< 1 Chronicles 11 >

1 Gbogbo àwọn Israẹli kó ara wọn jọ pọ̀ sí ọ̀dọ̀ Dafidi ní Hebroni, wọ́n sì wí pé, “Ẹran-ara rẹ àti ẹ̀jẹ̀ rẹ ni àwa í ṣe.
Then all Israel came together to David at Hebron, and said, Truly, we are your bone and your flesh.
2 Ní àtijọ́, kódà nígbà tí Saulu jẹ ọba, ìwọ ni ẹni tí ó darí Israẹli ní ojú ogun wọn. Olúwa Ọlọ́run rẹ sì wí fún ọ pé, ‘Ìwọ yóò sì jẹ́ olùṣọ́ Israẹli ènìyàn mi, ìwọ yóò sì jẹ́ olórí fún wọn.’”
In the past, when Saul was king, it was you who went at the head of Israel when they went out or came in; and the Lord your God said to you, You are to be the keeper of my people Israel, and their ruler.
3 Nígbà tí gbogbo àwọn ìjòyè Israẹli tí wọ́n ti wá sọ́dọ̀ ọba Dafidi ni Hebroni. Ó sì ṣe májẹ̀mú pẹ̀lú wọn ní Hebroni níwájú Olúwa, wọ́n sì fi òróró yan Dafidi ní ọba lórí Israẹli, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa láti ọwọ́ Samuẹli.
So all the responsible men of Israel came to the king at Hebron; and David made an agreement with them in Hebron before the Lord; and they put the holy oil on David and made him king over Israel, as the Lord had said by Samuel.
4 Dafidi àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jáde lọ sí Jerusalẹmu (tí ṣe Jebusi). Àwọn Jebusi ara ilẹ̀ náà ń gbé níbẹ̀.
Then David and all Israel went to Jerusalem (which is Jebus); and the Jebusites, the people of the land, were there.
5 Àwọn ará ìlú Jebusi sì wí fún Dafidi pé, “Ìwọ kò sì gbọdọ̀ wọ ìhín yìí wá.” Ṣùgbọ́n Dafidi kó ìlú odi Sioni—èyí tí í ṣe ìlú Dafidi.
And the people of Jebus said to David, You will not come in here. But still, David took the strong place of Zion, which is the town of David.
6 Dafidi ti wí pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá tètè kọlu àwọn ará Jebusi ni yóò di olórí àti balógun.” Joabu ọmọ Seruiah sì kọ́kọ́ gòkè lọ, bẹ́ẹ̀ ni ó sì gba olórí.
And David said, The first to overcome the Jebusites will be chief and captain. And Joab, the son of Zeruiah, went up first, and became chief.
7 Dafidi sì ń gbé inú ìlú odi, nítorí náà ni wọ́n fi ń pè é ni ìlú Dafidi.
And David took the strong tower for his living-place, so it was named the town of David.
8 Ó sì kọ́ àwọn ìlú náà yíkákiri; láti Millo yíkákiri; Joabu sì tún ìyókù àwọn ìlú náà ṣe.
And he took in hand the building of the town all round, starting from the Millo; and Joab put the rest of the town in order.
9 Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi ń ga, ó sì pọ̀ sí i, nítorí pé Olúwa àwọn ọmọ-ogun wà pẹ̀lú rẹ̀.
And David became greater and greater in power, because the Lord of armies was with him.
10 Àwọn wọ̀nyí sì ni ìjòyè alágbára ọkùnrin Dafidi, àwọn pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì fún ìjọba rẹ̀ ní àtìlẹ́yìn tó lágbára láti mú un tàn káàkiri gbogbo ilẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti ṣèlérí.
Now these are the chief of David's men of war who were his strong supporters in the kingdom, and, with all Israel, made him king, as the Lord had said about Israel.
11 Èyí sì ni iye àwọn akọni ọkùnrin Dafidi: Jaṣobeamu ọmọ Hakumoni, òun sì ni olórí nínú àwọn ìjòyè, ó sì gbé ọ̀kọ̀ rẹ̀ sókè lórí àwọn ọ̀ọ́dúnrún ènìyàn, àwọn ẹni tí ó pa ní ogun ẹ̀ẹ̀kan.
This is the list of David's men of war: Ishbaal, the son of a Hachmonite, the chief of the three: he put to death three hundred at one time with his spear.
12 Lẹ́yìn rẹ̀ sì ni Eleasari ọmọ Dodo àwọn ará Ahohi, ọ̀kan lára àwọn mẹ́ta ọkùnrin alágbára.
And after him was Eleazar, the son of Dodo the Ahohite, who was one of the three great fighters.
13 Ó sì wà pẹ̀lú Dafidi ní Pasi-Dammimu nígbà tí àwọn ará Filistini kó ara wọn jọ láti jagun, níbi tí ilẹ̀ kan wà tí ó kún fún ọkà barle. Àwọn ènìyàn sì sálọ kúrò níwájú Filistini.
