< 3 Mosebok 26 >
1 I skolen icke göra eder några av gudar, ej heller uppresa åt eder något beläte eller någon stod, eller uppsätta i edert land stenar med inhuggna bilder, för att tillbedja vid dem; ty jag är HERREN, eder Gud.
“‘Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ mọ ère òrìṣà, tàbí kí ẹ̀yin gbe ère kalẹ̀ tàbí kí ẹ̀yin gbẹ́ ère òkúta: kí ẹ̀yin má sì gbẹ́ òkúta tí ẹ̀yin yóò gbé kalẹ̀ láti sìn. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.
2 Mina sabbater skolen I hålla, och för min helgedom skolen I hava fruktan. Jag är HERREN.
“‘Ẹ pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́ kí ẹ̀yin sì bọ̀wọ̀ fún ibi mímọ́ mi. Èmi ni Olúwa.
3 Om I vandren efter mina stadgar och hållen mina bud och gören efter dem,
“‘Bí ẹ̀yin bá tẹ̀lé àṣẹ mi, tí ẹ̀yin sì ṣọ́ra láti pa òfin mi mọ́.
4 så skall jag giva eder regn i rätt tid, så att jorden giver sin gröda och träden på marken bära sin frukt.
Èmi yóò rọ̀jò fún yín ní àkókò rẹ̀, kí ilẹ̀ yín le mú èso rẹ̀ jáde bí ó tí yẹ kí àwọn igi eléso yín so èso.
5 Och trösktiden skall hos eder räcka intill vinbärgningen, och vinbärgningen skall räcka intill såningstiden, och I skolen hava bröd nog att äta och skolen bo trygga i edert land.
Èrè oko yín yóò pọ̀ dé bi pé ẹ ó máa pa ọkà títí di àsìkò ìkórè igi eléso, ẹ̀yin yóò sì máa gbé ní ilẹ̀ yín láìléwu.
6 Och jag skall skaffa frid i landet, och I skolen få ro, och ingen skall förskräcka eder. Jag skall göra slut på vilddjuren i landet, och intet svärd skall gå fram genom edert land.
“‘Èmi yóò fún yín ní àlàáfíà ní ilẹ̀ yín, ẹ̀yin yóò sì sùn láìsí ìbẹ̀rù ẹnikẹ́ni. Èmi yóò mú kí gbogbo ẹranko búburú kúrò ní ilẹ̀ náà, bẹ́ẹ̀ ni idà kì yóò la ilẹ̀ yín já.
7 I skolen jaga edra fiender framför eder, och de skola falla för edra svärd.
Ẹ̀yin yóò lé àwọn ọ̀tá yín, wọn yóò sì tipa idà kú.
8 Fem av eder skola jaga hundra framför sig, och hundra av eder skola jaga tiotusen, och edra fiender skola falla för edra svärd.
Àwọn márùn-ún péré nínú yín yóò máa ṣẹ́gun ọgọ́rùn-ún ènìyàn, àwọn ọgọ́rùn-ún yóò sì máa ṣẹ́gun ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá, àwọn ọ̀tá yín yóò tipa idà kú níwájú yín.
9 Och jag skall vända mig till eder och göra eder fruktsamma och för öka eder, och jag skall upprätthålla mitt förbund med eder.
“‘Èmi yóò fi ojúrere wò yín, Èmi yóò mú kí ẹ bí sí i, Èmi yóò jẹ́ kí ẹ pọ̀ sí i, Èmi yóò sì pa májẹ̀mú mi mọ́ pẹ̀lú yín.
10 Och gammal gröda, som länge har legat inne, skolen I hava att äta; I skolen nödgas skaffa den gamla undan för den nya.
Àwọn èrè oko yín yóò pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin ó máa jẹ èrè ọdún tí ó kọjá, ẹ̀yin ó sì kó wọn jáde, kí ẹ̀yin lè rí ààyè kó tuntun sí.
11 Och jag skall uppresa min boning mitt ibland eder, och min själ skall icke försmå eder.
Èmi yóò kọ́ àgọ́ mímọ́ mi sí àárín yín. Èmi kò sì ní kórìíra yín.
12 Jag skall vandra mitt ibland eder och vara eder Gud, och I skolen vara mitt folk.
Èmi yóò wà pẹ̀lú yín, Èmi yóò máa jẹ́ Ọlọ́run yín, ẹ̀yin yóò sì máa jẹ́ ènìyàn mi.
13 Jag är HERREN, eder Gud, som förde eder ut ur Egyptens land, för att I icke skullen vara trälar där; och jag har brutit sönder edert ok och låtit eder gå med upprätt huvud.
Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín tí ó mú yín jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, kí ẹ̀yin má ba à jẹ́ ẹrú fún wọn mọ́. Mo sì já ìdè àjàgà yín, mo sì mú kí ẹ̀yin máa rìn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a gbé lórí sókè.
14 Men om I icke hören mig och icke gören efter alla dessa bud,
“‘Bí ẹ̀yin kò bá fetí sí mi tí ẹ̀yin kò sì ṣe gbogbo òfin wọ̀nyí.
15 om I förkasten mina stadgar, och om edra själar försmå mina rätter, så att I icke gören efter alla mina bud, utan bryten mitt förbund,
Bí ẹ̀yin bá kọ àṣẹ mi tí ẹ̀yin sì kórìíra òfin mi, tí ẹ̀yin sì kùnà láti pa ìlànà mi mọ́, nípa èyí tí ẹ̀yin ti ṣẹ̀ sí májẹ̀mú mi.
16 då skall ock jag handla på samma sätt mot eder: jag skall hemsöka eder med förskräckliga olyckor, med tärande sjukdom och feber, så att edra ögon försmäkta och eder själ förtvinar; och I skolen förgäves så eder säd, ty edra fiender skola äta den.
Èmi yóò ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí sí yín, Èmi yóò mú ìpayà òjijì bá yín: àwọn ààrùn afiniṣòfò, àti ibà afọ́nilójú, tí í pa ni díẹ̀díẹ̀. Ẹ̀yin yóò gbin èso ilẹ̀ yín lásán, nítorí pé àwọn ọ̀tá yín ni yóò jẹ gbogbo ohun tí ẹ̀yin ti gbìn.
17 Jag skall vända mitt ansikte mot eder, och I skolen bliva slagna av edra fiender; och de som hata eder skola råda över eder, och I skolen fly, om ock ingen förföljer eder.
Èmi yóò dojúkọ yín títí tí ẹ̀yin ó fi di ẹni ìkọlù; àwọn tí ó kórìíra yín ni yóò sì ṣe àkóso lórí yín. Ìbẹ̀rù yóò mú yín dé bi pé ẹ̀yin yóò máa sá káàkiri nígbà tí ẹnikẹ́ni kò lé yín.
18 Om I, detta oaktat, icke hören mig, så skall jag tukta eder sjufalt värre för edra synders skull.
“‘Bí ẹ̀yin kò bá wá gbọ́ tèmi lẹ́yìn gbogbo èyí, Èmi yóò fi kún ìyà yín ní ìlọ́po méje nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín.
19 Jag skall krossa eder stolta makt. Jag skall låta eder himmel bliva såsom järn och eder jord såsom koppar.
Èmi yóò fọ́ agbára ìgbéraga yín, ojú ọ̀run yóò le koko bí irin, ilẹ̀ yóò sì le bí idẹ (òjò kò ní rọ̀: ilẹ̀ yín yóò sì le).
20 Och eder möda skall vara förspilld, ty eder jord skall icke giva sin gröda, och träden i landet skola icke bära sin frukt.
Ẹ ó máa lo agbára yín lásán torí pé ilẹ̀ yín kì yóò so èso, bẹ́ẹ̀ ni àwọn igi yín kì yóò so èso pẹ̀lú.
21 Om I ändå vandren mig emot och icke viljen höra mig, så skall jag slå eder sjufalt värre, såsom edra synder förtjäna.
“‘Bí ẹ bá tẹ̀síwájú láì gbọ́ tèmi, Èmi yóò tún fa ìjayà yín le ní ìgbà méje gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ yín.
22 Jag skall sända över eder vilddjur, som skola döda edra barn och fördärva eder boskap och minska edert eget antal, så att edra vägar bliva öde.
Èmi yóò rán àwọn ẹranko búburú sí àárín yín, wọn yóò sì pa àwọn ọmọ yín, wọn yóò run agbo ẹran yín, díẹ̀ nínú yín ni wọn yóò ṣẹ́kù kí àwọn ọ̀nà yín lè di ahoro.
23 Om I, detta oaktat, icke låten varna eder av mig, utan vandren mig emot,
“‘Bí ẹ kò bá tún yípadà lẹ́yìn gbogbo ìjìyà wọ̀nyí, tí ẹ sì tẹ̀síwájú láti lòdì sí mi.
24 så skall också jag vandra eder emot och slå eder sjufalt för edra synders skull.
Èmi náà yóò lòdì sí yín. Èmi yóò tún fa ìjìyà yín le ní ìlọ́po méje ju ti ìṣáájú.
