< Книга Судей 18 >

1 В те дни не было царя у Израиля; и в те дни колено Даново искало себе удела, где бы поселиться, потому что дотоле не выпало ему полного удела между коленами Израилевыми.
Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àwọn ọmọ Israẹli kò ní ọba. Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àwọn ẹ̀yà Dani ń wá ilẹ̀ tiwọn, níbi tí wọn yóò máa gbé, nítorí pé títí di àkókò náà wọn kò ì tí ì pín ogún ilẹ̀ fún wọn ní ìní láàrín àwọn ọmọ Israẹli.
2 И послали сыны Дановы от племени своего пять человек, мужей сильных, из Цоры и Естаола, чтоб осмотреть землю и узнать ее, и сказали им: пойдите, узнайте землю. Они пришли на гору Ефремову к дому Михи и ночевали там.
Nítorí náà àwọn ẹ̀yà Dani rán àwọn jagunjagun márùn-ún lọ láti Sora àti Eṣtaoli láti yọ́ ilẹ̀ náà wò àti láti rìn ín wò. Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ṣe ojú fún gbogbo àwọn ẹ̀yà wọn. Wọ́n wí fún wọn pé, “Ẹ lọ kí ẹ rin ilẹ̀ náà ká, kí ẹ sì wò ó fínní fínní.” Àwọn ọkùnrin náà wọ àwọn ìlú tí ó wà ní agbègbè òkè Efraimu, wọ́n sì dé ilé Mika, níbi tí wọ́n sùn ní òru náà.
3 Находясь у дома Михи, узнали они голос молодого левита и зашли туда и спрашивали его: кто тебя привел сюда? что ты здесь делаешь и зачем ты здесь?
Nígbà tí wọ́n súnmọ́ tòsí ilé e Mika, wọ́n dá ohùn ọ̀dọ́mọkùnrin Lefi náà mọ̀, torí náà wọ́n yípadà, wọ́n sì wọ inú ilé náà lọ wọ́n sì bi í pé, “Tá ni ó mú ọ wa sí ibi? Kí ni ìwọ ń ṣe níhìn-ín yìí? Èéṣe tí o fi wà ní ibí?”
4 Он сказал им: то и то сделал для меня Миха, нанял меня, и я у него священником.
Ó sọ ohun tí Mika ti ṣe fún un, ó fi kún un fún wọn pé, “Ó gbà mí sí iṣẹ́, èmi sì ni àlùfáà rẹ̀.”
5 Они сказали ему: вопроси Бога, чтобы знать нам, успешен ли будет путь наш, в который мы идем.
Wọ́n wí fún un pé, “Jọ̀wọ́ béèrè ní ọwọ́ Ọlọ́run, kí àwa lè mọ̀ bí ìrìnàjò wa yóò yọrí sí rere.”
6 Священник сказал им: идите с миром; пред Господом путь ваш, в который вы идете.
Àlùfáà náà dá wọn lóhùn pé, “Ẹ máa lọ ní àlàáfíà. Ìrìnàjò yín tí ẹ̀yin ń rìn bá ojúrere Olúwa pàdé.”
7 И пошли те пять мужей, и пришли в Лаис, и увидели народ, который в нем, что он живет покойно, по обычаю Сидонян, тих и беспечен, и что не было в земле той, кто обижал бы в чем, или имел бы власть: от Сидонян они жили далеко, и ни с кем не было у них никакого дела.
Àwọn ọkùnrin márààrún náà kúrò, wọ́n sì wá sí Laiṣi, níbi tí wọ́n ti rí i pé àwọn ènìyàn tí ń gbé ibẹ̀ ní ààbò, bí àwọn ará Sidoni, láìsí ìfòyà àti ní ìpamọ́. Ní ìgbà tí ilẹ̀ wọn kò ṣe aláìní ohunkóhun, wọ́n ní ọrọ̀ púpọ̀. Ibùgbé wọn tún jìnnà sí ti àwọn ará Sidoni, wọn kò fi ohunkóhun bá ẹnikẹ́ni dàpọ̀.
8 И возвратились оные пять человек к братьям своим в Цору и Естаол, и сказали им братья их: с чем вы?
Nígbà tí wọ́n padà sí Sora àti Eṣtaoli, àwọn arákùnrin wọn bi wọ́n léèrè pé, “Báwo ni ibi tí ẹ lọ ti rí? Kí ni ìròyìn tí ẹ mú wá?”
9 Они сказали: встанем и пойдем на них; мы видели землю, она весьма хороша; а вы задумались: не медлите пойти и взять в наследие ту землю;
Wọ́n dáhùn pé, “Ẹ dìde ẹ jẹ́ kí a lọ kọlù wọ́n! A wá rí i pé ilẹ̀ náà dára gidigidi. Ṣé ẹ̀yin ó sì jókòó láìsí nǹkan nípa rẹ̀? Ẹ má ṣe lọ́ra láti lọ síbẹ̀ kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà.
