< Deuteronomii 11 >
1 Ama itaque Dominum Deum tuum, et observa præcepta ejus et cæremonias, judicia atque mandata, omni tempore.
Ẹ fẹ́ràn Olúwa Ọlọ́run yín, kí ẹ sì pa ìfẹ́ rẹ̀, ìlànà rẹ̀, òfin rẹ̀ àti àṣẹ rẹ̀ mọ́ ní ìgbà gbogbo.
2 Cognoscite hodie quæ ignorant filii vestri, qui non viderunt disciplinam Domini Dei vestri, magnalia ejus et robustam manum, extentumque brachium,
Ẹ rántí lónìí pé, kì í ṣe àwọn ọmọ yín, ni ó rí ìbáwí Olúwa Ọlọ́run yín; títóbi rẹ̀, ọwọ́ agbára rẹ̀, nína ọwọ́ rẹ̀;
3 signa et opera quæ fecit in medio Ægypti Pharaoni regi, et universæ terræ ejus,
iṣẹ́ àmì rẹ̀ àti ohun tí ó ṣe ní àárín àwọn ará Ejibiti, sí Farao ọba Ejibiti àti gbogbo orílẹ̀-èdè rẹ̀.
4 omnique exercitui Ægyptiorum, et equis ac curribus: quomodo operuerint eos aquæ maris Rubri, cum vos persequerentur, et deleverit eos Dominus usque in præsentem diem:
Ohun tí ó ṣe sí àwọn jagunjagun Ejibiti, sí kẹ̀kẹ́ ogun àti ẹlẹ́ṣin rẹ̀: bí ó ṣe rì wọ́n sínú Òkun Pupa, bí wọ́n ṣe ń lé e yín tí Olúwa fi pa wọ́n run pátápátá títí di òní olónìí yìí.
5 vobisque quæ fecerit in solitudine donec veniretis ad hunc locum:
Kì í ṣe àwọn ọmọ yín ni ó rí ohun tí ó ṣe fún un yín ní aginjù, títí ẹ fi dé ìhín yìí,
6 et Dathan atque Abiron filiis Eliab, qui fuit filius Ruben: quos aperto ore suo terra absorbuit, cum domibus et tabernaculis, et universa substantia eorum, quam habebant in medio Israël.
ohun tí ó ṣe sí Datani àti Abiramu, àwọn ọmọ Eliabu, ẹ̀yà Reubeni, bí ilẹ̀ ti lanu ní ojú gbogbo ará Israẹli tí ó sì gbé wọn mì pẹ̀lú gbogbo ìdílé wọn, gbogbo àgọ́ ọ wọn àti gbogbo ohun alààyè tí ó jẹ́ tiwọn.
7 Oculi vestri viderunt opera Domini magna quæ fecit,
Ṣùgbọ́n ojú u yín gan an ni ó rí gbogbo nǹkan ńlá wọ̀nyí tí Olúwa ti ṣe.
8 ut custodiatis universa mandata illius, quæ ego hodie præcipio vobis, et possitis introire, et possidere terram, ad quam ingredimini,
Nítorí náà, ẹ kíyèsi gbogbo àṣẹ tí mo ń fún yín lónìí, kí ẹ ba à lè lágbára àti lọ, kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà tí ẹ ó la Jordani kọjá lọ.
9 multoque in ea vivatis tempore: quam sub juramento pollicitus est Dominus patribus vestris, et semini eorum, lacte et melle manantem.
Kí ẹ ba à lè pẹ́ ní orí ilẹ̀ tí Olúwa ti búra fún àwọn baba ńlá a yín, láti fún àwọn àti àwọn ọmọ wọn: ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin.
10 Terra enim, ad quam ingrederis possidendam, non est sicut terra Ægypti, de qua existi, ubi jacto semine in hortorum morem aquæ ducuntur irriguæ:
Ilẹ̀ tí ẹ̀ ń wọ̀ lọ láti gbà kò rí bí ilẹ̀ Ejibiti, níbi tí ẹ ti wá, níbi tó jẹ́ wí pé ẹsẹ̀ yín ni ẹ fi ń rìn lọ bomirin irúgbìn tí ẹ gbìn bí oko ẹ̀fọ́.
11 sed montuosa est et campestris, de cælo expectans pluvias,
Ṣùgbọ́n ilẹ̀ tí ẹ ó la Jordani kọjá láti gbà, jẹ́ ilẹ̀ olókè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀ tí òjò ń rọ̀ sí latọ̀run.