He was with David at Pas-dammim, where the Philistines had come together for the fight, near a bit of land full of barley; and the people went in flight before the Philistines.
14 Ṣùgbọ́n wọ́n mú ìdúró wọn ní àárín pápá náà. Wọ́n sì gbà a wọ́n sì gún àwọn ará Filistini mọ́lẹ̀, Olúwa sì mú ìgbàlà ńlá fún wọn.
And he took up his position in the middle of the bit of land, and kept back their attack, and overcame the Philistines; and the Lord gave a great salvation.
15 Mẹ́ta nínú àwọn ọgbọ̀n ìjòyè sọ̀kalẹ̀ tọ́ Dafidi wá lọ sí orí àpáta nínú ihò Adullamu, nígbà tí àwọn ẹgbẹ́ Filistini sì dúró ní àfonífojì ní orí òkè Refaimu.
And three of the thirty went down to David, to the rock, into the strong place of Adullam; and the army of the Philistines had taken up their position in the valley of Rephaim.
16 Ní àsìkò náà Dafidi sì ń bẹ nínú ìlú odi, ẹgbẹ́ ogun àwọn ará Filistini sì ń bẹ ní Bẹtilẹhẹmu.
At that time David had taken cover in the strong place, and an armed force of the Philistines was in Beth-lehem.
17 Dafidi sí pòǹgbẹ fún omi ó sì wí pé, “Háà, ẹnìkan yóò ha bu omi láti inú kànga ní ẹ̀gbẹ́ ẹnu-bodè Bẹtilẹhẹmu fún un mu?”
And David, moved by a strong desire, said, If only someone would give me a drink of the water from the water-hole of Beth-lehem by the doorway into the town!
18 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn mẹ́ta náà sì là láti ogun ará Filistini, ó sì fa omi jáde láti inú kànga ní ẹ̀gbẹ́ ẹnu-bodè Bẹtilẹhẹmu ó sì gbé padà tọ Dafidi wá. Ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti mu ú: dípò, ó sì tú jáde níwájú Olúwa.
So the three, forcing a way through the Philistine army, got water from the water-hole of Beth-lehem, by the doorway into the town, and took it back to David; but David would not take it, but made an offering of it, draining it out to the Lord,
19 “Kí Ọlọ́run má jẹ́ kí èmi ó má ṣe ṣe èyí!” ó wí pé. “Ṣé kí èmi kí ó mú ẹ̀jẹ̀ ọkùnrin yí ẹni tí ó fi ẹ̀mí rẹ̀ wéwu?” Nítorí wọ́n fi ẹ̀mí wọn wéwu láti mú padà wá, Dafidi kò ní mu ú. Nǹkan wọ̀nyí ni àwọn akọni mẹ́ta ọkùnrin náà ṣe ohun ìyanu ńlá.
Saying, By my God, far be it from me to do this! How may I take as drink the life-blood of these men who have put their lives in danger? so he did not take it. These things did the three great men of war.
20 Abiṣai arákùnrin Joabu ìjòyè àwọn mẹ́ta. Ó sì gbé ọ̀kọ̀ rẹ̀ sókè lórí àwọn ọ̀ọ́dúnrún àwọn ènìyàn, àwọn ẹni tí ó pa, bẹ́ẹ̀ ni ó sì di olókìkí gẹ́gẹ́ bí àwọn mẹ́ta.
And Abishai, the brother of Joab, was chief of the thirty, for he put to death three hundred with his spear, but he had not a name among the three.
21 Ó sì gba ìlọ́po ọlá lórí àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ó sì di olórí wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò ka kún ara wọn.
Of the thirty, he was the noblest, and was made their captain, but he was not equal to the first three.
22 Benaiah ọmọ Jehoiada ó sì jẹ́ akọni oníjà láti Kabṣeeli, ẹni tí ó ṣe iṣẹ́ agbára ńlá. Ó sì pa àwọn ọmọ Arieli méjì ti Moabu, ó sì tún sọ̀kalẹ̀ lọ sí inú ihò lákokò yìnyín dídì, ó sì pa kìnnìún kan
Benaiah, the son of Jehoiada, a fighting-man of Kabzeel, had done great acts; he put to death two young lions going into their secret place; and he went down into a hole and put a lion to death in time of snow.
23 Ó sì pa ara Ejibiti ẹni tí ó ga ní ìwọ̀n ẹsẹ̀ méje àti ààbọ̀ ṣùgbọ́n àwọn ará Ejibiti wọn ní ọ̀kọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdábùú igi ahunṣọ àti ọ̀pá ní ọwọ́ rẹ̀, Benaiah sọ̀kalẹ̀ lórí rẹ̀ pẹ̀lú kùmọ̀. Ó sì gba ọ̀kọ̀ náà láti ọwọ́ ará Ejibiti ó sì pa á pẹ̀lú ọ̀kọ̀ rẹ̀.
