< Esdræ 7 >

1 Post haec autem verba in regno Artaxerxis regis Persarum, Esdras filius Saraiae, filii Azariae, filii Helciae,
Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, ní àkókò ìjọba ọba Artasasta ní Persia, Esra ọmọ Seraiah, ọmọ Asariah, ọmọ Hilkiah,
2 filii Sellum, filii Sadoc, filii Achitob,
ọmọ Ṣallumu, ọmọ Sadoku, ọmọ Ahitubu,
3 filii Amariae, filii Azariae, filii Maraioth,
ọmọ Amariah, ọmọ Asariah, ọmọ Meraioti,
4 filii Zarahiae, filii Ozi, filii Bocci,
ọmọ Serahiah, ọmọ Ussi, ọmọ Bukki,
5 filii Abisue, filii Phinees, filii Eleazar, filii Aaron sacerdotis ab initio.
ọmọ Abiṣua, ọmọ Finehasi, ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni olórí àlùfáà—
6 Ipse Esdras ascendit de Babylone, et ipse scriba velox in lege Moysi, quam Dominus Deus dedit Israel: et dedit ei rex secundum manum Domini Dei eius super eum, omnem petitionem eius.
Esra yìí sì gòkè wá láti Babeli. Olùkọ́ tí ó ní ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa òfin Mose, èyí tí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, ti fi fún wọn. Ọba sì fi gbogbo ohun tí ó béèrè fún un, nítorí ọwọ́ Olúwa Ọlọ́run wà lára rẹ̀.
7 Et ascenderunt de filiis Israel, et de filiis Sacerdotum, et de filiis Levitarum, et de cantoribus, et de ianitoribus, et de Nathinaeis, in Ierusalem anno septimo Artaxerxis regis.
Ní ọdún keje ọba Artasasta díẹ̀ lára àwọn ọmọ Israẹli, àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Lefi, àwọn akọrin, àwọn aṣọ́nà àti àwọn tí ń ṣiṣẹ́ nínú tẹmpili náà gòkè wá sí Jerusalẹmu.
8 Et venerunt in Ierusalem mense quinto, ipse est annus septimus regis.
Ní oṣù karùn-ún ọdún keje ọba yìí ni Esra dé sí Jerusalẹmu.
9 Quia in primo die mensis primi coepit ascendere de Babylone, et in primo die mensis quinti venit in Ierusalem, iuxta manum Dei sui bonam super se.
Ó bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò rẹ̀ láti Babeli ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kìn-ín-ní, ó sì dé Jerusalẹmu ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù karùn-ún nítorí ọwọ́ àánú Ọlọ́run rẹ̀ wà ní ara rẹ̀.
10 Esdras enim paravit cor suum, ut investigaret legem Domini, et faceret et doceret in Israel praeceptum et iudicium.
Esra ti fi ara rẹ̀ jì fún kíkọ́ àti pípa òfin Olúwa mọ́, ó sì ń kọ́ òfin àti ìlànà Mose ní Israẹli.
11 Hoc est autem exemplar epistolae edicti, quod dedit rex Artaxerxes Esdrae sacerdoti, scribae erudito in sermonibus et praeceptis Domini, et ceremoniis eius in Israel.
Èyí ni ẹ̀dà lẹ́tà ti ọba Artasasta fún àlùfáà Esra olùkọ́ni, ẹni tó ní ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nínú àkọsílẹ̀ òfin àti ìlànà Olúwa fún Israẹli.
12 Artaxerxes rex regum Esdrae sacerdoti, scribae legis Dei caeli doctissimo, salutem.
Artasasta, ọba àwọn ọba. Sí àlùfáà Esra, olùkọ́ òfin Ọlọ́run ọ̀run. Àlàáfíà.
13 A me decretum est, ut cuicumque placuerit in regno meo de populo Israel, et de Sacerdotibus eius, et de Levitis ire in Ierusalem, tecum vadat.
