< 느헤미야 9 >
1 그 달 이십 사 일에 이스라엘 자손이 다 모여 금식하며 굵은 베를 입고 티끌을 무릅쓰며
Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kan náà, àwọn ọmọ Israẹli péjọpọ̀, wọ́n gbààwẹ̀, wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀, wọ́n sì da eruku sórí ara wọn.
2 모든 이방 사람과 절교하고 서서 자기의 죄와 열조의 허물을 자복하고
Àwọn ọkùnrin Israẹli sì ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò nínú gbogbo àwọn àjèjì. Wọ́n dúró ní ààyè e wọn, wọ́n sì ń jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ẹ wọn àti iṣẹ́ búburú àwọn baba wọn.
3 이 날에 낮 사분지 일은 그 처소에 서서 그 하나님 여호와의 율법책을 낭독하며 그 하나님 여호와께 경배하는데
Wọ́n dúró sí ibi tí wọ́n wà, wọ́n sì fi ìdámẹ́rin ọjọ́ kà nínú ìwé òfin Olúwa Ọlọ́run wọn, wọ́n sì tún fi ìdámẹ́rin mìíràn ní ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ní sí sin Olúwa Ọlọ́run wọn.
4 레위 사람 예수아와, 바니와, 갓미엘과, 스바냐와, 분니와, 세레뱌와, 바니와, 그나니는 대에 올라서서 큰 소리로 그 하나님 여호와께 부르짖고
Nígbà náà ni Jeṣua, àti Bani, Kadmieli, Ṣebaniah, Bunni, Ṣerebiah, Bani àti Kenaani gòkè dúró lórí àwọn àtẹ̀gùn àwọn ọmọ Lefi, wọ́n sì fi ohùn rara kígbe sí Olúwa Ọlọ́run wọn.
5 또 레위 사람 예수아와, 갓미엘과, 바니와, 하삽느야와, 세레뱌와, 호다야와, 스바냐와, 브다히야는 이르기를 너희 무리는 마땅히 일어나 영원부터 영원까지 계신 너희 하나님 여호와를 송축할지어다! 주여, 주의 영화로운 이름을 송축하올 것은 주의 이름이 존귀하여 모든 송축이나 찬양에서 뛰어남이니이다
Nígbà náà ni àwọn ọmọ Lefi: Jeṣua, Kadmieli, Bani, Haṣbneiah, Ṣerebiah, Hodiah, Ṣebaniah àti Petahiah—wí pé, “Ẹ dìde ẹ fi ìyìn fún Olúwa Ọlọ́run yín, tí ó wà láé àti láéláé.” “Ìbùkún ni fún orúkọ rẹ tí ó ní ògo, kí ó sì di gbígbéga ju gbogbo ìbùkún àti ìyìn lọ.
6 오직 주는 여호와시라! 하늘과 하늘들의 하늘과 일월 성신과 땅과 땅 위의 만물과 바다와 그 가운데 모든 것을 지으시고 다 보존하시오니 모든 천군이 주께 경배하나이다!
Ìwọ nìkan ni Olúwa. Ìwọ ni ó dá ọ̀run, àní àwọn ọ̀run tí ó ga jù pẹ̀lú gbogbo ogun wọn, ayé àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀, òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀. Ìwọ sì pa gbogbo wọn mọ́ láàyè, ogun ọ̀run sì ń sìn ọ́.
7 주는 하나님 여호와시라! 옛적에 아브람을 택하시고 갈대아 우르에서 인도하여 내시고 아브라함이라는 이름을 주시고
“Ìwọ ni Olúwa Ọlọ́run, tí ó yan Abramu tí ó sì mú u jáde láti Uri ti Kaldea, tí ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Abrahamu.
8 그 마음이 주 앞에서 충성됨을 보시고 더불어 언약을 세우사 가나안 족속과, 헷 족속과, 아모리 족속과, 브리스 족속과, 여부스 족속과, 기르가스 족속의 땅을 그 씨에게 주리라 하시더니 그 말씀대로 이루셨사오니 주는 의로우심이로소이다
Ìwọ sì rí í pé ọkàn rẹ̀ jẹ́ olóòtítọ́ sí ọ, ìwọ sì dá májẹ̀mú pẹ̀lú u rẹ̀ láti fi ilẹ̀ àwọn ará a Kenaani, Hiti, Amori, Peresi, Jebusi àti Girgaṣi fún irú àwọn ọmọ rẹ̀. Ìwọ ti pa ìpinnu rẹ̀ mọ́ nítorí tí ìwọ jẹ́ olódodo.
