< 1 Chronicles 23 >

1 Nígbà tí Dafidi sì dàgbà, tí ó sì di arúgbó, ó sì fi Solomoni ọmọ rẹ̀ jẹ ọba lórí Israẹli.
ודויד זקן ושבע ימים וימלך את שלמה בנו על ישראל׃
2 Ó sì kó gbogbo àgbàgbà Israẹli jọ, àti gẹ́gẹ́ bí àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi.
ויאסף את כל שרי ישראל והכהנים והלוים׃
3 Àwọn ọmọ Lefi láti ọgbọ̀n ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ni wọ́n kà àpapọ̀ iye àwọn ọkùnrin wọn sì jẹ́ ẹgbàá mọ́kàndínlógún.
ויספרו הלוים מבן שלשים שנה ומעלה ויהי מספרם לגלגלתם לגברים שלשים ושמונה אלף׃
4 Dafidi sì wí pe, ní ti èyí, ẹgbàá méjìlá ni kí wọn jẹ́ alábojútó iṣẹ́ ilé fún Olúwa àti ẹgbẹ̀rún mẹ́fà ni kí ó ṣe olórí àti onídàájọ́.
מאלה לנצח על מלאכת בית יהוה עשרים וארבעה אלף ושטרים ושפטים ששת אלפים׃
5 Ẹgbàajì ni kí ó jẹ́ olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà àti ẹgbàajì ni kí o sì jẹ́ ẹni ti yóò máa yin Olúwa pẹ̀lú ohun èlò orin, mo ti ṣe èyí fún ìdí pàtàkì yìí.
וארבעת אלפים שערים וארבעת אלפים מהללים ליהוה בכלים אשר עשיתי להלל׃
6 Dafidi sì pín àwọn ọmọ Lefi sí ẹgbẹgbẹ́ láàrín àwọn ọmọ Lefi: Gerṣoni, Kohati àti Merari.
ויחלקם דויד מחלקות לבני לוי לגרשון קהת ומררי׃
7 Àwọn tí ó jẹ́ ọmọ Gerṣoni: Laadani àti Ṣimei.
לגרשני לעדן ושמעי׃
8 Àwọn ọmọ Laadani Jehieli ẹni àkọ́kọ́, Setamu àti Joẹli, mẹ́ta ní gbogbo wọn.
בני לעדן הראש יחיאל וזתם ויואל שלשה׃
9 Àwọn ọmọ Ṣimei: Ṣelomiti, Hasieli àti Harani mẹ́ta ní gbogbo wọn. Àwọn wọ̀nyí sì ni olórí àwọn ìdílé Laadani.
בני שמעי שלמות וחזיאל והרן שלשה אלה ראשי האבות ללעדן׃
10 Àti ọmọ Ṣimei: Jahati, Sina, Jeuṣi àti Beriah. Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Ṣimei mẹ́rin ni gbogbo wọn.
ובני שמעי יחת זינא ויעוש ובריעה אלה בני שמעי ארבעה׃
11 Jahati sì ni alákọ́kọ́ Sinah sì ni ẹlẹ́ẹ̀kejì, ṣùgbọ́n Jeuṣi àti Beriah kò ní àwọn ọmọ púpọ̀; bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ka ara wọn sí ìdílé kan pẹ̀lú ìfilé lọ́wọ́ kan.
ויהי יחת הראש וזיזה השני ויעוש ובריעה לא הרבו בנים ויהיו לבית אב לפקדה אחת׃
12 Àwọn ọmọ Kohati: Amramu, Isari, Hebroni àti Usieli mẹ́rin ni gbogbo wọn.
בני קהת עמרם יצהר חברון ועזיאל ארבעה׃
13 Àwọn ọmọ Amramu. Aaroni àti Mose. A sì ya Aaroni sọ́tọ̀ òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ títí láéláé, láti kọjú sí ohun mímọ́ jùlọ, láti fi rú ẹbọ sísun níwájú Olúwa, láti máa ṣe òjíṣẹ́ níwájú rẹ̀ àti láti kéde ìbùkún ní orúkọ rẹ̀ títí láéláé.
בני עמרם אהרן ומשה ויבדל אהרן להקדישו קדש קדשים הוא ובניו עד עולם להקטיר לפני יהוה לשרתו ולברך בשמו עד עולם׃
14 Àwọn ọmọ Mose ènìyàn Ọlọ́run ni wọ́n kà gẹ́gẹ́ bí apá kan ẹ̀yà Lefi.
ומשה איש האלהים בניו יקראו על שבט הלוי׃
15 Àwọn ọmọ Mose: Gerṣomu àti Elieseri.
בני משה גרשם ואליעזר׃
16 Àwọn ọmọ Gerṣomu: Ṣubaeli sì ni alákọ́kọ́.
בני גרשום שבואל הראש׃
17 Àwọn ọmọ Elieseri: Rehabiah sì ni ẹni àkọ́kọ́. Elieseri kò sì tún ní ọmọ mìíràn, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Rehabiah wọ́n sì pọ̀ níye.
ויהיו בני אליעזר רחביה הראש ולא היה לאליעזר בנים אחרים ובני רחביה רבו למעלה׃
18 Àwọn ọmọ Isari: Ṣelomiti sì ni ẹni àkọ́kọ́.
