< 1 Yuhanna 5 >

1 İsa'nın Mesih olduğuna inanan herkes Tanrı'dan doğmuştur. Baba'yı seven O'ndan doğmuş olanı da sever.
Olúkúlùkù ẹni tí ó bá gbàgbọ́ pé Jesu ni Kristi, a bí i nípa ti Ọlọ́run: àti olúkúlùkù ẹni tí ó fẹ́ràn. Ẹni tí ó bi nì, ó fẹ́ràn ẹni tí a bí nípasẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú.
2 Tanrı'yı sevip buyruklarını yerine getirmekle, Tanrı'nın çocuklarını sevdiğimizi anlarız.
Nípa èyí ni àwa mọ̀ pé àwa fẹ́ràn àwọn ọmọ Ọlọ́run, nígbà tí a bá fẹ́ràn Ọlọ́run, tí a sì ń pa òfin rẹ̀ mọ́.
3 Tanrı'yı sevmek O'nun buyruklarını yerine getirmek demektir. O'nun buyrukları da ağır değildir.
Nítorí èyí ni ìfẹ́ Ọlọ́run, pé kí àwa pa òfin rẹ̀ mọ́: òfin rẹ̀ kò sì nira,
4 Çünkü Tanrı'dan doğmuş olan herkes dünyayı yener. Bize dünyaya karşı zafer kazandıran imanımızdır.
nítorí olúkúlùkù ẹni tí a bí nípa tí Ọlọ́run, ó ṣẹ́gun ayé. Èyí sì ni ìṣẹ́gun tí ó ṣẹ́gun ayé, àní ìgbàgbọ́ wa.
5 İsa'nın Tanrı Oğlu olduğuna iman edenden başka dünyayı yenen kim?
Ta ni ẹni tí ó ṣẹ́gun ayé, bí kò ṣe ẹni tí ó gbàgbọ́ pé Ọmọ Ọlọ́run ni Jesu jẹ́?
6 Suyla ve kanla gelen İsa Mesih'tir. O yalnız suyla değil, suyla ve kanla gelmiştir. Buna tanıklık eden Ruh'tur. Çünkü Ruh gerçektir.
Èyí ni ẹni tí ó wá nípa omi àti ẹ̀jẹ̀, Jesu Kristi, kì í ṣe nípa omi nìkan, bí kò ṣe nípa omi àti ẹ̀jẹ̀. Àti pé Ẹ̀mí ni ó sì ń jẹ́rìí, nítorí pé òtítọ́ ni Ẹ̀mí.
7 Şöyle ki, tanıklık edenler üçtür: Ruh, su ve kan. Bunların üçü de uyum içindedir.
Nítorí pé àwọn mẹ́ta ni ó ń jẹ́rìí.
8
Ẹ̀mí, omi, àti ẹ̀jẹ̀: àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sì wà ni ìṣọ̀kan.
9 İnsanların tanıklığını kabul ediyoruz, oysa Tanrı'nın tanıklığı daha üstündür. Çünkü bu, Tanrı'nın tanıklığıdır, kendi Oğlu'yla ilgili olarak yaptığı tanıklıktır.
Bí àwa ba ń gba ẹ̀rí ènìyàn, ẹ̀rí Ọlọ́run tóbi jù: nítorí ẹ̀rí Ọlọ́run ni èyí pé, Ó tí jẹ́rìí ní ti Ọmọ rẹ̀.
10 Tanrı'nın Oğlu'na inanan, yüreğinde Tanrı'nın tanıklığına sahiptir. Tanrı'ya inanmayansa O'nu yalancı durumuna düşürmüş olur. Çünkü Tanrı'nın Oğlu'yla ilgili tanıklığına inanmamıştır.
Ẹni tí ó bá gba Ọmọ Ọlọ́run gbọ́, ó ni ẹ̀rí nínú ara rẹ̀; ẹni tí kò bá gba Ọlọ́run gbọ́, ó ti mú un ni èké; nítorí kò gba ẹ̀rí náà gbọ́ tí Ọlọ́run jẹ́ ní ti Ọmọ rẹ̀.
11 Tanıklık da şudur: Tanrı bize sonsuz yaşam verdi, bu yaşam O'nun Oğlu'ndadır. (aiōnios g166)
Ẹ̀rí náà sì ni èyí pé Ọlọ́run fún wa ní ìyè àìnípẹ̀kun, ìyè yìí sì ń bẹ nínú Ọmọ rẹ̀. (aiōnios g166)
12 Kendisinde Tanrı Oğlu bulunanda yaşam vardır, kendisinde Tanrı Oğlu bulunmayanda yaşam yoktur.
Ẹni tí ó bá ni Ọmọ, ó ni ìyè; ẹni tí kò bá sì ni Ọmọ Ọlọ́run, kò ní ìyè.
