< Книга пророка Исаии 37 >

1 И бысть егда услыша царь Езекиа, растерза ризы и облечеся во вретище и вниде во храм Господень:
Nígbà tí ọba Hesekiah gbọ́ èyí, ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ bo ara rẹ̀, ó sì wọ inú tẹmpili Olúwa lọ.
2 и посла Елиакима домостроителя, и Сомну книгочия, и старейшины жречески оболчены во вретища ко Исаии пророку сыну Амосову.
Òun sì rán Eliakimu alákòóso ààfin, Ṣebna akọ̀wé, àti aṣíwájú àwọn àlùfáà, gbogbo wọn nínú aṣọ ọ̀fọ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ wòlíì Isaiah ọmọ Amosi.
3 И рекоша ему: сия глаголет Езекиа: день печали и укоризны и обличения и гнева днешний день, понеже прииде болезнь раждающей, крепости же не имеет родити:
Wọ́n sọ fún un pé, “Báyìí ni Hesekiah wí, ọjọ́ òní jẹ́ ọjọ́ ìbànújẹ́, ìbáwí àti ẹ̀gàn gẹ́gẹ́ bí ìgbà ìbí àwọn ọmọdé tí kò sì ṣí agbára láti bí wọn.
4 да услышит Господь Бог твой словеса Рапсакова, яже посла царь Ассирийский, господин его, укаряти Бога живаго и поносити словесы, яже слыша Господь Бог твой, и да помолишися ко Господеви Богу твоему о оставшихся сих.
Ó lè jẹ́ pé Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò gbọ́ ọ̀rọ̀ ọ̀gágun ẹni tí ọ̀gá rẹ̀ ọba Asiria ti rán láti fi Ọlọ́run alààyè ṣe ẹlẹ́yà, àti pé òun ni yóò bá a wí nítorí àwọn ọ̀rọ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti gbọ́. Nítorí náà gbàdúrà fún àwọn tí ó ṣẹ́kù tí wọ́n sì wà láààyè.”
5 И приидоша отроцы царя Езекии ко Исаии.
Nígbà tí àwọn ìjòyè ọba Hesekiah dé ọ̀dọ̀ Isaiah,
6 И рече им Исаиа: сице рцыте ко господину вашему: сия глаголет Господь: не убойся от словес, яже еси слышал, имиже укориша Мя послы царя Ассирийска:
Isaiah sọ fún wọn pé, “Ẹ sọ fún ọ̀gá yín pé, ‘Ohun tí Olúwa sọ nìyìí. Má ṣe bẹ̀rù ohun tí ẹ ti gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tí ọba Asiria tí ó wà nínú ìdè ti fi sọ̀rọ̀-òdì sí mi.
7 се, Аз вложу в него дух, и услышав весть возвратится во страну свою и падет мечем на своей земли.
Tẹ́tí sílẹ̀! Èmi yóò fi ẹ̀mí kan sínú rẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé bí o bá ti gbọ́ ìròyìn kan, òun yóò padà sí orílẹ̀-èdè rẹ̀, níbẹ̀ ni n ó sì ti jẹ́ kí wọn ké e lulẹ̀ pẹ̀lú idà.’”
8 И возвратися Рапсак и обрете царя Ассирийскаго облежаща Ловну: и услыша царь Ассирийск, яко отиде от Лахиса,
Nígbà tí ọ̀gágun gbọ́ pé ọba Asiria ti fi Lakiṣi sílẹ̀, ó padà sẹ́yìn, ó sì bá ọba tí ń bá Libina jà.
9 и изыде Фарака царь Ефиопский воевати нань: и услышав возвратися и посла послы ко Езекии, глаголя:
Ní àkókò yìí Sennakeribu gbọ́ ìròyìn kan pé Tirakah ará Kuṣi ọba Ejibiti ń jáde bọ̀ wá bá òun jà. Nígbà tí ó gbọ́ èyí, ó rán oníṣẹ́ sí Hesekiah pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí,
10 сице рцыте Езекии царю Иудейску: да не прельщает Бог твой тебе, на Негоже уповая еси, глаголя, яко не предастся Иерусалим в руце царя Ассирийска:
“Ẹ sọ fún Hesekiah ọba Juda pé: Má ṣe jẹ́ kí òrìṣà tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé tàn ọ́ jẹ nígbà tí ó sọ pé, ‘A kì yóò jọ̀wọ́ Jerusalẹmu fún ọba Asiria.’
