< Salomos Høisang 2 >
1 «Ein engblom frå Saron er eg, ei lilja frå dalom.»
Èmi ni ìtànná Ṣaroni bí ìtànná lílì àwọn àfonífojì.
2 «Ja, som ei lilja i klunger-holt millom møyar min hugnad er.»
Bí ìtànná lílì ní àárín ẹ̀gún ni olólùfẹ́ mi ní àárín àwọn wúńdíá.
3 «Liksom ein apall, i skogen stend er venen min millom sveinar. Eg sitje so ljuvt i skuggen hans, og søt er frukti i munn.
Bí igi ápù láàrín àwọn igi inú igbó, ni olólùfẹ́ mí láàrín àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin. Mo fi ayọ̀ jókòó ní abẹ́ òjìji rẹ̀, èso rẹ̀ sì dùn mọ́ mi ní ẹnu.
4 Inn i vinhuset hev han meg ført, og hans merke yver meg det er kjærleik.
Ó mú mi lọ sí ibi gbọ̀ngàn àsè, ìfẹ́ sì ni ọ̀págun rẹ̀ lórí mi.
5 Å, styrk meg med druvekakor, med eple meg kveik! For eg er sjuk av kjærleik.
Fi agbára adùn àkàrà dá mi dúró. Fi èso ápù tù mi lára nítorí àìsàn ìfẹ́ ń ṣe mí.
6 Hans vinstre hand er under mitt hovud, med den høgre femner han meg.
Ọwọ́ òsì rẹ ń bẹ lábẹ́ orí mi ọwọ́ ọ̀tún rẹ sì ń gbà mí mọ́ra.
7 Eg hjarteleg bed dykk, Jerusalems døtter, ved gasellor og hindar i skog, at ikkje de vekkje eller eggje kjærleik, fyrr sjølv han so vil!»
Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu, mo fi abo egbin àti ọmọ àgbọ̀nrín fi yín bú kí ẹ má ṣe ru ìfẹ́ olùfẹ́ mi sókè kí ẹ má sì ṣe jí i títí yóò fi wù ú.
8 «Høyr! Min ven! Sjå der, han kjem! Yver fjelli, sjå, han sprett, yver haugarne han renn.
Gbọ́ ohùn olùfẹ́ mi! Wò ó! Ibí yìí ni ó ń bọ̀. Òun ń fò lórí àwọn òkè ńlá, òun bẹ́ lórí àwọn òkè kéékèèké.
9 Min ven ei gasella er lik eller som ungan hjort. Sjå der! No han stend attum vår vegg. Gjenom glyttom ser han inn.
Olùfẹ́ mi dàbí abo egbin tàbí ọmọ àgbọ̀nrín. Wò ó! Níbẹ̀ ni ó wà lẹ́yìn ògiri wa Ó yọjú ní ojú fèrèsé Ó ń fi ara rẹ̀ hàn lójú fèrèsé ọlọ́nà.
10 Han tek til min ven å tala til meg: «Du, min hugnad, statt upp, du, mi fagre, kom ut!
Olùfẹ́ mi fọhùn ó sì sọ fún mi pé, “Dìde, Olólùfẹ́ mi, arẹwà mi, kí o sì wà pẹ̀lú mi.
11 For sjå, no er vinteren slutt, regnet hev kvorve burt.
Wò ó! Ìgbà òtútù ti kọjá; òjò ti rọ̀ dawọ́, ó sì ti lọ.
12 Du ser blomarne sprett utpå voll. D’er det bilet dei vintrei skjer, og turtelduva ho syng i vårt land.
Àwọn òdòdó fi ara hàn lórí ilẹ̀ àsìkò ìkọrin àwọn ẹyẹ dé a sì gbọ́ ohùn àdàbà ní ilẹ̀ wa.
13 Fiketreet skyt frukt, vintrei stend alt i blom med angande dåm, du, min hugnad, statt upp, du, mi fagre, kom!
Igi ọ̀pọ̀tọ́ mú èso tuntun jáde, àwọn àjàrà nípa ìtànná wọ́n fún ni ní òórùn dídùn. Dìde, wá, Olólùfẹ́ mi, Arẹwà mi nìkan ṣoṣo, wá pẹ̀lú mi.”
14 Du, mi duva, i bergeskard, som i fjellveggen sit, lat ditt andlit meg sjå, lat meg høyra ditt mål, for ditt mål er so ljuvt, og ditt andlit so vænt.»
Àdàbà mi wà nínú pàlàpálá òkúta, ní ibi ìkọ̀kọ̀ ní orí òkè gíga, fi ojú rẹ hàn mí, jẹ́ kí èmi gbọ́ ohùn rẹ; nítorí tí ohùn rẹ dùn, tí ojú rẹ sì ní ẹwà.
15 «Fare av og revarne slå, dei revarne små, som i hagom mun gå, for hagarne no, dei tek til å gro.»
Bá wa mú àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀, àní àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ kéékèèké tí ń ba ọgbà àjàrà jẹ́, àwọn ọgbà àjàrà wa tó ní ìtànná.
16 Min ven er min, og eg er hans, han som gjæter millom liljor.»
Olùfẹ́ mi ni tèmi èmi sì ni tirẹ̀; Ó ń jẹ láàrín àwọn koríko lílì.
17 «Skrid du, min ven, til dagen vert sval, og skuggarne flyr, ei gasella lik eller ungan hjort uppi skardefjellom.»
Títí ìgbà ìtura ọjọ́ títí òjìji yóò fi fò lọ, yípadà, olùfẹ́ mi, kí o sì dàbí abo egbin tàbí ọmọ àgbọ̀nrín lórí òkè Beteri.