12 quam Dominus Deus tuus semper invisit, et oculi illius in ea sunt a principio anni usque ad finem ejus.
Ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run yín ń mójútó ni, ojú Olúwa Ọlọ́run yín sì ń fi ìgbà gbogbo wà lórí rẹ̀, láti ìbẹ̀rẹ̀ ọdún dé òpin ọdún.
13 Si ergo obedieritis mandatis meis, quæ ego hodie præcipio vobis, ut diligatis Dominum Deum vestrum, et serviatis ei in toto corde vestro, et in tota anima vestra:
Nítorí náà, bí ẹ bá gbọ́rọ̀ sí àṣẹ tí mo fún un yín lónìí tọkàntọkàn: tí ẹ fẹ́ràn Olúwa Ọlọ́run yín, tí ẹ sì sìn ín, pẹ̀lú gbogbo àyà yín àti gbogbo ọkàn yín:
14 dabit pluviam terræ vestræ temporaneam et serotinam, ut colligatis frumentum, et vinum, et oleum,
nígbà náà, èmi yóò rọ òjò sórí ilẹ̀ ẹ yín lákòókò rẹ̀, àti òjò àkọ́rọ̀ àti ti àrọ̀kẹ́yìn, kí ẹ ba à lè kórè oúnjẹ yín wọlé àní wáìnì tuntun àti òróró.
15 fœnumque ex agris ad pascenda jumenta, et ut ipsi comedatis ac saturemini.
Èmi yóò mú kí koríko hù lórí ilẹ̀ yín fún àwọn ohun ọ̀sìn in yín, ẹ ó sì jẹ, ẹ ó sì yó.
16 Cavete ne forte decipiatur cor vestrum, et recedatis a Domino, serviatisque diis alienis, et adoretis eos:
Ẹ ṣọ́ra, kí a má ba à tàn yín jẹ láti yípadà kí ẹ sì sin ọlọ́run mìíràn àti láti máa foríbalẹ̀ fún wọn.
17 iratusque Dominus claudat cælum, et pluviæ non descendant, nec terra det germen suum, pereatisque velociter de terra optima, quam Dominus daturus est vobis.
Nígbà náà ni ìbínú Olúwa yóò sì ru sí i yín, Òun yóò ti ìlẹ̀kùn ọ̀run kí òjò má ba à rọ̀, ilẹ̀ kì yóò sì so èso kankan, ẹ ó sì ṣègbé ní ilẹ̀ rere tí Olúwa fi fún un yín.
18 Ponite hæc verba mea in cordibus et in animis vestris, et suspendite ea pro signo in manibus, et inter oculos vestros collocate.
Ẹ fi gbogbo ọ̀rọ̀ mi wọ̀nyí sí àyà a yín, àti ọkàn an yín, ẹ so wọ́n bí àmì sórí ọwọ́ yín, kí ẹ sì so wọ́n mọ́ iwájú orí yín.
19 Docete filios vestros ut illa meditentur: quando sederis in domo tua, et ambulaveris in via, et accubueris atque surrexeris.
Ẹ máa fi wọ́n kọ́ àwọn ọmọ yín, ẹ máa sọ̀rọ̀ nípa wọn bí ẹ bá jókòó nínú ilé, àti ní ojú ọ̀nà bí ẹ bá ń rìn lọ, bí ẹ bá sùn àti bí ẹ bá jí.
20 Scribes ea super postes et januas domus tuæ,
Kí ìwọ kí ó kọ wọ́n sára òpó ilé rẹ̀, àti sí ara ìlẹ̀kùn ọ̀nà òde rẹ.
21 ut multiplicentur dies tui, et filiorum tuorum in terra, quam juravit Dominus patribus tuis, ut daret eis quamdiu cælum imminet terræ.
Kí ọjọ́ ọ yín àti ti àwọn ọmọ yín lè pọ̀ ní ilẹ̀ tí Olúwa ti búra láti fi fún àwọn baba ńlá a yín, ní ìwọ̀n ìgbà tí ọ̀run wà lókè tí ayé sì ń bẹ ní ìsàlẹ̀.
22 Si enim custodieritis mandata quæ ego præcipio vobis, et feceritis ea, ut diligatis Dominum Deum vestrum, et ambuletis in omnibus viis ejus, adhærentes ei,
Bí ẹ bá fi ara balẹ̀ kíyèsi àwọn òfin tí mo ń fún un yín, láti tẹ̀lé, láti fẹ́ Olúwa Ọlọ́run yín, láti máa rìn ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀ àti láti dìímú ṣinṣin:
23 disperdet Dominus omnes gentes istas ante faciem vestram, et possidebitis eas, quæ majores et fortiores vobis sunt.
Olúwa yóò sì lé gbogbo orílẹ̀-èdè wọ̀nyí kúrò níwájú u yín. Ẹ ó sì gba orílẹ̀-èdè tí ó lágbára tí ó sì tóbi jù yín lọ.
24 Omnis locus, quem calcaverit pes vester, vester erit. A deserto, et a Libano, a flumine magno Euphrate usque ad mare occidentale erunt termini vestri.
Gbogbo ibi tí ẹ bá fi ẹsẹ̀ ẹ yín tẹ̀ ni yóò jẹ́ tiyín, ilẹ̀ ẹ yín yóò gbilẹ̀ láti aginjù dé Lebanoni, àti láti odò Eufurate dé Òkun Ńlá.
25 Nullus stabit contra vos: terrorem vestrum et formidinem dabit Dominus Deus vester super omnem terram quam calcaturi estis, sicut locutus est vobis.
Kò sí ẹni náà tí yóò lè kò yín lójú ìjà, Olúwa Ọlọ́run yín yóò fi ẹ̀rù àti ìwárìrì i yín sórí gbogbo ilẹ̀ náà bí ó ti ṣèlérí fún un yín ní gbogbo ibi tí ẹ bá lọ.
26 En propono in conspectu vestro hodie benedictionem et maledictionem:
Ẹ kíyèsi i, mo fi ìbùkún àti ègún lélẹ̀ níwájú u yín lónìí:
27 benedictionem, si obedieritis mandatis Domini Dei vestri, quæ ego hodie præcipio vobis:
ìbùkún ni, bí ẹ bá pa òfin Olúwa Ọlọ́run yín, tí mo ń fún un yín lónìí mọ́.
28 maledictionem, si non obedieritis mandatis Domini Dei vestri, sed recesseritis de via, quam ego nunc ostendo vobis, et ambulaveritis post deos alienos, quos ignoratis.
Ègún ni, bí ẹ bá ṣàìgbọ́ràn, sí òfin Olúwa Ọlọ́run yín, tí ẹ sì yapa kúrò ní ọ̀nà tí mo ti là sílẹ̀ fún yín lónìí, nípa títẹ̀lé ọlọ́run mìíràn, tí ẹ kò tí ì mọ̀.
29 Cum vero introduxerit te Dominus Deus tuus in terram, ad quam pergis habitandam, pones benedictionem super montem Garizim, maledictionem super montem Hebal:
Nígbà tí Olúwa Ọlọ́run yín bá ti mú un yín dé ilẹ̀ náà tí ẹ ń wọ̀ láti gbà, kí ẹ kéde àwọn ìbùkún náà ní orí òkè Gerisimu, kí ẹ sì kéde àwọn ègún ní orí òkè Ebali.
30 qui sunt trans Jordanem, post viam quæ vergit ad solis occubitum in terra Chananæi, qui habitat in campestribus contra Galgalam, quæ est juxta vallem tendentem et intrantem procul.
Bí ẹ ti mọ̀ pé àwọn òkè wọ̀nyí wà ní ìkọjá a Jordani ní apá ìwọ̀-oòrùn lójú ọ̀nà lọ sí ìhà ìlà-oòrùn, ní ẹ̀gbẹ́ igi ńlá igbó More, ní ilẹ̀ àwọn ará a Kenaani, tí wọ́n ń gbé ní aginjù, ni agbègbè Gilgali.
31 Vos enim transibitis Jordanem, ut possideatis terram quam Dominus Deus vester daturus est vobis, ut habeatis et possideatis illam.
Ẹ ti ṣetán láti la Jordani kọjá láti lè gba ilẹ̀ náà tí Olúwa Ọlọ́run yín ń fún un yín. Nígbà tí ẹ bá gbà á, tí ẹ bá sì ń gbé ibẹ̀,
32 Videte ergo ut impleatis cæremonias atque judicia, quæ ego hodie ponam in conspectu vestro.
ẹ rí i dájú pé ẹ̀ ń gbọ́rọ̀ sí gbogbo ìlànà àti òfin tí mo ń gbé kalẹ̀ fún un yín lónìí.