< Otra Samuela 11 >

1 Un kad gads bija pagājis, ap to laiku, kad ķēniņi mēdz iziet, tad Dāvids sūtīja Joabu un savus kalpus viņam līdz un visu Israēli, un tie postīja Amona bērnus un apmetās pret Rabu; bet Dāvids palika Jeruzālemē.
Lẹ́yìn ìgbà tí ọdún yípo, ní àkókò ìgbà tí àwọn ọba máa ń jáde ogun, Dafidi sì rán Joabu, àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, àti gbogbo Israẹli; wọ́n sì pa àwọn ọmọ Ammoni, wọ́n sì dó ti Rabba. Dafidi sì jókòó ní Jerusalẹmu.
2 Un notikās ap vakara laiku, ka Dāvids cēlās no savas gultas un staigāja pa ķēniņa nama jumtu un redzēja no jumta sievu mazgājamies, un šī sieva bija ļoti skaista no skata.
Ó sì ṣe, ní ìgbà àṣálẹ́ kan, Dafidi sì dìde ní ibùsùn rẹ̀, ó sì ń rìn lórí òrùlé ilé ọba, láti orí òrùlé náà ni ó sì rí obìnrin kan tí ó ń wẹ̀ ara rẹ̀; obìnrin náà sì ṣe arẹwà lójú láti wò.
3 Un Dāvids nosūtīja un lika vaicāt pēc tās sievas; tad sacīja: tā ir Batseba, Elijama meita, Hetieša Ūrijas sieva.
Dafidi sì ránṣẹ́ ó sì béèrè obìnrin náà. Ẹnìkan sì wí pé, “Èyí ha kọ́ ni Batṣeba, ọmọbìnrin Eliamu, aya Uriah ará Hiti.”
4 Tad Dāvids sūtīja vēstnešus un to lika atvest, un tā nāca pie viņa un viņš pie tās gulēja, un kad viņa no savas nešķīstības bija šķīstījusies, tad viņa atkal gāja mājās.
Dafidi sì rán àwọn ìránṣẹ́, ó sì mú un; ó sì wọ inú ilé tọ̀ ọ́ lọ, ó sì bá a dàpọ̀, nígbà tí ó sì wẹ ara rẹ̀ mọ́ tán, ó sì padà lọ sí ilé rẹ̀.
5 Un tā sieva tapa grūta. Tad viņa nosūtīja un deva Dāvidam ziņu un sacīja: es esmu grūta.
Obìnrin náà sì lóyún, ó sì ránṣẹ́ ó sì sọ fún Dafidi, ó sì wí pé, “Èmi ti lóyún.”
6 Tad Dāvids sūtīja pie Joaba sacīdams: sūti to Etieti Ūriju pie manis. Un Joabs sūtīja Ūriju pie Dāvida.
Dafidi sì ránṣẹ́ sí Joabu, pé, “Rán Uriah ará Hiti sí mi.” Joabu sì rán Uriah sí Dafidi.
7 Kad nu Ūrija pie viņa atnāca, tad Dāvids vaicāja: kā iet Joabam, kā iet ļaudīm un kā iet karā.
Nígbà tí Uriah sì dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, Dafidi sì bi í léèrè báwo ni Joabu ti ṣe àti àlàáfíà àwọn ènìyàn náà, àti bí ogun náà ti ń ṣe.
8 Un Dāvids sacīja uz Ūriju: noej savā namā un mazgā savas kājas. Un kad Ūrija no ķēniņa nama izgāja, tad viņam ķēniņa dāvanas tapa nestas pakaļ.
Dafidi sì wí fún Uriah pé, “Sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ, kí o sì wẹ ẹsẹ̀ rẹ.” Uriah sì jáde kúrò ní ilé ọba, oúnjẹ láti ọ̀dọ̀ ọba wá sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.
9 Bet Ūrija apgūlās priekš ķēniņa nama durvīm ar visiem sava kunga kalpiem un negāja mājās.
Ṣùgbọ́n Uriah sun ní ẹnu-ọ̀nà ilé ọba lọ́dọ̀ gbogbo ìránṣẹ́ olúwa rẹ̀, kò sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ̀.
10 Un Dāvidam deva ziņu un sacīja: Ūrija nav gājis uz mājām. Tad Dāvids sacīja uz Ūriju: Vai tu nenāci no ceļa? Kāpēc tu nenoej savā namā?
