< Exodus 22 >

1 Si quis furatus fuerit bovem aut ovem, et occiderit vel vendiderit: quinque boves pro uno bove restituet, et quatuor oves pro una ove.
“Bí ọkùnrin kan bá jí akọ màlúù tàbí àgùntàn, tí ó sì pa á tàbí tà á. Ó gbọdọ̀ san akọ màlúù márùn-ún padà fún ọ̀kan tí ó jí, àti àgùntàn mẹ́rin mìíràn fún ọ̀kan tí ó jí.
2 Si effringens fur domum sive suffodiens fuerit inventus, et accepto vulnere mortuus fuerit, percussor non erit reus sanguinis.
“Bí a bá mú olè níbi ti ó ti ń fọ́lé, ti a sì lù ú pa, ẹni tí ó lù ú pa náà kò ní ẹ̀bi ìtàjẹ̀ sílẹ̀.
3 Quod si orto sole hoc fecerit, homicidium perpetravit, et ipse morietur. Si non habuerit quod pro furto reddat, ipse venundabitur.
Ṣùgbọ́n ti ó bá ṣẹlẹ̀ ni ojú ọ̀sán, a ó kà á si ìpànìyàn. Ọkùnrin ti ó lù ú pa náà yóò ni ẹ̀bi ìtàjẹ̀ sílẹ̀. “Olè gbọdọ̀ san ohun tí ó jí padà. Ṣùgbọ́n tí kò bá ni ohun ti ó lè fi san án padà, a ó tà á, a ó sì fi sanwó ohun tí ó jí gbé padà.
4 Si inventum fuerit apud eum quod furatus est, vivens: sive bos, sive asinus, sive ovis, duplum restituet.
Bí a bá rí ẹran tí ó jí gbé náà ni ọwọ́ rẹ̀ ní ààyè: ìbá ṣe akọ màlúù, akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tàbí àgùntàn, yóò san án padà ní ìlọ́po méjì.
5 Si læserit quispiam agrum vel vineam, et dimiserit jumentum suum ut depascatur aliena: quidquid optimum habuerit in agro suo, vel in vinea, pro damni æstimatione restituet.
“Bí ọkùnrin kan bá ń bọ́ ẹran ọ̀sìn rẹ̀ lórí pápá tàbí nínú ọgbà àjàrà, tí ó sì jẹ́ kí ó lọ jẹ nínú oko ẹlòmíràn, a ó mú kí ó san ohun ti ẹran rẹ̀ jẹ padà pẹ̀lú èyí tí ó dára jù nínú oko tàbí nínú ọgbà rẹ̀ (ẹlòmíràn padà fún un).
6 Si egressus ignis invenerit spinas, et comprehenderit acervos frugum, sive stantes segetes in agris, reddet damnum qui ignem succenderit.
“Bí iná bá ṣẹ́ tí ó kán lu igbó tí ó sì jó àká ọkà tàbí gbogbo oko náà, ẹni tí iná ṣẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ yóò san ohun tí iná ti ó ṣẹ́ jó padà.
7 Si quis commendaverit amico pecuniam aut vas in custodiam, et ab eo, qui susceperat, furto ablata fuerint: si invenitur fur, duplum reddet:
“Bí ọkùnrin kan bá fún aládùúgbò rẹ̀ ní fàdákà tàbí ohun èlò fún ìtọ́jú, ti wọ́n sì jí gbé lọ́dọ̀ aládùúgbò rẹ̀, tí a bá mú irú olè bẹ́ẹ̀, yóò san án padà ní ìlọ́po méjì.
8 si latet fur, dominus domus applicabitur ad deos, et jurabit quod non extenderit manum in rem proximi sui,
Ṣùgbọ́n ti a kò bá rí olè náà mú, baálé ilé náà yóò fi ara hàn níwájú ìdájọ́ láti jẹ́ kí a mọ̀ bí òun fúnra rẹ̀ ni ó gbé ohun ti ó sọnù náà.
9 ad perpetrandam fraudem, tam in bove quam in asino, et ove ac vestimento, et quidquid damnum inferre potest: ad deos utriusque causa perveniet, et si illi judicaverit, duplum restituet proximo suo.
Bí ẹnìkan bá ni akọ màlúù, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àgùntàn, aṣọ tàbí ohun ìní mìíràn tí ó sọnù ní ọ̀nà ti kò bá òfin mu, tí a sì rí ẹni ti ó sọ pé òun ni ó ní ín, àwọn méjèèjì yóò mú ẹjọ́ wọn wá sí iwájú adájọ́. Ẹnikẹ́ni tí adájọ́ bá dá lẹ́bi yóò san án ni ìlọ́po méjì padà fún ẹnìkejì rẹ̀.
10 Si quis commendaverit proximo suo asinum, bovem, ovem, et omne jumentum ad custodiam, et mortuum fuerit, aut debilitatum, vel captum ab hostibus, nullusque hoc viderit:
“Bí ẹnikẹ́ni bá fún aládùúgbò rẹ̀ ní kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, akọ màlúù, àgùntàn tàbí ẹranko mìíràn láti bá òun tọ́jú rẹ̀, tí ó sì kú, tàbí tí ó fi ara pa, tàbí tí a jí gbé, níbi tí kò ti sí ẹni tí o ṣe àkíyèsí.
11 jusjurandum erit in medio, quod non extenderit manum ad rem proximi sui: suscipietque dominus juramentum, et ille reddere non cogetur.
Wọn yóò búra sí ọ̀rọ̀ náà láàrín ara wọn ni iwájú Olúwa láti fihàn pé òun kò ní ọwọ́ nínú sísọnù ohun ọ̀sìn náà, olóhun gbọdọ̀ gba bẹ́ẹ̀, a kò sì ní san ohunkóhun fún un.
12 Quod si furto ablatum fuerit, restituet damnum domino;
Ṣùgbọ́n ti wọ́n bá jí ẹranko náà gbé ni ọ̀dọ̀ aládùúgbò rẹ̀, yóò san ẹ̀san padà fún olúwa rẹ̀.
13 si comestum a bestia, deferat ad eum quod occisum est, et non restituet.
Bí ẹranko búburú bá fà á ya, ó ní láti mú àyakù ẹran náà wá gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí, kò sì ní san ẹran náà padà.
14 Qui a proximo suo quidquam horum mutuo postulaverit, et debilitatum aut mortuum fuerit domino non præsente, reddere compelletur.
“Bí ẹnìkan bá sì yá ẹranko lọ́dọ̀ aládùúgbò rẹ̀, tí ẹranko náà sì fi ara pa, tàbí kí ó kú nígbà tí ẹni tí ó ni í kò sí nítòsí. O gbọdọ̀ san án padà.
15 Quod si impræsentiarum dominus fuerit, non restituet, maxime si conductum venerat pro mercede operis sui.
Ṣùgbọ́n ti ó bá jẹ́ wí pé olóhun bá wà pẹ̀lú ẹranko náà, ẹni tí ó ya lò kò ní san ẹ̀san padà. Bí a bá yá ẹranko náà lò, owó tí ó fi yá a lò ni yóò fi tan àdánù ẹranko tí ó kú.
16 Si seduxerit quis virginem necdum desponsatam, dormieritque cum ea: dotabit eam, et habebit eam uxorem.
“Bí ọkùnrin kan bá fi àrékérekè mú wúńdíá kan, ẹni tí kò pinnu láti fẹ́, tí ó sì bá a lòpọ̀, yóò san owó orí rẹ̀, yóò sì fi ṣe aya rẹ̀.
17 Si pater virginis dare noluerit, reddet pecuniam juxta modum dotis, quam virgines accipere consueverunt.
Bí baba ọmọbìnrin náà bá kọ̀ jálẹ̀ láti fi fún un ní aya, ó ni láti san owó tó tó owó orí rẹ̀ fún fífẹ́ ẹ ní wúńdíá.
18 Maleficos non patieris vivere.
“Má ṣe jẹ́ kí àjẹ́ kí ó wà láààyè.
