< 1 Samuel 12 >

1 Samuel dijo a todo Israel: “He aquí que he escuchado vuestra voz en todo lo que me habéis dicho, y he puesto un rey sobre vosotros.
Samuẹli sì wí fún gbogbo Israẹli pé, “Èmi tí gbọ́ gbogbo ohun tí ẹ sọ fún mi, èmi sì ti yan ọba fún un yín.
2 Ahora, he aquí que el rey camina delante de ustedes. Yo soy viejo y canoso. He aquí que mis hijos están contigo. He caminado delante de ti desde mi juventud hasta hoy.
Nísinsin yìí ẹ ti ní ọba bí olórí yín. Bí ó ṣe tèmi, èmi ti di arúgbó, mo sì ti hewú, àwọn ọmọ mi sì ń bẹ níhìn-ín yìí pẹ̀lú yín. Èmi ti ń ṣe olórí yín láti ìgbà èwe mi wá títí di òní yìí.
3 Aquí estoy. Atestigüen contra mí ante el Señor y ante su ungido. ¿De quién es el buey que he tomado? ¿De quién he tomado el asno? ¿A quién he defraudado? ¿A quién he oprimido? ¿De quién he tomado un soborno para que me ciegue los ojos? Te lo devolveré”.
Èmi dúró níhìn-ín yìí, ẹ jẹ́rìí sí mi níwájú Olúwa àti níwájú ẹni àmì òróró rẹ̀. Màlúù ta ni mo gbà rí? Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ta ni mo gbà rí? Ta ni mo rẹ́ jẹ rí? Ọwọ́ ta ni mo ti gba owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ kan rí láti fi bo ara mi lójú? Bí mo bá ti ṣe nǹkan kan nínú ohun wọ̀nyí, èmi yóò sì san án padà fún yín.”
4 Dijeron: “No nos has defraudado, ni nos has oprimido, ni has tomado nada de la mano de nadie”.
Wọ́n sì dáhùn wí pé, “Ìwọ kò rẹ́ wa jẹ tàbí pọ́n wa lójú rí, ìwọ kò sì gba ohunkóhun lọ́wọ́ ẹnìkankan.”
5 Les dijo: “Yahvé es testigo contra vosotros, y su ungido es testigo hoy, de que no habéis encontrado nada en mi mano.” Dijeron: “Él es testigo”.
Samuẹli sì wí fún wọn pé, “Olúwa ni ẹlẹ́rìí sí i yín, àti ẹni àmì òróró rẹ̀ ni ẹlẹ́rìí lónìí pé, ẹ̀yin kò rí ohunkóhun lọ́wọ́ mi.” Wọ́n sì sọ wí pé, “Òun ni ẹlẹ́rìí.”
6 Samuel dijo al pueblo: “Es Yahvé quien designó a Moisés y a Aarón, y quien sacó a vuestros padres de la tierra de Egipto.
Nígbà náà ni Samuẹli wí fún àwọn ènìyàn náà pé, “Olúwa ni ó yan Mose àti Aaroni àti ti ó mú àwọn baba ńlá yín gòkè wá láti Ejibiti.
7 Ahora, pues, quédense quietos, para que yo pueda alegar ante Yahvé todos los actos justos de Yahvé, que hizo con ustedes y con sus padres.
Nísinsin yìí, ẹ dúró níbi, nítorí èmi ń lọ láti bá a yín sọ̀rọ̀ níwájú Olúwa ní ti gbogbo ìṣe òdodo rẹ̀ tí ó ti ṣe fún un yín àti fún àwọn baba yín.
8 “Cuando Jacob entró en Egipto, y vuestros padres clamaron a Yahvé, entonces Yahvé envió a Moisés y a Aarón, quienes sacaron a vuestros padres de Egipto y los hicieron habitar en este lugar.
“Lẹ́yìn ìgbà tí Jakọbu wọ Ejibiti, wọ́n ké pe Olúwa fún ìrànlọ́wọ́, Olúwa sì rán Mose àti Aaroni, tí wọ́n mú àwọn baba ńlá yín jáde láti Ejibiti láti mú wọn jókòó níbí yìí.
9 Pero ellos se olvidaron de Yahvé, su Dios, y él los vendió en manos de Sísara, capitán del ejército de Hazor, y en manos de los filisteos, y en manos del rey de Moab; y pelearon contra ellos.
“Ṣùgbọ́n wọ́n gbàgbé Olúwa Ọlọ́run wọn; bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì tà wọ́n sí ọwọ́ àwọn Sisera, olórí ogun Hasori, àti sí ọwọ́ àwọn Filistini àti sí ọwọ́ ọba Moabu, tí ó bá wọn jà.
10 Ellos clamaron a Yahvé y dijeron: “Hemos pecado, porque hemos abandonado a Yahvé y hemos servido a los baales y a Astarot; pero líbranos ahora de la mano de nuestros enemigos, y te serviremos”.
Wọ́n kégbe pe Olúwa, wọ́n sì wí pé, ‘Àwa ti ṣẹ̀; a ti kọ Olúwa sílẹ̀, a sì ti sin Baali, àti Aṣtoreti. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, àwa yóò sì sìn ọ́.’
11 Yahvé envió a Jerobaal, a Bedán, a Jefté y a Samuel, y os libró de la mano de vuestros enemigos de todas partes, y vivisteis seguros.
Nígbà náà ni Olúwa rán Jerubbaali, Bedani, Jefta àti Samuẹli, ó sì gbà yín lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá a yín gbogbo, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin ń gbé ní àlàáfíà.
12 “Cuando viste que Nahas, el rey de los hijos de Amón, venía contra ti, me dijiste: ‘No, sino que un rey reinará sobre nosotros’, cuando Yahvé, tu Dios, era tu rey.
“Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀yin sì rí i pé Nahaṣi ọba àwọn Ammoni dìde sí i yín, ẹ sọ fún mi pé, ‘Rárá, àwa ń fẹ́ ọba tí yóò jẹ́ lórí wa,’ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa Ọlọ́run yín jẹ́ ọba yín.
13 Ahora, pues, vean al rey que han elegido y al que han pedido. He aquí que el Señor ha puesto un rey sobre ustedes.
Nísinsin yìí èyí ni ọba tí ẹ̀yin ti yàn, tí ẹ̀yin béèrè fún; wò ó, Olúwa ti fi ọba jẹ lórí yín.
14 Si temes a Yahvé, le sirves y escuchas su voz, y no te rebelas contra el mandamiento de Yahvé, tanto tú como el rey que reina sobre ti son seguidores de Yahvé vuestro Dios.
Bí ẹ̀yin bá bẹ̀rù Olúwa àti bí ẹ̀yin bá ń sìn ín, tí ẹ sì gbọ́ tirẹ̀, tí ẹ̀yin kò sì ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ rẹ̀, àti tí ẹ̀yin àti ọba tí ó jẹ lórí yín bá ń tẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run yín: ó dára
15 Pero si no escuchan la voz de Yahvé y se rebelan contra el mandamiento de Yahvé, la mano de Yahvé estará contra ustedes, como lo estuvo contra sus padres.
ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá gbọ́ tí Olúwa, tí ẹ sì ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ rẹ̀, ọwọ́ rẹ̀ yóò wà lára yín sí ibi, bí ó ti wà lára baba yín.
16 “Ahora, pues, quédense quietos y vean esta gran cosa que el Señor va a hacer ante sus ojos.
“Nítorí náà, ẹ dúró jẹ́ẹ́ kí ẹ sì wo ohun ńlá yìí tí Olúwa fẹ́ ṣe ní ojú u yín!
17 ¿No es hoy la cosecha de trigo? Invocaré a Yahvé, para que envíe truenos y lluvia; y ustedes sabrán y verán que es grande la maldad que han hecho ante los ojos de Yahvé, al pedir un rey.”
Òní kì í ha á ṣe ọjọ́ ìkórè ọkà alikama bí? Èmi yóò ké pe Olúwa kí ó rán àrá àti òjò. Ẹ̀yin yóò sì mọ irú ohun búburú tí ẹ ti ṣe níwájú Olúwa nígbà tí ẹ̀ ń béèrè fún ọba.”
18 Entonces Samuel invocó a Yahvé, y Yahvé envió truenos y lluvia aquel día. Entonces todo el pueblo temió mucho a Yahvé y a Samuel.
Nígbà náà ni Samuẹli ké pe Olúwa, Olúwa sì rán àrá àti òjò ní ọjọ́ náà. Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ènìyàn sì bẹ̀rù Olúwa àti Samuẹli púpọ̀.
19 Todo el pueblo dijo a Samuel: “Ruega por tus siervos a Yahvé, tu Dios, para que no muramos, pues hemos añadido a todos nuestros pecados esta maldad de pedir un rey.”
Gbogbo àwọn ènìyàn sì wí fún Samuẹli pé, “Gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run rẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ kí a má ba à kú, nítorí tí àwa ti fi búburú yìí kún ẹ̀ṣẹ̀ wa ní bíbéèrè fún ọba.”
20 Samuel dijo al pueblo: “No tengan miedo. Ciertamente han hecho todo este mal; pero no se aparten de seguir a Yahvé, sino que sirvan a Yahvé con todo su corazón.
Samuẹli sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ má bẹ̀rù, ẹ ti ṣe gbogbo búburú yìí; síbẹ̀ ẹ má ṣe yípadà kúrò lọ́dọ̀ Olúwa, ṣùgbọ́n ẹ fi gbogbo àyà yín sin Olúwa.
21 No se aparten para ir en pos de cosas vanas que no pueden aprovechar ni liberar, porque son vanas.
Ẹ má ṣe yípadà sọ́dọ̀ àwọn òrìṣà. Wọn kò le ṣe ohun rere kan fún un yín, tàbí kí wọ́n gbà yín là, nítorí asán ni wọ́n.
22 Porque Yahvé no abandonará a su pueblo por causa de su gran nombre, porque a Yahvé le ha gustado hacer de ustedes un pueblo para sí mismo.
Nítorí orúkọ ńlá rẹ̀ Olúwa kì yóò kọ àwọn ènìyàn rẹ̀ sílẹ̀, nítorí tí inú Olúwa dùn láti fi yín ṣe ènìyàn rẹ̀.
23 Además, en cuanto a mí, lejos de pecar contra Yahvé al dejar de orar por ustedes, los instruiré en el camino bueno y correcto.
Bí ó ṣe ti èmi ni, kí á má rí i pé èmi dẹ́ṣẹ̀ sí Olúwa nípa dídẹ́kun àti gbàdúrà fún un yín. Èmi yóò sì kọ́ ọ yín ní ọ̀nà rere àti ọ̀nà òtítọ́.
24 Sólo temed a Yahvé y servidle de verdad con todo vuestro corazón, pues considerad las grandes cosas que ha hecho por vosotros.
Ṣùgbọ́n ẹ rí i dájú pé, ẹ bẹ̀rù Olúwa, kí ẹ sì sìn ín nínú òtítọ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn an yín, ẹ kíyèsi ohun ńlá tí ó ti ṣe fún un yín.
25 Pero si sigues haciendo el mal, serás consumido, tanto tú como tu rey”.
Síbẹ̀ bí ẹ̀yin bá ń ṣe búburú, ẹ̀yin àti ọba yín ni a ó gbá kúrò.”

< 1 Samuel 12 >