< Exodus 5 >
1 post haec ingressi sunt Moses et Aaron et dixerunt Pharaoni haec dicit Dominus Deus Israhel dimitte populum meum ut sacrificet mihi in deserto
Lẹ́yìn náà ni Mose àti Aaroni tọ Farao lọ, wọ́n sì wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli sọ, ‘Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn kí ó lè ṣe àjọ mi ní ijù.’”
2 at ille respondit quis est Dominus ut audiam vocem eius et dimittam Israhel nescio Dominum et Israhel non dimittam
Farao dáhùn wí pé, “Ta ni Olúwa, tí èmi yóò fi gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu, tí èmi yóò fi jẹ́ kí Israẹli ó lọ? Èmi kò mọ Olúwa, èmi kò sì ní jẹ́ kí Israẹli ó lọ.”
3 dixerunt Deus Hebraeorum vocavit nos ut eamus viam trium dierum in solitudinem et sacrificemus Domino Deo nostro ne forte accidat nobis pestis aut gladius
Lẹ́yìn náà ni wọ́n wí pé, “Ọlọ́run àwọn Heberu tí pàdé wa. Ní ìsinsin yìí, jẹ́ kí a lọ ní ìrìn ọjọ́ mẹ́ta sínú aginjù láti rú ẹbọ sí Olúwa Ọlọ́run wa, kí Ó má ba á fi àjàkálẹ̀-ààrùn tàbí idà bá wa jà.”
4 ait ad eos rex Aegypti quare Moses et Aaron sollicitatis populum ab operibus suis ite ad onera vestra
Ṣùgbọ́n ọba Ejibiti sọ wí pé, “Mose àti Aaroni, èéṣe ti ẹ̀yin fi mú àwọn ènìyàn kúrò lẹ́nu iṣẹ́ wọn? Ẹ padà sẹ́nu iṣẹ́ yín.”
5 dixitque Pharao multus est populus terrae videtis quod turba succreverit quanto magis si dederitis eis requiem ab operibus
Nígbà náà ni Farao sọ pé, “Ẹ wò ó àwọn ènìyàn náà ti pọ̀ sí ì nílẹ̀ yìí ní ìsinsin yìí, ẹ̀yin sì ń dá wọn dúró láti máa bá iṣẹ́ lọ.”
6 praecepit ergo in die illo praefectis operum et exactoribus populi dicens
Ní ọjọ́ yìí kan náà ni Farao pàṣẹ fún àwọn akóniṣiṣẹ́ àti àwọn ti ń ṣe alábojútó iṣẹ́ lórí àwọn ènìyàn.
7 nequaquam ultra dabitis paleas populo ad conficiendos lateres sicut prius sed ipsi vadant et colligant stipulam
“Ẹ̀yin kò ní láti pèsè koríko gbígbẹ fún bíríkì sísun mọ́ fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí; ẹ jẹ́ kí wọn máa wá koríko gbígbẹ fún ara wọn.
8 et mensuram laterum quos prius faciebant inponetis super eos nec minuetis quicquam vacant enim et idcirco vociferantur dicentes eamus et sacrificemus Deo nostro
Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí wọn ó ṣe iye bíríkì kan náà bí ì ti àtẹ̀yìnwá, kí ẹ má ṣe dín iye rẹ̀ kú. Ọ̀lẹ ni wọ́n, ìwà ọ̀lẹ yìí náà ló mú wọn pariwo pé, ‘Ẹ jẹ́ kí a lọ, kí a sì rú ẹbọ sí Ọlọ́run wa.’
9 opprimantur operibus et expleant ea ut non adquiescant verbis mendacibus
Ẹ mú iṣẹ́ náà le fún wọn, kí wọn bá a le è tẹramọ́ iṣẹ́ wọn, ẹ má fi ààyè gba irọ́ wọn.”
10 igitur egressi praefecti operum et exactores ad populum dixerunt sic dicit Pharao non do vobis paleas
Ní ìgbà náà ni àwọn akóniṣiṣẹ́ àti àwọn tí ń ṣe alábojútó iṣẹ́ jáde tọ̀ wọ́n lọ láti sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Èyí ni ohun tí Farao sọ, ‘Èmi kò ní fún un yín ni koríko gbígbẹ mọ́.
11 ite et colligite sicubi invenire potueritis nec minuetur quicquam de opere vestro
Ẹ lọ wá koríko gbígbẹ ni ibi tí ẹ bá ti lè rí i, ṣùgbọ́n iṣẹ́ yín kí yóò dínkù.’”