19 Qui coierit cum jumento, morte moriatur.
“Ẹnikẹ́ni ti ó bá bá ẹranko lòpọ̀ ní a ó pa.
20 Qui immolat diis, occidetur, præterquam Domino soli.
“Ẹnikẹ́ni ti ó bá rú ẹbọ sí òrìṣà yàtọ̀ sí Olúwa nìkan, ni a ó yà sọ́tọ̀ fún ìparun.
21 Advenam non contristabis, neque affliges eum: advenæ enim et ipsi fuistis in terra Ægypti.
“Ẹ má ṣe fi ìyà jẹ àlejò tàbí ni wọ́n lára, nítorí ìwọ pẹ̀lú ti jẹ́ àjèjì ni ilẹ̀ Ejibiti rí.
22 Viduæ et pupillo non nocebitis.
“Má ṣe yan opó tàbí ọmọ òrukàn jẹ.
23 Si læseritis eos, vociferabuntur ad me, et ego audiam clamorem eorum:
Bí ìwọ bá ṣe bẹ́ẹ̀, bí wọn bá ké pè mi. Èmi yóò sì gbọ́ ohùn igbe wọn.
24 et indignabitur furor meus, percutiamque vos gladio, et erunt uxores vestræ viduæ, et filii vestri pupilli.
Ìbínú mi yóò ru sókè. Èmi yóò sì fi idà pa ọ. Ìyàwó rẹ yóò di opó, àwọn ọmọ rẹ yóò sì di aláìní baba.
25 Si pecuniam mutuam dederis populo meo pauperi qui habitat tecum, non urgebis eum quasi exactor, nec usuris opprimes.
“Bí ìwọ bá yá ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn mi tí ìyà ń jẹ láàrín yín lówó, má ṣe dàbí ayánilówó, kí o má sì gba èlé.
26 Si pignus a proximo tuo acceperis vestimentum, ante solis occasum reddes ei.
Bí ìwọ bá gba aṣọ aládùúgbò rẹ ni ẹ̀jẹ́, ìwọ gbọdọ̀ fún un padà kí oòrùn tó ó wọ̀,
27 Ipsum enim est solum, quo operitur, indumentum carnis ejus, nec habet aliud in quo dormiat: si clamaverit ad me, exaudiam eum, quia misericors sum.
nítorí aṣọ yìí nìkan ní ó ní ti ó lè fi bo àṣírí ara. Kí ni ohun mìíràn ti yóò fi sùn? Nígbà ti ó bá gbé ohun rẹ̀ sókè sí mi, èmi yóò gbọ́ nítorí aláàánú ni èmi.
28 Diis non detrahes, et principi populi tui non maledices.
“Ìwọ kò gbọdọ̀ sọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run tàbí gégùn lé orí ìjòyè àwọn ènìyàn rẹ.
29 Decimas tuas et primitias tuas non tardabis reddere: primogenitum filiorum tuorum dabis mihi.
“Ìwọ kò gbọdọ̀ lọ́ra láti mú ọrẹ wá fún mi láti inú ìre oko rẹ àti láti inú wáìnì rẹ. “Àkọ́bí ọmọ rẹ ọkùnrin ni ìwọ yóò fi fún mi.
30 De bobus quoque, et ovibus similiter facies: septem diebus sit cum matre sua, die octava reddes illum mihi.
Ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ pẹ̀lú agbo màlúù rẹ àti agbo àgùntàn rẹ. Jẹ́ kí wọn wà lọ́dọ̀ ìyá wọn fún ọjọ́ méje, kí ìwọ kí ó sì fi wọ́n fún mi ní ọjọ́ kẹjọ.
31 Viri sancti eritis mihi: carnem, quæ a bestiis fuerit prægustata, non comedetis, sed projicietis canibus.
“Ẹ̀yin yóò jẹ́ ènìyàn mímọ́ mi. Nítorí náà má ṣe jẹ ẹran ti ẹranko búburú fàya: ẹ fi fún ajá jẹ.

< Exodus 22 >