10 когда пойдете вы, придете к народу беспечному, и земля та обширна; Бог предает ее в руки ваши; это такое место, где нет ни в чем недостатка, что получается от земли.
Nígbà tí ẹ̀yin bá dé ibẹ̀, ẹ yóò rí àwọn ènìyàn tí ọkàn wọn balẹ̀ àti ilẹ̀ tí ó tẹ́jú tí Ọlọ́run ti fi fún yín, ilẹ̀ tí kò ṣe aláìní nǹkan kan.”
11 И отправились оттуда из колена Данова, из Цоры и Естаола, шестьсот мужей, препоясавшись воинским оружием.
Nígbà náà ni ẹgbẹ̀ta ọkùnrin tí ó múra ogun láti ìran Dani, jáde lọ láti Sora àti Eṣtaoli ní mímú ra láti jagun.
12 Они пошли и стали станом в Кириаф-Иариме, в Иудее. Посему и называют то место станом Дановым до сего дня. Он позади Кириаф-Иарима.
Wọ́n sì jáde lọ, ní ojú ọ̀nà wọn, wọ́n tẹ̀dó ogun sí ẹ̀bá Kiriati-Jearimu ní Juda. Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń gbé ìwọ̀-oòrùn Kiriati-Jearimu ni Mahane-Dani títí di òní yìí.
13 Оттуда отправились они на гору Ефремову и пришли к дому Михи.
Láti ibẹ̀ wọ́n kọjá lọ sí àwọn ìlú agbègbè òkè Efraimu, wọ́n sì dé ilé Mika.
14 И сказали те пять мужей, которые ходили осматривать землю Лаис, братьям своим: знаете ли, что в одном из домов сих есть ефод, терафим, истукан и литый кумир? итак подумайте, что сделать.
Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin márùn-ún tí ó lọ yọ́ ilẹ̀ Laiṣi wò sọ fún àwọn arákùnrin wọn pé, “Ǹjẹ́ ẹ̀yin mọ̀ pé ọ̀kan nínú àwọn ilé yìí ní ẹ̀wù efodu, àwọn yòókù ní òrìṣà, ère gbígbẹ́ àti ère dídà? Ẹ mọ ohun tí ó yẹ kí ẹ ṣe báyìí.”
15 И зашли туда, и вошли в дом молодого левита, в дом Михи, и приветствовали его.
Wọ́n sì yà sí ibẹ̀, wọ́n sì wọ ilé ọ̀dọ́mọkùnrin Lefi náà, sí ilé Mika, wọ́n sì béèrè àlàáfíà rẹ̀.
16 А шестьсот человек из сынов Дановых, препоясанные воинским оружием, стояли у ворот.
Àwọn ẹgbẹ̀ta ọkùnrin ará Dani náà tí ó hámọ́ra ogun, dúró ní àbáwọlé ẹnu odi.
17 Пять же человек, ходивших осматривать землю, пошли, вошли туда, взяли истукан и ефод и терафим и литый кумир. Священник стоял у ворот с теми шестьюстами человек, препоясанных воинским оружием.
Àwọn ọkùnrin márùn-ún tí wọ́n lọ yọ́ ilẹ̀ náà wò wọlé lọ wọ́n sì kó ère gbígbẹ́ náà, efodu náà, àwọn òrìṣà ìdílé àti ère dídà náà nígbà tí àlùfáà náà àti àwọn ẹgbẹ̀ta ọkùnrin tí ó hámọ́ra ogun dúró ní à bá wọ ẹnu odi náà.
18 Когда они вошли в дом Михи и взяли истукан, ефод, терафим и литый кумир, священник сказал им: что вы делаете?
Nígbà tí àwọn ọkùnrin yìí wọ ilé e Mika lọ tí wọ́n sì kó ère fínfín náà, efodu náà, àwọn òrìṣà ìdílé mìíràn àti ère dídà náà, àlùfáà náà béèrè lọ́wọ́ wọn wí pé, “Kí ni ẹ̀yin ń ṣe?”
19 Они сказали ему: молчи, положи руку твою на уста твои и иди с нами и будь у нас отцом и священником; лучше ли тебе быть священником в доме одного человека, нежели быть священником в колене или в племени Израилевом?
Wọ́n dá a lóhùn pé, “Dákẹ́! Ma sọ nǹkan kan, tẹ̀lé wa kí o sì di baba àti àlùfáà wa. Kò ha sàn fún ọ láti máa ṣe ìránṣẹ́ ẹ̀yà àti ìdílé kan tí ó wá láti Israẹli bí àlùfáà ju ilé ẹnìkan ṣoṣo lọ?”
20 Священник обрадовался, и взял ефод, терафим и истукан и литый кумир, и пошел с народом.
Nígbà náà ni inú àlùfáà náà sì dùn, òun mú efodu náà, àwọn òrìṣà ìdílé mìíràn àti ère fínfín náà, ó sì bá àwọn ènìyàn náà lọ.
