< Números 30 >

1 Moisés habló a los jefes de las tribus de los hijos de Israel: Esta es la Palabra que Yavé ordenó:
Mose sì sọ fún olórí àwọn ẹ̀yà ọmọ Israẹli pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa pàṣẹ,
2 Cuando un hombre haga voto a Yavé, o jure para imponerse una promesa, no quebrantará su palabra. Todo lo que salga de su boca lo cumplirá.
nígbà tí ọkùnrin kan bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ sí Olúwa tàbí búra láti fi de ara rẹ̀ ní ìdè kí òun má bà ba ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ kí ó ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sọ.
3 También, si una mujer hace un voto a Yavé, y se impone una obligación en su juventud mientras está en casa de su padre,
“Nígbà tí ọmọbìnrin kan bá sì wà ní ilé baba rẹ̀ tó bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa tàbí búra láti fi de ara rẹ̀
4 y su padre escucha su voto y la obligación que se impuso, y su padre nada le dice, entonces todos los votos de ella y toda promesa que se impuso serán firmes.
tí baba rẹ̀ bá sì gbọ́ ẹ̀jẹ́ rẹ̀ tàbí ìdè rẹ̀ tí kò sì sọ nǹkan kan sí i, kí gbogbo ẹ̀jẹ́ rẹ̀ kí ó dúró àti gbogbo ìdè tí ó fi de ara rẹ̀ yóò sì dúró.
5 Pero si su padre se lo prohíbe el día cuando se entera, ninguno de sus votos o promesas que se impuso será firme. Yavé la perdonará por cuanto su padre se opuso.
Ṣùgbọ́n tí baba rẹ̀ bá kọ̀ fun un ní ọjọ́ tí ó gbọ́, kò sí ọ̀kan nínú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ tàbí nínú ìdè tí ó fi de ara rẹ̀ tí yóò dúró; Olúwa yóò sì tú u sílẹ̀ nítorí baba rẹ̀ kọ̀ fún un.
6 Pero si es casada y hace votos, o pronuncia con sus labios cosa con la cual obligue su alma,
“Tí ó bá sì ní ọkọ lẹ́yìn ìgbà tí ó jẹ́ ẹ̀jẹ́ tàbí lẹ́yìn ìgbà tí ó sọ ọ̀rọ̀ kan láti ẹnu rẹ̀ jáde nínú èyí tí ó fi de ara rẹ̀ ní ìdè,
7 y su esposo oye, y cuando oye se calla, los votos de ella y la obligación que se impuso serán firmes.
tí ọkọ rẹ̀ sì gbọ́ nípa èyí ṣùgbọ́n tí kò sọ nǹkan kan, nígbà náà ni ẹ̀jẹ́ tàbí ìdè tí ó fi de ara rẹ̀ tó dúró.
8 Pero si el día cuando su esposo la oye, se lo prohíbe, entonces anulará el voto bajo el cual ella está y la declaración imprudente de sus labios con la cual se comprometió, y Yavé la perdonará.
Ṣùgbọ́n tí ọkọ rẹ̀ bá kọ̀ nígbà tí ó gbọ́, ǹjẹ́ òun yóò mú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ tí ó jẹ́ àti ohun tí ó ti ti ẹnu rẹ̀ jáde, èyí tí ó fi de ara rẹ̀ dasán, Olúwa yóò sì dáríjì í.
9 Pero el voto de una viuda o una repudiada, todo aquello con lo cual se comprometió, será firme para ella.
“Ṣùgbọ́n ẹ̀jẹ́ kí ẹ̀jẹ́ tàbí ìdè kí ìdè tí opó tàbí obìnrin tí a kọ̀sílẹ̀ bá ṣe yóò wà lórí rẹ̀.
10 Sin embargo, si hizo voto cuando estaba en casa de su esposo, y ligó su alma con obligación de juramento,
“Bí obìnrin tí ó ń gbé pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ tàbí de ara rẹ̀ ní ìdè lábẹ́ ìbúra,
11 y su esposo oyó, y calló ante ello, y no se lo prohibió, entonces todos sus votos y toda obligación con la cual ligó su alma serán firmes.
tí ọkọ rẹ̀ bá sì gbọ́, ṣùgbọ́n tí kò sọ̀rọ̀, tí kò sì kọ̀, nígbà náà ni ẹ̀jẹ́ rẹ̀ yóò dúró.
12 Pero si su esposo en verdad los anula el día cuando los oye, todo lo que salió de sus labios en cuanto a sus votos, o en cuanto a obligarse a ella misma, será nulo. Su esposo los anuló, y Yavé la perdonará.
Ṣùgbọ́n tí ọkọ rẹ̀ bá sọ wọ́n dasán, nígbà tí ó gbọ́, nígbà náà kò sí ẹ̀jẹ́ tàbí ìdè tí ó ti ẹnu rẹ̀ jáde tí yóò dúró, ọkọ rẹ̀ ti sọ wọ́n dasán, Olúwa yóò tú u sílẹ̀.
13 Todo voto y todo juramento que la obligue a humillarse a ella misma, su esposo lo confirmará o anulará.
Ọkọ rẹ̀ lè ṣe ìwádìí tàbí sọ ọ́ dasán ẹ̀jẹ́ tàbí ìbúra ìdè tí ó ti ṣe láti fi de ara rẹ̀.
14 Pero si su esposo calla ante ello de día en día, entonces confirmó todos sus votos y todas las obligaciones que están sobre ella. Las confirma por cuanto calló ante ello el día cuando lo oyó.
Ṣùgbọ́n tí ọkọ rẹ̀ kò bá sọ nǹkan kan sí í nípa rẹ̀ ní ọjọ́ dé ọjọ́, nígbà náà ni ó ṣe ìwádìí nípa ẹ̀jẹ́ àti ìbúra ìdè tí ó dè é. Kí ọkùnrin náà ṣe ìwádìí lórí rẹ̀ láìsọ nípa rẹ̀ si nígbà tí ó gbọ́ nípa rẹ̀.
15 Si los anula después de oírlos, entonces él llevará la iniquidad de ella.
Bí ó ti wù kí ó rí, bí ọkùnrin náà bá sọ ọ́ dasán, ní àkókò kan lẹ́yìn tí ó ti gbọ́ wọn, nígbà náà ó jẹ̀bi ọ̀rọ̀ náà.”
16 Estos son los Estatutos que Yavé ordenó a Moisés sobre las relaciones entre el esposo y su esposa, y entre el padre y su hija durante la juventud de ésta en casa de su padre.
Èyí ni ìlànà tí Olúwa fún Mose nípa ìbátan láàrín ọkùnrin àti obìnrin àti láàrín baba àti ọ̀dọ́mọbìnrin rẹ̀ tí ó sì ń gbé ní ilé rẹ̀.

< Números 30 >