< Psalmorum 119 >

1 Alleluja. Beati immaculati in via, qui ambulant in lege Domini.
Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ọ̀nà wọn wà láìlẹ́ṣẹ̀, ẹni tí í rìn ní ìbámu pẹ̀lú òfin Olúwa.
2 Beati qui scrutantur testimonia ejus; in toto corde exquirunt eum.
Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ń pa òfin rẹ̀ mọ́ tí wọn sì ń wá a pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn.
3 Non enim qui operantur iniquitatem in viis ejus ambulaverunt.
Wọn kò ṣe ohun tí kò dára; wọ́n rìn ní ọ̀nà rẹ̀.
4 Tu mandasti mandata tua custodiri nimis.
Ìwọ ti la ìlànà rẹ̀ sílẹ̀ kí a sì pa wọ́n mọ́ gidigidi.
5 Utinam dirigantur viæ meæ ad custodiendas justificationes tuas.
Ọ̀nà mi ìbá dúró ṣinṣin láti máa pa òfin rẹ̀ mọ́!
6 Tunc non confundar, cum perspexero in omnibus mandatis tuis.
Nígbà náà, ojú kò ní tì mí nígbà tí mo bá ń kíyèsi àṣẹ rẹ̀ gbogbo.
7 Confitebor tibi in directione cordis, in eo quod didici judicia justitiæ tuæ.
Èmi yóò yìn ọ́ pẹ̀lú ọkàn ìdúró ṣinṣin bí èmi bá ti kọ́ òfin òdodo rẹ̀.
8 Justificationes tuas custodiam; non me derelinquas usquequaque.
Èmi yóò gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ̀, má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀ pátápátá.
9 In quo corrigit adolescentior viam suam? in custodiendo sermones tuos.
Báwo ni àwọn ọ̀dọ́ yóò ti ṣe pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́? Láti máa gbé ní ìbámu sí ọ̀rọ̀ rẹ.
10 In toto corde meo exquisivi te; ne repellas me a mandatis tuis.
Èmi wá ọ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi má ṣe jẹ́ kí èmi yapa kúrò nínú àṣẹ rẹ.
11 In corde meo abscondi eloquia tua, ut non peccem tibi.
Èmi ti pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́ ní ọkàn mi kí èmi má ba à ṣẹ̀ sí ọ.
12 Benedictus es, Domine; doce me justificationes tuas.
Ìyìn ni fún Olúwa; kọ́ mi ní àṣẹ rẹ.
13 In labiis meis pronuntiavi omnia judicia oris tui.
Pẹ̀lú ètè mi èmi tún ṣírò gbogbo òfin tí ó wá láti ẹnu rẹ.
14 In via testimoniorum tuorum delectatus sum, sicut in omnibus divitiis.
Èmi ń yọ̀ ní ọ̀nà ẹ̀rí rẹ, bí ènìyàn ṣe ń yọ̀ nínú ọláńlá.
15 In mandatis tuis exercebor, et considerabo vias tuas.
Èmi ń ṣe àṣàrò nínú ìlànà rẹ èmi sì kíyèsi ọ̀nà rẹ.
16 In justificationibus tuis meditabor: non obliviscar sermones tuos.
Inú mi dùn sí àṣẹ rẹ; èmi kì yóò gbàgbé ọ̀nà rẹ.
17 Retribue servo tuo, vivifica me, et custodiam sermones tuos.
Ṣe rere sí ìránṣẹ́ rẹ, èmi yóò sì wà láààyè; èmi yóò ṣe ìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ rẹ.
18 Revela oculos meos, et considerabo mirabilia de lege tua.
La ojú mi kí èmi lè ríran rí ohun ìyanu tí ó wà nínú òfin rẹ.
19 Incola ego sum in terra: non abscondas a me mandata tua.
Àlejò ní èmi jẹ́ láyé, má ṣe pa àṣẹ rẹ mọ́ fún mi.
20 Concupivit anima mea desiderare justificationes tuas in omni tempore.
Ọkàn mi pòruurù pẹ̀lú ìfojúsọ́nà nítorí òfin rẹ nígbà gbogbo.
21 Increpasti superbos; maledicti qui declinant a mandatis tuis.
Ìwọ fi àwọn agbéraga bú, àwọn tí a fi gégùn ún tí ó ṣìnà kúrò nínú àṣẹ rẹ.
22 Aufer a me opprobrium et contemptum, quia testimonia tua exquisivi.
Mú ẹ̀gàn àti àbùkù kúrò lára mi, nítorí èmi pa òfin rẹ mọ́.
23 Etenim sederunt principes, et adversum me loquebantur; servus autem tuus exercebatur in justificationibus tuis.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn alákòóso kójọpọ̀, wọ́n ń sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí mi, ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ rẹ ń ṣe àṣàrò nínú àṣẹ rẹ.