21 Они обратились и пошли, и отпустили детей, скот и тяжести вперед.
Wọ́n kó àwọn ọmọdé wọn, àwọn ohun ọ̀sìn wọn àti gbogbo ohun ìní wọn síwájú, wọ́n yípadà wọ́n sì lọ.
22 Когда они удалились от дома Михи, Миха и жители домов соседних с домом Михи собрались и погнались за сынами Дана,
Nígbà tí wọ́n ti rìn jìnnà díẹ̀ sí ilé Mika, àwọn ọkùnrin tí ó wà ní agbègbè Mika kó ara wọn jọ, wọ́n sì lé àwọn ará Dani bá.
23 и кричали сынам Дана. Сыны Дановы оборотились и сказали Михе: что тебе, что ты так кричишь?
Bí wọ́n ṣe ń pariwo tẹ̀lé wọn lẹ́yìn, àwọn ará Dani yípadà wọ́n sì bi Mika pé, “Kí ló ṣe ọ́ tí o fi pe àwọn ọkùnrin rẹ jáde láti jà?”
24 Миха сказал: вы взяли богов моих, которых я сделал, и священника, и ушли; чего еще более? как же вы говорите: что тебе?
Ó dáhùn pé, “Ẹ̀yin kó àwọn ère tí mo ṣe, àti àlùfáà mi lọ. Kí ni ó kù tí mo ní? Báwo ni ẹ̀yin ò ṣe béèrè pé, ‘Kí ló ṣe ọ́?’”
25 Сыны Дановы сказали ему: молчи, чтобы мы не слышали голоса твоего; иначе некоторые из нас, рассердившись, нападут на вас, и ты погубишь себя и семейство твое.
Àwọn ọkùnrin Dani náà dáhùn pé, “Má ṣe bá wa jiyàn, tàbí àwọn oníbìínú fùfù ènìyàn lè kọlù yín, ìwọ àti àwọn ìdílé yóò sì sọ ẹ̀mí yín nù.”
26 И пошли сыны Дановы путем своим; Миха же, видя, что они сильнее его, пошел назад и возвратился в дом свой.
Àwọn ọkùnrin Dani náà sì bá ọ̀nà wọn lọ. Nígbà tí Mika rí í pé wọ́n lágbára púpọ̀ fún òun, ó sì padà sí ilé rẹ̀.
27 А сыны Дановы взяли то, что сделал Миха, и священника, который был у него, и пошли в Лаис, против народа спокойного и беспечного, и побили его мечом, а город сожгли огнем.
Wọ́n sì kó àwọn ohun tí Mika ti ṣe àti àlùfáà rẹ̀, wọ́n sì kọjá lọ sí Laiṣi, ní ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí ó ní ìbàlẹ̀ ọkàn tí wọ́n sì wà ní àlàáfíà. Wọ́n fi ojú idà kọlù wọ́n, wọ́n sì jó ìlú wọn run.
28 Некому было помочь, потому что он был отдален от Сидона и ни с кем не имел дела. Город сей находился в долине, что близ Беф-Рехова. И построили снова город, и поселились в нем,
Kò sì sí ẹnikẹ́ni tí yóò gbà wọ́n sílẹ̀ nítorí pé ibi tí wọ́n ń gbé jìnà sí àwọn ará Sidoni, wọn kò sì ní àṣepọ̀ pẹ̀lú ẹnikẹ́ni. Ìlú náà wà ní inú àfonífojì lẹ́bàá a Beti-Rehobu. Àwọn ará Dani sì tún ìlú náà kọ́, wọ́n sì ń gbé inú rẹ̀.
29 и нарекли имя городу: Дан, по имени отца своего Дана, сына Израилева; а прежде имя города тому было: Лаис.
Wọ́n sọ orúkọ ìlú náà ní Dani gẹ́gẹ́ bí orúkọ baba ńlá wọn Dani, ẹni tí wọ́n bí fún Israẹli: bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Laiṣi ni orúkọ ìlú náà tẹ́lẹ̀ rí.
30 И поставили у себя сыны Дановы истукан; Ионафан же, сын Гирсона, сына Манассии, сам и сыновья его были священниками в колене Дановом до дня переселения жителей той земли;
Àwọn ọmọ Dani sì gbé àwọn ère kalẹ̀ fún ara wọn níbẹ̀; Jonatani ọmọ Gerṣomu, ọmọ Mose, àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni àlùfáà fún àwọn ẹ̀yà Dani títí di àkókò tí a kó ilẹ̀ náà ní ìgbèkùn.
31 и имели у себя истукан, сделанный Михою, во все то время, когда дом Божий находился в Силоме.
Wọ́n tẹ̀síwájú láti lo àwọn ère tí Mika ṣe, ní gbogbo àkókò tí ilé Ọlọ́run wà ní Ṣilo.

< Книга Судей 18 >