< Hebrajczyków 2 >
1 Przetoż musimy tem pilniej przestrzegać tego, cośmy słyszeli, byśmy snać nie przeciekli.
Nítorí náà, ó yẹ kí àwa máa fi iyè sí àwọn nǹkan wọ̀n-ọn-nì gidigidi tí àwa ti gbọ́, kí a má ba à gbá wa lọ kúrò nínú wọn nígbà kan.
2 Bo ponieważ przez Anioły mówione słowo było pewne, a każde przestępstwo i nieposłuszeństwo wzięło sprawiedliwą zapłatę pomsty:
Nítorí bí ọ̀rọ̀ tí a tí ẹnu àwọn angẹli sọ bá sì dúró ṣinṣin, àti tí olúkúlùkù ẹ̀ṣẹ̀ sí òfin àti àìgbọ́ràn gba ìjìyà tí ó tọ́ sí i,
3 Jakoż my ucieczemy, jeźli zaniedbamy tak wielkiego zbawienia, które wziąwszy początek opowiadania przez samego Pana od tych, którzy go słyszeli, nam jest potwierdzone?
kín ni ohun náà tí ó mú wa lérò pé a lè bọ́ kúrò nínú ìjìyà bí a kò bá náání ìgbàlà ńlá yìí? Ìgbàlà tí Olúwa fúnra rẹ̀ kọ́kọ́ kéde, èyí tí a sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ fún wa láti ọwọ́ àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà lẹ́nu rẹ̀.
4 Którym i Bóg świadectwo wydawał przez znamiona i cuda, i rozliczne mocy, i przez udzielanie Ducha Świętego według woli swojej.
Ọlọ́run jẹ́rìí sí i nípa àwọn iṣẹ́ àmì àti ìyanu àti oríṣìíríṣìí iṣẹ́ agbára àti nípa ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ tí a pín gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀.
5 Albowiem nie Aniołom poddał świat przyszły, o którym mówimy.
Nítorí pé, kì í ṣe abẹ́ ìṣàkóso àwọn angẹli ni ó fi ayé tí ń bọ̀, tí àwa ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ sí.
6 A świadczył ktoś na niektórem miejscu, mówiąc: Cóż jest człowiek, iż nań pamiętasz, albo syn człowieczy, iż go nawiedzasz?
Ṣùgbọ́n ibìkan wà tí ẹnìkan tí jẹ́rìí pé “Kí ni ènìyàn tí ìwọ fi ń ṣe ìrántí rẹ̀, tàbí ọmọ ènìyàn, tí ìwọ fi ń bẹ̀ ẹ́ wò?
7 Na małą chwilę mniejszym uczyniłeś go od Aniołów, chwałą i czcią ukoronowałeś go i postanowiłeś go nad uczynkami rąk twoich,
Ìwọ dá a ní onírẹ̀lẹ̀ díẹ̀ ju àwọn angẹli lọ; ìwọ fi ògo àti ọlá de e ni adé, ìwọ sì fi í jẹ olórí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ,
8 Wszystkoś poddał pod nogi jego. A poddawszy mu wszystko, nic nie zostawił, co by mu poddanego nie było; lecz teraz jeszcze nie widzimy, aby mu wszystko poddane było.
Ìwọ fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.” Ní ti fífi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n àwa kò ì tí ì rí ohun kan tí ó kù tí kò sí ní abẹ́ àkóso rẹ̀. Síbẹ̀ nísinsin yìí àwa kò ì tí ì rí pé ó fi ohun gbogbo sábẹ́ ìṣàkóso rẹ̀.
9 Ale tego, który na małą chwilę mniejszym stał się od Aniołów, Jezusa, widzimy przez ucierpienie śmierci chwałą i czcią ukoronowanego, aby z łaski Bożej za wszystkich śmierci skosztował.
Ṣùgbọ́n àwa rí Jesu ẹni tí a rẹ̀ sílẹ̀ díẹ̀ ju àwọn angẹli lọ fún àkókò díẹ̀, àní Jesu, ẹni tí a fi ògo àti ọlá dé ní adé nítorí ìjìyà wa; kí ó lè tọ́ ikú wò fún olúkúlùkù ènìyàn nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.
