< Књига пророка Језекиља 11 >

1 Тада ме подиже дух, и однесе ме на источна врата дома Господњег, која гледају на исток, и гле, на вратима беше двадесет и пет људи, и међу њима видех Језанију, сина Азуровог и Фелатију сина Венајиног, поглаваре народне.
Ẹ̀mí sì gbé mi sókè, ó mú mi lọ sí ẹnu-ọ̀nà ilé Olúwa èyí tó dojúkọ ìlà-oòrùn. Ní àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà yìí ni àwọn ọkùnrin mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n wá, mo rí Jaaṣaniah ọmọ Assuri àti Pelatiah ọmọ Benaiah, tí wọ́n jẹ́ ìjòyè àwọn ènìyàn.
2 И рече ми: Сине човечји, ови људи смишљају безакоње, и зло саветују у том граду,
Olúwa sì sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, àwọn ọkùnrin yìí ló ń pète ibi, wọ́n sì ń gbé ìmọ̀ràn búburú kalẹ̀ nínú ìlú.
3 Говорећи: Није близу; да градимо куће; овај је град лонац а ми месо.
Wọ́n ní, ‘Kò ha tí ì tó àsìkò láti kọ́lé? Ìlú yìí ni ìkòkò ìdáná, àwa sì ni ẹran’.
4 Зато пророкуј против њих, пророкуј, сине човечји.
Nítorí náà sọtẹ́lẹ̀ nípa wọn; ọmọ ènìyàn, sọtẹ́lẹ̀.”
5 И паде на ме дух Господњи и рече ми: Реци: Овако вели Господ: Доме Израиљев, тако говористе, и знам мисли срца вашег.
Ẹ̀mí Olúwa sì bà lé mi, ó sì wí pé, “Sọ̀rọ̀!” Báyìí ni Olúwa wí, ohun tí ẹ ń sọ nìyìí, ilé Israẹli, mo mọ ohun tó wà lọ́kàn yín.
6 Многе побисте у том граду, и напунисте улице њихове побијених.
Ẹ̀yin ti sọ òkú yín di púpọ̀ nínú ìlú yìí, òkú sì ti kún gbogbo ìgboro rẹ̀.
7 Зато овако вели Господ Господ: Које побисте и побацасте усред њега, они су месо, а он је лонац, а вас ћу извести из њега.
“Torí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí, àwọn òkú tí ẹ fọn sílẹ̀ sí àárín yín ni ẹran, ìlú yìí sì ni ìkòkò ìdáná ṣùgbọ́n èmi yóò le yín jáde níbẹ̀.
8 Бојите се мача; мач ћу пустити на вас, говори Господ Господ.
Ẹ bẹ̀rù idà, èmi yóò sì mú idà wá sórí yín, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa Olódùmarè wí.
9 И извешћу вас из њега, и даћу вас у руке туђинцима, и извршићу на вама судове.
Èmi yóò lé yín jáde kúrò ní ìlú yìí, èmi yóò sì fà yín lé àjèjì lọ́wọ́, èmi yóò sì mú ìdájọ́ ṣẹ lé yín lórí.
10 Од мача ћете пасти, на међи Израиљевој судићу вам, и познаћете да сам ја Господ.
Nípa idà ni ẹ̀yin yóò ṣubú, èmi yóò sì ṣe ìdájọ́ yín ní àwọn ààlà ìlú Israẹli. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa.
11 Овај град неће вам бити лонац нити ћете ви бити у њему месо; на међи Израиљевој судићу вам.
Ìlú yìí kò ní i jẹ́ ìkòkò ìdáná, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin náà kò sì ní jẹ́ ẹran nínú rẹ̀, Èmi yóò ṣe ìdájọ́ yín ní àwọn ààlà ìlú Israẹli.
12 И познаћете да сам ја Господ, јер по уредбама мојим не ходисте нити законе моје извршавасте, него чинисте по законима тих народа што су око вас.
Ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa, nítorí pé ẹ̀yin kò tẹ̀lé àṣẹ mi ẹ̀yin kò sì pa òfin mi mọ́, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti hùwà gẹ́gẹ́ bí àwọn aláìgbàgbọ́ orílẹ̀-èdè tó yí yín ká.”
13 А кад пророковах, умре Фелатија син Венајин; тада падох на лице своје и повиках гласно и рекох: Јаох Господе Господе! Хоћеш ли да истребиш остатак Израиљев?
Bí mo ṣe ń sọtẹ́lẹ̀ lọ́wọ́, Pelatiah ọmọ Benaiah kú. Mo sì dojúbolẹ̀, mo sì kígbe sókè pé, “Háà! Olúwa Olódùmarè! Ṣé ìwọ yóò ha pa ìyókù Israẹli run pátápátá ni?”