9 주께서 우리 열조가 애굽에서 고난 받는 것을 감찰하시며 홍해에서 부르짖음을 들으시고
“Ìwọ rí ìpọ́njú àwọn baba ńlá wa ní Ejibiti; ìwọ gbọ́ igbe ẹkún wọn ní Òkun Pupa.
10 이적과 기사를 베푸사 바로와 그 모든 신하와 그 나라 온 백성을 치셨사오니 이는 저희가 우리의 열조에게 교만히 행함을 아셨음이라 오늘날과 같이 명예를 얻으셨나이다
Ìwọ rán iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu sí Farao, sí gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀ àti sí gbogbo ènìyàn ilẹ̀ ẹ rẹ̀, nítorí ìwọ mọ ìwà ìgbéraga tí àwọn ará Ejibiti hù sí wọn. Ìwọ ra orúkọ fún ara à rẹ, èyí tí ó sì wà títí di òní yìí.
11 주께서 또 우리 열조 앞에서 바다를 갈라지게 하시사 저희로 바다 가운데를 육지 같이 통과하게 하시고 쫓아 오는 자를 돌을 큰물에 던짐같이 깊은 물에 던지시고
Ìwọ pín òkun níwájú wọn, nítorí kí wọn lè kọjá ní ìyàngbẹ ilẹ̀, ṣùgbọ́n ìwọ sọ àwọn tí ń lépa wọn sínú ibú, bí òkúta sínú omi ńlá.
12 낮에는 구름 기둥으로 인도하시고 밤에는 불 기둥으로 그 행할 길을 비취셨사오며
Ní ọ̀sán ìwọ darí i wọn pẹ̀lú ọ̀wọn àwọsánmọ̀ àti ní òru ni ìwọ darí i wọn pẹ̀lú ọ̀wọn iná láti fún wọn ní ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀nà tí wọn yóò gbà.
13 또 시내산에 강림하시고 하늘에서부터 저희와 말씀하사 정직한 규례와 진정한 율법과 선한 율례와 계명을 저희에게 주시고
“Ìwọ sọ̀kalẹ̀ wá sí orí òkè Sinai; ìwọ bá wọn sọ̀rọ̀ láti ọ̀run. Ìwọ fún wọn ní ìlànà àti àwọn òfin tí ó jẹ́ òdodo tí ó sì tọ́ àti ìlànà tí ó dára.
14 거룩한 안식일을 저희에게 알리시며 주의 종 모세로 계명과 율례와 율법을 저희에게 명하시고
Ìwọ mú ọjọ́ ìsinmi rẹ mímọ́ di mí mọ̀ fún wọn, o sì fún wọn ní àwọn ìlànà, àwọn àṣẹ àti àwọn òfin láti ọwọ́ Mose ìránṣẹ́ rẹ.
15 저희의 주림을 인하여 하늘에서 양식을 주시며 저희의 목마름을 인하여 반석에서 물을 내시고 또 주께서 옛적에 손을 들어 맹세하시고 주마 하신 땅을 들어가서 차지하라 명하셨사오나
Ìwọ fún wọn ní oúnjẹ láti ọ̀run wá nígbà tí ebi ń pa wọ́n àti nígbà òǹgbẹ, o fún wọn ní omi láti inú àpáta; o sì sọ fún wọn pé, kí wọ́n lọ láti lọ gba ilẹ̀ náà tí ìwọ ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ láti fi fún wọn nípa ìgbọ́wọ́sókè.
16 저희와 우리 열조가 교만히 하고 목을 굳게 하여 주의 명령을 듣지 아니하고
“Ṣùgbọ́n àwọn, baba ńlá wa, wọ́n ṣe ìgbéraga, wọ́n sì ṣe agídí, wọn kò sì tẹríba fún àwọn ìlànà rẹ.