And he made an attack on an Egyptian, a very tall man about five cubits high, armed with a spear like a cloth-worker's rod; he went down to him with a stick, and pulling his spear out of the hand of the Egyptian, put him to death with that same spear.
24 Nǹkan wọ̀nyí sì ní ìwà akin Benaiah ọmọ Jehoiada; ohun náà pẹ̀lú sì di olókìkí gẹ́gẹ́ bí àwọn akọni ọkùnrin mẹ́ta.
These were the acts of Benaiah, the son of Jehoiada, who had a great name among the thirty men of war.
25 Ó sì ní ọlá púpọ̀ ju àwọn ọgbọ̀n lọ, ṣùgbọ́n a kò kà á láàrín àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Dafidi sì fi sí ìkáwọ́ àwọn ẹ̀ṣọ́.
He was honoured over the thirty, but he was not equal to the first three: and David put him over his servants.
26 Àwọn akọni ọkùnrin náà nìyí: Asaheli arákùnrin Joabu, Elhanani ọmọ Dodo láti Bẹtilẹhẹmu,
And these were the great men of war: Asahel, the brother of Joab, Elhanan, the son of Dodo of Beth-lehem,
27 Ṣamotu ará Harori, Helesi ará Peloni
Shammoth the Harodite, Helez the Pelonite,
28 Ira ọmọ Ikẹsi láti Tekoa, Abieseri láti Anatoti,
Ira, the son of Ikkesh the Tekoite, Abiezer the Anathothite,
29 Sibekai ará Huṣati, láti ará Ahohi
Sibbecai the Hushathite, Ilai the Ahohite,
30 Maharai ará Netofa, Heledi ọmọ Baanah ará Netofa,
Maharai the Netophathite, Heled, the son of Baanah the Netophathite,
31 Itai ọmọ Ribai láti Gibeah ní Benjamini, Benaiah ará Piratoni,
Ithai, the son of Ribai of Gibeah, of the children of Benjamin, Benaiah the Pirathonite,
32 Hurai láti àfonífojì Gaaṣi, Abieli ará Arbati,
Hurai of Nahale-gaash, Abiel the Arbathite,
33 Asmafeti ará Bahurimu Eliaba ará Ṣaalboni.
Azmaveth of Bahurim, Eliahba the Shaalbonite,
34 Àwọn ọmọ Haṣemu ará Gisoni Jonatani ọmọ Ṣage ará Harari.
The sons of Hashem the Gizonite, Jonathan, the son of Shage the Hararite,
35 Ahiamu ọmọ Sakari ará Harari, Elifali ọmọ Uri
Ahiam, the son of Sacar the Hararite, Eliphal, the son of Ur,
36 Heferi ará Mekerati, Ahijah ará Peloni,
Hepher the Mecherathite, Ahijah the Pelonite,
37 Hesro ará Karmeli Naarai ọmọ Esbai,
Hezro the Carmelite, Naarai, the son of Ezbai,
38 Joẹli arákùnrin Natani Mibari ọmọ Hagari,
Joel, the brother of Nathan, Mibhar, the son of Hagri,
39 Seleki ará Ammoni, Naharai ará Beroti ẹni tí ó jẹ́ ẹni tí n ru ìhámọ́ra Joabu ọmọ Seruiah.
Zelek the Ammonite, and Naharai the Berothite, the servant who had the care of the arms of Joab, the son of Zeruiah;
40 Ira ará Itri, Garebu ará Itri,
Ira the Ithrite, Gareb the Ithrite,
41 Uriah ará Hiti Sabadi ọmọ Ahlai.
Uriah the Hittite, Zabad, the son of Ahlai,
42 Adina ọmọ Ṣisa ará Reubeni, ẹni tí ó jẹ́ ìjòyè ará Reubeni, àti pẹ̀lú ọgbọ́n rẹ̀.
Adina, the son of Shiza the Reubenite, a chief of the Reubenites, and thirty with him;
43 Hanani ọmọ Maaka. Jehoṣafati ará Mitini.
Hanan, the son of Maacah, and Joshaphat the Mithnite,
44 Ussia ará Asiterati, Ṣama àti Jeieli àwọn ọmọ Hotami ará Aroeri,
Uzzia the Ashterathite, Shama and Jeiel, the sons of Hotham the Aroerite,
45 Jediaeli ọmọ Ṣimri, àti arákùnrin Joha ará Tisi
Jediael, the son of Shimri, and Joha his brother, the Tizite,
46 Elieli ará Mahafi Jeribai àti Joṣafia àwọn ọmọ Elnaamu, Itimah ará Moabu,
Eliel the Mahavite, and Jeribai and Joshaviah, the sons of Elnaam, and Ithmah the Moabite,
47 Elieli, Obedi àti Jaasieli ará Mesoba.
Eliel and Obed, and Jaasiel the Mezobaite.

< 1 Chronicles 11 >