13 Tanrı Oğlu'nun adına iman eden sizlere, sonsuz yaşama sahip olduğunuzu bilesiniz diye bunları yazdım. (aiōnios g166)
Nǹkan wọ̀nyí ni mo kọ̀wé rẹ̀ sí yín, àní sí ẹ̀yin tí ó gba orúkọ Ọmọ Ọlọ́run gbọ́; kí ẹ̀yin lè mọ̀ pé ẹ̀yin ní ìyè àìnípẹ̀kun, àní fún ẹ̀yin tí ó gba orúkọ Ọmọ Ọlọ́run gbọ́. (aiōnios g166)
14 Tanrı'nın önünde güvenimiz şu ki, O'nun isteğine uygun ne dilersek bizi işitir.
Èyí sì ni ìgboyà tí àwa ní níwájú rẹ̀, pé bí àwa bá béèrè ohunkóhun gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀, ó ń gbọ́ tí wa.
15 Her ne dilersek bizi işittiğini bildiğimize göre, O'ndan dilediklerimizi aldığımızı da biliriz.
Bí àwa bá sì mọ̀ pé ó ń gbọ́ tí wa, ohunkóhun tí àwa bá béèrè, àwa mọ̀ pé àwa rí ìbéèrè tí àwa ti béèrè lọ́dọ̀ rẹ̀ gbà.
16 Kardeşinin ölümcül olmayan bir günah işlediğini gören, onun için dua etsin. Duasıyla kardeşine yaşam verecektir. Bu, ölümcül olmayan günah işleyenler için geçerlidir. Ölümcül günah da vardır, bunun için dua etsin demiyorum.
Bí ẹnikẹ́ni bá rí arákùnrin rẹ̀ tí ń dẹ́ṣẹ̀ tí kì í ṣe sí ikú, òun yóò béèrè, Ọlọ́run yóò sì fún un ni ìyè, àní, fún àwọn tí ń dẹ́ṣẹ̀ tí kì í ṣe sí ikú. Ẹ̀ṣẹ̀ kan ń bẹ sì ikú, èmi kò wí pé ki òun gbàdúrà fún èyí.
17 Her kötülük günahtır, ama ölümcül olmayan günah da vardır.
Gbogbo àìṣòdodo ni ẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀ṣẹ̀ kan ń bẹ tí kì í ṣe sí ikú.
18 Tanrı'dan doğmuş olanın günah işlemediğini biliriz. Tanrı'dan doğmuş olan İsa Mesih onu korur ve kötü olan ona dokunamaz.
Àwa mọ̀ pé ẹnikẹ́ni tí a bí nípa ti Ọlọ́run kì í dẹ́ṣẹ̀: ṣùgbọ́n ẹni tí a bí nípa tí Ọlọ́run a pa ara rẹ̀ mọ́, ẹni búburú kò ní lè fọwọ́ kàn án.
19 Biliyoruz ki, biz Tanrı'danız, bütün dünya ise kötü olanın denetimindedir.
Àwa mọ̀ pé tí Ọlọ́run ni wá, àti gbogbo ayé ni ó wà lábẹ́ agbára ẹni búburú náà.
20 Yine biliyoruz ki, Tanrı'nın Oğlu gelmiş ve gerçek Olan'ı tanımamız için bize anlama gücü vermiştir. Biz gerçek Olan'dayız, O'nun Oğlu İsa Mesih'teyiz. O gerçek Tanrı ve sonsuz yaşamdır. (aiōnios g166)
Àwa sì mọ̀ pé Ọmọ Ọlọ́run dé, ó sì tí fi òye fún wa, kí àwa lè mọ ẹni tí í ṣe òtítọ́, àwa sì ń bẹ nínú ẹni tí í ṣe òtítọ́, àní, nínú Ọmọ rẹ̀, Jesu Kristi. Èyí ni Ọlọ́run òtítọ́, àti ìyè àìnípẹ̀kun. (aiōnios g166)
21 Yavrularım, kendinizi putlardan koruyun.
Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ pa ara yín mọ́ kúrò nínú òrìṣà.

< 1 Yuhanna 5 >