17 거역하며 주께서 저희 가운데 행하신 기사를 생각지 아니하고 목을 굳게하며 패역하여 스스로 한 두목을 세우고 종 되었던 땅으로 돌아가고자 하였사오나 오직 주는 사유하시는 하나님이시라 은혜로우시며 긍휼히 여기시며 더디 노하시며 인자가 풍부하시므로 저희를 버리지 아니하셨나이다
Wọ́n kọ̀ láti fetísílẹ̀, wọ́n sì kùnà láti rántí iṣẹ́ ìyanu tí ìwọ ṣe ní àárín wọn. Wọ́n ṣe agídí, nínú ìṣọ̀tẹ̀ wọn, wọ́n yan olórí láti padà sí oko ẹrú wọn. Ṣùgbọ́n ìwọ Ọlọ́run tí ó ń dáríjì, olóore-ọ̀fẹ́ àti aláàánú, ó lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́. Nítorí náà ìwọ kò sì kọ̀ wọ́n sílẹ̀,
18 또 저희가 송아지를 부어 만들고 이르기를 이는 곧 너희를 인도하여 애굽에서 나오게 하신 하나님이라 하여 크게 설만하게 하였사오나
nítòótọ́ nígbà tí wọ́n ṣe ẹgbọrọ màlúù dídá, tí wọ́n sì wí pé, ‘Èyí ni Ọlọ́run rẹ tí ó mú ọ gòkè láti Ejibiti wá; tàbí nígbà tí wọ́n sọ ọ̀rọ̀-òdì tí ó burú jàì’.
19 주께서는 연하여 긍휼을 베푸사 저희를 광야에 버리지 아니하시고 낮에는 구름 기둥으로 길을 인도하시며 밤에는 불 기둥으로 그 행할 길을 비취사 떠나게 아니하셨사오며
“Nítorí àánú ńlá rẹ, ìwọ kò kọ̀ wọ́n sílẹ̀ ní aginjù. Ní ọ̀sán ọ̀wọn ìkùùkuu kò kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn láti ṣe amọ̀nà an wọn, tàbí ọ̀wọ́n iná láti tàn sí wọn ní òru ní ọ̀nà tí wọn yóò rìn.
20 또 주의 선한 신을 주사 저희를 가르치시며 주의 만나로 저희 입에 끊어지지 않게 하시고 저희의 목마름을 인하여 물을 주시사
Ìwọ fi ẹ̀mí rere rẹ fún wọn láti kọ́ wọn. Ìwọ kò dá manna rẹ dúró ní ẹnu wọn, ó sì fún wọn ní omi fún òǹgbẹ.
21 사십년 동안을 들에서 기르시되 결핍함이 없게 하시므로 그 옷이 해어지지 아니하였고 발이 부릍지 아니하였사오며
Fún ogójì ọdún ni ìwọ fi bọ́ wọn ní aginjù; wọn kò ṣe aláìní ohunkóhun, aṣọ wọn kò gbó bẹ́ẹ̀ ni ẹsẹ̀ wọn kò wú.
22 또 나라들과 족속들을 저희에게 각각 나누어 주시매 저희가 시혼의 땅 곧 헤스본 왕의 땅과 바산 왕 옥의 땅을 차지하였나이다
“Ìwọ fi àwọn ìjọba àti àwọn orílẹ̀-èdè fún wọn, ó sì fi gbogbo ilẹ̀ náà fún wọ́n. Wọ́n sì gba ilẹ̀ ọba Sihoni ará a Heṣboni àti ilẹ̀ Ogu ọba Baṣani.
23 주께서 그 자손을 하늘의 별같이 많게 하시고 전에 그 열조에게 명하사 들어가서 차지하라고 하신 땅으로 인도하여 이르게 하셨으므로
Ìwọ ti mú àwọn ọmọ wọn pọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, ó sì mú wọn wá sí ilẹ̀ tí o ti sọ fún àwọn baba wọn pé kí wọn wọ̀, kí wọn sì jogún un rẹ̀.
24 그 자손이 들어가서 땅을 차지하되 주께서 그 땅 가나안 거민으로 저희 앞에 복종케 하실 때에 가나안 사람과 그 왕들과 본토 여러 족속을 저희 손에 붙여 임의로 행하게 하시매
Àwọn ọkùnrin wọn wọ inú rẹ̀, wọ́n sì gbà ilẹ̀ náà. Ìwọ sì tẹ orí àwọn ará a Kenaani, tí ń gbé inú ilẹ̀ náà ba níwájú wọn; ó fi àwọn ará a Kenaani lé wọn lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn ọba wọn àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà kí wọn ṣe wọn bí ó ti wù wọ́n.
