< Ecclesiastes 2 >

1 dixi ego in corde meo vadam et affluam deliciis et fruar bonis et vidi quod hoc quoque esset vanitas
Mo rò nínú ọkàn mi, “Wá nísinsin yìí, èmi yóò sì dán ọ wò pẹ̀lú ìgbádùn láti ṣe àwárí ohun tí ó dára.” Ṣùgbọ́n eléyìí náà jásí asán.
2 risum reputavi errorem et gaudio dixi quid frustra deciperis
“Mo wí fún ẹ̀rín pé òmùgọ̀ ni. Àti fún ìre-ayọ̀ pé kí ni ó ń ṣe?”
3 cogitavi in corde meo abstrahere a vino carnem meam ut animum meum transferrem ad sapientiam devitaremque stultitiam donec viderem quid esset utile filiis hominum quod facto opus est sub sole numero dierum vitae suae
Mo tiraka láti dun ara mi nínú pẹ̀lú ọtí wáìnì, àti láti fi ọwọ́ lé òmùgọ̀—ọkàn mi sì ń tọ́ mi pẹ̀lú ọgbọ́n. Mo fẹ́ wo ohun tí ó yẹ ní ṣíṣe fún ènìyàn ní abẹ́ ọ̀run ní ìwọ̀nba ọjọ́ ayé rẹ̀.
4 magnificavi opera mea aedificavi mihi domos plantavi vineas
Mo ṣe àwọn iṣẹ́ ńlá ńlá. Mo kọ́ ilé púpọ̀ fún ara mi, mo sì gbin ọgbà àjàrà púpọ̀.
5 feci hortos et pomeria et consevi ea cuncti generis arboribus
Mo ṣe ọgbà àti àgbàlá, mo sì gbin onírúurú igi eléso sí inú wọn.
6 extruxi mihi piscinas aquarum ut inrigarem silvam lignorum germinantium
Mo gbẹ́ adágún láti máa bu omi rin àwọn igi tí ó ń hù jáde nínú ọgbà.
7 possedi servos et ancillas multamque familiam habui armenta quoque et magnos ovium greges ultra omnes qui fuerunt ante me in Hierusalem
Mo ra àwọn ẹrú ọkùnrin àti àwọn ẹrú obìnrin, mo sì tún ní àwọn ẹrú mìíràn tí a bí sí ilé mi. Mo sì tún ní ẹran ọ̀sìn ju ẹnikẹ́ni ní Jerusalẹmu lọ.
8 coacervavi mihi argentum et aurum et substantias regum ac provinciarum feci mihi cantores et cantrices et delicias filiorum hominum scyphos et urceos in ministerio ad vina fundenda
Mo kó fàdákà àti wúrà jọ fún ara mi àti àwọn ohun ìṣúra ti ọba àti ìgbèríko. Mo ní àwọn akọrin ọkùnrin àti obìnrin, àti dídùn inú ọmọ ènìyàn, aya àti obìnrin púpọ̀.
9 et supergressus sum opibus omnes qui fuerunt ante me in Hierusalem sapientia quoque perseveravit mecum
Mo di ẹni ńlá ju ẹnikẹ́ni tí ó wà ní Jerusalẹmu ṣáájú mi. Nínú gbogbo èyí, ọgbọ́n mi kò fi mí sílẹ̀.
10 et omnia quae desideraverunt oculi mei non negavi eis nec prohibui cor quin omni voluptate frueretur et oblectaret se in his quae paraveram et hanc ratus sum partem meam si uterer labore meo
Èmi kò jẹ́ kí ojú mi ṣe aláìrí ohun tí ó bá ń fẹ́. N kò sì jẹ́ kí ọkàn mi ó ṣe aláìní ìgbádùn. Ọkàn mi yọ̀ nínú gbogbo iṣẹ́ mi, èyí sì ni èrè fún gbogbo wàhálà mi.
11 cumque me convertissem ad universa opera quae fecerant manus meae et ad labores in quibus frustra sudaveram vidi in omnibus vanitatem et adflictionem animi et nihil permanere sub sole
Síbẹ̀, nígbà tí mo wo gbogbo ohun tí ọwọ́ mi ti ṣe àti ohun tí mo ti ṣe wàhálà láti ní: gbogbo rẹ̀, asán ni. Ó dàbí ẹni gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́, kò sí èrè kan ní abẹ́ oòrùn; ọgbọ́n àti òmùgọ̀, asán ni.
12 transivi ad contemplandam sapientiam erroresque et stultitiam quid est inquam homo ut sequi possit regem factorem suum
Nígbà náà ni mo tún bẹ̀rẹ̀ sí ọgbọ́n, àti ìsínwín àti àìgbọ́n kí ni ọba tí ó jẹ lẹ́yìn tí ọba kan kú le è ṣe ju èyí tí ọba ìṣáájú ti ṣe lọ.
13 et vidi quia tantum praecederet sapientia stultitiam quantum differt lux tenebris
Mo sì ri wí pé ọgbọ́n dára ju òmùgọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ ti dára ju òkùnkùn lọ.
14 sapientis oculi in capite eius stultus in tenebris ambulat et didici quod unus utriusque esset interitus
Ojú ọlọ́gbọ́n ń bẹ lágbárí rẹ̀, nígbà tí aṣiwèrè ń rìn nínú òkùnkùn, ṣùgbọ́n mo wá padà mọ̀ wí pé ìpín kan náà ni ó ń dúró de ìsọ̀rí àwọn ènìyàn méjèèjì.
