< 1 Chronicles 12 >
1 Àwọn wọ̀nyí ni ọkùnrin tí ó wá sí ọ̀dọ̀ Dafidi ní Siklagi, nígbà tí ó sá kúrò níwájú Saulu ọmọ Kiṣi (wọ́n wà lára àwọn jagunjagun ẹni tí ó ràn án lọ́wọ́ láti ibi ìjà.
These were the men who came to David to Ziklag, while he was still banished from the presence of Saul son of Kish. They were among the soldiers, his helpers in battle.
2 Wọ́n sì mú wọn pẹ̀lú ìtẹríba wọ́n sì lágbára láti ta ọfà tàbí láti ta kànnàkànnà òkúta ní ọwọ́ òsì tàbí ní ọwọ́ ọ̀tún, wọ́n sì jẹ́ ìbátan ọkùnrin Saulu láti ẹ̀yà Benjamini):
They were armed with bows and could use both the right hand and the left in slinging stones and in shooting arrows from the bow. They were Benjamites, Saul's fellow tribesmen.
3 Ahieseri olórí wọn àti Joaṣi àwọn ọmọ Ṣemaah ará Gibeah: Jeṣieli àti Peleti ọmọ Asmafeti, Beraka, Jehu ará Anatoti.
The chief was Ahiezer, then Joash, both sons of Shemaah the Gibeathite. There were Jeziel and Pelet, sons of Azmaveth. There were also Berakah, Jehu the Anathothite,
4 Àti Iṣmaiah ará Gibeoni, ọkùnrin alágbára kan lára àwọn ọgbọ̀n ẹni tí ó jẹ́ olórí nínú àwọn ọgbọ̀n; Jeremiah, Jahasieli, Johanani, Josabadi ará Gedera,
Ishmaiah the Gibeonite, a soldier among the thirty (and in command of the thirty); Jeremiah, Jahaziel, Johanan, Jozabad the Gederathite,
5 Elusai, Jerimoti, Bealiah, Ṣemariah àti Ṣefatia ará Harufiti;
Eluzai, Jerimoth, Bealiah, Shemariah, Shephatiah the Haruphite,
6 Elkana, Iṣiah, Asareeli, Joeseri àti Jaṣobeamu ará Kora;
the Korahites Elkanah, Isshiah, Azarel, Joezer, Jashobeam, and
7 àti Joẹla, àti Sebadiah àwọn ọmọ Jerohamu láti Gedori.
Joelah and Zebadiah, sons of Jeroham of Gedor.
8 Díẹ̀ lára àwọn ará Gadi yà sọ́dọ̀ Dafidi ní ibi gíga ní aginjù. Wọ́n sì jẹ́ onígboyà ológun tí ó múra fún ogun tí ó sì lágbára láti di asà àti ẹṣin mú. Ojú wọn sì dàbí ojú kìnnìún, wọ́n sì yára bí àgbọ̀nrín lórí àwọn òkè.
Some Gadites joined David at the stronghold in the wilderness. They were fighting men, men trained for battle, who could handle shield and spear; whose faces were as fierce as the faces of lions. They were as swift as gazelles on the mountains.
9 Eseri sì jẹ́ ìjòyè, Obadiah sì jẹ́ igbákejì akọgun, Eliabu ẹlẹ́ẹ̀kẹta,
There were Ezer the leader, Obadiah the second, Eliab the third,
10 Miṣimana ẹlẹ́ẹ̀kẹrin, Jeremiah ẹlẹ́ẹ̀karùnún
Mishmannah the fourth, Jeremiah the fifth,
11 Attai ẹlẹ́ẹ̀kẹfà, Elieli èkeje,
Attai the sixth, Eliel the seventh,
12 Johanani ẹlẹ́ẹ̀kẹjọ Elsabadi ẹlẹ́ẹ̀kẹsàn-án
Johanan the eighth, Elzabad the ninth,
13 Jeremiah ẹlẹ́ẹ̀kẹwàá àti Makbannai ẹlẹ́ẹ̀kọkànlá.
Jeremiah the tenth, Makbannai the eleventh.
14 Àwọn ará Gadi wọ́n sì jẹ́ olórí ogun; ẹni tí ó kéré jù sì jẹ́ àpapọ̀ ọgọ́rùn-ún, àti fún ẹni tí ó pọ̀jù fún ẹgbẹ̀rún.
These sons of Gad were leaders of the army. The least led a hundred, and the greatest led a thousand.
15 Àwọn ni ẹni tí ó rékọjá Jordani ní oṣù àkọ́kọ́ nígbà tí ó kún bo gbogbo bèbè rẹ̀, wọ́n sì lé gbogbo àwọn tí ó ń gbé nínú àfonífojì, lọ sí ìlà-oòrùn àti níhà ìwọ̀-oòrùn.
They crossed the Jordan in the first month, when it overflowed its banks, and chased away all those living in the valleys, both toward the east and toward the west.
16 Ìyókù ará Benjamini àti àwọn díẹ̀ ọkùnrin láti Juda lọ sí ọ̀dọ̀ Dafidi ní ibi gíga.