25 Jag skall låta eder drabbas av ett hämndesvärd, som skall hämnas mitt förbund, och I skolen nödgas församla eder i städerna; men där skall jag sända pest bland eder, och I skolen bliva givna i fiendehand.
Èmi yóò mú idà wá bá yín nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín láti fi gbẹ̀san májẹ̀mú mi tí ẹ kò pamọ́. Bí ẹ ba sálọ sí ìlú yín fún ààbò, Èmi yóò rán àjàkálẹ̀-ààrùn sí àárín yín, àwọn ọ̀tá yín, yóò sì ṣẹ́gun yín.
26 Jag skall så fördärva edert livsuppehälle, att edert bröd skall kunna bakas i en enda ugn av tio kvinnor, och edert bröd skall lämnas ut efter vikt, och när I äten, skolen I icke bliva mätta.
Èmi yóò dá ìpèsè oúnjẹ yín dúró, dé bi pé: inú ààrò kan ni obìnrin mẹ́wàá yóò ti máa se oúnjẹ yín. Òsùwọ̀n ni wọn yóò fi máa yọ oúnjẹ yín, ẹ ó jẹ ṣùgbọ́n, ẹ kò ní yó.
27 Om I, detta oaktat, icke hören mig, utan vandren mig emot,
“‘Lẹ́yìn gbogbo èyí, bí ẹ kò bá gbọ́ tèmi, tí ẹ sì lòdì sí mi,
28 så skall också jag i vrede vandra eder emot och tukta eder sjufalt för edra synders skull.
ní ìbínú mi, èmi yóò korò sí yín, èmi tìkára mi yóò fìyà jẹ yín ní ìgbà méje nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín.
29 I skolen nödgas äta edra söners kött och äta edra döttrars kött.
Ebi náà yóò pa yín dé bi pé ẹ ó máa jẹ ẹran-ara àwọn ọmọ yín ọkùnrin, àti àwọn ọmọ yín obìnrin.
30 Jag skall ödelägga edra offerhöjder och utrota edra solstoder; jag skall kasta edra döda kroppar på edra eländiga avgudars döda kroppar, ty min själ skall försmå eder.
Èmi yóò wó àwọn pẹpẹ òrìṣà yín, lórí òkè níbi tí ẹ ti ń sìn, Èmi yóò sì kó òkú yín jọ, sórí àwọn òkú òrìṣà yín. Èmi ó sì kórìíra yín.
31 Och jag skall göra edra städer till ruiner och föröda edra helgedomar, och jag skall icke mer med välbehag känna lukten av edra offer.
Èmi yóò sọ àwọn ìlú yín di ahoro, èmi yóò sì ba àwọn ilé mímọ́ yín jẹ́. Èmi kì yóò sì gbọ́ òórùn dídùn yín mọ́.
32 Jag skall själv ödelägga landet, så att edra fiender, som bo däri, skola häpna däröver.
Èmi yóò pa ilẹ̀ yín run dé bi pé ẹnu yóò ya àwọn ọ̀tá yín tí ó bá gbé ilẹ̀ náà.
33 Men eder skall jag förströ bland hedningarna, och jag skall förfölja eder med draget svärd; så skall edert land bliva en ödemark, och edra städer skola bliva ruiner.
Èmi yóò sì tú yín ká sínú àwọn orílẹ̀-èdè, Èmi yóò sì yọ idà tì yín lẹ́yìn, ilẹ̀ yín yóò sì di ahoro, àwọn ìlú yín ni a ó sì parun.
34 Då skall landet få gottgörelse för sina sabbater, då, under hela den tid det ligger öde och I ären i edra fienders land. Ja, då skall landet hålla sabbat och giva gottgörelse för sina sabbater.
Ilẹ̀ náà yóò ní ìsinmi fún gbogbo ìgbà tí ẹ fi wà ní ilẹ̀ àjèjì tí ẹ kò fi lò ó. Ilẹ̀ náà yóò sinmi láti fi dípò ọdún tí ẹ kọ̀ láti fún un.
35 Hela den tid det ligger öde skall det hålla sabbat och få den vila det icke fick på edra sabbater, då I bodden däri.
Níwọ́n ìgbà tí ẹ kò lò ó, ilẹ̀ náà yóò ní ìsinmi tí kò ní lákòókò ìsinmi rẹ̀ lákokò tí ẹ fi ń gbé orí rẹ̀.
36 Och åt dem som bliva kvar av eder skall jag giva försagda hjärtan i deras fienders länder, så att de jagas på flykten av ett prasslande löv som röres av vinden, och fly, såsom flydde de för svärd, och falla, om ock ingen förföljer dem.