14 А глас Господњи дође ми говорећи:
Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé,
15 Сине човечји, браћа су твоја, браћа твоја, родбина твоја и дом Израиљев васколики, којима говорише Јерусалимљани: Идите далеко од Господа, нама је дата земља у наследство.
“Ọmọ ènìyàn, àwọn arákùnrin rẹ, àní àwọn ará rẹ, àwọn ọkùnrin nínú ìbátan rẹ, àti gbogbo ilé Israẹli pátápátá, ni àwọn ará Jerusalẹmu ti wí fún pé, ‘Ẹ jìnnà sí Olúwa, àwa ni a fi ilẹ̀ yìí fún yín ní ìní.’
16 Зато реци: Овако вели Господ Господ: Ако их и одагнах далеко међу народе, ако их и расејах по земљама, опет ћу им бити светиња за мало у земљама у које отидоше.
“Nítorí náà, sọ fún àwọn tó wà ní ìgbèkùn pé, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti fọ́n wọn káàkiri orílẹ̀-èdè, síbẹ̀ fún ìgbà díẹ̀, èmi yóò jẹ́ ibi mímọ́ fún wọn níbi tí wọ́n lọ.’
17 Зато реци: Овако вели Господ Господ: Сабраћу вас из народа и покупићу вас из земаља у које се расејасте, и даћу вам земљу Израиљеву.
“Nítorí náà, wí pé, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí, Èmi yóò kó wọn jọ kúrò láàrín àwọn orílẹ̀-èdè tí mo fọ́n wọn ká sí, Èmi yóò sì fún wọn ní ilẹ̀ Israẹli padà.’
18 И кад дођу у њу, избациће из ње све гадове њене и све гнусобе њене.
“Wọn yóò padà síbẹ̀, wọn yóò sì mú gbogbo àwòrán ìríra rẹ̀ àti ìbọ̀rìṣà rẹ̀ kúrò.
19 И даћу им једно срце, и нов дух метнућу у њих, и извадићу из тела њиховог камено срце и даћу им срце месно,
Èmi yóò fún wọn ní ọ̀kankan; èmi yóò sì fi ẹ̀mí tuntun sínú wọn, Èmi yóò mú ọkàn òkúta kúrò lára wọn, èmi yóò sì fún wọn ní ọkàn tó rọ̀ bí ara ẹran.
20 Да би ходили по мојим уредбама и држали моје законе и извршавали их; и биће ми народ, и ја ћу им бити Бог.
Kí wọn le tẹ̀lé àṣẹ mi, kí wọn sì le pa òfin mi mọ́. Wọ́n yóò jẹ́ ènìyàn mi, Èmi náà yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn.
21 А којима срце иде по жељи гнусоба њихових и гадова њихових, њихов ћу пут обратити на њихову главу, говори Господ Господ.
Ṣùgbọ́n fún àwọn tí wọ́n ń fi gbogbo ọkàn wọn sin àwọn àwòrán ìríra àti àwọn òrìṣà, Èmi yóò mú ẹ̀san ohun tí wọ́n ṣe wá sí orí wọn bẹ́ẹ̀ ni Olúwa Olódùmarè wí.”
22 Потом махнуше херувими крилима својим, и точкови отидоше према њима, и слава Бога Израиљевог беше озго над њима.
Àwọn kérúbù sì gbé ìyẹ́ wọn sókè pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn, ògo Ọlọ́run Israẹli sì wà lókè orí wọn.
23 И подиже се слава Господња исред града, и стаде на гори која је с истока граду.
Ògo Olúwa sì gòkè lọ kúrò láàrín ìlú, ó sì dúró lórí òkè tó wà ní ìlà-oòrùn ìlú náà.
24 А мене дух подиже и однесе у утвари духом Божјим у Халдејску к робљу: и утвара коју видех отиде од мене.
Lẹ́yìn náà, Ẹ̀mí gbé mi sókè, ó sì mú mi wá sí Kaldea lójú ìran, nípa ti Ẹ̀mí Ọlọ́run sí ọ̀dọ̀ àwọn ti ìgbèkùn. Bẹ́ẹ̀ ni ìran tí mo rí lọ kúrò ní ọ̀dọ̀ mi,
25 И казах робљу све речи Господње што ми показа.
mo sì sọ gbogbo ohun tí Olúwa fihàn mí fún àwọn tó wà ní ìgbèkùn.

< Књига пророка Језекиља 11 >