< 1 Chronicles 13 >

1 Dafidi sì gbèrò pẹ̀lú olúkúlùkù àwọn ìjòyè rẹ̀, àwọn aláṣẹ ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti àwọn aláṣẹ ọgọ́rùn-ún
David consultou os capitães de milhares e de centenas, mesmo com todos os líderes.
2 Dafidi sì wí fún gbogbo àwọn ìjọ Israẹli pé, tí ó bá dára lójú yín àti tí ó bá ṣe jẹ́ àṣẹ Olúwa Ọlọ́run wa, jẹ́ kí a ránṣẹ́ sí ọ̀nà jíjìn àti gbígbòòrò sí àwọn arákùnrin wa tókù ní gbogbo àwọn agbègbè ìlú Israẹli àti pẹ̀lú àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi àwọn tí ó wà pẹ̀lú wọn nínú ìlú wọn àti pápá oko tútù, láti wá kó ara wọn jọ pọ̀ sọ́dọ̀ wa.
David disse a toda a assembléia de Israel: “Se vos parece bom, e se é de Javé nosso Deus, mandemos notícias por toda parte aos nossos irmãos que ficam em toda a terra de Israel, com quem os sacerdotes e levitas estão em suas cidades que têm terras de pasto, para que se reúnam a nós”.
3 Ẹ jẹ́ kí a gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa padà sọ́dọ̀ wa, nítorí wí pé àwa kò ṣe ìwádìí nípa rẹ̀ ní àsìkò ìjọba Saulu.
Também, vamos trazer a arca de nosso Deus de volta para nós, pois não a buscamos nos dias de Saul”.
4 Gbogbo ìjọ náà sì gbà láti ṣe èyí nítorí ó dàbí wí pé ó tọ lójú gbogbo àwọn ènìyàn.
Toda a assembléia disse que o fariam, pois a coisa estava certa aos olhos de todo o povo.
5 Nígbà náà ni Dafidi pe gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ, láti ọ̀dọ̀ Ṣihori ní Ejibiti lọ sí Lebo ní ọ̀nà à bá wọ Hamati, láti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run padà láti Kiriati-Jearimu.
Então David reuniu todo Israel, desde o rio Shihor do Egito até a entrada de Hamath, para trazer a arca de Deus de Kiriath Jearim.
6 Dafidi àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli pẹ̀lú rẹ̀ lọ sí Baalahi ti Juda (Kiriati-Jearimu) láti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run Olúwa tí a fi orúkọ rẹ̀ pè, tí ó jókòó láàrín kérúbù gòkè wá.
David subiu com todo Israel para Baalah, ou seja, para Kiriath Jearim, que pertencia a Judah, para trazer de lá a arca de Deus Yahweh que está acima dos querubins, que é chamada pelo Nome.
7 Wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run láti ilé Abinadabu lórí kẹ̀kẹ́ tuntun, Ussa àti Ahio ń ṣọ́ ọ.
Eles carregaram a arca de Deus em um novo carrinho, e a trouxeram para fora da casa de Abinadab; e Uzza e Ahio dirigiram o carrinho.
8 Dafidi àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ni wọ́n ṣe àjọyọ̀ pẹ̀lú gbogbo agbára wọn níwájú Ọlọ́run, pẹ̀lú orin àti pẹ̀lú dùùrù, ohun èlò orin olókùn, tambori, kimbali pẹ̀lú ìpè.
David e todo Israel tocaram diante de Deus com todas as suas forças, mesmo com canções, com harpas, com instrumentos de cordas, com pandeiros, com címbalos e com trombetas.
9 Nígbà tí wọ́n dé sí ilẹ̀ ìpakà Kidoni, Ussa sì na ọwọ́ rẹ̀ síta láti di àpótí ẹ̀rí Olúwa mú, nítorí màlúù kọsẹ̀.
Quando chegaram à eira de Chidon, Uzza estendeu sua mão para segurar a arca, pois os bois tropeçaram.
10 Ìbínú Olúwa, sì ru sí Ussa, ó sì lù ú bolẹ̀ nítorí o ti fi ọwọ́ rẹ̀ lórí àpótí ẹ̀rí. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì kú síbẹ̀ níwájú Ọlọ́run.
A raiva de Yahweh queimou contra Uzza, e ele o atingiu porque colocou sua mão sobre a arca; e ele morreu lá diante de Deus.
11 Nígbà náà Dafidi sì bínú nítorí ìbínú Olúwa ké jáde lórí Ussa, àti títí di òní, wọ́n sì ń pe ibẹ̀ ní Peresi-Usa.
David ficou descontente, porque Yahweh havia fugido contra Uzza. Ele chamou aquele lugar de Perez Uzza, até os dias de hoje.
12 Dafidi sì bẹ̀rù Ọlọ́run ní ọjọ́ náà, ó sì béèrè pé, báwo ni èmi náà ó ṣe gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run sí ọ̀dọ̀ mi?
David tinha medo de Deus naquele dia, dizendo: “Como posso levar a arca de Deus para casa”?
13 Kò gbé àpótí ẹ̀rí náà wá sí ọ̀dọ̀ ará rẹ̀ ní ìlú ti Dafidi dípò èyí, ó sì gbé e yà sí ilé Obedi-Edomu ará Gitti.
Então David não moveu a arca com ele para a cidade de David, mas a levou para a casa de Obed-Edom, o Gittita.
14 Àpótí ẹ̀rí Olúwa sì wà lọ́dọ̀ àwọn ará ilé Obedi-Edomu ní ilé rẹ̀ fún oṣù mẹ́ta, Olúwa sì bùkún agbo ilé àti gbogbo ohun tí ó ní.
A arca de Deus permaneceu com a família de Obed-Edom em sua casa três meses; e Yahweh abençoou a casa de Obed-Edom e tudo que ele tinha.

< 1 Chronicles 13 >