< 2 Мојсијева 31 >

1 И рече Господ Мојсију говорећи:
Olúwa wí fún Mose pé,
2 Гле, позвах по имену Веселеила сина Урије сина Оровог од племена Јудиног.
“Wò ó, Èmi ti yan Besaleli ọmọ Uri, ọmọ Huri, ti ẹ̀yà Juda,
3 И напуних га Духа Светог, мудрости и разума и знања и сваке вештине,
Èmi sì ti fi Ẹ̀mí Ọlọ́run kún un pẹ̀lú ọgbọ́n, òye àti ìmọ̀ ní gbogbo onírúurú iṣẹ́ ọnà.
4 Да вешто измишља како се шта може начинити од злата и од сребра и од бронзе,
Láti ṣe aláràbarà iṣẹ́ ní wúrà, fàdákà àti idẹ,
5 Да уме резати камење и укивати, да уме тесати дрво, и сваки посао радити.
láti gbẹ́ òkúta àti láti tò wọ́n, láti ṣiṣẹ́ ní igi, àti láti ṣiṣẹ́ ní gbogbo onírúurú iṣẹ́ ọnà.
6 И ево удружих с њим Елијава, сина Ахисамаховог од племена Дановог, и сваком вештом човеку у срце дадох вештину да израде све што сам ти заповедио.
Síwájú sí i, èmi ti yan Oholiabu ọmọ Ahisamaki, ti ẹ̀yà Dani, láti ràn án lọ́wọ́. “Bákan náà, Èmi ti fi ọgbọ́n fún gbogbo àwọn oníṣẹ́-ọnà láti ṣe ohun gbogbo tí mo pàṣẹ fún ọ:
7 Шатор од састанка, и ковчег за сведочанство и заклопац на њ, и све справе у шатору,
“àgọ́ àjọ náà, àpótí ẹ̀rí pẹ̀lú ìtẹ́ àánú tí ó wà lórí rẹ̀, àti gbogbo ohun èlò àgọ́ náà,
8 И сто и справе његове, и свећњак чисти са свим справама његовим, и олтар кадиони,
tábìlì àti ohun èlò rẹ̀, ọ̀pá fìtílà tí ó jẹ́ kìkì wúrà àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, pẹpẹ tùràrí,
9 И олтар за жртву паљеницу са свим справама његовим, и умиваоницу и подножје њено,
pẹpẹ ẹbọ sísun àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, agbada pẹ̀lú ẹsẹ̀ rẹ̀,
10 И хаљине службене и свете хаљине Арону свештенику и хаљине синовима његовим, да врше службу свештеничку,
àti aṣọ híhun pẹ̀lú, papọ̀ pẹ̀lú aṣọ mímọ́ fún Aaroni àlùfáà àti aṣọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ bí àlùfáà,
11 И уље помазања, и кад мирисни за светињу. Све нека начине онако како сам ти заповедио.
òróró ìtasórí àti tùràrí olóòórùn dídùn fún Ibi Mímọ́. “Kí wọ́n ṣe wọ́n gẹ́gẹ́ bí mo ṣe pàṣẹ fún ọ.”
12 И рече Господ Мојсију говорећи:
Olúwa wí fún Mose pé,
13 А ти кажи синовима Израиљевим и реци: Али суботе моје чувајте, јер је знак између мене и вас од колена до колена, да знате да сам ја Господ који вас посвећујем.
“Kí ìwọ kí ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Ẹ̀yin gbọdọ̀ máa pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́. Èyí ni yóò jẹ́ àmì láàrín Èmi àti ẹ̀yin fún ìrandíran tó ń bọ̀, nítorí kí ẹ̀yin lè mọ̀ pé Èmi ni Olúwa, ẹni tí ó yà yín sí mímọ́.
14 Чувајте дакле суботу, јер вам је света; ко би је оскврнио, да се погуби; јер ко би год радио какав посао у њу, истребиће се она душа из народа свог.
“‘Nítorí náà, kí ẹ̀yin kí ó máa pa ọjọ́ ìsinmi mọ́, nítorí mímọ́ ni fún un yín. Ẹnikẹ́ni tí ó bá bà á jẹ́, ni a yóò pa; ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà ni a yóò gé kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ.
15 Шест дана нека се ради; а седми је дан субота, одмор, свет Господу; ко би год радио посао у дан суботни, да се погуби.
Ọjọ́ mẹ́fà ni kí ẹ fi ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ọjọ́ keje ní ọjọ́ ìsinmi tí ẹ̀yin yóò fi sinmi, mímọ́ ni fún Olúwa. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣiṣẹ́ ní ọjọ́ ìsinmi ni a ó pa nítòótọ́.
16 Зато ће чувати синови Израиљеви суботу празнујући суботу од колена до колена заветом вечним.
Nítorí náà ni àwọn ọmọ Israẹli yóò ṣe máa pa ọjọ́ ìsinmi mọ́, ẹ máa ṣe àkíyèsí rẹ̀ dé ìrandíran tó ń bọ̀ bí i májẹ̀mú títí láé.
17 То је знак између мене и синова Израиљевих довека; јер је за шест дана створио Господ небо и земљу, а у седми дан почину и одмори се.
Yóò jẹ́ àmì láàrín Èmi àti àwọn ọmọ Israẹli títí láé, nítorí ní ọjọ́ mẹ́fà ni Olúwa dá ọ̀run àti ayé, àti ní ọjọ́ keje ni ó fi iṣẹ́ sílẹ̀, ó sì sinmi.’”
18 И изговоривши ово Мојсију на гори Синајској, даде му две плоче сведочанства, плоче камене писане прстом Божијим.
Nígbà tí Olúwa parí ọ̀rọ̀ sísọ fún Mose lórí òkè Sinai, ó fún un ní òkúta wàláà ẹ̀rí méjì, òkúta wàláà òkúta tí a fi ìka Ọlọ́run kọ.

< 2 Мојсијева 31 >