Some of the men of Benjamin and Judah came to the stronghold to David.
17 Dafidi sì lọ láti lọ pàdé wọn ó sì wí fún wọn pé, “Tí ẹ bá wá sọ́dọ̀ mi lálàáfíà, láti ràn mí lọ́wọ́ mo ṣetán láti mú un yín wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi ṣùgbọ́n tí ẹ bá wá láti dá mi sí fún àwọn ọ̀tá mi nígbà tí ọwọ́ mi bá mọ́ kúrò nínú ìwà agbára, kí Ọlọ́run àwọn baba wa kí ó sì ri kí ó sì ṣe ìdájọ́.”
David went out to meet them and addressed them: “If you have come in peace to me to help me, you may join me. But if you have come to betray me to my adversaries, may the God of our ancestors see and rebuke you, since I have done no wrong.”
18 Nígbà náà Ẹ̀mí Mímọ́ wa sórí Amasai ìjòyè àwọn ọgbọ̀n, ó sì wí pé, “Tìrẹ ni àwa ń ṣe, ìwọ Dafidi! Àwa pẹ̀lú rẹ, ìwọ ọmọ Jese! Àlàáfíà, àlàáfíà fún ọ, àti àlàáfíà fún àwọn tí ó ràn ó lọ́wọ́, nítorí Ọlọ́run rẹ̀ yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi sì gbà wọ́n ó sì mú wọn jẹ olórí ẹgbẹ́ ogun.
Then the Spirit came on Amasai, who was chief of the thirty. Amasai said, “We are yours, David. We are on your side, son of Jesse. Peace, may peace be to whoever helps you. May peace be to your helpers, for your God is helping you.” Then David received them and made them commanders over his men.
19 Díẹ̀ nínú àwọn ọkùnrin Manase sì yà sí ọ̀dọ̀ Dafidi nígbà tí ó lọ pẹ̀lú àwọn ará Filistini láti bá Saulu jà. (Òun àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ wọn kò sì ran ará Filistini lọ́wọ́ nítorí, lẹ́yìn tiwọn sọ̀rọ̀ papọ̀, àwọn olórí wọn rán wọn jáde, wọ́n sì wí pé, “Yóò jẹ́ ìparun fún wa tí ó bá padà tọ ọ̀gá rẹ̀ Saulu lọ.”)
Some from Manasseh also deserted to David when he came with the Philistines against Saul to battle. Yet they did not help the Philistines, because the Philistine lords consulted with each other and sent David away. They said, “He will desert to his master Saul at the risk of our lives.”
20 Nígbà tí Dafidi lọ sí Siklagi, àwọn wọ̀nyí ni ọkùnrin ti Manase ẹni tí ó sì yà sọ́dọ̀ rẹ̀. Adina, Josabadi, Jediaeli, Mikaeli, Josabadi, Elihu àti Siletai, àwọn olórí ìrẹ́pọ̀ ti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ní Manase.
When he went to Ziklag, the men of Manasseh who joined him were Adnah, Jozabad, Jediael, Michael, Jozabad, Elihu, and Zillethai, captains over thousands of Manasseh.
21 Wọ́n sì ran Dafidi lọ́wọ́ lórí ẹgbẹ́ ogun náà, nítorí gbogbo wọn ni akọni ènìyàn àwọn sì tún ni olórí nínú àwọn ọmọ-ogun rẹ̀.
They helped David fight against the roving bands, for they were fighting men. Later they became commanders in the army.
22 Ọjọ́ dé ọjọ́ ni àwọn ọkùnrin wá láti ran Dafidi lọ́wọ́, títí tí ó fi ní àwọn ológun ńlá, bí ogun Ọlọ́run.
Day after day, men came to David to help him, until there was a great army, like the army of God.
23 Àwọn wọ̀nyí sì ni iye ọkùnrin tí ó ti di ìhámọ́ra fún ogun àwọn ẹni tí ó wá sọ́dọ̀ Dafidi ní Hebroni láti yí ìjọba Dafidi padà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ.
This is the record of the armed soldiers for war, who came to David to Hebron, to turn the kingdom of Saul over to him, which carried out Yahweh's word.
24 Ọkùnrin Juda, tí o ń gbé asà àti ọ̀kọ̀, ẹgbàáta lé lẹ́gbẹ̀rin tí ó ti di ìhámọ́ra fún ogun.
From Judah those who carried shield and spear were 6,800, armed for war.
25 Àwọn ọkùnrin Simeoni, akọni tó mú fún ogun sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin ó lé ọgọ́rùn-ún;
From the Simeonites there were 7,100 fighting men.
26 àwọn ọkùnrin Lefi ẹgbàajì ó le ẹgbẹ̀ta,
From the Levites there were 4,600 fighting men.
27 pẹ̀lú Jehoiada, olórí ìdílé Aaroni pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ènìyàn,
Jehoiada was the leader of Aaron's descendants, and with him were 3,700.