24 Nam et testimonia tua meditatio mea est, et consilium meum justificationes tuæ.
Òfin rẹ ni dídùn inú mi; àwọn ní olùbádámọ̀ràn mi.
25 Adhæsit pavimento anima mea: vivifica me secundum verbum tuum.
Ọkàn mí lẹ̀ mọ́ erùpẹ̀; ìwọ sọ mí di ààyè gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
26 Vias meas enuntiavi, et exaudisti me; doce me justificationes tuas.
Èmi tún ọ̀nà mi ṣírò ìwọ sì dá mi lóhùn; kọ́ mi ní àṣẹ rẹ.
27 Viam justificationum tuarum instrue me, et exercebor in mirabilibus tuis.
Jẹ́ kí n mọ ẹ̀kọ́ ìlànà rẹ: nígbà náà ni èmi yóò ṣe àṣàrò iṣẹ́ ìyanu rẹ.
28 Dormitavit anima mea præ tædio: confirma me in verbis tuis.
Ọkàn mi ń ṣe àárẹ̀ pẹ̀lú ìbànújẹ́; fi agbára fún mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
29 Viam iniquitatis amove a me, et de lege tua miserere mei.
Pa mí mọ́ kúrò nínú ọ̀nà ẹ̀tàn fún mi ní oore-ọ̀fẹ́ nípa òfin rẹ.
30 Viam veritatis elegi; judicia tua non sum oblitus.
Èmi ti yan ọ̀nà òtítọ́ èmi ti gbé ọkàn mi lé òfin rẹ.
31 Adhæsi testimoniis tuis, Domine; noli me confundere.
Èmi yára di òfin rẹ mú. Olúwa má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí.
32 Viam mandatorum tuorum cucurri, cum dilatasti cor meum.
Èmi sáré ní ipa ọ̀nà àṣẹ rẹ, nítorí ìwọ, ti tú ọkàn mi sílẹ̀.
33 Legem pone mihi, Domine, viam justificationum tuarum, et exquiram eam semper.
Kọ́ mi, Olúwa, láti tẹ̀lé àṣẹ rẹ; nígbà náà ni èmi yóò pa wọ́n mọ́ dé òpin.
34 Da mihi intellectum, et scrutabor legem tuam, et custodiam illam in toto corde meo.
Fún mi ní òye, èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́ èmi yóò sì máa kíyèsi i pẹ̀lú ọkàn mi.
35 Deduc me in semitam mandatorum tuorum, quia ipsam volui.
Fi ipa ọ̀nà àṣẹ rẹ hàn mí, nítorí nínú rẹ̀ ni èmi rí inú dídùn.
36 Inclina cor meum in testimonia tua, et non in avaritiam.
Yí ọkàn mi padà sí òfin rẹ kí ó má ṣe sí ojúkòkòrò mọ́.
37 Averte oculos meos, ne videant vanitatem; in via tua vivifica me.
Yí ojú mi padà kúrò láti máa wo ohun asán: pa ọ̀nà mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
38 Statue servo tuo eloquium tuum in timore tuo.
Mú ìlérí rẹ sẹ sí ìránṣẹ́ rẹ, nítorí òfin rẹ dára.
39 Amputa opprobrium meum quod suspicatus sum, quia judicia tua jucunda.
Yí ẹ̀gàn mi padà tí mo bẹ̀rù nítorí tí ìdájọ́ rẹ dára.
40 Ecce concupivi mandata tua: in æquitate tua vivifica me.
Kíyèsi i, ọkàn mi ti fà sí ẹ̀kọ́ rẹ! Pa ayé mi mọ́ nínú òdodo rẹ.
41 Et veniat super me misericordia tua, Domine; salutare tuum secundum eloquium tuum.
Jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà wá bá mi, Olúwa, ìgbàlà rẹ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ.
42 Et respondebo exprobrantibus mihi verbum, quia speravi in sermonibus tuis.
Nígbà náà ni èmi yóò dá ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí mi lóhùn, nítorí èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ.
43 Et ne auferas de ore meo verbum veritatis usquequaque, quia in judiciis tuis supersperavi.
Má ṣe gba ọ̀rọ̀ òtítọ́ láti ẹnu mi nítorí èmi ti gbé ìrètí mi sínú àṣẹ rẹ.
44 Et custodiam legem tuam semper, in sæculum et in sæculum sæculi.
Èmi yóò máa gbọ́rọ̀ sí òfin rẹ nígbà gbogbo láé àti láéláé.
45 Et ambulabam in latitudine, quia mandata tua exquisivi.
Èmi yóò máa rìn káàkiri ní òmìnira, nítorí èmi ti kígbe ẹ̀kọ́ rẹ jáde.
