< Thessalonicenses Ii 2 >

1 rogamus autem vos fratres per adventum Domini nostri Iesu Christi et nostrae congregationis in ipsum
Ní ti bíbọ̀ Jesu Kristi Olúwa wa, àti ti ìpéjọ wa sọ́dọ̀ rẹ̀, àwa wí fún yín ará,
2 ut non cito moveamini a sensu neque terreamini neque per spiritum neque per sermonem neque per epistulam tamquam per nos quasi instet dies Domini
kí ọkàn yín má ṣe àìbalẹ̀, tàbí kí ẹ má ṣe jáyà nípa àsọtẹ́lẹ̀, ìròyìn tàbí lẹ́tà tí ó lè fi ara jọ èyí tí ó le wá láti ọ̀dọ̀ wa, tí yóò máa wí pé ọjọ́ Olúwa ti dé ná.
3 ne quis vos seducat ullo modo quoniam nisi venerit discessio primum et revelatus fuerit homo peccati filius perditionis
Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kí ó tàn yín jẹ ní ọ̀nàkọnà, nítorí pé ọjọ́ náà kì yóò dé, bí kò ṣe pé ìṣọ̀tẹ̀ bá kọ́ ṣẹlẹ̀, tí a sì fi ẹni ẹ̀ṣẹ̀ hàn, tí í ṣe ọmọ ègbé.
4 qui adversatur et extollitur supra omne quod dicitur Deus aut quod colitur ita ut in templo Dei sedeat ostendens se quia sit Deus
Òun yóò lòdì sí, yóò sì gbé ara rẹ̀ ga sí gbogbo ohun tí a ń pè ní Ọlọ́run tàbí tí a ń sìn, dé ibi pé yóò gbé ara rẹ̀ jókòó nínú tẹmpili Ọlọ́run, tí yóò sì pe ara rẹ̀ ní Ọlọ́run.
5 non retinetis quod cum adhuc essem apud vos haec dicebam vobis
Ṣé ẹ̀yin kò rántí pé nígbà tí mo wà pẹ̀lú yín, mo ń sọ àwọn nǹkan wọ̀nyí fún un yín.
6 et nunc quid detineat scitis ut reveletur in suo tempore
Àti pé nísinsin yìí, ẹ̀yin mọ ohun tí ń dá a dúró, kí a bá a lè fi í hàn ní àkókò rẹ̀ gan an.
7 nam mysterium iam operatur iniquitatis tantum ut qui tenet nunc donec de medio fiat
Nítorí agbára ìkọ̀kọ̀ ẹni ẹ̀ṣẹ̀ ti ń ṣiṣẹ́; ṣùgbọ́n ẹni tí ń dènà yóò máa ṣe bẹ́ẹ̀ títí a ó fi mú un kúrò ní ọ̀nà.
8 et tunc revelabitur ille iniquus quem Dominus Iesus interficiet spiritu oris sui et destruet inlustratione adventus sui
Nígbà náà ni a ó fi ẹni ẹ̀ṣẹ̀ hàn, ẹni tí Jesu Olúwa yóò fi èémí ẹnu rẹ̀ pa, tí yóò sì fi ọlá ìpadàbọ̀ rẹ̀ parun.
9 eum cuius est adventus secundum operationem Satanae in omni virtute et signis et prodigiis mendacibus
Wíwá ẹni ẹ̀ṣẹ̀ yóò rí bí iṣẹ́ Satani, gbogbo èyí tí a fihàn gẹ́gẹ́ bí àdàmọ̀dì iṣẹ́ ìyanu, àdàmọ̀dì àmì àti àdàmọ̀dì idán,
10 et in omni seductione iniquitatis his qui pereunt eo quod caritatem veritatis non receperunt ut salvi fierent
ní gbogbo ọ̀nà búburú tí a fi ń tan àwọn tí ń ṣègbé jẹ. Wọ́n ṣègbé nítorí wọ́n kọ̀ láti fẹ́ràn òtítọ́ kí wọn sì di ẹni ìgbàlà.
11 ideo mittit illis Deus operationem erroris ut credant mendacio
Nítorí ìdí èyí, Ọlọ́run rán ohun tó ń ṣiṣẹ́ ìṣìnà sí wọn kí wọn lè gba èké gbọ́,
12 ut iudicentur omnes qui non crediderunt veritati sed consenserunt iniquitati
kí wọn kí ó lè gba ìdálẹ́bi, àní àwọn tí kò gba òtítọ́ gbọ́, ṣùgbọ́n tí wọ́n ní inú dídùn nínú ìwà búburú.
13 nos autem debemus gratias agere Deo semper pro vobis fratres dilecti a Deo quod elegerit nos Deus primitias in salutem in sanctificatione Spiritus et fide veritatis
Ṣùgbọ́n, ohun tí ó tọ́ fún wa ni láti máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà gbogbo nítorí yín, ará olùfẹ́ ní ti Olúwa, nítorí láti ìbẹ̀rẹ̀ ni Ọlọ́run ti yàn yín sí ìgbàlà nípa ìsọdimímọ́ ti Ẹ̀mí àti nípa gbígba òtítọ́ gbọ́.
14 ad quod et vocavit vos per evangelium nostrum in adquisitionem gloriae Domini nostri Iesu Christi
Òun ti pè yín sí èyí nípa ìyìnrere wa, kí ẹ̀yin kí ó lè pín nínú ògo Jesu Kristi Olúwa wa.
15 itaque fratres state et tenete traditiones quas didicistis sive per sermonem sive per epistulam nostram
Nítorí náà ará, ẹ dúró ṣinṣin, kí ẹ sì di àwọn ẹ̀kọ́ wọ̀n-ọn-nì tí a kọ́ yín mú, yálà nípa ọ̀rọ̀ ẹnu tàbí lẹ́tà.
16 ipse autem Dominus noster Iesus Christus et Deus et Pater noster qui dilexit nos et dedit consolationem aeternam et spem bonam in gratia (aiōnios g166)
Ǹjẹ́ kí Jesu Kristi Olúwa wa tìkálára rẹ̀, àti Ọlọ́run Baba wa, ẹni to ti fẹ́ wa, tí ó sì ti fi ìtùnú àìnípẹ̀kun àti ìrètí rere nípa oore-ọ̀fẹ́ fún wa. (aiōnios g166)
17 exhortetur corda vestra et confirmet in omni opere et sermone bono
Kí ó mú ọkàn yín le, kí ó sì kún yín pẹ̀lú agbára nínú iṣẹ́ gbogbo àti ọ̀rọ̀ rere gbogbo.

< Thessalonicenses Ii 2 >