< Faptele 11 >

1 Apostolii și frații care erau în Iudeea au auzit că și neamurile au primit cuvântul lui Dumnezeu.
Àwọn aposteli àti àwọn arákùnrin ti ó wà ni Judea sì gbọ́ pé àwọn aláìkọlà pẹ̀lú ti gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
2 După ce Petru s-a suit la Ierusalim, cei care erau din circumcizie s-au certat cu el,
Nígbà tí Peteru sì gòkè wá sí Jerusalẹmu, àwọn ti ìkọlà ń bá a wíjọ́
3 spunând: “Ai intrat la oameni netăiați împrejur și ai mâncat cu ei!”.
wí pé, “Ìwọ wọlé tọ àwọn ènìyàn aláìkọlà lọ, ó sì bá wọn jẹun.”
4 Dar Petru a început și le-a explicat în ordine, zicând:
Ṣùgbọ́n Peteru bẹ̀rẹ̀ sí là á yé wọn lẹ́sẹẹsẹ, wí pé,
5 “Eram în cetatea Iope, rugându-mă, și am avut o vedenie: un vas care se cobora ca un cearșaf mare, care se lăsa din cer prin patru colțuri. A ajuns până la mine.
“Èmi wà ni ìlú Joppa, mo ń gbàdúrà, mo rí ìran kan lójúran. Ohun èlò kan sọ̀kalẹ̀ bí ewé tákàdá ńlá, tí a ti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá; ó sì wá títí de ọ̀dọ̀ mi.
6 După ce m-am uitat cu atenție la el, m-am gândit și am văzut animalele cu patru picioare de pe pământ, animalele sălbatice, târâtoarele și păsările cerului.
Mo tẹjúmọ́ ọn, mo sì fiyèsí i, mo sí rí ẹran ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin, àti ẹranko igbó, àti ohun tí ń rákò, àti ẹyẹ ojú ọ̀run.
7 Am auzit de asemenea un glas care îmi spunea: “Scoală-te, Petru, ucide și mănâncă!”
Mo sì gbọ́ ohùn kan ti ó fọ̀ sí mi pé, ‘Dìde, Peteru: máa pa, kí ó sì máa jẹ.’
8 Dar eu am zis: “Nu așa, Doamne, căci în gura mea nu a intrat niciodată nimic nesfânt sau necurat.
“Ṣùgbọ́n mo dáhùn wí pé, ‘Rara Olúwa! Nítorí ohun èèwọ̀ tàbí ohun aláìmọ́ kan kò wọ ẹnu mi rí láéláé.’
9 Dar un glas mi-a răspuns a doua oară din cer: “Ceea ce Dumnezeu a curățat, tu să nu numești necurat”.
“Ṣùgbọ́n ohùn kan dáhùn nígbà ẹ̀ẹ̀kejì láti ọ̀run wá pé, ‘Ohun tí Ọlọ́run bá ti wẹ̀mọ́, kí ìwọ má ṣe pè é ní àìmọ́.’
10 Aceasta s-a făcut de trei ori și toți au fost trași din nou în cer.
Èyí sì ṣẹlẹ̀ nígbà mẹ́ta; a sì tún fa gbogbo rẹ̀ sókè ọ̀run.
11 Iată că imediat au stat în fața casei în care mă aflam trei bărbați, trimiși de la Cezareea la mine.
“Sì wò ó, lójúkan náà ọkùnrin mẹ́ta dúró níwájú ilé ti a gbé wà, ti a rán láti Kesarea sí mi.
12 Duhul mi-a spus să merg cu ei fără să fac deosebire. M-au însoțit și acești șase frați și am intrat în casa acelui om.
Ẹ̀mí sì wí fún mi pé, kí èmi bá wọn lọ, ki èmi má ṣe kọminú ohunkóhun. Àwọn arákùnrin mẹ́fà wọ̀nyí sì bá mi lọ, a sì wọ ilé ọkùnrin náà.
13 El ne-a povestit cum îl văzuse pe înger stând în casa lui și spunându-i: “Trimite la Iope și adu-l pe Simon, care se numește Petru,
Ó sì sọ fún wa bí òun ti rí angẹli kan tí ó dúró ní ilé rẹ̀, tí ó sì wí pé, ‘Ránṣẹ́ lọ sí Joppa, kí ó sì pe Simoni tí àpèlé rẹ̀ jẹ́ Peteru;
14 care îți va spune cuvintele prin care vei fi mântuit, tu și toată casa ta.
ẹni tí yóò sọ ọ̀rọ̀ fún ọ, nípa èyí tí a ó fi gba ìwọ àti gbogbo ilé rẹ là.’
15 Când am început să vorbesc, Duhul Sfânt a căzut peste ei, ca și peste noi la început.
“Bí mo sì ti bẹ̀rẹ̀ sì sọ, Ẹ̀mí Mímọ́ sì bà lé wọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti bà lé wa ni àtètèkọ́ṣe.
16 Mi-am adus aminte de cuvântul Domnului, cum a spus: 'Ioan a botezat într-adevăr în apă, dar voi veți fi botezați în Duhul Sfânt'.
Nígbà náà ni mo rántí ọ̀rọ̀ Olúwa, bí ó ti wí pé, ‘Johanu fi omi bamitiisi nítòótọ́; ṣùgbọ́n a ó fi Ẹ̀mí Mímọ́ bamitiisi yín.’