Nígbà tí wọ́n sì sọ fún Dafidi pé, “Uriah kò sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ̀,” Dafidi sì wí fún Uriah pé, “Ṣe bí ọ̀nà àjò ni ìwọ ti wá? Èéha ti ṣe tí ìwọ kò fi sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ.”
11 Un Ūrija sacīja uz Dāvidu: Dieva šķirsts un Israēls un Jūda paliek teltīs, un mans kungs Joabs un mana kunga kalpi mīt laukā; vai tad es ietu mājās ēst un dzert un pie savas sievas gulēt? Tik tiešām kā tu dzīvs un tava dvēsele dzīva, es to nedarīšu.
Uriah sì wí fún Dafidi pé, “Àpótí ẹ̀rí, àti Israẹli, àti Juda jókòó nínú àgọ́; àti Joabu olúwa mi, àti àwọn ìránṣẹ́ olúwa mi wà ní ibùdó ní pápá, èmi ó ha lọ sí ilé mi, láti jẹ àti láti mu, àti láti bá obìnrin mi sùn? Bí ìwọ bá wà láààyè, àti bí ẹ̀mí rẹ́ si ti ń bẹ láààyè, èmi kì yóò ṣe nǹkan yìí.”
12 Tad Dāvids sacīja uz Ūriju: paliec arī šodien šeitan, tad es tev rītu atlaidīšu. Tā Ūrija palika Jeruzālemē šo un otru dienu.
Dafidi sì wí fún Uriah pé, “Sì dúró níhìn-ín lónìí, lọ́la èmi ó sì jẹ́ kí ìwọ ó lọ.” Uriah sì dúró ní Jerusalẹmu ní ọjọ́ náà, àti ọjọ́ kejì.
13 Un Dāvids to aicināja, ka tas viņa priekšā ēda un dzēra, un viņš to piedzirdināja. Un vakarā viņš izgāja apgulties savās cisās ar sava kunga kalpiem, un viņš nenogāja mājās.
Dafidi sì pè é, ó sì jẹ, ó sì mú nítorí rẹ̀; ó sì mu kí ọtí pa á; òun sì jáde ní alẹ́ lọ sí ibùsùn rẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ olúwa rẹ̀, kò sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ̀.
14 Un otrā rītā Dāvids rakstīja grāmatu Joabam un to sūtīja caur Ūriju.
Ó sì ṣe ní òwúrọ̀, Dafidi sì kọ̀wé sí Joabu, ó fi rán Uriah.
15 Un tai grāmatā viņš tā bija rakstījis: nostādiet Ūriju tai vietā, kur tā visgrūtākā kaušanās, un novēršaties aiz viņa, ka viņš top kauts un mirst.
Ó sì kọ sínú ìwé pé, “Fi Uriah síwájú ibi tí ogun gbé le, kí ẹ sì fàsẹ́yìn, kí wọn lè kọlù ú, kí ó sì kú.”
16 Un notikās, kad Joabs to pilsētu aplenca, tad viņš nostādīja Ūriju tādā vietā, kur viņš zināja, ka tur bija stipri vīri.
Ó sì ṣe nígbà tí Joabu ṣe àkíyèsí ìlú náà, ó sì yan Uriah sí ibi kàn ní ibi tí òun mọ̀ pé àwọn alágbára ọkùnrin ń bẹ níbẹ̀.
17 Kad nu pilsētas vīri izgāja un ar Joabu kāvās, tad krita kādi no tiem ļaudīm, no Dāvida kalpiem, un Etietis Ūrija arī nomira.
Àwọn ọkùnrin ìlú náà sì jáde wá, wọ́n sì bá Joabu jà, díẹ̀ sì ṣubú nínú àwọn ènìyàn náà nínú àwọn ìránṣẹ́ Dafidi, Uriah ará Hiti sì kú pẹ̀lú.
18 Tad Joabs sūtīja un deva Dāvidam ziņu par visām karalietām.
Joabu sì ránṣẹ́ ó sì ro gbogbo nǹkan ogun náà fún Dafidi.
19 Un viņš pavēlēja tam vēstnesim un sacīja: kad tu būsi ķēniņam izstāstījis visas karalietas,
Ó sì pàṣẹ fún ìránṣẹ́ náà pé, “Nígbà tí ìwọ bá sì parí àti máa ro gbogbo nǹkan ogun náà fún ọba.
