< 1 Yohani 5 >
1 Wowoti wahuposhela uYesu uKiristi huje apepwe nungolobhe. Wowoti wagene huje afumile hwa Daada nantele abhagene abhana bhakwe.
Olúkúlùkù ẹni tí ó bá gbàgbọ́ pé Jesu ni Kristi, a bí i nípa ti Ọlọ́run: àti olúkúlùkù ẹni tí ó fẹ́ràn. Ẹni tí ó bi nì, ó fẹ́ràn ẹni tí a bí nípasẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú.
2 Huhweli timenye huje tibhagene abhana bhangolobhe petuhugana ongolobhe nembombo zyakwe.
Nípa èyí ni àwa mọ̀ pé àwa fẹ́ràn àwọn ọmọ Ọlọ́run, nígbà tí a bá fẹ́ràn Ọlọ́run, tí a sì ń pa òfin rẹ̀ mọ́.
3 Hwahuje petihugana Ongolobhe tibhomba nembombo zyakwe embombo zyakwe nyororo.
Nítorí èyí ni ìfẹ́ Ọlọ́run, pé kí àwa pa òfin rẹ̀ mọ́: òfin rẹ̀ kò sì nira,
4 Hwahuje wapepwe nu Ngolobhe aimenile eensi. Ohwo huimene huimene eensi ulweteshelo lwetu.
nítorí olúkúlùkù ẹni tí a bí nípa tí Ọlọ́run, ó ṣẹ́gun ayé. Èyí sì ni ìṣẹ́gun tí ó ṣẹ́gun ayé, àní ìgbàgbọ́ wa.
5 Yonanu waimenile eensi? Yeyola wamweteshe huje Mwana wa Ngolobhe.
Ta ni ẹni tí ó ṣẹ́gun ayé, bí kò ṣe ẹni tí ó gbàgbọ́ pé Ọmọ Ọlọ́run ni Jesu jẹ́?
6 Ono wahenzele humenze ni danda O Yesu U Kiristi. Sagaahenzele namenze gene ahenzele namenze ni danda.
Èyí ni ẹni tí ó wá nípa omi àti ẹ̀jẹ̀, Jesu Kristi, kì í ṣe nípa omi nìkan, bí kò ṣe nípa omi àti ẹ̀jẹ̀. Àti pé Ẹ̀mí ni ó sì ń jẹ́rìí, nítorí pé òtítọ́ ni Ẹ̀mí.
7 Hwahuje bhatatu bhabhayanga.
Nítorí pé àwọn mẹ́ta ni ó ń jẹ́rìí.
8 Ompepo amenze nidanda ebha bhatatu bhahwetehana.
Ẹ̀mí, omi, àti ẹ̀jẹ̀: àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sì wà ni ìṣọ̀kan.
9 Nkashile mtejezya usimishizwo gwabhantu usimishizwo ogwangolobhe gosi ashile ego. Hwahuje usimishizwo ogwa golobhe gwagogu huje alinagwo usimishizwo gwa Mwana wakwe.
Bí àwa ba ń gba ẹ̀rí ènìyàn, ẹ̀rí Ọlọ́run tóbi jù: nítorí ẹ̀rí Ọlọ́run ni èyí pé, Ó tí jẹ́rìí ní ti Ọmọ rẹ̀.
10 Ola wahuposhela Omwana wa Ngolobhe alinagwo usimishizwi mhati yakwe yuyo. Wowoti wasaga huposhela Ongolobhe ubheshe aje wilenga hwahuje sagaposheye usimishizwo ogwa Ngolobhe auletile ashilile Omwana wakwe.
Ẹni tí ó bá gba Ọmọ Ọlọ́run gbọ́, ó ni ẹ̀rí nínú ara rẹ̀; ẹni tí kò bá gba Ọlọ́run gbọ́, ó ti mú un ni èké; nítorí kò gba ẹ̀rí náà gbọ́ tí Ọlọ́run jẹ́ ní ti Ọmọ rẹ̀.
11 Usimishizwo gwa Ngolobhe atipiye owomi ogwa wila, owomi ogwo guli mhati ya Mwana wakwe. (aiōnios )
Ẹ̀rí náà sì ni èyí pé Ọlọ́run fún wa ní ìyè àìnípẹ̀kun, ìyè yìí sì ń bẹ nínú Ọmọ rẹ̀. (aiōnios )
12 Wali numwana wakwe ai nuwomi wasagali numwana owa Ngolobhe sagali nuwomi.
Ẹni tí ó bá ni Ọmọ, ó ni ìyè; ẹni tí kò bá sì ni Ọmọ Ọlọ́run, kò ní ìyè.