12 dispersusque est populus per omnem terram Aegypti ad colligendas paleas
Gbogbo wọn sí fọ́n káàkiri ni ilẹ̀ Ejibiti láti sa ìdì koríko tí wọn yóò lò bí ì koríko gbígbẹ fún sísun bíríkì.
13 praefecti quoque operum instabant dicentes conplete opus vestrum cotidie ut prius facere solebatis quando dabantur vobis paleae
Àwọn akóniṣiṣẹ́ sì ń ni wọ́n lára, wọ́n wí pé, “Ẹ parí iṣẹ́ tí ẹ ni láti ṣe fún ọjọ́ kan bí ìgbà ti a ń fún un yin ní koríko gbígbẹ.”
14 flagellatique sunt qui praeerant operibus filiorum Israhel ab exactoribus Pharaonis dicentibus quare non impletis mensuram laterum sicut prius nec heri nec hodie
Àwọn alábojútó iṣẹ́ tí àwọn akóniṣiṣẹ́ Farao yàn lára ọmọ Israẹli ni wọn ń lù, tí wọn sì ń béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin kò ṣe iye bíríkì ti ẹ̀yin ń ṣe ní àná ní òní bí i tí àtẹ̀yìnwá?”
15 veneruntque praepositi filiorum Israhel et vociferati sunt ad Pharaonem dicentes cur ita agis contra servos tuos
Nígbà náà ni àwọn alábojútó iṣẹ́ tí a yàn lára àwọn ọmọ Israẹli tọ Farao lọ láti lọ bẹ̀bẹ̀ pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ọwọ́ líle mú àwa ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ báyìí?
16 paleae non dantur nobis et lateres similiter imperantur en famuli tui flagellis caedimur et iniuste agitur contra populum tuum
Wọn kò fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni koríko gbígbẹ, síbẹ̀ wọn sọ fún wa pé, ‘Ẹ ṣe bíríkì!’ Wọ́n na àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ, ṣùgbọ́n ẹ̀bi náà wá láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ.”
17 qui ait vacatis otio et idcirco dicitis eamus et sacrificemus Domino
Farao sí dáhùn wí pé, “Ọ̀lẹ ni yín, ọ̀lẹ! Èyí ni ó mú kí ẹ̀yin máa sọ ní ìgbà gbogbo pé, ‘Ẹ jẹ́ kí a lọ, kí a sì rú ẹbọ sí Olúwa.’
18 ite ergo et operamini paleae non dabuntur vobis et reddetis consuetum numerum laterum
Nísinsin yìí ẹ padà lọ sí ẹnu iṣẹ́ yín, a kò ní fún un yín ni koríko gbígbẹ, síbẹ̀ ẹ gbọdọ̀ ṣe iye bíríkì tí ó yẹ kí ẹ ṣe.”
19 videbantque se praepositi filiorum Israhel in malo eo quod diceretur eis non minuetur quicquam de lateribus per singulos dies
Àwọn ọmọ Israẹli tí ó jẹ́ alábojútó iṣẹ́ mọ̀ dájú wí pé àwọn ti wà nínú wàhálà ńlá ní ìgbà tí a sọ fún wọn pé, “Ẹ kò ní láti dín iye bíríkì tí ẹ ń ṣe ni ojoojúmọ́ kù.”
20 occurreruntque Mosi et Aaron qui stabant ex adverso egredientes a Pharaone
Ní ìgbà tí wọ́n kúrò ni ọ̀dọ̀ Farao wọ́n rí Mose àti Aaroni tí ó dúró láti pàdé wọn.
21 et dixerunt ad eos videat Dominus et iudicet quoniam fetere fecistis odorem nostrum coram Pharao et servis eius et praebuistis ei gladium ut occideret nos
Wọn sì wí pé, “Kí Olúwa kí ó wò yín, kí ó sì ṣe ìdájọ́! Ẹ̀yin ti mú wa dàbí òórùn búburú fún Farao àti àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀, ẹ sì ti fún wọn ni idà láti fi pa wá.”
22 reversusque Moses ad Dominum ait Domine cur adflixisti populum istum quare misisti me
Mose padà tọ Olúwa lọ, ó sì wí pé, “Olúwa, èéṣe tí ìwọ fi mú ìyọnu wá sí orí àwọn ènìyàn wọ̀nyí? Ṣe torí èyí ni ìwọ fi rán mi?
23 ex eo enim quo ingressus sum ad Pharaonem ut loquerer nomine tuo adflixit populum tuum et non liberasti eos
Láti ìgbà ti mo ti tọ Farao lọ láti bá a sọ̀rọ̀ ni orúkọ rẹ ni ó ti mú ìyọnu wá sí orí àwọn ènìyàn wọ̀nyí, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò sì gba àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀ rárá.”