< Isaiæ 62 >
1 Propter Sion non tacebo, et propter Ierusalem non quiescam, donec egrediatur ut splendor iustus eius, et salvator eius ut lampas accendatur.
Nítorí Sioni èmi kì yóò dákẹ́, nítorí i Jerusalẹmu èmi kì yóò sinmi ẹnu, títí tí òdodo rẹ̀ yóò fi tàn bí òwúrọ̀, àti ìgbàlà rẹ̀ bí i fìtílà tí ń jó geere.
2 Et videbunt Gentes iustum tuum, et cuncti reges inclytum tuum: et vocabitur tibi nomen novum, quod os Domini nominabit.
Àwọn orílẹ̀-èdè yóò rí òdodo rẹ, àti gbogbo ọba ògo rẹ a ó sì máa pè ọ́ ní orúkọ mìíràn èyí tí ẹnu Olúwa yóò fi fún un.
3 Et eris corona gloriæ in manu Domini, et diadema regni in manu Dei tui.
Ìwọ yóò sì jẹ́ adé dídán ní ọwọ́ Olúwa, adé ọba ní ọwọ́ Ọlọ́run rẹ.
4 Non vocaberis ultra Derelicta: et terra tua non vocabitur amplius Desolata: sed vocaberis Voluntas mea in ea, et terra tua inhabitata. quia complacuit Domino in te: et terra tua inhabitabitur.
Wọn kì yóò pè ọ́ ní ìkọ̀sílẹ̀ mọ́ tàbí kí wọ́n pe ilẹ̀ rẹ ní ahoro. Ṣùgbọ́n a ó máa pè ọ́ ní Hẹfsiba, àti ilẹ̀ rẹ ní Beula; nítorí Olúwa yóò yọ́nú sí ọ àti ilẹ̀ rẹ ni a ó gbé níyàwó.
5 Habitabit enim iuvenis cum virgine, et habitabunt in te filii tui. Et gaudebit sponsus super sponsam, et gaudebit super te Deus tuus.
Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́mọkùnrin tí í gbé ọ̀dọ́mọbìnrin níyàwó, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọkùnrin rẹ yóò gbé ọ níyàwó Gẹ́gẹ́ bí ọkọ ìyàwó ṣe é yọ̀ lórí ìyàwó rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Ọlọ́run rẹ yóò yọ̀ lórí rẹ.
6 Super muros tuos Ierusalem constitui custodes, tota die, et tota nocte in perpetuum non tacebunt. Qui reminiscimini Domini, ne taceatis,
Èmi ti fi olùṣọ́ ránṣẹ́ sórí odi rẹ ìwọ Jerusalẹmu; wọn kì yóò lè dákẹ́ tọ̀sán tòru. Ẹ̀yin tí ń ké pe Olúwa, ẹ má ṣe fúnra yín ní ìsinmi,
7 et ne detis silentium ei, donec stabiliat, et donec ponat Ierusalem laudem in terra.
àti kí ẹ má ṣe fún òun pẹ̀lú ní ìsinmi títí tí yóò fi fi ìdí Jerusalẹmu múlẹ̀ tí yóò sì fi ṣe ìyìn orí ilẹ̀ ayé.
8 Iuravit Dominus in dextera sua, et in brachio fortitudinis suæ: Si dedero triticum tuum ultra cibum inimicis tuis: et si biberint filii alieni vinum tuum, in quo laborasti.
Olúwa ti búra pẹ̀lú ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti nípa agbára apá rẹ: “Èmi kì yóò jẹ́ kí ìyẹ̀fun rẹ di oúnjẹ fún ọ̀tá rẹ bẹ́ẹ̀ ni àwọn àjèjì kì yóò mu wáìnì tuntun rẹ mọ́ èyí tí ìwọ ti ṣe làálàá fún;
9 Quia qui congregant illud, comedent, et laudabunt Dominum: et qui comportant illud, bibent in atriis sanctis meis.
ṣùgbọ́n àwọn tí ó bá kóórè rẹ̀ ni yóò jẹ ẹ́, tí wọn ó sì yin Olúwa, àti àwọn tí wọ́n bá kó àjàrà jọ ni wọn ó mú un, nínú àgbàlá ilé mímọ́ mi.”
10 Transite, transite per portas, præparate viam populo, planum facite iter, eligite lapides, et elevate signum ad Populos.
Ẹ kọjá, ẹ kọjá ní ẹnu ibodè náà! Ẹ tún ọ̀nà ṣe fún àwọn ènìyàn. Ẹ mọ ọ́n sókè, ṣe ojú ọ̀nà òpópó! Ẹ ṣa òkúta kúrò. Ẹ gbé àsíá sókè fún àwọn orílẹ̀-èdè.
11 Ecce Dominus auditum fecit in extremis terræ, dicite filiæ Sion: Ecce Salvator tuus venit: ecce merces eius cum eo, et opus eius coram illo.
Olúwa ti ṣe ìkéde títí dé òpin ilẹ̀ ayé: “Ẹ sọ fún ọmọbìnrin Sioni pé, ‘Kíyèsi i, Olùgbàlà rẹ ń bọ̀! Kíyèsi i, èrè ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀, àti ẹ̀san rẹ̀ pẹ̀lú n tẹ̀lé e lẹ́yìn.’”
12 Et vocabunt eos, Populus sanctus, redempti a Domino. Tu autem vocaberis: Quæsita civitas, et non Derelicta.
A ó sì pè wọ́n ní Ènìyàn Mímọ́, ẹni ìràpadà Olúwa; a ó sì máa pè ọ́ ní ìwákiri, ìlú tí a kì yóò kọ̀sílẹ̀.