Mo pàṣẹ pé ẹnikẹ́ni nínú àwọn ọmọ Israẹli, àwọn àlùfáà àti àwọn Lefi, ti ó wà ní abẹ́ ìṣàkóso ìjọba mi, tí ó bá fẹ́ láti bá ọ lọ sí Jerusalẹmu lè tẹ̀lé ọ lọ.
14 A facie enim regis, et septem consiliatorum eius missus es, ut visites Iudaeam et Ierusalem in lege Dei tui, quae est in manu tua:
Ọba àti àwọn ìgbìmọ̀ rẹ̀ méjèèje rán ọ lọ láti wádìí nípa òfin Ọlọ́run rẹ tí ó wà ní ọwọ́ rẹ nípa Juda àti Jerusalẹmu.
15 et ut feras argentum et aurum quod rex, et consiliatores eius sponte obtulerunt Deo Israel, cuius in Ierusalem tabernaculum est.
Síwájú sí i, kí ìwọ kí ó kó fàdákà àti wúrà lọ pẹ̀lú rẹ èyí tí ọba àti àwọn ìgbìmọ̀ rẹ fi tọkàntọkàn fún Ọlọ́run Israẹli, ẹni tí ibùjókòó rẹ̀ wà ní Jerusalẹmu,
16 Et omne argentum et aurum quodcumque inveneris in universa provincia Babylonis, et populus offerre voluerit, et de Sacerdotibus quae sponte obtulerint domui Dei sui, quae est in Ierusalem,
pẹ̀lú gbogbo fàdákà àti wúrà tí ìwọ lè rí ní agbègbè ìjọba Babeli àti àwọn ọrẹ àtinúwá àwọn ènìyàn àti ti àwọn àlùfáà fún tẹmpili Ọlọ́run wọn ní Jerusalẹmu.
17 libere accipe, et studiose eme de hac pecunia vitulos, arietes, agnos et sacrificia et libamina eorum, et offer ea super altare templi Dei vestri, quod est in Ierusalem.
Pẹ̀lú owó yìí, rí i dájú pé ó ra àwọn akọ màlúù, àwọn àgbò àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn, pẹ̀lú ọrẹ ohun jíjẹ, àti ọrẹ ohun mímu, kí ìwọ kí ó fi wọ́n rú ẹbọ lórí pẹpẹ tẹmpili Ọlọ́run rẹ ní Jerusalẹmu.
18 Sed et si quid tibi, et fratribus tuis placuerit de reliquo argento et auro ut faciatis, iuxta voluntatem Dei vestri facite.
Ìwọ àti àwọn Júù arákùnrin rẹ lè fi èyí tókù fàdákà àti wúrà ṣe ohunkóhun tí ó bá dára lójú yín, ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run yín.
19 Vasa quoque, quae dantur tibi in ministerium domus Dei tui, trade in conspectu Dei in Ierusalem.
Kó gbogbo ohun èlò tí a fi sí ìkáwọ́ rẹ fún Ọlọ́run Jerusalẹmu fún ìsìn nínú tẹmpili Ọlọ́run rẹ.
20 Sed et cetera, quibus opus fuerit in domum Dei tui, quantumcumque necesse est ut expendas, dabitur de thesauro, et de fisco regis,
Ohunkóhun mìíràn tí o bá nílò fún tẹmpili Ọlọ́run rẹ tí ó sì ní láti pèsè, o lè mú u láti inú ìṣúra ọba.
21 et a me. Ego Artaxerxes rex, statui atque decrevi omnibus custodibus arcae publicae, qui sunt trans Flumen, ut quodcumque petierit a vobis Esdras sacerdos, scriba legis Dei caeli, absque mora detis
Èmi, ọba Artasasta, pàṣẹ fún gbogbo olùtọ́jú ilé ìṣúra agbègbè Eufurate láìrójú láti pèsè ohunkóhun tí àlùfáà Esra, olùkọ́ni ní òfin Ọlọ́run ọ̀run bá béèrè lọ́wọ́ yín
22 usque ad argenti talenta centum, et usque ad frumenti coros centum, et usque ad vini batos centum, et usque ad batos olei centum, sal vero absque mensura.
tó ọgọ́rùn-ún kan tálẹ́ǹtì fàdákà, ọgọ́rùn-ún kan òsùwọ̀n àlìkámà, àti dé ọgọ́rùn-ún bati ọtí wáìnì, àti dé ọgọ́rùn-ún bati òróró olifi, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ iyọ̀.