46 Et loquebar in testimoniis tuis in conspectu regum, et non confundebar.
Èmi yóò sọ̀rọ̀ òfin rẹ níwájú àwọn ọba ojú kì yóò sì tì mí,
47 Et meditabar in mandatis tuis, quæ dilexi.
nítorí èmi ní inú dídùn nínú àṣẹ rẹ nítorí èmi ní ìfẹ́ wọn.
48 Et levavi manus meas ad mandata tua, quæ dilexi, et exercebar in justificationibus tuis.
Èmi gbé ọwọ́ mi sókè nítorí àṣẹ rẹ, èyí tí èmi fẹ́ràn, èmi sì ń ṣe àṣàrò òfin rẹ̀.
49 Memor esto verbi tui servo tuo, in quo mihi spem dedisti.
Rántí ọ̀rọ̀ rẹ sí ìránṣẹ́ rẹ, nítorí ìwọ ti fún mi ní ìrètí.
50 Hæc me consolata est in humilitate mea, quia eloquium tuum vivificavit me.
Ìtùnú mi nínú ìpọ́njú mi ni èyí: ìpinnu rẹ pa ayé mi mọ́.
51 Superbi inique agebant usquequaque; a lege autem tua non declinavi.
Àwọn agbéraga fi mí ṣe ẹlẹ́yà láì dádúró, ṣùgbọ́n èmi kò padà nínú òfin rẹ.
52 Memor fui judiciorum tuorum a sæculo, Domine, et consolatus sum.
Èmi rántí àwọn òfin rẹ ìgbàanì, Olúwa, èmi sì rí ìtùnú nínú wọn.
53 Defectio tenuit me, pro peccatoribus derelinquentibus legem tuam.
Ìbínú dì mímú ṣinṣin nítorí àwọn ẹni búburú, tí wọ́n ti kọ òfin rẹ sílẹ̀.
54 Cantabiles mihi erant justificationes tuæ in loco peregrinationis meæ.
Òfin rẹ ni ọ̀rọ̀ ìpìlẹ̀ orin mi níbikíbi tí èmi ń gbé.
55 Memor fui nocte nominis tui, Domine, et custodivi legem tuam.
Ní òru èmi rántí orúkọ rẹ, Olúwa, èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́
56 Hæc facta est mihi, quia justificationes tuas exquisivi.
nítorí tí mo gba ẹ̀kọ́ rẹ gbọ́.
57 Portio mea, Domine, dixi custodire legem tuam.
Ìwọ ni ìpín mi, Olúwa: èmi ti pinnu láti tẹríba sí ọ̀rọ̀ rẹ.
58 Deprecatus sum faciem tuam in toto corde meo; miserere mei secundum eloquium tuum.
Èmi ti wá ojú rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi: fún mi ní oore-ọ̀fẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ.
59 Cogitavi vias meas, et converti pedes meos in testimonia tua.
Èmi ti kíyèsi ọ̀nà mi èmi sì ti gbé ìgbésẹ̀ mi sí òfin rẹ.
60 Paratus sum, et non sum turbatus, ut custodiam mandata tua.
Èmi yóò yára, ń kò ni lọ́ra láti gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ.
61 Funes peccatorum circumplexi sunt me, et legem tuam non sum oblitus.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹni búburú dì mí pẹ̀lú okùn, èmi kò ní gbàgbé òfin rẹ.
62 Media nocte surgebam ad confitendum tibi, super judicia justificationis tuæ.
Ní àárín ọ̀gànjọ́ òru èmi dìde láti fi ọpẹ́ fún ọ nítorí òfin òdodo rẹ.
63 Particeps ego sum omnium timentium te, et custodientium mandata tua.
Èmi jẹ́ ọ̀rẹ́ sí gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ, sí gbogbo àwọn tí ń tẹ̀lé ẹ̀kọ́ rẹ.
64 Misericordia tua, Domine, plena est terra; justificationes tuas doce me.
Ayé kún fún ìfẹ́ rẹ, Olúwa, kọ́ mi ní òfin rẹ.
65 Bonitatem fecisti cum servo tuo, Domine, secundum verbum tuum.
Ṣe rere sí ìránṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ, Olúwa.
66 Bonitatem, et disciplinam, et scientiam doce me, quia mandatis tuis credidi.
Kọ́ mi ní ìmọ̀ àti ìdájọ́ rere, nítorí mo gbàgbọ́ nínú àṣẹ rẹ.
67 Priusquam humiliarer ego deliqui: propterea eloquium tuum custodivi.
Kí a tó pọ́n mi lójú èmi ti ṣìnà, ṣùgbọ́n ni ìsinsin yìí èmi gbọ́rọ̀ sí ọ̀rọ̀ rẹ.
68 Bonus es tu, et in bonitate tua doce me justificationes tuas.
Ìwọ dára, ohun tí ìwọ sì ń ṣe rere ni; kọ́ mi ní ìlànà rẹ.
