< Exod 40 >

1 Și DOMNUL i-a vorbit lui Moise, spunând:
Olúwa sì wí fún Mose pé,
2 În prima zi a primei luni ridică tabernacolul cortului întâlnirii.
“Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù kìn-ín-ní ni kí ó gbé àgọ́ náà, àgọ́ àjọ náà ró.
3 Și pune înăuntru chivotul mărturiei și acoperă chivotul cu perdeaua.
Gbé àpótí ẹ̀rí sí inú rẹ̀, kí ó sì bo àpótí náà pẹ̀lú aṣọ títa.
4 Și adu înăuntru masa și așază în ordine lucrurile care trebuie să fie așezate în ordine pe ea; și adu înăuntru sfeșnicul și aprinde-i lămpile.
Gbé tábìlì náà wọ ilé, kí o sì to àwọn ohun tí ó jẹ́ tirẹ̀ lé e lórí. Nígbà náà gbé ọ̀pá fìtílà wọlé, kí o sì to àwọn fìtílà rẹ̀.
5 Și așază altarul din aur pentru tămâie înaintea chivotului mărturiei și pune perdeaua ușii tabernacolului.
Gbé pẹpẹ wúrà ti tùràrí sí iwájú àpótí ẹ̀rí, kí o sì fi aṣọ títa ẹnu-ọ̀nà sí ara àgọ́ náà.
6 Și așază altarul ofrandei arse înaintea ușii tabernacolului cortului întâlnirii.
“Gbé pẹpẹ ẹbọ sísun sí iwájú ẹnu-ọ̀nà àgọ́ náà, àgọ́ àjọ;
7 Și așază ligheanul între cortul întâlnirii și altar și pune apă în el.
gbé agbada sí àárín àgọ́ àjọ àti pẹpẹ, kí o sì fi omi sí inú rẹ̀.
8 Și pune curtea de jur împrejur și atârnă perdeaua la poarta curții.
Gbé àgbàlá ró yìí ka, kí ó sì fi aṣọ títa sí ẹnu-ọ̀nà àgbàlá náà.
9 Și ia untdelemnul pentru ungere și unge tabernacolul și tot ce este în el și sfințește-l și toate vasele lui; și va fi sfânt.
“Mú òróró ìtasórí, kí ó sì ta á sára àgọ́ náà àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀, yà pẹpẹ sí mímọ́ àti gbogbo ọ̀ṣọ́ rẹ̀, yóò sì jẹ́ mímọ́.
10 Și unge altarul ofrandei arse și toate vasele lui și sfințește altarul; și va fi un altar preasfânt.
Ta òróró sára pẹpẹ ẹbọ sísun àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, ya pẹpẹ náà sí mímọ́, yóò sì jẹ́ mímọ́ jùlọ.
11 Și unge ligheanul și piciorul său și sfințește-l.
Ta òróró sára agbada náà àti ẹsẹ̀ rẹ, kí o sì yà wọ́n sí mímọ́.
12 Și adu pe Aaron și pe fiii săi la ușa tabernacolului întâlnirii și spală-i cu apă.
“Mú Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ wá sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ, kí o sì wẹ̀ wọ́n pẹ̀lú omi.
13 Și pune sfintele veșminte peste Aaron și unge-l și sfințește-l, ca el să îmi servească în serviciul de preot.
Nígbà náà wọ Aaroni ní aṣọ mímọ́, ta òróró sí i ní orí, kí o sì yà á sí mímọ́, nítorí kí ó lè máa sìn mi bí àlùfáà.
14 Și adu pe fiii săi și îmbracă-i cu haine;
Mú àwọn ọmọ rẹ̀ kí o sì fi aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀ wọ́n.
15 Și unge-i, precum ai uns pe tatăl lor, ca ei să îmi servească în serviciul de preot, pentru că ungerea lor va fi cu adevărat o preoție veșnică prin toate generațiile.
Ta òróró sí wọn ní orí gẹ́gẹ́ bí o ti ta òróró sí baba wọn ní orí, nítorí kì wọn lè máa sìn mi bí àlùfáà. Ìtasórí wọn yóò jẹ́ iṣẹ́ àlùfáà ti yóò máa lò fún gbogbo ìrandíran tó ń bọ̀.”
16 Astfel a făcut Moise, conform cu tot ceea ce DOMNUL i-a poruncit, așa a făcut el.
Mose ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún un.
17 Și s-a întâmplat, în prima lună, în al doilea an, în prima zi a lunii, că tabernacolul a fost înălțat.
Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbé àgọ́ náà ró ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kìn-ín-ní ní ọdún kejì.
18 Și Moise a ridicat tabernacolul și a fixat soclurile acestuia și a așezat scândurile lui și i-a pus drugii și i-a înălțat stâlpii.
Nígbà tí Mose gbé àgọ́ náà ró ó fi ihò ìtẹ̀bọ̀ sí ààyè rẹ̀, ó to pákó rẹ̀, ó fi ọ̀pá rẹ̀ bọ̀ ọ́, ó sì gbé àwọn òpó rẹ̀ ró.
19 Și a întins cortul peste tabernacol și a pus acoperământul cortului deasupra acestuia, precum DOMNUL i-a poruncit lui Moise.
Ó na aṣọ àgọ́ náà sórí àgọ́, ó sì fi ìbòrí bo orí àgọ́ náà, bí Olúwa ṣe pàṣẹ fún Mose.
