< 시편 47 >

1 (고라 자손의 시. 영장으로 한 노래) 너희 만민들아 손바닥을 치고 즐거운 소리로 하나님께 외칠지어다!
Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu. Ẹ pàtẹ́wọ́, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ẹ hó sí Ọlọ́run pẹ̀lú orin ayọ̀ tó rinlẹ̀.
2 지존하신 여호와는 엄위하시고 온땅에 큰 임군이 되심이로다
Báwo ni Olúwa Ọ̀gá-ògo ti ní ẹ̀rù tó ọba ńlá lórí gbogbo ayé.
3 여호와께서 만민을 우리에게 열방을 우리 발아래 복종케하시며
Ṣe ìkápá àwọn orílẹ̀-èdè lábẹ́ wa àwọn ènìyàn lábẹ́ ẹsẹ̀ wa
4 우리를 위하여 기업을 택하시나니 곧 사랑하신 야곱의 영화로다
Ó mú ilẹ̀ ìní wa fún wa, ọlá Jakọbu, ẹni tí ó fẹ́ wa.
5 하나님이 즐거이 부르는 중에 올라가심이여, 여호와께서 나팔소리 중에 올라가시도다
Ọlọ́run tó gòkè lọ tí òun tayọ̀, Olúwa ti òun ti ariwo ìpè.
6 찬양하라! 하나님을 찬양하라! 찬양하라! 우리 왕을 찬양하라!
Ẹ kọrin ìyìn sí Ọlọ́run, ẹ kọrin ìyìn. Ẹ kọrin ìyìn sí ọba wa, ẹ kọrin ìyìn!
7 하나님은 온 땅의 왕이심이라 지혜의 시로 찬양할지어다
Nítorí Ọlọ́run ni ọba gbogbo ayé, ẹ kọrin ìyìn pẹ̀lú Saamu!
8 하나님이 열방을 치리하시며 하나님이 그 거룩한 보좌에 앉으셨도다
Ọlọ́run jẹ ọba lórí gbogbo kèfèrí; Ọlọ́run jókòó lórí ìtẹ́ ìwà mímọ́ rẹ̀.
9 열방의 방백들이 모임이여 아브라함의 하나님의 백성이 되도다 세상의 모든 방패는 여호와의 것임이여 저는 지존하시도다
Àwọn aládé ayé kó ara wọn jọ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn Ọlọ́run Abrahamu nítorí asà ayé ti Ọlọ́run ni, òun ni ó ga jùlọ.

< 시편 47 >