17 Dacă deci Dumnezeu le-a dat același dar ca și nouă, când am crezut în Domnul Isus Hristos, cine eram eu, ca să mă împotrivesc lui Dumnezeu?”
Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run sì ti fi irú ẹ̀bùn kan náà fún wọn bí ó ti fi fún àwa pẹ̀lú nígbà tí a gba Jesu Kristi Olúwa gbọ́, ta ni èmi tí n ó fi rò pé mo le è de Ọlọ́run ní ọ̀nà?”
18 Când au auzit acestea, au tăcut și au slăvit pe Dumnezeu, zicând: “Dumnezeu a dat și neamurilor pocăința pentru viață!”
Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, wọ́n sì pa ẹnu wọn mọ́, wọ́n sì yin Ọlọ́run ògo wí pé, “Ǹjẹ́ Ọlọ́run fi ìrònúpìwàdà sí ìyè fún àwọn aláìkọlà pẹ̀lú!”
19 De aceea, cei ce se împrăștiaseră din pricina asupririi lui Ștefan au călătorit până în Fenicia, în Cipru și în Antiohia, și nu au vorbit nimănui decât numai iudeilor.
Nítorí náà àwọn tí a sì túká kiri nípasẹ̀ inúnibíni tí ó dìde ní ti Stefanu, wọ́n rìn títí de Fonisia, àti Saipurọsi, àti Antioku, wọn kò sọ ọ̀rọ̀ náà fún ẹnìkan bí kò ṣe fún kìkì àwọn Júù.
20 Dar au fost unii dintre ei, bărbați din Cipru și din Cirene, care, după ce au ajuns în Antiohia, au vorbit elinilor, propovăduind pe Domnul Isus.
Ṣùgbọ́n àwọn kan ń bẹ nínú wọn tí ó jẹ́ ará Saipurọsi àti Kirene; nígbà tí wọ́n dé Antioku, wọ́n sọ̀rọ̀ fún àwọn Helleni pẹ̀lú, wọ́n ń wàásù ìròyìn ayọ̀ nípa Jesu Olúwa.
21 Mâna Domnului a fost cu ei și un mare număr a crezut și s-a întors la Domnul.
Ọwọ́ Olúwa sì wà pẹ̀lú wọn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sì gbàgbọ́, wọ́n sì yípadà sí Olúwa.
22 Vestea despre ei a ajuns la urechile adunării care era la Ierusalim. Ei l-au trimis pe Barnaba să meargă până la Antiohia,
Ìròyìn nípa wọn sì dé etí ìjọ ti ó wà ni Jerusalẹmu; wọ́n sì rán Barnaba lọ títí dé Antioku;
23 care, după ce a ajuns și a văzut harul lui Dumnezeu, s-a bucurat. El i-a îndemnat pe toți, ca, cu hotărâre de inimă, să rămână aproape de Domnul.
Nígbà ti ó dé ti ó sì rí ẹ̀rí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, ó yọ̀, ó sì gba gbogbo wọn níyànjú pé, pẹ̀lú ìpinnu ọkàn ni kí wọn fi ara mọ́ Olúwa.
24 Căci era un om bun, plin de Duhul Sfânt și de credință, și mulți oameni s-au adăugat la Domnul.
Nítorí òun jẹ́ ènìyàn rere, ó sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ àti fún ìgbàgbọ́; ènìyàn púpọ̀ ni a sì kà kún Olúwa.
25 Barnaba a plecat la Tars, ca să caute pe Saul.
Barnaba sì jáde lọ sí Tarsu láti wá Saulu,
26 După ce l-a găsit, l-a adus la Antiohia. Timp de un an întreg au fost adunați împreună cu adunarea și au învățat mult popor. Discipolii au fost numiți pentru prima dată creștini în Antiohia.
nígbà tí ó sì rí i, ó mú un wá sí Antioku. Fún ọdún kan gbáko ni wọ́n fi ń bá ìjọ péjọpọ̀, tí wọ́n sì kọ́ ènìyàn púpọ̀. Ní Antioku ni a sì kọ́kọ́ ti pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ni “Kristiani.”
27 În zilele acestea, au coborât prooroci din Ierusalim în Antiohia.
Ní ọjọ́ wọ̀nyí ni àwọn wòlíì sì ti Jerusalẹmu sọ̀kalẹ̀ wá sí Antioku.
28 Unul dintre ei, pe nume Agabus, s-a ridicat în picioare și a arătat prin Duhul Sfânt că va fi o mare foamete în toată lumea, ceea ce s-a întâmplat și în zilele lui Claudius.
Nígbà tí ọ̀kan nínú wọn, ti a ń pè ni Agabu sí dìde, ó ti ipa Ẹ̀mí sọ pé, ìyàn ńlá yóò mú yíká gbogbo ilẹ̀ Romu. (Èyí sì ṣẹlẹ̀ nígbà ìṣèjọba Kilaudiu.)
29 Cum vreunul dintre discipoli avea belșug, fiecare a hotărât să trimită ajutoare fraților care locuiau în Iudeea;
Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì pinnu, olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ ti tó, láti rán ìrànlọ́wọ́ sí àwọn arákùnrin tí ó wà ní Judea.
30 ceea ce au și făcut, trimițându-le bătrânilor prin mâna lui Barnaba și a lui Saul.
Wọn sì ṣe bẹ́ẹ̀, wọn sì fi ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí àwọn àgbà láti ọwọ́ Barnaba àti Saulu.

< Faptele 11 >