69 Multiplicata est super me iniquitas superborum; ego autem in toto corde meo scrutabor mandata tua.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn agbéraga ti gbìmọ̀ èké sí mí, èmi pa ẹ̀kọ́ rẹ mọ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi.
70 Coagulatum est sicut lac cor eorum; ego vero legem tuam meditatus sum.
Ọkàn wọn yigbì kò sì ní àánú, ṣùgbọ́n èmi ní inú dídùn nínú òfin rẹ.
71 Bonum mihi quia humiliasti me, ut discam justificationes tuas.
Ó dára fún mi kí a pọ́n mi lójú nítorí kí èmi lè kọ́ òfin rẹ.
72 Bonum mihi lex oris tui, super millia auri et argenti.
Òfin tí ó jáde láti ẹnu rẹ ju iyebíye sí mi lọ ó ju ẹgbẹ̀rún ẹyọ fàdákà àti wúrà lọ.
73 Manus tuæ fecerunt me, et plasmaverunt me: da mihi intellectum, et discam mandata tua.
Ọwọ́ rẹ ni ó dá mi tí ó sì mọ mí; fún mi ní òye láti kọ́ àṣẹ rẹ.
74 Qui timent te videbunt me et lætabuntur, quia in verba tua supersperavi.
Jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ máa yọ̀ nígbà tí wọ́n bá rí mi, nítorí èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ.
75 Cognovi, Domine, quia æquitas judicia tua, et in veritate tua humiliasti me.
Èmi mọ, Olúwa, nítorí òfin rẹ òdodo ni, àti ní òtítọ́ ni ìwọ pọ́n mi lójú.
76 Fiat misericordia tua ut consoletur me, secundum eloquium tuum servo tuo.
Kí ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà jẹ́ ìtùnú mi, gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ sí ìránṣẹ́ rẹ.
77 Veniant mihi miserationes tuæ, et vivam, quia lex tua meditatio mea est.
Jẹ́ kí àánú rẹ kí ó tọ̀ mí wá, kí èmi kí ó lè yè, nítorí òfin rẹ jẹ́ ìdùnnú mi.
78 Confundantur superbi, quia injuste iniquitatem fecerunt in me; ego autem exercebor in mandatis tuis.
Kí ojú kí ó ti àwọn agbéraga nítorí wọn pa mí lára láìnídìí ṣùgbọ́n èmi yóò máa ṣe àṣàrò nínú ẹ̀kọ́ rẹ.
79 Convertantur mihi timentes te, et qui noverunt testimonia tua.
Kí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ yí padà sí mi, àwọn tí ó ní òye òfin rẹ.
80 Fiat cor meum immaculatum in justificationibus tuis, ut non confundar.
Jẹ́ kí ọkàn mi wà láìlẹ́bi sí òfin rẹ, kí ojú kí ó má ṣe tì mí.
81 Defecit in salutare tuum anima mea, et in verbum tuum supersperavi.
Ọkàn mi ń fojú ṣọ́nà nítorí ìgbàlà rẹ, ṣùgbọ́n èmi ti fi ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ.
82 Defecerunt oculi mei in eloquium tuum, dicentes: Quando consolaberis me?
Ojú mi kùnà, pẹ̀lú wíwo ìpinnu rẹ; èmi wí pé, “Nígbà wo ni ìwọ yóò tù mí nínú?”
83 Quia factus sum sicut uter in pruina; justificationes tuas non sum oblitus.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi dàbí awọ-wáìnì lójú èéfín, èmi kò gbàgbé ìlànà rẹ.
84 Quot sunt dies servi tui? quando facies de persequentibus me judicium?
Báwo ni ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò ṣe dúró pẹ́ tó? Nígbà wo ni ìwọ yóò bá àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí mi wí?
85 Narraverunt mihi iniqui fabulationes, sed non ut lex tua.
Àwọn agbéraga wa ihò ìṣubú fún mi, tí ó lòdì sí òfin rẹ.
86 Omnia mandata tua veritas: inique persecuti sunt me, adjuva me.
Gbogbo àṣẹ rẹ yẹ ní ìgbẹ́kẹ̀lé; ràn mí lọ́wọ́, nítorí ènìyàn ń ṣe inúnibíni sí mi láìnídìí.
87 Paulominus consummaverunt me in terra; ego autem non dereliqui mandata tua.
Wọ́n fẹ́rẹ pa mí rẹ́ kúrò nínú ayé, ṣùgbọ́n èmi kò kọ ẹ̀kọ́ rẹ.
88 Secundum misericordiam tuam vivifica me, et custodiam testimonia oris tui.
Pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ, èmi yóò sì gba ẹ̀rí ẹnu rẹ̀ gbọ́.
89 In æternum, Domine, verbum tuum permanet in cælo.
Ọ̀rọ̀ rẹ, Olúwa, títí láé ni; ó dúró ṣinṣin ní ọ̀run.