25 저희가 견고한 성들과 기름진 땅을 취하고 모든 아름다운 물건을 채운 집과 파서 만든 우물과 포도원과 감람원과 허다한 과목을 차지하여 배불리 먹어 살지고 주의 큰 복을 즐겼사오나
Wọ́n gba àwọn ìlú olódi àti ilẹ̀ ọlọ́ràá; wọ́n gba àwọn ilé tí ó kún fún onírúurú gbogbo nǹkan rere, àwọn kànga tí a ti gbẹ́, àwọn ọgbà àjàrà, àwọn ọgbà olifi àti àwọn igi eléso ní ọ̀pọ̀lọpọ̀. Wọ́n jẹ, wọ́n yó, wọ́n sì sanra dáradára; wọ́n sì yọ̀ nínú oore ńlá rẹ.
26 저희가 오히려 순종치 아니하고 주를 거역하며 주의 율법을 등 뒤에 두고 주께로 돌아오기를 권면하는 선지자들을 죽여 크게 설만하게 행하였나이다
“Ṣùgbọ́n wọ́n ṣe àìgbọ́ràn, wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí ọ; wọ́n gbàgbé òfin rẹ. Wọ́n pa àwọn wòlíì rẹ, tí o fi gbà wọn ni ìyànjú pé kí wọn yí padà sí ọ; wọ́n sì se ọ̀rọ̀-òdì tí ó burú jàì.
27 그러므로 주께서 그 대적의 손에 붙이사 곤고를 당하게 하시매 저희가 환난을 당하여 주께 부르짖을 때에 주께서 하늘에서 들으시고 크게 긍휼을 발하사 구원자들을 주어 대적의 손에서 구원하셨거늘
Nítorí náà, ìwọ fi wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́, àwọn tí ó ni wọ́n lára. Ṣùgbọ́n nígbà tí a ni wọ́n lára wọ́n kígbe sí ọ. Ìwọ gbọ́ wọn láti ọ̀run wá àti nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àánú rẹ, ìwọ fún wọn ní olùgbàlà, tí ó gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn.
28 저희가 평강을 얻은 후에 다시 주 앞에서 악을 행하므로 주께서 그 대적의 손에 버려 두사 대적에게 제어를 받게 하시다가 저희가 돌이켜서 주께 부르짖으매 주께서 하늘에서 들으시고 여러번 긍휼을 발하사 건져내시고
“Ṣùgbọ́n bí wọ́n bá ti wà nínú ìsinmi, wọn a sì túnṣe búburú lójú rẹ. Nígbà náà ni ìwọ kọ̀ wọ́n sílẹ̀ ṣọ́wọ́ àwọn ọ̀tá kí wọ́n lè jẹ ọba lórí wọn. Nígbà tí wọ́n bá sì tún kígbe sí ọ, ìwọ a gbọ́ láti ọ̀run wá, àti nínú àánú rẹ ni ìwọ gbà láti ìgbà dé ìgbà.
29 다시 주의 율법을 복종하게 하시려고 경계하셨으나 저희가 교만히 행하여 사람이 준행하면 그 가운데서 삶을 얻는 주의 계명을 듣지 아니하며 주의 규례를 범하여 고집하는 어깨를 내어밀며 목을 굳게 하여 듣지 아니하였나이다
“Ìwọ kìlọ̀ fún wọn láti padà sínú òfin rẹ, ṣùgbọ́n wọ́n hu ìwà ìgbéraga, wọ́n sì ṣe àìgbọ́ràn si àṣẹ rẹ. Wọ́n ṣẹ̀ sí ìlànà rẹ, nípa èyí tí ènìyàn yóò yè tí wọ́n bá pa wọ́n mọ́. Nínú agídí ọkàn wọ́n kọ ẹ̀yìn sí ọ, wọ́n jẹ́ olórí kunkun wọn kò sì fẹ́ gbọ́.
30 그러나 주께서 여러 해 동안 용서하시고 또 선지자로 말미암아 주의 신으로 저희를 경계하시되 저희가 듣지 아니하므로 열방 사람의 손에 붙이시고도
Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ni ìwọ fi ní sùúrù pẹ̀lú wọn. Nípa ẹ̀mí rẹ ni ìwọ kìlọ̀ fún wọn nípasẹ̀ àwọn wòlíì. Síbẹ̀ wọn kò fi etí sílẹ̀, nítorí náà ni ìwọ ṣe fi wọ́n lé àwọn aládùúgbò wọn lọ́wọ́.