15 et dixi in corde meo si unus et stulti et meus occasus erit quid mihi prodest quod maiorem sapientiae dedi operam locutusque cum mente mea animadverti quod hoc quoque esset vanitas
Nígbà náà ni mo rò nínú ọkàn wí pé, “Irú ìpín tí òmùgọ̀ ní yóò bá èmi náà pẹ̀lú kí wá ni ohun tí mo jẹ ní èrè nípa ọgbọ́n?” Mo sọ nínú ọkàn mi wí pé, “Asán ni eléyìí pẹ̀lú.”
16 non enim erit memoria sapientis similiter ut stulti in perpetuum et futura tempora oblivione cuncta pariter obruent moritur doctus similiter et indoctus
Nítorí pé ọlọ́gbọ́n ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí i òmùgọ̀, a kì yóò rántí rẹ̀ fún ìgbà pípẹ́; gbogbo wọn ni yóò di ohun ìgbàgbé ní ọjọ́ tó ń bọ̀. Ikú tí ó pa aṣiwèrè náà ni yóò pa ọlọ́gbọ́n ènìyàn.
17 et idcirco taeduit me vitae meae videntem mala esse universa sub sole et cuncta vanitatem atque adflictionem spiritus
Nítorí náà, mo kórìíra ìwàláàyè, nítorí pé iṣẹ́ tí wọn ń ṣe ní abẹ́ oòrùn ti mú ìdààmú bá mi. Gbogbo rẹ̀ asán ni, ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́ ni.
18 rursum detestatus sum omnem industriam meam quae sub sole studiosissime laboravi habiturus heredem post me
Mo kórìíra gbogbo ohun tí mo ti ṣiṣẹ́ fún ní abẹ́ oòrùn, nítorí pé mo ní láti fi wọ́n sílẹ̀ fún ẹni tí ó wà lẹ́yìn mi ni.
19 quem ignoro utrum sapiens an stultus futurus sit et dominabitur in laboribus meis quibus desudavi et sollicitus fui et est quicquam tam vanum
Ta ni ó wá mọ̀ bóyá ọlọ́gbọ́n ènìyàn ni yóò jẹ́ tàbí aṣiwèrè? Síbẹ̀ yóò ní láti ṣe àkóso lórí gbogbo iṣẹ́ tí mo tí ṣe yìí pẹ̀lú.
20 unde cessavi renuntiavitque cor meum ultra laborare sub sole
Nítorí náà, ọkàn mi bẹ̀rẹ̀ sí ní kábámọ̀ lórí gbogbo àìsimi iṣẹ́ ṣíṣe mi ní abẹ́ oòrùn.
21 nam cum alius laboret in sapientia et doctrina et sollicitudine homini otioso quaesita dimittit et hoc ergo vanitas et magnum malum
Nítorí pé ènìyàn le è ṣe iṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n, òye àti ìmọ̀ ní abẹ́ oòrùn, tí ó sì ti kọ́ ṣe iṣẹ́ fúnra rẹ̀. Asán ni eléyìí pẹ̀lú àti àdánù ńlá.
22 quid enim proderit homini de universo labore suo et adflictione spiritus qua sub sole cruciatus est
Kí ni ohun tí ènìyàn rí gbà fún gbogbo wàhálà àti ìpọ́njú tí ó fi ṣiṣẹ́ lábẹ́ oòrùn?
23 cuncti dies eius doloribus et aerumnis pleni sunt nec per noctem mente requiescit et haec non vanitas est
Gbogbo ọjọ́ rẹ, iṣẹ́ rẹ kún fún ìrora, àti ìbànújẹ́, kódà ọkàn rẹ̀ kì í ní ìsinmi ní alẹ́. Asán ni eléyìí pẹ̀lú.
24 nonne melius est comedere et bibere et ostendere animae suae bona de laboribus suis et hoc de manu Dei est
Ènìyàn kò le è ṣe ohunkóhun tí ó dára jù pé kí ó jẹ kí ó sì mu, kí ó sì rí ìtẹ́lọ́rùn nínú iṣẹ́ rẹ̀. Mo rí wí pé eléyìí pẹ̀lú wá láti ọwọ́ Ọlọ́run.
25 quis ita vorabit et deliciis affluet ut ego
Nítorí wí pé láìsí òun, ta ni ó le jẹ tàbí kí ó mọ adùn?
26 homini bono in conspectu suo dedit Deus sapientiam et scientiam et laetitiam peccatori autem dedit adflictionem et curam superfluam ut addat et congreget et tradat ei qui placuit Deo sed et hoc vanitas et cassa sollicitudo mentis
Fún ẹni tí ó bá tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn ni Ọlọ́run yóò fún ní ọgbọ́n, ìmọ̀ àti ìdùnnú, ṣùgbọ́n fún ẹni dẹ́ṣẹ̀, Ó fún un ní iṣẹ́ láti ṣà àti láti kó ohun ìní pamọ́ kí ó sì fi fún ẹni tí ó tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn. Eléyìí pẹ̀lú, asán ni, ó dàbí ẹni gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́.

< Ecclesiastes 2 >