90 In generationem et generationem veritas tua; fundasti terram, et permanet.
Òtítọ́ rẹ̀ ń lọ dé gbogbo ìran dé ìran; ìwọ ti dá ayé, ó sì dúró ṣinṣin.
91 Ordinatione tua perseverat dies, quoniam omnia serviunt tibi.
Òfin rẹ dúró di òní nítorí ohun gbogbo ń sìn ọ́.
92 Nisi quod lex tua meditatio mea est, tunc forte periissem in humilitate mea.
Bí òfin rẹ̀ kò bá jẹ́ dídùn inú mi, èmi ìbá ti ṣègbé nínú ìpọ́njú mi.
93 In æternum non obliviscar justificationes tuas, quia in ipsis vivificasti me.
Èmi kì yóò gbàgbé ẹ̀kọ́ rẹ láé, nítorí nípa wọn ni ìwọ ti pa ayé mi mọ́.
94 Tuus sum ego; salvum me fac: quoniam justificationes tuas exquisivi.
Gbà mí, nítorí èmi jẹ́ tìrẹ èmi ti wá ẹ̀kọ́ rẹ.
95 Me exspectaverunt peccatores ut perderent me; testimonia tua intellexi.
Àwọn ẹni búburú dúró láti pa mí run, ṣùgbọ́n èmi yóò kíyèsi ẹ̀rí rẹ.
96 Omnis consummationis vidi finem, latum mandatum tuum nimis.
Sí ohun pípé gbogbo èmi ti rí òpin; ṣùgbọ́n àṣẹ rẹ aláìlópin ni.
97 Quomodo dilexi legem tuam, Domine! tota die meditatio mea est.
Báwo ni èmi ti fẹ́ òfin rẹ tó! Èmi ń ṣe àṣàrò nínú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ pípẹ́ wá.
98 Super inimicos meos prudentem me fecisti mandato tuo, quia in æternum mihi est.
Àṣẹ rẹ mú mi gbọ́n ju àwọn ọ̀tá mi lọ, nítorí wọ́n wà pẹ̀lú mi láé.
99 Super omnes docentes me intellexi, quia testimonia tua meditatio mea est.
Èmi ní iyè inú ju gbogbo olùkọ́ mi lọ, nítorí èmi ń ṣe àṣàrò nínú òfin rẹ.
100 Super senes intellexi, quia mandata tua quæsivi.
Èmi ni òye ju àwọn àgbà lọ, nítorí mo gba ẹ̀kọ́ rẹ.
101 Ab omni via mala prohibui pedes meos, ut custodiam verba tua.
Èmi ti pa ẹsẹ̀ mi mọ́ nínú gbogbo ọ̀nà ibi nítorí kí èmi lè gba ọ̀rọ̀ rẹ.
102 A judiciis tuis non declinavi, quia tu legem posuisti mihi.
Èmi kò yà kúrò nínú òfin rẹ, nítorí ìwọ fúnra rẹ̀ ni ó kọ́ mi.
103 Quam dulcia faucibus meis eloquia tua! super mel ori meo.
Báwo ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe dùn mọ́ mi lẹ́nu tó, ó dùn ju oyin lọ ní ẹnu mi!
104 A mandatis tuis intellexi; propterea odivi omnem viam iniquitatis.
Èmi rí òye gbà nínú ẹ̀kọ́ rẹ; nítorí náà èmi kórìíra gbogbo ọ̀nà tí kò tọ́.
105 Lucerna pedibus meis verbum tuum, et lumen semitis meis.
Ọ̀rọ̀ rẹ ni fìtílà sí ẹsẹ̀ mi àti ìmọ́lẹ̀ sí ipa ọ̀nà mi.
106 Juravi et statui custodire judicia justitiæ tuæ.
Èmi ti ṣe ìbúra èmi sì ti tẹnumọ́ ọn wí pé èmi yóò máa tẹ̀lé òfin òdodo rẹ.
107 Humiliatus sum usquequaque, Domine; vivifica me secundum verbum tuum.
A pọ́n mi lójú gidigidi; Olúwa, sọ mi di ààyè, gẹ́gẹ́ bi ọ̀rọ̀ rẹ
108 Voluntaria oris mei beneplacita fac, Domine, et judicia tua doce me.
Olúwa, gba ìyìn àtinúwá ẹnu mi, kí o sì kọ́ mi ní òfin rẹ̀.
109 Anima mea in manibus meis semper, et legem tuam non sum oblitus.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ayé mi wà ni ọwọ́ mi nígbà gbogbo, èmi kò ní gbàgbé òfin rẹ.
110 Posuerunt peccatores laqueum mihi, et de mandatis tuis non erravi.
Àwọn ẹni búburú ti dẹ okùn sílẹ̀ fún mi, ṣùgbọ́n èmi kò ṣìnà kúrò nínú ẹ̀kọ́ rẹ.