10 Albowiem należało na tego, dla którego jest wszystko i przez którego jest wszystko, aby wiele synów do chwały przywodząc wodza zbawienia ich przez ucierpienie doskonałym uczynił.
Nítorí pé ó yẹ fún Ọlọ́run, nítorí nípasẹ̀ ẹni tí ohun gbogbo ṣẹ̀ wà, láti mú àwọn ọmọ púpọ̀ wá sínú ògo, láti ṣe balógun ìgbàlà wọn ni àṣepé nípa ìjìyà.
11 Bo ten, który poświęca i ci, którzy bywają poświęceni, z jednego są wszyscy, dla której przyczyny nie wstydzi się ich braćmi nazywać,
Nítorí àti ẹni tí ń sọ ni di mímọ́ àti àwọn tí a ń sọ di mímọ́, láti ọ̀dọ̀ ẹnìkan ṣoṣo ni gbogbo wọn ti wá, nítorí èyí ni kò ṣe tijú láti pè wọ́n ni arákùnrin.
12 Mówiąc: Opowiem imię twoje braciom moim, w pośrodku zgromadzenia śpiewać ci będę.
Àti wí pé, “Èmi ó sọ̀rọ̀ orúkọ rẹ̀ fún àwọn ará mi, ni àárín ìjọ ni èmi yóò kọrin ìyìn rẹ̀.”
13 I zasię: Ja w nim ufać będę; a zasię: Oto ja i dzieci, które mi dał Bóg.
Àti pẹ̀lú, “Èmi yóò gbẹ́kẹ̀ mi lé e.” Àti pẹ̀lú, “Kíyèsi í, èmi rèé, èmi àti àwọn ọmọ tí Ọlọ́run fi fún mi.”
14 Ponieważ tedy dzieci społeczność mają ciała i krwi, i on także stał się ich uczestnikiem, aby przez śmierć zniszczył tego, który miał władzę śmierci, to jest dyjabła,
Ǹjẹ́ ni ìwọ̀n bí àwọn ọmọ tí ṣe alábápín ará àti ẹ̀jẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni òun pẹ̀lú sì ṣe alábápín nínú ohun kan náà; kí ó lè ti ipa ikú rẹ̀ pa ẹni tí ó ní agbára ikú run, èyí ni èṣù.
15 A iżby wyswobodził tych, którzy dla bojaźni śmierci po wszystek czas żywota podlegli byli niewoli.
Kí o sì lè gba gbogbo àwọn tí ó tìtorí ìbẹ̀rù ikú wà lábẹ́ ìdè lọ́jọ́ ayé wọn gbogbo kúrò lọ́wọ́ ìbẹ̀rù.
16 Bo zaiste nigdzie nie przyjął Aniołów, ale nasienie Abrahamowe przyjął.
Nítorí pé, nítòótọ́, kì í ṣe àwọn angẹli ni ó ṣe ìrànlọ́wọ́ fún, ṣùgbọ́n àwọn irú-ọmọ Abrahamu ni ó ṣe ìrànlọ́wọ́ fún.
17 Skąd miał być we wszystkiem podobny braciom, aby był miłosiernym i wiernym najwyższym kapłanem w tem, co się u Boga na ubłaganie za grzechy ludzkie dziać miało.
Nítorí náà, ó yẹ pé nínú ohun gbogbo kí ó dàbí àwọn ará rẹ̀, kí ó lè jẹ́ aláàánú àti olóòtítọ́ alábojútó Àlùfáà nínú ohun tí i ṣe ti Ọlọ́run, kí o lè ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn.
18 Albowiem że sam cierpiał będąc kuszony, może tych, którzy są w pokusach, ratować.
Nítorí níwọ̀n bí òun tìkára rẹ̀ ti jìyà tí a sì ti dán an wò, òun ní agbára láti ran àwọn tí a ń dánwò lọ́wọ́.