< Job 42 >

1 Y respondió Job en respuesta al Señor:
Nígbà náà ní Jobu dá Olúwa lóhùn, ó sì wí pé,
2 Veo que eres capaz de hacer todo, y no hay pensamiento que se esconda de ti.
“Èmi mọ̀ pé, ìwọ lè e ṣe ohun gbogbo, àti pé, kò si ìrò inú tí a lè fa sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ.
3 ¿Quién es este que oculta el consejo de Dios con palabras sin conocimiento? Porque he estado hablando sin saber acerca de las maravillas que yo no sabía.
Ìwọ béèrè, ta ni ẹni tí ń fi ìgbìmọ̀ pamọ́ láìní ìmọ̀? Nítorí náà ní èmi ṣe ń sọ èyí tí èmi kò mọ̀, ohun tí ó ṣe ìyanu jọjọ níwájú mi, ti èmi kò mòye.
4 Escúchame, y diré lo que tengo en mente; Te haré preguntas y tú me darás las respuestas.
“Ìwọ wí pé, ‘Gbọ́ tèmi báyìí, èmi ó sì sọ; èmi ó béèrè lọ́wọ́ rẹ, ìwọ yóò sì dá mi lóhùn.’
5 Te conocía sólo de oídas, pero ahora mi ojo te ha visto.
Etí mi sì ti gbọ́ nípa rẹ, ṣùgbọ́n nísinsin yìí ojú mi ti rí ọ.
6 Por esta razón, doy testimonio de que lo que dije es falso, y con dolor me siento en el polvo.
Ǹjẹ́ nítorí náà èmi kórìíra ara mi, mo sì ronúpìwàdà nínú ekuru àti eérú.”
7 Y después de haberle dicho estas palabras a Job, el Señor le dijo a Elifaz el Temanita: Estoy muy enojado contigo y con tus dos amigos, porque no has dicho lo que es correcto acerca de mí, como lo dijo mi siervo Job.
Bẹ́ẹ̀ ó sì rí, lẹ́yìn ìgbà tí Olúwa ti sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún Jobu, Olúwa sì wí fún Elifasi, ará Temani pé, mo bínú sí ọ, àti sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ méjèèjì, nítorí pé ẹ̀yin kò sọ̀rọ̀, ní ti èmi, ohun tí ó tọ́, bí Jobu ìránṣẹ́ mi ti sọ.
8 Y ahora, toma siete bueyes y siete ovejas, y ve a mi siervo Job, y haz una ofrenda quemada por ti mismo, y mi siervo Job hará oración por ti, para que no pueda enviarte castigo; porque no han dicho lo que es correcto acerca de mí, como lo ha hecho mi sirviente Job.
Nítorí náà, ẹ mú akọ ẹgbọrọ màlúù méje, àti àgbò méje, kí ẹ sì tọ̀ Jobu ìránṣẹ́ mi lọ, kí ẹ sì fi rú ẹbọ sísun fún ara yín; Jobu ìránṣẹ́ mi yóò sì gbàdúrà fún yin; nítorí pé àdúrà rẹ̀ ní èmi yóò gbà; kí èmi kí ó má ba ṣe si yín bí ìṣìnà yín, ní ti pé ẹ̀yin kò sọ̀rọ̀ ohun tí ó tọ́ sí mi bi Jobu ìránṣẹ́ mi ti ṣe.
9 Y Elifaz el Temanita, y Bildad el Suhita, y Zofar el Naamatita, fueron e hicieron lo que el Señor había dicho. Y el SEÑOR dio oído a Job.
Bẹ́ẹ̀ ní Elifasi, ara Temani, àti Bilidadi, ará Ṣuhi, àti Sofari, ará Naama lọ, wọ́n sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún wọn. Olúwa sì gbọ́ àdúrà Jobu.
10 Y el Señor recompensó a Job por todas sus pérdidas, después de haber orado por sus amigos: y todo lo que Job tenía antes fue aumentado por el Señor el doble.
Olúwa sì yí ìgbèkùn Jobu padà, nígbà tí ó gbàdúrà fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀; Olúwa sì bùsi ohun gbogbo ti Jobu ní rí ní ìṣẹ́po méjì ohun tí ó ní tẹ́lẹ̀ rí.
11 Y todos sus hermanos y hermanas, y sus antiguos amigos, vinieron y comieron con él en su casa; y aclararon su dolor por él, y le dieron consuelo por todo el mal que el Señor le había enviado; y todos le dieron un poco de dinero y un anillo de oro.
Nígbà náà ní gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀, àti gbogbo àwọn arábìnrin rẹ̀, àti gbogbo àwọn tí ó ti ṣe ojúlùmọ̀ rẹ̀ rí; wọ́n bá a jẹun nínú ilé rẹ̀. Wọ́n sì ṣe ìdárò rẹ̀, wọ́n sì ṣìpẹ̀ fún un nítorí ibi gbogbo tí Olúwa ti mú bá a. Olúkúlùkù ènìyàn pẹ̀lú sì fún un ní ẹyọ owó kọ̀ọ̀kan àti olúkúlùkù ni òrùka wúrà etí kọ̀ọ̀kan.
12 Y la bendición del Señor fue mayor en el final de la vida de Job que en su inicio; y así llegó a tener catorce mil ovejas y cabras, seis mil camellos, dos mil bueyes y mil asnas.
Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa bùkún ìgbẹ̀yìn Jobu ju ìṣáájú rẹ̀ lọ; ẹgbàá méje àgùntàn, ẹgbẹ̀rún mẹ́fà ìbákasẹ, àti ẹgbẹ̀rún àjàgà ọ̀dá màlúù, àti ẹgbẹ̀rún abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.
13 Y tuvo catorce hijos y tres hijas.
Ó sì ní ọmọkùnrin méje àti ọmọbìnrin mẹ́ta.
14 Y le dio a la primera el nombre de Jemima, la segunda Cesia y la tercero Kerenhapuc;
Ó sì sọ orúkọ àkọ́bí ní Jemima, àti orúkọ èkejì ni Kesia àti orúkọ ẹ̀kẹta ní Kereni-Happuki.
15 Y no había mujeres tan hermosas como las hijas de Job en toda la tierra: y su padre les dio una herencia entre sus hermanos.
Àti ní gbogbo ilẹ̀ náà, a kò rí obìnrin tí ó ní ẹwà bí ọmọ Jobu; baba wọ́n sì pínlẹ̀ fún wọn nínú àwọn arákùnrin wọn.
16 Y después de esto, Job tuvo ciento cuarenta años de vida, y vio a sus hijos, y los hijos de sus hijos, incluso cuatro generaciones.
Lẹ́yìn èyí Jobu wà ní ayé ní ogóje ọdún, ó sì rí àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin àti ọmọ ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, àní ìran mẹ́rin.
17 Y Job llegó a su fin, viejo y lleno de días.
Bẹ́ẹ̀ ni Jobu kú, ó gbó, ó sì kún fún ọjọ́ púpọ̀.

< Job 42 >