< 1 Samuels 5 >

1 Filistrene tok Guds ark og førte den fra Eben-Eser til Asdod.
Lẹ́yìn ìgbà tí àwọn Filistini ti gba àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run lọ, wọ́n gbé e láti Ebeneseri sí Aṣdodu.
2 Der tok filistrene Guds ark og førte den inn i Dagons hus og stilte den op ved siden av Dagon.
Nígbà tí àwọn Filistini gbé àpótí Ọlọ́run náà lọ sí tẹmpili Dagoni, wọ́n gbé e kalẹ̀ sí ẹ̀bá Dagoni.
3 Tidlig den følgende dag fikk asdodittene se at Dagon var falt ned med ansiktet mot jorden foran Herrens ark; og de tok Dagon og satte ham igjen på hans plass.
Nígbà tí àwọn ará Aṣdodu jí ní òwúrọ̀ kùtùkùtù ní ọjọ́ kejì, Dagoni ṣubú, ó dojúbolẹ̀ níwájú àpótí Olúwa, wọ́n sì gbé Dagoni, wọ́n tún fi sí ààyè rẹ̀.
4 Men tidlig om morgenen den næste dag fikk de se at Dagon var falt ned med ansiktet mot jorden foran Herrens ark, og at Dagons hode og begge hans hender lå avhugget på dørtreskelen; bare kroppen var tilbake av Dagon.
Ṣùgbọ́n ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì nígbà tí wọ́n dìde, Dagoni ṣì wá, ó ṣubú ó dojúbolẹ̀ níwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa. Orí àti ọwọ́ rẹ̀ sì ti gé kúrò, ó sì dùbúlẹ̀ ní orí ìloro ẹnu-ọ̀nà, ara rẹ̀ nìkan ni ó kù.
5 Derfor er det at Dagons prester og alle som går inn i Dagons hus, like til denne dag ikke treder på Dagons dørtreskel i Asdod.
Ìdí nìyìí títí di òní tí ó fi jẹ́ pé àlùfáà Dagoni tàbí àwọn mìíràn tí ó wọ inú tẹmpili Dagoni ní Aṣdodu fi ń tẹ orí ìloro ẹnu-ọ̀nà.
6 Og Herrens hånd lå tungt på asdodittene, og han ødela dem og slo dem med bylder, både i Asdod selv og i de omliggende bygder.
Ọwọ́ Olúwa wúwo lára àwọn ènìyàn Aṣdodu àti gbogbo agbègbè rẹ̀: ó mú ìparun wá sórí wọn, ó sì pọ́n wọn lójú pẹ̀lú ààrùn oníkókó.
7 Da Asdods menn så at det gikk således, sa de: Israels Guds ark skal ikke bli hos oss; for hans hånd ligger hårdt på oss og på Dagon vår gud.
Nígbà tí àwọn ọkùnrin Aṣdodu rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, wọ́n wí pé, “Àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run ti Israẹli kò gbọdọ̀ dúró níbí yìí pẹ̀lú wa, nítorí ọwọ́ rẹ̀ wúwo lára wa àti lára Dagoni ọlọ́run wá.”
8 Og de sendte bud og samlet alle filistrenes høvdinger hos sig og sa: Hvad skal vi gjøre med Israels Guds ark? De svarte: La Israels Guds ark bli flyttet til Gat! Så flyttet de Israels Guds ark dit.
Nígbà náà ni wọ́n pè gbogbo àwọn olórí Filistini jọ wọ́n sì bi wọ́n pé, “Kí ni a ó ṣe pẹ̀lú àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run àwọn Israẹli?” Wọ́n dáhùn pé, “Ẹ jẹ́ kí á gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run àwọn Israẹli lọ sí Gati.” Wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run Israẹli.
9 Men efterat de hadde flyttet den dit, kom Herrens hånd over byen og voldte stor forferdelse, og han slo byens folk, både små og store, så det brøt bylder ut på dem.
Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti gbé e, ọwọ́ Olúwa sì wá sí ìlú náà, ó mú jìnnìjìnnì bá wọn. Ó sì pọ́n àwọn ènìyàn ìlú náà lójú, ọmọdé àti àgbà, pẹ̀lú àjàkálẹ̀-ààrùn oníkókó.
10 Da sendte de Guds ark til Ekron. Men da Guds ark kom til Ekron, da skrek ekronittene: De har flyttet Israels Guds ark hit til mig for å drepe mig og mitt folk.
Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run lọ sí Ekroni. Bí àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run ṣe wọ Ekroni, àwọn ará Ekroni fi igbe ta pé, “Wọ́n ti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run Israẹli tọ̀ wá wá láti pa wá àti àwọn ènìyàn wa.”
11 Og de sendte bud og samlet alle filistrenes høvdinger og sa: Send Israels Guds ark bort, og la den komme tilbake til sin plass, så den ikke skal drepe mig og mitt folk! For det var kommet en dødsens forferdelse over hele byen; Herrens hånd lå meget tungt på den.
Nígbà náà ni wọ́n pe gbogbo àwọn olórí àwọn Filistini jọ wọ́n sì wí pé, “Ẹ gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run àwọn Israẹli lọ: ẹ jẹ́ kí ó padà sí ààyè rẹ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ yóò pa wá àti àwọn ènìyàn wa.” Ikú ti mú jìnnìjìnnì bá àwọn ará ìlú, ọwọ́ Ọlọ́run sì wúwo lára wọn.
12 De menn som ikke døde, blev slått med bylder, og skriket fra byen steg op til himmelen.
Àwọn tí kò kú wọ́n pọ́n wọn lójú pẹ̀lú ààrùn oníkókó, ẹkún ìlú náà sì gòkè lọ sí ọ̀run.

< 1 Samuels 5 >