìjòyè lórí ẹ̀yà Israẹli.
管但人的是耶罗罕的儿子亚萨列。以上是以色列众支派的首领。
23 Dafidi kò kọ iye àwọn ọkùnrin náà ní ogún ọdún sẹ́yìn tàbí dín nítorí Olúwa ti ṣe ìlérí láti ṣe Israẹli gẹ́gẹ́ bí iye ìràwọ̀ ojú ọ̀run.
以色列人二十岁以内的,大卫没有记其数目;因耶和华曾应许说,必加增以色列人如天上的星那样多。
24 Joabu ọmọ Seruiah bẹ̀rẹ̀ sí ní kà wọ́n, ṣùgbọ́n kò parí kíkà wọ́n nítorí, ìbínú dé sórí àwọn Israẹli nípasẹ̀ kíka iye àti iye náà, a kò kọ ọ́ sínú ìwé ìtàn ayé ti ọba Dafidi.
洗鲁雅的儿子约押动手数点,当时耶和华的烈怒临到以色列人;因此,没有点完,数目也没有写在大卫王记上。
25 Asmafeti ọmọ Adieli wà ní ìdí ilé ìṣúra ti ọba. Jonatani ọmọ Ussiah wà ní ìdí ilé ìṣúra ní iwájú agbègbè nínú àwọn ìlú, àwọn ìletò àti àwọn ilé ìṣọ́.
掌管王府库的是亚叠的儿子押斯马威。掌管田野城邑村庄保障之仓库的是乌西雅的儿子约拿单。
26 Esri ọmọ Kelubu wà ní ìdí àwọn òṣìṣẹ́ lórí pápá, tí wọ́n ń ko ilẹ̀ náà.
掌管耕田种地的是基绿的儿子以斯利。
27 Ṣimei ará Ramoti wà ní ìdí àwọn ọgbà àjàrà. Sabdi ará Sifmi wà ní ìdí mímú jáde ti èso àjàrà fún ọpọ́n ńlá tí a ń fi ọ̀tún èso àjàrà sí.
掌管葡萄园的是拉玛人示每。掌管葡萄园酒窖的是实弗米人撒巴底。
28 Baali-Hanani ará Gederi wà ní ìdí olifi àti àwọn igi sikamore ní apá ìhà ìwọ̀-oòrùn àwọn ní ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀. Joaṣi wà ní ìdí fífún ni ní òróró olifi.
掌管高原橄榄树和桑树的是基第利人巴勒·哈南。掌管油库的是约阿施。
29 Ṣitrai ará Ṣaroni wà ní ìdí fífi ọwọ́ ẹran jẹ oko ní Ṣaroni. Ṣafati ọmọ Adlai wà ní ìdí àwọn ọ̀wọ́ ẹran ní àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀.
掌管沙 牧放牛群的是沙 人施提赉。掌管山谷牧养牛群的是亚第赉的儿子沙法。
30 Obili ará Iṣmaeli wà ní ìdí àwọn ìbákasẹ. Jehdeiah ará Meronoti wà ní ìdí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.
掌管驼群的是以实玛利人阿比勒。掌管驴群的是米 人耶希底亚。掌管羊群的是夏甲人雅悉。
31 Jasisi ará Hagari wà ní ìdí àwọn agbo ẹran. Gbogbo wọ̀nyí ni àwọn oníṣẹ́ tí wọ́n wà ní ìdí ẹrù ọba Dafidi.
这都是给大卫王掌管产业的。
32 Jonatani, arákùnrin Dafidi jẹ́ olùdámọ̀ràn, ọkùnrin onímọ̀ àti akọ̀wé. Jehieli ọmọ Hakmoni bojútó àwọn ọmọ ọba.
大卫的叔叔约拿单作谋士;这人有智慧,又作书记。哈摩尼的儿子耶歇作王众子的师傅。
33 Ahitofeli jẹ́ olùdámọ̀ràn ọba. Huṣai ará Arki jẹ́ ọ̀rẹ́ ọba.
亚希多弗也作王的谋士。亚基人户筛作王的陪伴。
34 (Jehoiada ọmọ Benaiah àti nípasẹ̀ Abiatari jẹ ọba rọ́pò Ahitofeli.) Joabu jẹ́ olórí ọmọ-ogun ọba.
亚希多弗之后,有比拿雅的儿子耶何耶大和亚比亚他接续他作谋士。约押作王的元帅。

< 1 Chronicles 27 >