11 или не слышал еси ты, что сотвориша царие Ассирийстии, како всю землю погубиша, и ты ли избавишися?
Dájúdájú, ìwọ ti gbọ́ ohun tí ọba Asiria ti ṣe sí àwọn orílẹ̀-èdè, tí ó pa wọ́n run pátápátá. Ǹjẹ́ a ó ha dá ọ nídè bí?
12 Еда избавиша сих бози язычестии, ихже погубиша отцы мои Гозан и Харран и Расем, иже суть во стране Феемафи?
Ǹjẹ́ àwọn òrìṣà àwọn orílẹ̀-èdè tí àwọn baba ńlá mi parun ha gbà wọ́n sílẹ̀ bí àwọn òrìṣà Gosani, Harani, Reṣefu àti àwọn ènìyàn Edeni tí wọ́n wà ní Teli-Assari?
13 Где суть царие Емафовы, и где Арфафовы, и где града Епфаруема, Анагугана?
Níbo ni ọba Hamati wà, ọba Arpadi, ọba ìlú Sefarfaimi tàbí Hena tàbí Iffa?”
14 И взя Езекиа книгу от послов и прочте ю, и вниде во храм Господень и отверзе ю пред Господем.
Hesekiah gba ìwé náà lọ́wọ́ àwọn oníṣẹ́ ó sì kà á. Lẹ́yìn náà ni ó gòkè lọ sí tẹmpili Olúwa ó sì tẹ́ ìwé náà sílẹ̀ níwájú Olúwa.
15 И помолися Езекиа ко Господеви, глаголя:
Hesekiah sì gbàdúrà sí Olúwa:
16 Господи Саваоф, Боже Израилев, седяй на Херувимех, Ты еси Бог един Царь всякаго царства вселенныя, Ты сотворил еси небо и землю:
Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli, tí ó gúnwà láàrín àwọn kérúbù, ìwọ nìkan ni Ọlọ́run lórí i gbogbo ìjọba orílẹ̀ ayé. Ìwọ ti dá ọ̀run àti ayé.
17 приклони, Господи, ухо Твое, услыши, Господи, отверзи, Господи, очи Твои, призри, Господи, и виждь и слыши вся словеса Сеннахиримля, яже посла укаряти Бога живаго:
Tẹ́tí sílẹ̀, ìwọ Olúwa, kí o gbọ́, ya ojú rẹ, Ìwọ Olúwa, kí o rí i; tẹ́tí sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí Sennakeribu rán láti fi àbùkù kan Ọlọ́run alààyè.
18 поистинне бо, Господи, пусту сотвориша царие Ассирийстии всю землю и страны их,
“Òtítọ́ ni Olúwa pé àwọn ọba Asiria ti sọ àwọn ènìyàn àti ilẹ̀ wọn di asán.
19 и ввергоша кумиры их во огнь, не беша бо бози, но дела рук человеческих, древа и камение, и погубиша я:
Wọ́n ti da àwọn òrìṣà wọn sínú iná wọ́n sì ti pa wọ́n run, nítorí àwọn wọ̀nyí kì í ṣe ọlọ́run bí kò ṣe igi àti òkúta lásán, tí a ti ọwọ́ ènìyàn ṣe.
20 ныне же, Господи Боже наш, спаси ны от руки их, да уведят вся царствия земная, яко Ты еси (Господь) Бог един.
Nísinsin yìí, ìwọ Olúwa, Ọlọ́run wa, gbà wá lọ́wọ́ rẹ̀, tí ó fi jẹ́ pé gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé yóò fi mọ̀ pé Ìwọ, Ìwọ nìkan, Olúwa ni Ọlọ́run.”