111 Hæreditate acquisivi testimonia tua in æternum, quia exsultatio cordis mei sunt.
Òfin rẹ ni ogún mi láéláé; àwọn ni ayọ̀ ọkàn mi.
112 Inclinavi cor meum ad faciendas justificationes tuas in æternum, propter retributionem.
Ọkàn mi ti lé pípa òfin rẹ mọ́ láé dé òpin.
113 Iniquos odio habui, et legem tuam dilexi.
Èmi kórìíra àwọn ọlọ́kàn méjì, ṣùgbọ́n èmi fẹ́ òfin rẹ.
114 Adjutor et susceptor meus es tu, et in verbum tuum supersperavi.
Ìwọ ni ààbò mi àti asà mi; èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ.
115 Declinate a me, maligni, et scrutabor mandata Dei mei.
Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin olùṣe búburú, kí èmi lè pa àṣẹ Ọlọ́run mi mọ́!
116 Suscipe me secundum eloquium tuum, et vivam, et non confundas me ab exspectatione mea.
Gbé mi sókè gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ, kí èmi kí ó lè yè Má sì jẹ́ kí ojú ìrètí mi kí ó tì mí.
117 Adjuva me, et salvus ero, et meditabor in justificationibus tuis semper.
Gbé mi sókè, èmí yóò sì wa láìléwu; nígbà gbogbo ni èmi yóò máa júbà òfin rẹ.
118 Sprevisti omnes discedentes a judiciis tuis, quia injusta cogitatio eorum.
Ìwọ kọ gbogbo àwọn tí ó ṣìnà kúrò nínú òfin rẹ, nítorí ẹ̀tàn wọn asán ni.
119 Prævaricantes reputavi omnes peccatores terræ; ideo dilexi testimonia tua.
Gbogbo àwọn ẹni búburú ní ayé ni ìwọ yọ kúrò bí i ìdàrọ́; nítorí náà, èmi fẹ́ òfin rẹ̀.
120 Confige timore tuo carnes meas; a judiciis enim tuis timui.
Ara mi wárìrì ní ìbẹ̀rù nítorí rẹ̀: èmi dúró ní ìbẹ̀rù òfin rẹ.
121 Feci judicium et justitiam: non tradas me calumniantibus me.
Èmi ti ṣe ohun tí i ṣe òdodo àti ẹ̀tọ́: má ṣe fi mí sílẹ̀ fún àwọn tó ń ni mí lára.
122 Suscipe servum tuum in bonum: non calumnientur me superbi.
Mú kí àlàáfíà ìránṣẹ́ rẹ dájú: má ṣe jẹ́ kí àwọn agbéraga ni mi lára.
123 Oculi mei defecerunt in salutare tuum, et in eloquium justitiæ tuæ.
Ojú mi kùnà, fún wíwo ìgbàlà rẹ, fún wíwo ìpinnu òdodo rẹ.
124 Fac cum servo tuo secundum misericordiam tuam, et justificationes tuas doce me.
Ṣe pẹ̀lú ìránṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí dídúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ kí o sì kọ́ mi ní àṣẹ rẹ.
125 Servus tuus sum ego: da mihi intellectum, ut sciam testimonia tua.
Èmi ni ìránṣẹ́ rẹ; ẹ fún mi ní òye kí èmi lè ní òye òfin rẹ
126 Tempus faciendi, Domine: dissipaverunt legem tuam.
Ó tó àsìkò fún ọ láti ṣe iṣẹ́, Olúwa; nítorí òfin rẹ ti fọ́.
127 Ideo dilexi mandata tua super aurum et topazion.
Nítorí èmi fẹ́ràn àṣẹ rẹ ju wúrà, àní ju wúrà dídára lọ,
128 Propterea ad omnia mandata tua dirigebar; omnem viam iniquam odio habui.
nítorí èmi kíyèsi gbogbo ẹ̀kọ́ òtítọ́ rẹ̀, èmi kórìíra gbogbo ipa ọ̀nà búburú.
129 Mirabilia testimonia tua: ideo scrutata est ea anima mea.
Òfin rẹ̀ ìyanu ni: nítorí náà èmi gbà wọ́n gbọ́.
130 Declaratio sermonum tuorum illuminat, et intellectum dat parvulis.
Ìṣípayá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú ìmọ́lẹ̀ wá; ó fi òye fún àwọn òpè.
131 Os meum aperui, et attraxi spiritum: quia mandata tua desiderabam.
Èmi ya ẹnu mi mo sì mí hẹlẹ, nítorí èmi fojú ṣọ́nà sí àṣẹ rẹ.
132 Aspice in me, et miserere mei, secundum judicium diligentium nomen tuum.
Yí padà sí mi kí o sì ṣàánú fún mi, bí ìwọ ṣe máa ń ṣe nígbà gbogbo sí àwọn tí ó fẹ́ràn orúkọ rẹ.