20 Un ķēniņam dusmas celsies un viņš uz tevi sacīs: kāpēc jūs tik tuvu pie pilsētas esat gājuši kauties? Vai jūs nezinājāt, ka no mūra šaus?
Bí ó bá ṣe pé, ìbínú ọba bá ru, ti òun sì wí fún ọ pé, ‘Èéṣe tí ẹ̀yin fi súnmọ́ ìlú náà láti bá wọn jà, ẹ̀yin kò mọ̀ pé wọn ó tafà láti orí odi wá.
21 Kas Abimeleku, JerubBezeta dēlu, ir nokāvis? Vai sieva uz viņu nemeta dzirnu akmeni no mūra, ka tas Tebecā nomira? Kāpēc esat gājuši tik tuvu pie mūra? Tad saki: tavs kalps Ūrija, tas Etietis, arīdzan nomiris.
Ta ni ó pa Abimeleki ọmọ Jerubu-Beṣeti? Kì í ṣe obìnrin ni ó yí òkúta-ọlọ lù ú láti orí odi wá, tí ó sì kú ní Tebesi? Èéha ti rí tí ẹ̀yin fi súnmọ́ odi náà? Ìwọ yóò sì wí fún un pé, Uriah ìránṣẹ́ rẹ ará Hiti kú pẹ̀lú.’”
22 Un tas vēstnesis nogāja un nāca un stāstīja Dāvidam visu, par ko Joabs viņu bija sūtījis.
Ìránṣẹ́ náà sì lọ, ó sì wá, ó sì jẹ́ gbogbo iṣẹ́ tí Joabu rán an fún Dafidi.
23 Un tas vēstnesis sacīja uz Dāvidu: tie vīri bija stiprāki nekā mēs, un iznāca pret mums laukā, bet mēs viņiem pretī turējāmies līdz pat vārtu durvīm.
Ìránṣẹ́ náà sì wí fún Dafidi pé, “Nítòótọ́ àwọn ọkùnrin náà lágbára jù wá lọ, wọ́n sì jáde tọ̀ wá wá ní pápá, àwa sì tẹ̀lé wọn títí wọ́n fi dé ẹ̀yìn odi.
24 Tad strēlnieki no mūra šāva uz taviem kalpiem, ka kādi no ķēniņa kalpiem nomira,
Àwọn tafàtafà sì ta sí ìránṣẹ́ rẹ láti orí odi wá, díẹ̀ nínú àwọn ìránṣẹ́ ọba sì kú, ìránṣẹ́ rẹ̀ Uriah ará Hiti sì kú pẹ̀lú.”
25 Un tavs kalps Ūrija, tas Etietis, arīdzan nomiris. Tad Dāvids sacīja uz to vēstnesi: Tā saki uz Joabu: lai tev sirds neēdās šīs lietas dēļ, jo zobens rij te šo, te citu, stāvi jo stipri karā pret to pilsētu un izposti to, - un tā iedrošini viņu.
Dafidi sì wí fún ìránṣẹ́ náà pé, “Báyìí ni ìwọ yóò wí fún Joabu pé, ‘Má ṣe jẹ́ kí nǹkan yìí burú ní ojú rẹ, nítorí pé idà a máa pa lọ́tùn ún lósì, mú ìjà rẹ le sí ìlú náà, kí o sì bì í ṣubú.’ Kí ìwọ sì mú un lọ́kàn le.”
26 Kad nu Ūrijas sieva dzirdēja, ka viņas vīrs Ūrija bija miris, tad viņa gaudās par savu kungu.
Nígbà tí aya Uriah sì gbọ́ pé Uriah ọkọ rẹ̀ kú, ó sì ṣọ̀fọ̀ nítorí ọkọ rẹ̀.
27 Un kad gaudu laiks bija pagājis, tad Dāvids nosūtīja un to ņēma savā namā, un tā viņam palika par sievu un viņam dzemdēja dēlu. Bet šī lieta, ko Dāvids darīja, Tam Kungam nepatika.
Nígbà tí ìṣọ̀fọ̀ náà sì kọjá tan, Dafidi sì ránṣẹ́, o sì mú un wá sí ilé rẹ̀, ó sì di aya rẹ̀, ó sì bí ọmọkùnrin kan fún un, ṣùgbọ́n nǹkan náà tí Dafidi ṣe burú níwájú Olúwa.

< Otra Samuela 11 >