< 1 Chronicles 24 >
1 Àwọn wọ̀nyí sì ni pínpín àwọn ọmọ Aaroni. Àwọn ọmọ Aaroni ni Nadabu, Abihu, Eleasari àti Itamari.
アロンの子孫の組は次のとおりである。すなわちアロンの子らはナダブ、アビウ、エレアザル、イタマル。
2 Ṣùgbọ́n Nadabu àti Abihu kú kí ó tó di wí pé baba wọn kú, wọn kò sì ní àwọn ọmọ; bẹ́ẹ̀ ni Eleasari àti Itamari sì ṣe gẹ́gẹ́ bí àlùfáà.
ナダブとアビウはその父に先だって死に、子がなかったので、エレアザルとイタマルが祭司となった。
3 Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Sadoku ọmọ Eleasari àti Ahimeleki ọmọ Itamari, Dafidi sì yà wọ́n nípa nínú ìpín fún ìyàsọ́tọ̀ àwọn iṣẹ́ ìsìn wọn.
ダビデはエレアザルの子孫ザドクとイタマルの子孫アヒメレクの助けによって彼らを分けて、それぞれの勤めにつけた。
4 A rí ọ̀pọ̀ àwọn olórí lára àwọn ọmọ Eleasari ju lára àwọn ọmọ Itamari lọ, wọ́n sì pín wọn lẹ́sẹ lẹ́sẹ: mẹ́rìndínlógún olórí láti ìdílé ọmọ Eleasari ìran wọn àti olórí méjọ ìdílé láti ara àwọn ọmọ Itamari.
エレアザルの子孫のうちにはイタマルの子孫のうちよりも長たる人々が多かった。それでエレアザルの子孫で氏族の長である十六人と、イタマルの子孫で氏族の長である者八人にこれを分けた。
5 Wọ́n sì pín wọn láìṣègbè nípa yíya ìpín, nítorí àwọn olórí ibi mímọ́ àti àwọn olórí ilé Ọlọ́run wà láàrín àwọn ọmọ méjèèjì Eleasari àti Itamari.
このように彼らは皆ひとしく、くじによって分けられた。聖所のつかさ、および神のつかさは、ともにエレアザルの子孫とイタマルの子孫から出たからである。
6 Ṣemaiah ọmọ Netaneli, akọ̀wé ọ̀kan lára àwọn ọmọ Lefi sì kọ orúkọ wọn níwájú ọba àti àwọn ìjòyè: Sadoku àlùfáà, Ahimeleki ọmọ Abiatari àti olórí ìdílé àwọn àlùfáà tí a mú láti ọ̀dọ̀ Eleasari àti ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ Itamari.
レビびとネタネルの子である書記シマヤは、王とつかさたちと祭司ザドクとアビヤタルの子アヒメレクと祭司およびレビびとの氏族の長たちの前で、これを書きしるした。すなわちエレアザルのために氏族一つを取れば、イタマルのためにも一つを取った。
7 Ìpín èkínní jáde sí Jehoiaribu, èkejì sí Jedaiah,
第一のくじはヨアリブに当り、第二はエダヤに当り、
8 ẹlẹ́ẹ̀kẹta sì ni Harimu, ẹ̀kẹrin sì ní Seorimu,
第三はハリムに、第四はセオリムに、
9 ẹ̀karùnún sì ni Malkiah, ẹlẹ́ẹ̀kẹfà sì ni Mijamini,
第五はマルキヤに、第六はミヤミンに、
10 èkeje sì ni Hakosi, ẹlẹ́ẹ̀kẹjọ sí ni Abijah,
第七はハッコヅに、第八はアビヤに、
11 ẹ̀kẹsànán sì ni Jeṣua, ẹ̀kẹwàá sì ni Ṣekaniah,
第九はエシュアに、第十はシカニヤに、
12 ẹ̀kọkànlá sì ni Eliaṣibu, ẹlẹ́ẹ̀kẹjìlá sì ni Jakimu,
第十一はエリアシブに、第十二はヤキムに、
13 ẹ̀kẹtàlá sì ni Hupa, ẹlẹ́ẹ̀kẹrìnlá sì ni Jeṣebeabu,
第十三はホッパに、第十四はエシバブに、
14 ẹ̀kẹdógún sì ni Bilgah, ẹ̀kẹrìndínlógún sì ni Immeri,
第十五はビルガに、第十六はインメルに、
15 ẹ̀kẹtàdínlógún sì ni Hesiri, èkejìdínlógún sì ni Hafisesi,
第十七はヘジルに、第十八はハピセツに、
16 ẹ̀kọkàndínlógún sì ni Petahiah, ogún sì ni Jeheskeli,
第十九はペタヒヤに、第二十はエゼキエルに、
17 ẹ̀kọkànlélógún sì ni Jakini, ẹ̀kẹrìnlélógún sì ni Gamuli,
第二十一はヤキンに、第二十二はガムルに、
18 ẹ̀kẹtàlélógún sì ni Delaiah, ẹ̀kẹrìnlélógún sì ni Maasiah.
