< Iosue 1 >
1 et factum est ut post mortem Mosi servi Domini loqueretur Dominus ad Iosue filium Nun ministrum Mosi et diceret ei
Lẹ́yìn ikú u Mose ìránṣẹ́ Olúwa, Olúwa sọ fún Joṣua ọmọ Nuni, olùrànlọ́wọ́ ọ Mose,
2 Moses servus meus mortuus est surge et transi Iordanem istum tu et omnis populus tecum in terram quam ego dabo filiis Israhel
“Mose ìránṣẹ́ mi ti kú. Nísinsin yìí, ìwọ àti gbogbo àwọn ènìyàn wọ̀nyí, ẹ múra láti kọjá odò Jordani lọ sí ilẹ̀ tí Èmi ó fi fún wọn fún àwọn ará Israẹli.
3 omnem locum quem calcaverit vestigium pedis vestri vobis tradam sicut locutus sum Mosi
Èmi yóò fún un yín ní gbogbo ibi tí ẹ bá fi ẹsẹ̀ ẹ yín tẹ̀, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe ìlérí fún Mose.
4 a deserto et Libano usque ad fluvium magnum Eufraten omnis terra Hettheorum usque ad mare Magnum contra solis occasum erit terminus vester
Ilẹ̀ ẹ yín yóò fẹ̀ láti aginjù Lebanoni, àti láti odò ńlá, ti Eufurate—gbogbo orílẹ̀-èdè Hiti títí ó fi dé Òkun Ńlá ní ìwọ̀-oòrùn.
5 nullus vobis poterit resistere cunctis diebus vitae tuae sicut fui cum Mose ero et tecum non dimittam nec derelinquam te
Kì yóò sí ẹnikẹ́ni tí yóò le è dúró níwájú rẹ ní ọjọ́ ayé è rẹ gbogbo. Bí mo ti wà pẹ̀lú u Mose, bẹ́ẹ̀ ni Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ, Èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Èmi kì yóò kọ̀ ọ́.
6 confortare et esto robustus tu enim sorte divides populo huic terram pro qua iuravi patribus suis ut traderem eam illis
“Jẹ́ alágbára kí o sì mú àyà le, nítorí ìwọ ni yóò ṣe amọ̀nà àwọn ènìyàn wọ̀nyí, láti lè jogún ilẹ̀ tí mo ti búra fún àwọn baba ńlá a wọn láti fi fún wọn.
7 confortare igitur et esto robustus valde ut custodias et facias omnem legem quam praecepit tibi Moses servus meus ne declines ab ea ad dextram vel ad sinistram ut intellegas cuncta quae agis
Jẹ́ alágbára, kí o sì mú àyà le gidigidi. Kí o sì ṣọ́ra láti pa gbogbo òfin tí Mose ìránṣẹ́ mi fún ọ mọ́, má ṣe yà kúrò nínú u rẹ̀ sí ọ̀tún tàbí sí òsì, kí ìwọ kí ó lè ṣe rere níbikíbi tí ìwọ bá ń lọ.
8 non recedat volumen legis huius de ore tuo sed meditaberis in eo diebus ac noctibus ut custodias et facias omnia quae scripta sunt in eo tunc diriges viam tuam et intelleges eam
Má ṣe jẹ́ kí ìwé òfin yìí kúrò ní ẹnu rẹ, máa ṣe àṣàrò nínú u rẹ̀ ní ọ̀sán àti ní òru, kí ìwọ kí ó lè ṣọ́ra láti ṣe gbogbo nǹkan tí a kọ sí inú u rẹ̀. Nígbà náà ni yóò dára fún ọ, ìwọ yóò sì ní àṣeyọrí.
9 ecce praecipio tibi confortare et esto robustus noli metuere et noli timere quoniam tecum est Dominus Deus tuus in omnibus ad quaecumque perrexeris
Èmi kò ha ti pàṣẹ fún ọ bí? Jẹ́ alágbára kí o sì mú àyà le. Má ṣe bẹ̀rù, má sì ṣe rẹ̀wẹ̀sì, nítorí pé Olúwa à rẹ yóò wà pẹ̀lú rẹ ní ibikíbi tí ìwọ bá ń lọ.”