23 Omne, quod ad ritum Dei caeli pertinet, tribuatur diligenter in domo Dei caeli: ne forte irascatur contra regnum regis, et filiorum eius.
Ohunkóhun tí Ọlọ́run ọ̀run bá fẹ́, jẹ́ kí ó di ṣíṣe ní pípé fún tẹmpili Ọlọ́run ọ̀run. Èéṣe tí ìbínú yóò ṣe wá sí agbègbè ọba àti sí orí àwọn ọmọ rẹ̀?
24 Vobis quoque notum facimus de universis Sacerdotibus, et Levitis, et cantoribus, et ianitoribus, Nathinaeis, et ministris domus Dei huius, ut vectigal, et tributum, et annonas non habeatis potestatem imponendi super eos.
Ìwọ sì ní láti mọ̀ pé ìwọ kò ní àṣẹ láti sọ sísan owó orí, owó òde tàbí owó bodè di dandan fún àwọn àlùfáà, àwọn Lefi, àwọn akọrin, àwọn aṣọ́nà, àwọn òṣìṣẹ́ tẹmpili tàbí àwọn òṣìṣẹ́ mìíràn nínú ilé Ọlọ́run yìí.
25 Tu autem Esdra secundum sapientiam Dei tui, quae est in manu tua, constitue iudices et praesides ut iudicent omni populo, qui est trans Flumen, his videlicet qui noverunt legem Dei tui, sed et imperitos docete libere.
Ìwọ Esra, ní ìbámu pẹ̀lú ọgbọ́n Ọlọ́run rẹ̀, èyí tí ó ní, yan àwọn adájọ́ àgbà àti àwọn onídàájọ́ láti máa ṣe ìdájọ́ fún àwọn ènìyàn agbègbè Eufurate, gbogbo àwọn tí ó mọ òfin Ọlọ́run rẹ. Ìwọ yóò sì kọ́ ẹnikẹ́ni tí kò mọ̀ àwọn òfin náà.
26 Et omnis qui non fecerit legem Dei tui, et legem regis diligenter, iudicium erit de eo sive in mortem, sive in exilium, sive in condemnationem substantiae eius, vel certe in carcerem.
Ẹnikẹ́ni tí kò bá ṣe ìgbọ́ràn sí òfin Ọlọ́run rẹ àti sí òfin ọba ní ó gbọdọ̀ kú tàbí kí a lé e jáde tàbí kí a gbẹ́sẹ̀ lé ẹrù rẹ̀ tàbí kí a sọ ọ́ sínú ẹ̀wọ̀n.
27 Benedictus Dominus Deus patrum nostrorum, qui dedit hoc in corde regis ut glorificaret domum Domini, quae est in Ierusalem,
Olùbùkún ni Olúwa, Ọlọ́run àwọn baba wa, ẹni tí ó fi sí ọkàn ọba láti mú ọlá wá sí ilé Olúwa ní Jerusalẹmu ní ọ̀nà yìí.
28 et in me inclinavit misericordiam suam coram rege et consiliatoribus eius, et universis principibus regis potentibus: et ego confortatus manu Domini Dei mei, quae erat in me, congregavi de Israel principes qui ascenderent mecum.
Ẹni tí ó jẹ́ kí ojúrere rẹ̀ tàn kàn mí níwájú ọba àti àwọn olùbádámọ̀ràn àti ní iwájú àwọn alágbára ìjòyè ọba. Nítorí ọwọ́ Olúwa Ọlọ́run wà lára mi, mo mú ọkàn le, mo sì kó àwọn olórí jọ láàrín àwọn ènìyàn Israẹli láti gòkè lọ pẹ̀lú mi.

< Esdræ 7 >