28 àti Sadoku akọni ọ̀dọ́mọkùnrin, pẹ̀lú àwọn méjìlélógún ìjòyè láti ọ̀dọ̀ àwọn ìdílé rẹ̀;
With Zadok, a young, strong, and courageous man, were twenty-two leaders from his father's family.
29 àwọn arákùnrin Benjamini ìbátan ọkùnrin Saulu ẹgbẹ̀rún mẹ́ta, ọ̀pọ̀ nínú àwọn ẹni tí ó si kù ní olóòtítọ́ sí ilé Saulu títí di ìgbà náà;
From Benjamin, Saul's tribe, were three thousand. Most of them had remained loyal to Saul until this time.
30 àwọn arákùnrin Efraimu, ògbójú akọni, ènìyàn Ọlọ́run ni wọ́n nílé baba wọn ogún ẹgbẹ̀rún ó le ẹgbẹ̀rin;
From the Ephraimites there were 20,800 fighting men, men who were famous in their fathers' houses.
31 àwọn ọkùnrin nínú ààbọ̀ ẹ̀yà Manase, tí a yàn nípa orúkọ láti wá àti láti yan Dafidi gẹ́gẹ́ bí ọba, ẹgbàá mẹ́sàn.
From the half tribe of Manasseh there were eighteen thousand famous men who came to make David king.
32 Àti ní ti àwọn ọmọ Isakari, àwọn ẹni tí ó ní òye àkókò, láti mọ ohun tí Israẹli ìbá máa ṣe; olórí wọn jẹ́ ìgbà; àti gbogbo àwọn ìbátan wọn ń bẹ ní ìkáwọ́ wọn.
From Issachar, there were two hundred leaders who had understanding of the times and knew what Israel ought to do. All their relatives were under their command.
33 Àwọn ọkùnrin Sebuluni, àti àwọn jagunjagun tí ó ti nípa ogun múra fún ogun pẹ̀lú oríṣìíríṣìí ohun èlò ìjà, láti ran Dafidi lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn tí kò fi iyèméjì ṣe ìjólóòótọ́ wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n.
From Zebulun there were fifty thousand fighting men, prepared for battle, with all the weapons of war, and ready to give undivided loyalty.
34 Àwọn ọkùnrin Naftali, ẹgbẹ̀rún ìjòyè àpapọ̀ pẹ̀lú ẹgbàá méjìdínlógún. Ọkùnrin tí wọ́n gbé asà àti ọ̀kọ̀ wọn.
From Naphtali there were one thousand officers, and with them thirty-seven thousand men with shields and spears.
35 Àwọn ọkùnrin Dani, tí wọ́n ṣetán fún ogun ẹgbàá mẹ́tàlá.
From the Danites there were 28,600 men prepared for battle.
36 Àwọn ọkùnrin Aṣeri, àwọn tí ó ti ní ìmọ̀ ogun múra fún ogun ọ̀kẹ́ méjì.
From Asher there were forty thousand men prepared for battle.
37 Láti ìlà-oòrùn Jordani, ọkùnrin Reubeni, Gadi, àti ìdajì ẹ̀yà Manase, dìmọ́ra pẹ̀lú gbogbo onírúurú ohun èlò ìjà ọ̀kẹ́ mẹ́fà.
From the other side of the Jordan, from the Reubenites, Gadites, and the half tribe of Manasseh, there were 120,000 men armed with all kinds of weapons for battle.
38 Gbogbo èyí ni àwọn ọkùnrin ológun tí ó fi ara wọn fún ogun láti ṣe iṣẹ́ fún nínú ẹgbẹ́. Wọ́n wá sí Hebroni tí ó kún fún ìpinnu láti fi Dafidi jẹ́ ọba lórí gbogbo Israẹli. Gbogbo àwọn ìyókù lára àwọn ọmọ Israẹli sì jẹ́ onínú kan láti fi Dafidi jẹ ọba.
All these soldiers, equipped for battle, came to Hebron with firm intentions to make David king over all Israel. All the rest of Israel were in agreement to make David king also.
39 Àwọn ọkùnrin náà lo ọjọ́ mẹ́ta níbẹ̀ pẹ̀lú Dafidi, wọ́n jẹ, wọ́n sì ń mu, nítorí ìdílé wọn ti pèsè oúnjẹ fún wọn.
They were there with David three days, eating and drinking, for their relatives had sent them with provisions.
40 Àwọn aládùúgbò láti ọ̀nà jíjìn gẹ́gẹ́ bí Isakari, Sebuluni àti Naftali gbé oúnjẹ wá lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, lórí ràkunmí, àti lórí ìbáaka àti lórí màlúù, àní oúnjẹ ti ìyẹ̀fun, èso àjàrà gbígbẹ, èso ọ̀pọ̀tọ́, àkàrà dídùn, ọtí wáìnì, òróró, màlúù àti àgùntàn, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ayọ̀ wà ní Israẹli.
In addition, those who were near to them, as far as Issachar and Zebulun and Naphtali, brought bread on donkeys, camels, mules, and oxen, and cakes of figs, clusters of raisins, wine, oil, oxen, and sheep, for Israel was celebrating.