21 И послан бысть Исаиа сын Амосов ко Езекии и рече ему: сия глаголет Господь Бог Израилев: слышах, о нихже молился еси ко Мне о Сеннахириме цари Ассирийстем.
Lẹ́yìn náà Isaiah ọmọ Amosi rán iṣẹ́ kan sí Hesekiah: “Èyí ni ohun tí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli sọ pé, nítorí pé ìwọ ti gbàdúrà sí mi nípa Sennakeribu ọba Asiria,
22 Сие слово, еже глагола о нем Бог: похули тя и поругася тебе девица дщи Сионя, на тя главою покива дщи Иерусалимля:
èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ nípa rẹ̀: “Wúńdíá ọmọbìnrin Sioni ti kẹ́gàn rẹ, ó sì ti fi ọ ṣe ẹlẹ́yà. Ọmọbìnrin Jerusalẹmu ti mi orí rẹ̀ bí ó ti ń sálọ.
23 кого укорил и разгневал еси? Или к кому возвысил еси глас твой, и не воздвигл еси на высоту очес твоих? Ко Святому Израилеву!
Ta ni ìwọ ti bú tí ìwọ sì ti sọ̀rọ̀-òdì sí? Sí ta ní ìwọ ti gbé ohùn rẹ sókè tí o sì gbé ojú rẹ sókè ní ìgbéraga? Sí Ẹni Mímọ́ Israẹli!
24 Яко послами укорил еси Господа, ты бо рекл еси: множеством колесниц аз взыдох на высоту гор и на последняя Ливана, и посекох высоту кедра его и доброту кипарисову, и внидох в высоту части дубравныя
Nípa àwọn ìránṣẹ́ rẹ, ìwọ ti sọ̀rọ̀ búburú sí Olúwa. Tì wọ sì wí pé, ‘Pẹ̀lú ọ̀pọ̀ kẹ̀kẹ́ mi ni èmi sì fi dé orí àwọn òkè ńlá, sí ibi gíga jùlọ Lebanoni. Èmi a sì ké igi kedari gíga rẹ̀ lulẹ̀, àti ààyò igi firi rẹ̀. Èmi ti dé ibi rẹ̀ tí ó ga jùlọ, igbó rẹ̀ tí ó dára jùlọ.
25 и положих мост, и опустоших воды и все собрание водное:
Èmi ti gbẹ́ kànga ní ilẹ̀ àjèjì mo sì mu omi ní ibẹ̀, pẹ̀lú àtẹ́lẹsẹ̀ mi Èmi ti gbẹ́ gbogbo omi àwọn odò Ejibiti.’
26 не слышал ли еси издревле сих, яже Аз сотворих? От древних дний совещах, ныне же показах опустошити языки в твердынех и живущыя во твердых градех:
“Ṣé o kò tí ì gbọ́? Tipẹ́tipẹ́ ni mo ti fìdí rẹ̀ mulẹ̀. Láti ìgbà pípẹ́ ni mo ti ṣètò rẹ̀; ní àkókò yìí ni mo mú wá sí ìmúṣẹ, pé o ti sọ àwọn ìlú olódi di àkójọpọ̀ àwọn òkúta.
27 опустих руце, и изсхоша и быша аки сухо сено на кровех и аки троскот:
Àwọn ènìyàn, tí agbára ti wọ̀ lẹ́wù, ni wọ́n banújẹ́ tí a sì dójútì. Wọ́n dàbí ohun ọ̀gbìn nínú pápá, gẹ́gẹ́ bí ọ̀jẹ̀lẹ̀ èhíhù tuntun, gẹ́gẹ́ bí i koríko tí ó ń hù lórí òrùlé, tí ó jóná kí ó tó dàgbàsókè.
28 ныне же покой твой и исход твой и вход твой Аз вем,
“Ṣùgbọ́n mo mọ ibi tí o wà àti ìgbà tí o wá tí o sì lọ àti bí inú rẹ ṣe ru sí mi.
29 ярость же твоя, еюже разгневался еси, и огорчение твое взыде ко Мне, и вложу брозду в ноздри твоя, и узду во уста твоя, и возвращу тя путем, имже еси пришел.