第二十三はデラヤに、第二十四はマアジヤに当った。
19 Àwọn wọ̀nyí ni a yàn fún iṣẹ́ ìsìn nígbà tí wọ́n wọ ilé Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ìlànà àti àṣẹ tí a ti fi fún wọn láti ọwọ́ baba ńlá wọn Aaroni gẹ́gẹ́ bí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, tí pàṣẹ fun un.
これは、彼らの先祖アロンによって設けられた定めにしたがい、主の家にはいって務をなす順序であって、イスラエルの神、主の彼に命じられたとおりである。
20 Ìyókù àwọn ọmọ Lefi. Láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Amramu: Ṣubaeli láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ṣubaeli; Jehdeiah.
このほかのレビの子孫は次のとおりである。すなわちアムラムの子らのうちではシュバエル。シュバエルの子らのうちではエデヤ。
21 Àti gẹ́gẹ́ bí Rehabiah, láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Rehabiah, Iṣiah sì ni alákọ́kọ́.
レハビヤについては、レハビヤの子らのうちでは長子イシア。
22 Láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Isari: Ṣelomiti; láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ṣelomoti: Jahati.
イヅハリびとのうちではシロミテ。シロミテの子らのうちではヤハテ。
23 Àwọn ọmọ Hebroni: Jeriah alákọ́kọ́, Amariah ẹlẹ́ẹ̀kejì, Jahasieli ẹlẹ́ẹ̀kẹta àti Jekameamu ẹlẹ́ẹ̀kẹrin.
ヘブロンの子らは長子はエリヤ、次はアマリヤ、第三はヤハジエル、第四はエカメアム。
24 Àwọn ọmọ Usieli: Mika; nínú àwọn ọmọ Mika: Ṣamiri.
ウジエルの子らのうちではミカ。ミカの子らのうちではシャミル。
25 Àwọn arákùnrin Mika: Iṣi; nínú àwọn ọmọ Iṣiah: Sekariah.
ミカの兄弟はイシア。イシアの子らのうちではゼカリヤ。
26 Àwọn ọmọ Merari: Mahili àti Muṣi. Àwọn ọmọ Jaasiah: Beno.
メラリの子らはマヘリとムシ。ヤジアの子らはベノ。
27 Àwọn ọmọ Merari. Láti Jaasiah: Beno, Ṣohamu, Sakkuri àti Ibri.
メラリの子孫のヤジアから出た者はベノ、ショハム、ザックル、イブリ。
28 Láti Mahili: Eleasari, ẹni tí kò ni àwọn ọmọ.
マヘリからエレアザルが出た。彼には子がなかった。
29 Láti Kiṣi. Àwọn ọmọ Kiṣi: Jerahmeeli.
キシについては、キシの子はエラメル。
30 Àti àwọn ọmọ Muṣi: Mahili, Ederi àti Jerimoti. Èyí ni àwọn ọmọ Lefi, gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn.
ムシの子らはマヘリ、エデル、エリモテ。これらはレビびとの子孫で、その氏族によっていった者である。
31 Wọ́n sì ṣé kèké gẹ́gẹ́ bí àwọn arákùnrin wọn àwọn ọmọ Aaroni ṣe ṣẹ́, níwájú ọba Dafidi àti Sadoku, Ahimeleki, àti olórí ìdílé àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi. Àwọn ìdílé àgbàgbà arákùnrin wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀ lórí àwọn arákùnrin wọn kéékèèké.
これらの者もまた氏族の兄もその弟も同様に、ダビデ王と、ザドクと、アヒメレクと、祭司およびレビびとの氏族の長たちの前で、アロンの子孫であるその兄弟たちのようにくじを引いた。