31 주의 긍휼이 크시므로 저희를 아주 멸하지 아니하시며 버리지도 아니하셨사오니 주는 은혜로우시고 긍휼히 여기시는 하나님이심이니이다
Ṣùgbọ́n nínú ọ̀pọ̀ àánú rẹ, ìwọ kò mú òpin bá wọn tàbí kọ̀ wọ́n sílẹ̀, nítorí ìwọ ni Ọlọ́run olóore-ọ̀fẹ́ àti aláàánú.
32 우리 하나님이여, 광대하시고 능하시고 두려우시며 언약과 인자를 지키시는 하나님이여, 우리와 우리 열왕과 방백들과 제사장들과 선지자들과 열조와 주의 모든 백성이 앗수르 열왕의 때로부터 오늘날까지 당한바 환난을 이제 작게 여기시지 마옵소서
“Ǹjẹ́ nítorí náà, Ọlọ́run wa, Ọlọ́run tí ó tóbi, tí ó lágbára, tí ó sì ní ẹ̀rù, ẹni tí ó pa májẹ̀mú ìfẹ́ mọ́, má ṣe jẹ́ gbogbo ìnira yìí dàbí ohun kékeré ní ojú rẹ—ìnira tí ó ti wá sórí wa, sórí àwọn ọba wa àti àwọn olórí wa, sórí àwọn àlùfáà wa àti àwọn wòlíì, sórí àwọn baba wa àti sórí gbogbo ènìyàn rẹ̀, láti àwọn ọjọ́ àwọn ọba Asiria wá títí di òní.
33 그러나 우리의 당한 모든 일에 주는 공의로우시니 우리는 악을 행하였사오나 주는 진실히 행하셨음이니이다
Ìwọ jẹ́ olódodo nínú ohun gbogbo tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí wa; ìwọ sì ti ṣe òtítọ́, nígbà tí a bá ṣe búburú.
34 우리 열왕과 방백들과 제사장들과 열조가 주의 율법을 지키지 아니하며 주의 명령과 주의 경계하신 말씀을 순종치 아니하고
Àwọn ọba wa, àwọn olórí wa, àwọn àlùfáà wa, àti àwọn baba wa kò tẹ̀lé òfin rẹ; wọn kò fetísílẹ̀ sí àṣẹ rẹ tàbí àwọn ìkìlọ̀ tí ìwọ fún wọn.
35 저희가 그 나라와 주의 베푸신 큰 복과 자기 앞에 주신 넓고 기름진 땅을 누리면서도 주를 섬기지 아니하며 악행을 그치지 아니한고로
Àní nígbà tí wọ́n wà nínú ìjọba wọn, tí wọ́n ń gbádùn oore ńlá tí ìwọ fi fún wọn, ní ilẹ̀ tí ó tóbi tí ó sì lọ́ràá, wọn kò sìn ọ́ tàbí padà kúrò nínú àwọn ọ̀nà búburú wọn.
36 우리가 오늘날 종이 되었삽는데 곧 주께서 우리 열조에게 주사 그 실과를 먹고 그 아름다운 소산을 누리게 하신 땅에서 종이 되었나이다
“Ṣùgbọ́n wò ó, àwa jẹ́ ẹrú lónìí, àwa jẹ́ ẹrú ní ilẹ̀ tí ìwọ fún àwọn baba ńlá wa, nítorí kí wọn bá máa jẹ èso rẹ̀ àti ìre mìíràn tí ó mú jáde.
37 우리의 죄로 인하여 주께서 우리 위에 세우신 이방 열왕이 이 땅의 많은 소산을 얻고 저희가 우리의 몸과 육축을 임의로 관할하오니 우리의 곤난이 심하오며
Nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkórè rẹ lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ọba tí ó fi ṣe olórí wa. Wọ́n ń ṣe àkóso lórí wa àti lórí ẹran wa bí ó ti wù wọ́n, àwa sì wà nínú ìpọ́njú ńlá.
38 우리가 이 모든 일을 인하여 이제 견고한 언약을 세워 기록하고 우리의 방백들과 레위 사람들과 제사장들이 다 인을 치나이다 하였느니라
“Nítorí gbogbo èyí, a ń ṣe àdéhùn tí ó fẹsẹ̀múlẹ̀, a sì kọ ọ́ sínú ìwé, àwọn olórí ọmọ Lefi àwọn àlùfáà sì fi èdìdì dì í.”