< 1 Chronicles 10 >
1 Nísinsin yìí, àwọn ará Filistini dojú ìjà kọ Israẹli, àwọn ará Israẹli sì sálọ kúrò níwájú wọn, a sì pa ọ̀pọ̀ wọn sí orí òkè Gilboa.
And the Philistines have fought with Israel, and the men of Israel flee from the face of the Philistines, and fall wounded in Mount Gilboa,
2 Àwọn ará Filistini sí lépa Saulu gidigidi àti àwọn ọmọ rẹ̀. Wọ́n sì pa àwọn ọmọ rẹ̀. Jonatani, Abinadabu àti Malikiṣua.
and the Philistines pursue after Saul, and after his sons, and the Philistines strike Jonathan, and Abinadab, and Malchi-Shua, sons of Saul.
3 Ogun náà sí gbóná janjan fún Saulu, nígbà tí àwọn tafàtafà sì lé e bá, wọ́n sì ṣá a lọ́gbẹ́.
And the battle [is] heavy on Saul, and those shooting with the bow find him, and he is wounded by those shooting,
4 Saulu sì sọ fún ẹni tí ó gbé ìhámọ́ra rẹ̀ pé, “Fa idà rẹ yọ, kí o sì fi gún mi, kí àwọn aláìkọlà wọ̀nyí má wá láti bú mi.” Ṣùgbọ́n ẹni tí ó ń gbé ìhámọ́ra rẹ̀ ń bẹ̀rù, kò sì le ṣe é, bẹ́ẹ̀ ni Saulu mú idà tirẹ̀ ó sì ṣubú lé e.
and Saul says to the bearer of his weapons, “Draw your sword and pierce me with it, lest these uncircumcised come and have abused me.” And the bearer of his weapons has not been willing, for he fears exceedingly, and Saul takes the sword, and falls on it;
5 Nígbà tí agbé-ìhámọ́ra rí pé Saulu ti kú, òhun pẹ̀lú ṣubú lórí idà tirẹ̀, ó sì kú.
and the bearer of his weapons sees that Saul [is] dead, and falls, he also, on the sword, and dies;
6 Bẹ́ẹ̀ ni Saulu àti ọmọ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta kú, gbogbo ilé rẹ̀ sì kú ṣọ̀kan, lọ́jọ́ kan náà.
and Saul dies, and his three sons, and all his house—they died together.
7 Nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ rí wí pé àwọn ọmọ-ogun ti sálọ àti pé Saulu àti àwọn ọmọ rẹ̀ ti kú wọ́n kọ àwọn ìlú wọn sílẹ̀, wọ́n sì sálọ. Àwọn ará Filistini wá, wọ́n sì jókòó nínú wọn.
And all the men of Israel who [are] in the valley see that they have fled and that Saul and his sons have died, and they forsake their cities and flee, and the Philistines come and dwell in them.
8 Ní ọjọ́ kejì, nígbà tí àwọn ará Filistini wá láti kó òkú, wọ́n rí Saulu àti àwọn ọmọ rẹ̀ tí wọ́n ṣubú sórí òkè Gilboa.
And it comes to pass, on the next day, that the Philistines come to strip the wounded, and find Saul and his sons fallen in Mount Gilboa,
9 Wọ́n bọ́ ní aṣọ, wọ́n sì gbé orí rẹ̀ àti ìhámọ́ra rẹ̀, wọ́n sì rán ìránṣẹ́ lọ káàkiri ilẹ̀ àwọn ará Filistini láti kéde ìròyìn náà láàrín àwọn òrìṣà wọn àti àwọn ènìyàn wọn.
and strip him, and carry away his head and his weapons, and send [them] into the land of the surrounding Philistines to proclaim tidings [to] their idols and the people;
10 Wọ́n gbé ìhámọ́ra rẹ̀ sí inú ilé tí wọ́n kọ́ fún òrìṣà wọn, wọ́n sì fi orí rẹ̀ kọ́ sí inú ilé Dagoni.
and they put his weapons in the house of their gods, and have fixed his skull in the house of Dagon.
11 Nígbà tí gbogbo àwọn olùgbé Jabesi—Gileadi gbọ́ gbogbo ohun tí àwọn ará Filistini ṣe fún Saulu,
And all Jabesh-Gilead hears of all that the Philistines have done to Saul,
12 gbogbo àwọn akọni ọkùnrin wọn lọ láti mú àwọn ará Saulu àti àwọn ọmọ rẹ̀, wọ́n sì kó wọn wá sí Jabesi. Nígbà náà, wọ́n sin egungun wọn sábẹ́ igi óákù ní Jabesi, wọ́n sì gbààwẹ̀ fún ọjọ́ méje.
and all the men of valor rise and carry away the body of Saul, and the bodies of his sons, and bring them to Jabesh, and bury their bones under the oak in Jabesh, and fast seven days.
13 Saulu kú nítorí kò ṣe òtítọ́ sí Olúwa, kò pa ọ̀rọ̀ Olúwa mọ́ pẹ̀lú, ó tọ abókùúsọ̀rọ̀ lọ fún ìtọ́sọ́nà.
And Saul dies because of his trespass that he trespassed against YHWH, against the word of YHWH that he did not keep, and also for asking to inquire of a familiar spirit;
14 Kò sì béèrè lọ́wọ́ Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa pa á, Ó sì yí ìjọba náà padà sọ́dọ̀ Dafidi ọmọ Jese.
and he did not inquire of YHWH, and He puts him to death, and turns around the kingdom to David son of Jesse.