“‘Èmi yóò jẹ́ kí ó burú fún àwọn tí ó wà ní ilẹ̀ ìgbèkùn dé bi pé ìró ewé tí ń mì lásán yóò máa lé wọn sá. Ẹ ó máa sá bí ẹni tí ń sá fún idà. Ẹ ó sì ṣubú láìsí ọ̀tá láyìíká yín.
37 Och de skola stupa på varandra, likasom för svärd, om ock ingen förföljer dem. Ja, I skolen icke kunna hålla stånd mot edra fiender.
Wọn yóò máa ṣubú lu ara wọn, bí ẹni tí ń sá fún idà nígbà tí kò sí ẹni tí ń lé yín. Ẹ̀yin kì yóò sì ní agbára láti dúró níwájú ọ̀tá yín.
38 I skolen förgås bland hedningarna, och edra fienders land skall förtära eder.
Ẹ̀yin yóò ṣègbé láàrín àwọn orílẹ̀-èdè abọ̀rìṣà. Ilẹ̀ ọ̀tá yín yóò sì jẹ yín run.
39 Och de som bliva kvar av eder skola försmäkta i edra fienders land, genom sin egen missgärning, och försmäkta tillika genom sina fäders missgärning, likasom dessa hava gjort.
Àwọn tí ó ṣẹ́kù nínú yín ni yóò ṣòfò dànù ní ilẹ̀ ọ̀tá yín torí ẹ̀ṣẹ̀ yín àti ti àwọn baba ńlá yín.
40 Och de skola nödgas bekänna den missgärning de själva hava begått, och den deras fäder hava begått, genom att handla trolöst mot mig, och huru de hava vandrat mig emot
“‘Bí wọ́n bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn àti ti baba ńlá wọn, ìwà ìṣọ̀tẹ̀ wọn àti bí wọ́n ti ṣe lòdì sí mi.
41 -- varför också jag måste vandra dem emot och föra dem bort i deras fienders land -- ja, då skola deras oomskurna hjärtan nödgas ödmjuka sig, då skola de få umgälla sin missgärning.
Èyí tó mú mi lòdì sí wọn tí mo fi kó wọn lọ sí ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn. Nígbà tí wọ́n bá rẹ àìkọlà àyà wọn sílẹ̀ tí wọ́n bá sì gba ìbáwí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
42 Och då skall jag tänka på mitt förbund med Jakob, då skall jag ock tänka på mitt förbund med Isak och på mitt förbund med Abraham, och på landet skall jag tänka.
Nígbà náà ni Èmi yóò rántí májẹ̀mú mi pẹ̀lú Jakọbu àti pẹ̀lú Isaaki àti pẹ̀lú Abrahamu, Èmi yóò sì rántí ilẹ̀ náà.
43 Ty landet måste bliva övergivet av dem och så få gottgörelse för sina sabbater genom att bliva öde när folket är borta, och själva skola de få umgälla sin missgärning, därför, ja, därför att de förkastade mina rätter, och därför att deras själar försmådde mina stadgar.
Àwọn ènìyàn náà yóò sì fi ilẹ̀ náà sílẹ̀, yóò sì ní ìsinmi rẹ̀ nígbà tí ó bá wà lófo láìsí wọn níbẹ̀. Wọn yóò sì jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn torí pé wọ́n kọ àwọn òfin mi. Wọ́n sì kórìíra àwọn àṣẹ mi.
44 Men detta oaktat skall jag, medan de äro i sina fienders land, icke så förkasta eller försmå dem, att jag förgör dem och bryter mitt förbund med dem; ty jag är HERREN, deras Gud.
Pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, nígbà tí wọ́n bá wà nílé àwọn ọ̀tá wọn, èmi kì yóò ta wọ́n nù, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò kórìíra wọn pátápátá, èyí tí ó lè mú mi dá májẹ̀mú mi pẹ̀lú wọn. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn.
45 Nej, till fromma för dem skall jag tänka på förbundet med förfäderna, som jag förde ut ur Egyptens land, inför hedningarnas ögon, på det att jag skulle vara deras Gud. Jag är HERREN.
Nítorí wọn, èmi ó rántí májẹ̀mú mi tí mo ti ṣe pẹ̀lú baba ńlá wọn. Àwọn tí mo mú jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti lójú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè láti jẹ́ Ọlọ́run wọn. Èmi ni Olúwa.’”
46 Dessa äro de stadgar och rätter och lagar som HERREN fastställde mellan sig och Israels barn, på Sinai berg genom Mose.
Ìwọ̀nyí ni òfin àti ìlànà tí Olúwa fún Mose ní orí òkè Sinai láàrín òun àti àwọn ọmọ Israẹli.