133 Gressus meos dirige secundum eloquium tuum, et non dominetur mei omnis injustitia.
Fi ìṣísẹ̀ mi múlẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ rẹ, má ṣe jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ borí mi.
134 Redime me a calumniis hominum ut custodiam mandata tua.
Rà mí padà lọ́wọ́ aninilára ènìyàn, kí èmi lè gbọ́ ẹ̀kọ́ rẹ.
135 Faciem tuam illumina super servum tuum, et doce me justificationes tuas.
Jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tàn sí ìránṣẹ́ rẹ lára kí ó sì kọ́ mi ní àṣẹ rẹ.
136 Exitus aquarum deduxerunt oculi mei, quia non custodierunt legem tuam.
Omijé sàn jáde ní ojú mi, nítorí wọn kò gba pé òfin rẹ̀ jẹ́ òtítọ́.
137 Justus es, Domine, et rectum judicium tuum.
Olódodo ni ìwọ Olúwa ìdájọ́ rẹ sì dúró ṣinṣin.
138 Mandasti justitiam testimonia tua, et veritatem tuam nimis.
Òfin ti ìwọ gbé kalẹ̀ jẹ́ òdodo: wọ́n yẹ ni ìgbẹ́kẹ̀lé.
139 Tabescere me fecit zelus meus, quia obliti sunt verba tua inimici mei.
Ìtara mi ti pa mí run, nítorí àwọn ọ̀tá mi fi ojú fo ọ̀rọ̀ rẹ dá.
140 Ignitum eloquium tuum vehementer, et servus tuus dilexit illud.
Wọ́n ti dán ìpinnu rẹ wò pátápátá ìránṣẹ́ rẹ sì fẹ́ràn wọ́n.
141 Adolescentulus sum ego et contemptus; justificationes tuas non sum oblitus.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti ẹni ẹ̀gàn èmi kò ni gbàgbé ẹ̀kọ́ rẹ.
142 Justitia tua, justitia in æternum, et lex tua veritas.
Òdodo rẹ wà títí láé òtítọ́ ni òfin rẹ̀.
143 Tribulatio et angustia invenerunt me; mandata tua meditatio mea est.
Ìyọnu àti ìpọ́njú wá sórí mi, ṣùgbọ́n àṣẹ rẹ ni inú dídùn mi.
144 Æquitas testimonia tua in æternum: intellectum da mihi, et vivam.
Òfin rẹ jẹ́ òtítọ́ láé; fún mi ní òye kí èmi lè yè.
145 Clamavi in toto corde meo: exaudi me, Domine; justificationes tuas requiram.
Èmi kígbe pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi: dá mi lóhùn Olúwa, èmi yóò sì gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ.
146 Clamavi ad te; salvum me fac: ut custodiam mandata tua.
Èmi kígbe pè ọ́; gbà mí èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́.
147 Præveni in maturitate, et clamavi: quia in verba tua supersperavi.
Èmi dìde ṣáájú àfẹ̀mọ́júmọ́ èmi ké fún ìrànlọ́wọ́; èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ.
148 Prævenerunt oculi mei ad te diluculo, ut meditarer eloquia tua.
Ojú mi ṣáájú ìṣọ́ òru, nítorí kí èmi lè ṣe àṣàrò nínú ọ̀rọ̀ rẹ.
149 Vocem meam audi secundum misericordiam tuam, Domine, et secundum judicium tuum vivifica me.
Gbọ́ ohùn mi ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ: pa ayé mi mọ́, Olúwa, gẹ́gẹ́ bí òfin rẹ.
150 Appropinquaverunt persequentes me iniquitati: a lege autem tua longe facti sunt.
Àwọn tí ń gbìmọ̀ ìlànà búburú wà ní tòsí, ṣùgbọ́n wọ́n jìnnà sí òfin rẹ.
151 Prope es tu, Domine, et omnes viæ tuæ veritas.
Síbẹ̀ ìwọ wà ní tòsí, Olúwa, àti gbogbo àṣẹ rẹ jẹ́ òtítọ́.
152 Initio cognovi de testimoniis tuis, quia in æternum fundasti ea.
Láti ọjọ́ pípẹ́ wá èmi ti kọ́ nínú òfin rẹ tí ìwọ ti fi ìdí wọn múlẹ̀ láéláé.
153 Vide humilitatem meam, et eripe me, quia legem tuam non sum oblitus.
Wo ìpọ́njú mi kí o sì gbà mí, nítorí èmi kò gbàgbé òfin rẹ.
154 Judica judicium meum, et redime me: propter eloquium tuum vivifica me.
Gba ẹjọ́ mi rò kí o sì rà mí padà; pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ.
155 Longe a peccatoribus salus, quia justificationes tuas non exquisierunt.
Ìgbàlà jìnnà sí àwọn ẹni búburú nítorí wọn kò wá àṣẹ rẹ.