Nítorí pé inú rẹ ru sí mi àti nítorí pé orí kunkun rẹ ti dé etí ìgbọ́ mi, Èmi yóò fi ìwọ̀ mi sí ọ ní imú, àti ìjẹ mi sí ọ lẹ́nu, èmi yóò sì jẹ́ kí o padà láti ọ̀nà tí o gbà wá.
30 Сие же тебе знамение: яждь сего лета, еже еси всеял, а во второе лето, еже от себе растет: а в третие насеявше пожнете и насадите винограды и снесте плоды их:
“Èyí ni yóò ṣe àmì fún ọ, ìwọ Hesekiah: “Ní ọdún yìí, ìwọ yóò jẹ ohun tí ó hù fúnra rẹ̀, àti ní ọdún kejì ohun tí ó jáde láti ara rẹ. Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹta, ẹ gbìn kí ẹ sì kórè, ẹ gbin ọgbà àjàrà kí ẹ sì jẹ èso wọn.
31 и будут оставшии во Иудеи, прорастят корение долу и сотворят в верх плод,
Lẹ́ẹ̀kan sí i, àṣẹ́kù láti ilé Juda yóò ta gbòǹgbò nísàlẹ̀ yóò sì ṣo èso lókè.
32 яко от Иерусалима будут оставшиися и спасшиися от горы Сиони: ревность Господа Саваофа сотворит сия.
Nítorí láti Jerusalẹmu ni àwọn àṣẹ́kù yóò ti wá, àti láti òkè Sioni ni ikọ̀ àwọn tí ó sálà. Ìtara Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni yóò mú èyí ṣẹ.
33 Сего ради тако глаголет Господь на царя Ассирийска: не внидет в сей град, ниже пустит нань стрелу, ниже возложит нань щита, ниже оградит окрест его ограждения:
“Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa wí nípa ọba Asiria, “Òun kì yóò wọ ìlú yìí wá tàbí ta ẹyọ ọfà kan níhìn-ín Òun kì yóò wá síwájú rẹ pẹ̀lú asà tàbí kí ó kó dágunró sílẹ̀ fún un.
34 но путем, имже прииде, темже возвратится, и во град сей не внидет. Сия глаголет Господь:
Nípa ọ̀nà tí ó gbà wá náà ni yóò padà lọ; òun kì yóò wọ inú ìlú yìí,” ni Olúwa wí.
35 защищу град сей, еже спасти его Мене ради и ради Давида раба Моего.
“Èmi yóò dáàbò bo ìlú yìí èmi ó sì gbà á là, nítorí mi àti nítorí Dafidi ìránṣẹ́ mi!”
36 И изыде Ангел Господень и изби от полка Ассирийска сто осмьдесят пять тысящ. И воставше заутра, обретоша вся телеса мертва.
Lẹ́yìn náà ni angẹli Olúwa jáde lọ ó sì pa ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ènìyàn ní i ibùdó àwọn Asiria. Nígbà tí àwọn ènìyàn yìí jí ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì gbogbo wọn ti dòkú!
37 И отиде возвращься Сеннахирим царь Ассирийский и вселися во Ниневии.
Nítorí náà Sennakeribu ọba Asiria fọ́ bùdó ó sì pẹsẹ̀dà. Òun sì padà sí Ninefe, ó sì dúró síbẹ̀.
38 И внегда покланятися ему и в дому Насараху отечествоначалнику своему, Адрамелех и Сарасар сынове его убиста его мечьми, сами же убежаста во Армению. И воцарися Асордан сын его вместо его.
Ní ọjọ́ kan, bí ó ti ń jọ́sìn nínú tẹmpili Nisroki òrìṣà rẹ̀, àwọn ọmọ rẹ̀ Adrameleki àti Ṣareseri gé e lulẹ̀ pẹ̀lú idà, wọ́n sì sálọ sí ilẹ̀ Ararati. Bẹ́ẹ̀ ni Esarhadoni ọmọ rẹ̀ sì gba ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

< Книга пророка Исаии 37 >