< Job 19 >
1 respondens autem Iob dixit
Ìgbà náà ni Jobu dáhùn, ó sì wí pé:
2 usquequo adfligitis animam meam et adteritis me sermonibus
“Yóò ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin ó fi máa fi ìyà jẹ mí, tí ẹ̀yin ó fi máa fi ọ̀rọ̀ yìí?
3 en decies confunditis me et non erubescitis opprimentes me
Ìgbà mẹ́wàá ní yin yọ mi lénu ẹ̀yin ti ń gàn mí; ojú kò tì yín tí ẹ fi jẹ mí ní yà.
4 nempe et si ignoravi mecum erit ignorantia mea
Kí a sì wí bẹ́ẹ̀ pé, mo ṣìnà nítòótọ́, ìṣìnà mi wà lára èmi tìkára mi.
5 at vos contra me erigimini et arguitis me obprobriis meis
Bí ó tilẹ̀ ṣe pé ẹ̀yin ó ṣògo si mi lórí nítòótọ́, tí ẹ ó sì máa fi ẹ̀gàn mi gún mí lójú,
6 saltim nunc intellegite quia Deus non aequo iudicio adflixerit me et flagellis suis me cinxerit
kí ẹ mọ̀ nísinsin yìí pé, Ọlọ́run ni ó bì mí ṣubú, ó sì nà àwọ̀n rẹ̀ yí mi ká.
7 ecce clamabo vim patiens et nemo audiet vociferabor et non est qui iudicet
“Kíyèsi, èmi ń kígbe pe, ‘Ọwọ́ alágbára!’ Ṣùgbọ́n a kò gbọ́ ti èmi; mo kígbe fún ìrànlọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìdájọ́.
8 semitam meam circumsepsit et transire non possum et in calle meo tenebras posuit
Ó ṣọgbà dí ọ̀nà mi tí èmi kò le è kọjá, Ó sì mú òkùnkùn ṣú sí ipa ọ̀nà mi.
9 spoliavit me gloria mea et abstulit coronam de capite meo
Ó ti bọ́ ògo mi, ó sì ṣí adé kúrò ní orí mi.
10 destruxit me undique et pereo et quasi evulsae arbori abstulit spem meam
Ó ti bà mí jẹ́ ní ìhà gbogbo, ẹ̀mí sì pin; ìrètí mi ni a ó sì fàtu bí igi.
11 iratus est contra me furor eius et sic me habuit quasi hostem suum
Ó sì tiná bọ ìbínú rẹ̀ sí mi, ó sì kà mí sí bí ọ̀kan nínú àwọn ọ̀tá rẹ̀.
12 simul venerunt latrones eius et fecerunt sibi viam per me et obsederunt in gyro tabernaculum meum
Ẹgbẹ́ ogun rẹ̀ sì dàpọ̀ sí mi, wọ́n sì mọ odi yí mi ká, wọ́n sì yí àgọ́ mi ká.
13 fratres meos longe fecit a me et noti mei quasi alieni recesserunt a me
“Ó mú àwọn arákùnrin mi jìnà sí mi réré, àti àwọn ojúlùmọ̀ mi di àjèjì sí mi pátápátá.
14 dereliquerunt me propinqui mei et qui me noverant obliti sunt mei
Àwọn alájọbí mi fàsẹ́yìn, àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ mi sì di onígbàgbé mi.
15 inquilini domus meae et ancillae meae sicut alienum habuerunt me et quasi peregrinus fui in oculis eorum
Àwọn ará inú ilé mi àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin mi kà mí sí àjèjì; èmi jásí àjèjì ènìyàn ní ojú wọn.
16 servum meum vocavi et non respondit ore proprio deprecabar illum
Mo pe ìránṣẹ́ mi, òun kò sì dá mi lóhùn; mo fi ẹnu mi bẹ̀ ẹ́.
17 halitum meum exhorruit uxor mea et orabam filios uteri mei
Ẹ̀mí mi ṣú àyà mi, àti òórùn mi ṣú àwọn ọmọ inú ìyá mi.
18 stulti quoque despiciebant me et cum ab eis recessissem detrahebant mihi
Àní àwọn ọmọdékùnrin fi mí ṣẹ̀sín, mo dìde, wọ́n sì sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí mi.
19 abominati sunt me quondam consiliarii mei et quem maxime diligebam aversatus est me
Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ kòríkòsùn mi kórìíra mi, àwọn olùfẹ́ mi sì kẹ̀yìndà mí.
20 pelli meae consumptis carnibus adhesit os meum et derelicta sunt tantummodo labia circa dentes meos
Egungun mi lẹ̀ mọ́ ara mi àti mọ́ ẹran-ara mi, mo sì yọ́ pẹ̀lú awọ eyín mi.
21 miseremini mei miseremini mei saltim vos amici mei quia manus Domini tetigit me
“Ẹ ṣàánú fún mi, ẹ ṣàánú fún mi, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, nítorí ọwọ́ Ọlọ́run ti bà mí.
22 quare persequimini me sicut Deus et carnibus meis saturamini
Nítorí kí ni ẹ̀yin ṣe lépa mi bí Ọlọ́run, tí ẹran-ara mi kò tẹ́ yín lọ́rùn?
23 quis mihi tribuat ut scribantur sermones mei quis mihi det ut exarentur in libro
“Háà! Ìbá ṣe pé a le kọ̀wé ọ̀rọ̀ mi nísinsin yìí, ìbá ṣe pé a le kọ ọ sínú ìwé!
24 stilo ferreo et plumbi lammina vel certe sculpantur in silice
Kí a fi kálámù irin àti ti òjé kọ wọ́n sínú àpáta fún láéláé.
25 scio enim quod redemptor meus vivat et in novissimo de terra surrecturus sim
Nítorí èmi mọ̀ pé olùdáǹdè mi ń bẹ láààyè àti pe òun ni yóò dìde dúró lórí ilẹ̀ ní ìkẹyìn;
26 et rursum circumdabor pelle mea et in carne mea videbo Deum
àti lẹ́yìn ìgbà tí a pa àwọ̀ ara mi run, síbẹ̀ láìsí ẹran-ara mi ni èmi ó rí Ọlọ́run,
27 quem visurus sum ego ipse et oculi mei conspecturi sunt et non alius reposita est haec spes mea in sinu meo
ẹni tí èmi ó rí fún ara mi, tí ojú mi ó sì wo, kì sì í ṣe ti ẹlòmíràn; ọkàn mi sì dákú ní inú mi.
28 quare ergo nunc dicitis persequamur eum et radicem verbi inveniamus contra eum
“Bí ẹ̀yin bá wí pé, ‘Àwa ó ti lépa rẹ̀ tó! Àti pé, gbogbo ọ̀rọ̀ náà ni a sá à rí ní ọwọ́ rẹ̀,’
29 fugite ergo a facie gladii quoniam ultor iniquitatum gladius est et scitote esse iudicium
kí ẹ̀yin kí ó bẹ̀rù, nítorí ìbínú ní í mú ìjìyà wá nípa idà, kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ pé ìdájọ́ kan ń bẹ.”