156 Misericordiæ tuæ multæ, Domine; secundum judicium tuum vivifica me.
Ìyọ́nú rẹ̀ tóbi, Olúwa; pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin rẹ.
157 Multi qui persequuntur me, et tribulant me; a testimoniis tuis non declinavi.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn ọ̀tá tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí mi, ṣùgbọ́n èmi kò tí ì yípadà kúrò nínú òfin rẹ.
158 Vidi prævaricantes et tabescebam, quia eloquia tua non custodierunt.
Èmi wo àwọn ẹlẹ́tàn, inú mi sì bàjẹ́ nítorí wọn kò gba ọ̀rọ̀ rẹ gbọ́.
159 Vide quoniam mandata tua dilexi, Domine: in misericordia tua vivifica me.
Wo bí èmi ṣe fẹ́ràn ẹ̀kọ́ rẹ; pa ayé mi mọ́, Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ.
160 Principium verborum tuorum veritas; in æternum omnia judicia justitiæ tuæ.
Òtítọ́ ni gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ; gbogbo òfin òdodo rẹ láéláé ni.
161 Principes persecuti sunt me gratis, et a verbis tuis formidavit cor meum.
Àwọn alákòóso ṣe inúnibíni sí mi láìnídìí, ṣùgbọ́n ọkàn mi wárìrì sí ọ̀rọ̀ rẹ.
162 Lætabor ego super eloquia tua, sicut qui invenit spolia multa.
Èmi yọ̀ nínú ìpinnu rẹ bí ẹni tí ó rí ìkógun púpọ̀.
163 Iniquitatem odio habui, et abominatus sum, legem autem tuam dilexi.
Èmi kórìíra mo sì kọ èké ṣíṣe ṣùgbọ́n mo fẹ́ràn òfin rẹ.
164 Septies in die laudem dixi tibi, super judicia justitiæ tuæ.
Èmi yìn ọ́ ní ìgbà méje lójúmọ́ nítorí òfin òdodo rẹ.
165 Pax multa diligentibus legem tuam, et non est illis scandalum.
Àlàáfíà púpọ̀ wà fún àwọn tí ó ní ìfẹ́ sí òfin rẹ, kò sì ṣí ohun tí ó lè mú wọn kọsẹ̀.
166 Exspectabam salutare tuum, Domine, et mandata tua dilexi.
Èmi yóò dúró de ìgbàlà rẹ, Olúwa, èmi yóò sì tẹ̀lé àṣẹ rẹ.
167 Custodivit anima mea testimonia tua, et dilexit ea vehementer.
Èmi gba òfin rẹ gbọ́, nítorí mo fẹ́ràn wọn púpọ̀púpọ̀.
168 Servavi mandata tua et testimonia tua, quia omnes viæ meæ in conspectu tuo.
Èmi ṣe ìgbọ́ràn sí ẹ̀kọ́ rẹ àti òfin rẹ, nítorí ìwọ mọ gbogbo ọ̀nà mi.
169 Appropinquet deprecatio mea in conspectu tuo, Domine; juxta eloquium tuum da mihi intellectum.
Jẹ́ kí igbe mi wá sí iwájú rẹ, Olúwa; fún mi ní òye gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
170 Intret postulatio mea in conspectu tuo; secundum eloquium tuum eripe me.
Jẹ́ kí ẹ̀bẹ̀ mi wá sí iwájú rẹ; gbà mí gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ.
171 Eructabunt labia mea hymnum, cum docueris me justificationes tuas.
Ètè mi yóò sọ ìyìn jáde, nítorí ìwọ kọ́ mi ní ìlànà rẹ.
172 Pronuntiabit lingua mea eloquium tuum, quia omnia mandata tua æquitas.
Jẹ́ kí ahọ́n mi kọ orin ọ̀rọ̀ rẹ, nítorí gbogbo àṣẹ rẹ jẹ́ òdodo.
173 Fiat manus tua ut salvet me, quoniam mandata tua elegi.
Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ ṣetán láti ràn mí lọ́wọ́, nítorí èmi ti yan ẹ̀kọ́ rẹ.
174 Concupivi salutare tuum, Domine, et lex tua meditatio mea est.
Èmi wo ọ̀nà fún ìgbàlà rẹ, Olúwa, àti òfin rẹ jẹ́ dídùn inú mi.
175 Vivet anima mea, et laudabit te, et judicia tua adjuvabunt me.
Jẹ́ kí èmi wà láààyè ki èmi lè yìn ọ́, kí o sì jẹ́ kí òfin rẹ mú mi dúró.
176 Erravi sicut ovis quæ periit: quære servum tuum, quia mandata tua non sum oblitus.
Èmí ti ṣìnà bí àgùntàn tí ó sọnù. Wá ìránṣẹ́ rẹ, nítorí èmi kò gbàgbé àṣẹ rẹ.

< Psalmorum 119 >