20 Și a luat și a pus mărturia în chivot și a pus drugii la chivot și a pus șezământul milei deasupra, peste chivot.
Ó mu ẹ̀rí, ó sì fi sínú àpótí, ó so àwọn òpó mọ́ àpótí náà, ó sì fi àánú bo orí rẹ.
21 Și a adus chivotul în tabernacol și a pus perdeaua acoperământului și a acoperit chivotul mărturiei, precum DOMNUL a poruncit lui Moise.
Ó sì gbé àpótí náà wá sínú àgọ́; ó sì sọ aṣọ títa, ó sì ta á bo àpótí ẹ̀rí, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.
22 Și a pus masa în cortul întâlnirii, pe partea tabernacolului spre nord, dincoace de perdea.
Mose gbé tábìlì sínú àgọ́ àjọ sí ìhà àríwá àgọ́ náà lẹ́yìn aṣọ títa,
23 Și a pus pâinea prezentării în ordine pe aceasta înaintea DOMNULUI, precum DOMNUL i-a poruncit lui Moise.
ó sì to àkàrà sórí rẹ̀ níwájú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.
24 Și a pus sfeșnicul în cortul întâlnirii, lângă masă, pe partea tabernacolului spre sud.
Ó gbé ọ̀pá fìtílà sínú àgọ́ àjọ ní òdìkejì tábìlì ní ìhà gúúsù àgọ́ náà.
25 Și a aprins lămpile înaintea DOMNULUI, precum DOMNUL i-a poruncit lui Moise.
Ó sì tan àwọn fìtílà náà níwájú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.
26 Și a pus altarul din aur în cortul întâlnirii înaintea perdelei;
Mose gbé pẹpẹ wúrà sínú àgọ́ àjọ níwájú aṣọ títa
27 Și a ars tămâie dulce pe acesta, precum DOMNUL i-a poruncit lui Moise.
ó sì jó tùràrí dídùn lórí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.
28 Și a pus perdeaua la ușa tabernacolului.
Ó sì ta aṣọ títa sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ náà.
29 Și a pus altarul ofrandei arse la ușa tabernacolului cortului întâlnirii și a oferit pe acesta ofranda arsă și darul de mâncare, precum DOMNUL i-a poruncit lui Moise.
Ó gbé pẹpẹ ẹbọ sísun sí ẹ̀gbẹ́ ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ, ó sì rú ẹbọ sísun àti ẹbọ oúnjẹ, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.
30 Și a așezat ligheanul între cortul întâlnirii și altar și a pus apă acolo pentru spălare.
Ó gbé agbada sí àárín àgọ́ àjọ àti pẹpẹ, ó sì pọn omi sínú rẹ̀ fún wíwẹ̀,
31 Și Moise și Aaron și fiii săi și-au spălat mâinile și picioarele acolo;
Mose, Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ lò ó láti fi wẹ ọwọ́ àti ẹsẹ̀ wọn.
32 Când au intrat în cortul întâlnirii și când s-au apropiat de altar, s-au spălat, precum DOMNUL i-a poruncit lui Moise.
Wọ́n máa ń wẹ̀ nígbàkígbà tí wọ́n bá wọ àgọ́ àjọ tàbí tí wọ́n bá súnmọ́ pẹpẹ, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.
33 Și a înălțat curtea de jur împrejurul tabernacolului și altarului și a atârnat perdeaua porții curții. Astfel Moise a terminat lucrarea.
Mose sì gbé àgbàlá tí ó yí àgọ́ náà kà ró àti pẹpẹ, ó sì ta aṣọ títa ti ẹnu-ọ̀nà sí àgbàlá náà. Bẹ́ẹ̀ ni Mose ṣe parí iṣẹ́ náà.
34 Atunci un nor a acoperit cortul întâlnirii și gloria DOMNULUI a umplut tabernacolul.
Nígbà náà ni àwọsánmọ̀ bo àgọ́ àjọ, ògo Olúwa bo àgọ́ náà.
35 Și Moise nu a fost în stare să intre în cortul întâlnirii, deoarece norul a rămas peste el și gloria DOMNULUI a umplut tabernacolul.
Mose kò sì lè wọ inú àgọ́ àjọ, nítorí àwọsánmọ̀ wà ní orí àgọ́, ògo Olúwa sì ti kún inú àgọ́ náà.
36 Și după ce norul s-a ridicat de pe tabernacol, copiii lui Israel au mers înainte în toate călătoriile lor;
Ní gbogbo ìrìnàjò àwọn ọmọ Israẹli nígbàkígbà tí a bá ti fa ìkùùkuu àwọsánmọ̀ náà sókè kúrò lórí àgọ́, wọ́n máa ń jáde lọ;
37 Dar dacă norul nu s-a ridicat, nu au călătorit până în ziua în care acesta s-a ridicat.
ṣùgbọ́n tí àwọsánmọ̀ kò bá gòkè wọn kò ní jáde títí di ọjọ́ tí ó bá gòkè.
38 Căci norul DOMNULUI era peste tabernacol în timpul zilei și foc era peste el în timpul nopții, înaintea ochilor întregii case a lui Israel, prin toate călătoriile lor.
Nítorí náà àwọsánmọ̀ Olúwa wà lórí àgọ́ ní ọ̀sán, iná sì wà nínú àwọsánmọ̀ ní alẹ́, ní ojú gbogbo ilé Israẹli ní gbogbo ìrìnàjò wọn.

< Exod 40 >