13 Embasimbiye ega mmanye huje mli nuwomi ogwo wila amwe mwemhutejezya hwitawa lya Mwana wa Ngolobhe. (aiōnios )
Nǹkan wọ̀nyí ni mo kọ̀wé rẹ̀ sí yín, àní sí ẹ̀yin tí ó gba orúkọ Ọmọ Ọlọ́run gbọ́; kí ẹ̀yin lè mọ̀ pé ẹ̀yin ní ìyè àìnípẹ̀kun, àní fún ẹ̀yin tí ó gba orúkọ Ọmọ Ọlọ́run gbọ́. (aiōnios )
14 Elitinalyo tibagaje hwitagalila lyakwe huje nkatilabhe ahatu hohoti shishiza mlugano lwakwe ahonvwa.
Èyí sì ni ìgboyà tí àwa ní níwájú rẹ̀, pé bí àwa bá béèrè ohunkóhun gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀, ó ń gbọ́ tí wa.
15 Nkashile timenye huje ontovwa hohoti hetihulabha timenye huje tilinalyo lyatilaabhile.
Bí àwa bá sì mọ̀ pé ó ń gbọ́ tí wa, ohunkóhun tí àwa bá béèrè, àwa mọ̀ pé àwa rí ìbéèrè tí àwa ti béèrè lọ́dọ̀ rẹ̀ gbà.
16 Nkashile omuntu alolile uwomba embibhi yasagahutwale afwe, hahwanziwa alabhe hwa Ngolobhe abhapele owomi. Iyanga nabhala embibhi zyawo saga ziwatwala afwe sayanga huje ahwaziwa alabhe humbibhi ezwo.
Bí ẹnikẹ́ni bá rí arákùnrin rẹ̀ tí ń dẹ́ṣẹ̀ tí kì í ṣe sí ikú, òun yóò béèrè, Ọlọ́run yóò sì fún un ni ìyè, àní, fún àwọn tí ń dẹ́ṣẹ̀ tí kì í ṣe sí ikú. Ẹ̀ṣẹ̀ kan ń bẹ sì ikú, èmi kò wí pé ki òun gbàdúrà fún èyí.
17 Nkakosele embibhi hwahiye zihweli embibhi zyasaga zya aafwe.
Gbogbo àìṣòdodo ni ẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀ṣẹ̀ kan ń bẹ tí kì í ṣe sí ikú.
18 Hwahuje wapepwe nu Ngolobhe saga bhabhomba embibhi. Wapepwe nu Ngolobhe, alelwa abhapinza wila nula ohwimbibhi hawezizye huvwalazye.
Àwa mọ̀ pé ẹnikẹ́ni tí a bí nípa ti Ọlọ́run kì í dẹ́ṣẹ̀: ṣùgbọ́n ẹni tí a bí nípa tí Ọlọ́run a pa ara rẹ̀ mọ́, ẹni búburú kò ní lè fọwọ́ kàn án.
19 Timenye huje ante tili bhana bhangolobhe ensi yonti pansi elogozya nuula obhibhi.
Àwa mọ̀ pé tí Ọlọ́run ni wá, àti gbogbo ayé ni ó wà lábẹ́ agbára ẹni búburú náà.
20 Hwahuje Omwana wa Ngolobhe ayezele atipiye enjele hwahuje timenye omwene lyoli, huyetili mhati yakwe umwene lyoli hwoyo Umwana wakwe uYesu Kiristi nu Ngolobhe uwelyoli nowomi weiwene. (aiōnios )
Àwa sì mọ̀ pé Ọmọ Ọlọ́run dé, ó sì tí fi òye fún wa, kí àwa lè mọ ẹni tí í ṣe òtítọ́, àwa sì ń bẹ nínú ẹni tí í ṣe òtítọ́, àní, nínú Ọmọ rẹ̀, Jesu Kristi. Èyí ni Ọlọ́run òtítọ́, àti ìyè àìnípẹ̀kun. (aiōnios )
21 Mubhana mwaganwa muhwiyetwe neshifwani.
Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ pa ara yín mọ́ kúrò nínú òrìṣà.