בני יצהר שלמית הראש׃
19 Àwọn ọmọ Hebroni: Jeriah sì ni ẹni àkọ́kọ́, Amariah sì ni ẹni ẹ̀ẹ̀kejì, Jahasieli sì ni ẹ̀ẹ̀kẹ́ta àti Jekameamu ẹ̀ẹ̀kẹrin.
בני חברון יריהו הראש אמריה השני יחזיאל השלישי ויקמעם הרביעי׃
20 Àwọn ọmọ Usieli: Mika ni àkọ́kọ́ àti Iṣiah ẹ̀ẹ̀kejì.
בני עזיאל מיכה הראש וישיה השני׃
21 Àwọn ọmọ Merari: Mahili àti Muṣi. Àwọn ọmọ Mahili: Eleasari àti Kiṣi.
בני מררי מחלי ומושי בני מחלי אלעזר וקיש׃
22 Eleasari sì kú pẹ̀lú àìní àwọn ọmọkùnrin: Ó ní ọmọbìnrin nìkan. Àwọn ọmọ ẹ̀gbọ́n, àwọn ọmọ Kiṣi, sì fẹ́ wọn.
וימת אלעזר ולא היו לו בנים כי אם בנות וישאום בני קיש אחיהם׃
23 Àwọn ọmọ Muṣi: Mahili, Ederi àti Jerimoti mẹ́ta ni gbogbo wọn.
בני מושי מחלי ועדר וירמות שלשה׃
24 Àwọn wọ̀nyí sì ni ọmọ Lefi bí ìdílé wọn. Olórí ìdílé gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti fi orúkọ sílẹ̀ lábẹ́ orúkọ wọn, ó sì kà wọn ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan, wí pé, àwọn òṣìṣẹ́ tí ó jẹ́ ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tí ń ṣiṣẹ́ ìsìn nínú ilé Olúwa.
אלה בני לוי לבית אבתיהם ראשי האבות לפקודיהם במספר שמות לגלגלתם עשה המלאכה לעבדת בית יהוה מבן עשרים שנה ומעלה׃
25 Nítorí pé Dafidi ti sọ pé, “Níwọ̀n ìgbà tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli, ti fi ìsinmi fún àwọn ènìyàn tí ó kù tí sì ń gbé Jerusalẹmu títí láéláé,
כי אמר דויד הניח יהוה אלהי ישראל לעמו וישכן בירושלם עד לעולם׃
26 àwọn ọmọ Lefi kò sì tún ru àgọ́ tàbí ọ̀kankan lára àwọn ohun èlò tí wọ́n ń lò níbi ìsìn rẹ̀.”
וגם ללוים אין לשאת את המשכן ואת כל כליו לעבדתו׃
27 Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ìkẹyìn Dafidi sí, àwọn ọmọ Lefi, wọ́n sì kà wọ́n, bẹ̀rẹ̀ láti orí àwọn ọmọ ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ.
כי בדברי דויד האחרנים המה מספר בני לוי מבן עשרים שנה ולמעלה׃
28 Iṣẹ́ àwọn ọmọ Lefi ni láti ran àwọn ọmọ Aaroni lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ wọn fún ti ilé Olúwa: láti wà lábẹ́ ìkáwọ́ agbára ìlú, àti ẹ̀gbẹ́ ilé, àti ìwẹ̀nùmọ́ ti gbogbo ohun ìyàsọ́tọ̀ àti ṣíṣe ohun tí í ṣe iṣẹ́ ìsìn nínú ilé Olúwa.
כי מעמדם ליד בני אהרן לעבדת בית יהוה על החצרות ועל הלשכות ועל טהרת לכל קדש ומעשה עבדת בית האלהים׃
29 Wọ́n sì wà ní ìkáwọ́ àkàrà tí wọ́n mú jáde láti orí tábìlì, àti ìyẹ̀fun fún ẹbọ, àti àkàrà aláìwú, àti fún púpọ̀ àti èyí tí a pòpọ̀, àti gbogbo onírúurú ìwọ̀n àti wíwọ̀n àti òsùwọ̀n.
וללחם המערכת ולסלת למנחה ולרקיקי המצות ולמחבת ולמרבכת ולכל משורה ומדה׃
30 Wọ́n sì gbọdọ̀ dúró ní gbogbo òwúrọ̀ láti dúpẹ́ àti láti yin Olúwa. Wọ́n sì gbọdọ̀ ṣe irú kan náà ní àṣálẹ́.
ולעמד בבקר בבקר להדות ולהלל ליהוה וכן לערב׃
31 Àti láti rú ẹbọ sísun fún Olúwa ní ọjọ́ ìsinmi àti ní àsìkò oṣù tuntun àti ní àjọ̀dún tí a yàn. Wọ́n gbọdọ̀ sìn níwájú Olúwa lójoojúmọ́ ní iye tó yẹ àti ní ọ̀nà tí a ti pàṣẹ fún wọn.
ולכל העלות עלות ליהוה לשבתות לחדשים ולמעדים במספר כמשפט עליהם תמיד לפני יהוה׃
32 Bẹ́ẹ̀ ni nígbà náà, àwọn ọmọ Lefi gbé ìgbékalẹ̀ jáde fún ìpàdé àgọ́, fún Ibi Mímọ́ àti, lábẹ́ àwọn arákùnrin àwọn ọmọ Aaroni fún ìsìn ilé Olúwa.
ושמרו את משמרת אהל מועד ואת משמרת הקדש ומשמרת בני אהרן אחיהם לעבדת בית יהוה׃

< 1 Chronicles 23 >