10 praecepitque Iosue principibus populi dicens transite per medium castrorum et imperate populo ac dicite
Báyìí ni Joṣua pàṣẹ fún olórí àwọn ènìyàn rẹ̀,
11 praeparate vobis cibaria quoniam post diem tertium transibitis Iordanem et intrabitis ad possidendam terram quam Dominus Deus vester daturus est vobis
“Ẹ la ibùdó já, kí ẹ sì sọ fún àwọn ènìyàn, ‘Ẹ pèsè oúnjẹ yín sílẹ̀. Ní ìwòyí ọ̀túnla, ẹ̀yin yóò la Jordani yìí kọjá, láti gba ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run yín fi fún un yín láti ní.’”
12 Rubenitis quoque et Gadditis et dimidiae tribui Manasse ait
Ṣùgbọ́n Joṣua sọ fún àwọn ará a Reubeni, àwọn ará Gadi àti fún ìdajì ẹ̀yà Manase pé,
13 mementote sermonis quem praecepit vobis Moses famulus Domini dicens Dominus Deus vester dedit vobis requiem et omnem terram
“Rántí àṣẹ tí Mose ìránṣẹ́ Olúwa pa fún yín: ‘Olúwa Ọlọ́run yín á fún yin ní ìsinmi, òun yóò sì fún un yín ní ilẹ̀ yìí.’
14 uxores vestrae et filii ac iumenta manebunt in terra quam tradidit vobis Moses trans Iordanem vos autem transite armati ante fratres vestros omnes fortes manu et pugnate pro eis
Àwọn ìyàwó yín, àwọn ọmọ yín àti àwọn ẹran ọ̀sìn yín lè dúró ní ilẹ̀ tí Mose fún un yin ní ìlà-oòrùn Jordani; ṣùgbọ́n gbogbo àwọn jagunjagun un yín, pẹ̀lú ìhámọ́ra ogun gbọdọ̀ kọjá síwájú àwọn arákùnrin yín. Ẹ̀yin yóò sì rán àwọn arákùnrin yín lọ́wọ́
15 donec det requiem Dominus fratribus vestris sicut et vobis dedit et possideant ipsi quoque terram quam Dominus Deus vester daturus est eis et sic revertemini in terram possessionis vestrae et habitabitis in ea quam vobis dedit Moses famulus Domini trans Iordanem contra solis ortum
títí Olúwa yóò fi fún wọn ní ìsinmi, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe fún un yín, àti títí tí àwọn pẹ̀lú yóò fi gba ilẹ̀ náà tí Olúwa Ọlọ́run yín fi fún wọn. Lẹ́yìn náà, ẹ̀yin lè padà sí ilẹ̀ ìní in yín, tí Mose ìránṣẹ́ Olúwa fi fún un yin ní agbègbè ìlà-oòrùn ti Jordani.”
16 responderuntque ad Iosue atque dixerunt omnia quae praecepisti nobis faciemus et quocumque miseris ibimus
Nígbà náà ni wọ́n dá Joṣua lóhùn pé, “Ohunkóhun tí ìwọ pàṣẹ fún wa ni àwa yóò ṣe, ibikíbi tí ìwọ bá rán wa ni àwa yóò lọ.
17 sicut oboedivimus in cunctis Mosi ita oboediemus et tibi tantum sit Dominus Deus tecum sicut fuit cum Mose
Gẹ́gẹ́ bí àwa ti gbọ́rọ̀ sí Mose nínú ohun gbogbo, bẹ́ẹ̀ ni àwa yóò máa gbọ́ tìrẹ. Kí Olúwa Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà pẹ̀lú u Mose.
18 qui contradixerit ori tuo et non oboedierit cunctis sermonibus quos praeceperis ei moriatur tu tantum confortare et viriliter age
Ẹnikẹ́ni tí ó bá tàpá sí ọ̀rọ̀ rẹ, tí kò sì ṣe ìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ rẹ nínú ohun gbogbo tí ìwọ yóò pàṣẹ fún wọn, pípa ni a ó pa á. Kí ìwọ sá à ṣe gírí, kí ó sì mú àyà le!”