< 역대상 27 >
1 이스라엘 자손의 모든 족장과 천부장과 백부장과 왕을 섬기는 유사들이 그 인수대로 반차가 나누이니 각 반열이 이만 사천명씩이라 일년동안 달마다 체번하여 들어가며 나왔으니
Wọ̀nyí ni ìwé àkójọ orúkọ àwọn ọmọ Israẹli, àwọn olórí àwọn ìdílé, àwọn balógun ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti àwọn balógun ọ̀rọ̀ọ̀rún àti àwọn ìjòyè wọn. Tí ó n sin ọba nínú gbogbo ohun tí ó kan ìpín àwọn ọmọ-ogun tí ó wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ní oṣooṣù ní gbogbo ọdún. Ìpín kọ̀ọ̀kan jẹ́ ẹgbàá méjìlá ọkùnrin.
2 정월 첫반의 반장은 삽디엘의 아들 야소브암이요 그 반열에 이만 사천명이라
Ní ti alákòóso lórí ìpín kìn-ín-ní fún oṣù kìn-ín-ní jẹ́ Jaṣobeamu ọmọ Sabdieli àwọn ọkùnrin ẹgbàá méjìlá ní ó wà ní abẹ́ ìpín tirẹ̀.
3 저는 베레스의 자손으로서 정월반의 모든 장관의 두목이 되었고
Ó jẹ́ ìran ọmọ Peresi àti olóyè fún gbogbo àwọn ìjòyè ológun fún oṣù kìn-ín-ní.
4 이월반의 반장은 아호아 사람 도대요 또 미글롯이 그 반의 주장이 되었으니 그 반열에 이만 사천명이요
Alákòóso fún ìpín àwọn ọmọ-ogun fún oṣù kejì jẹ́ Dodai ará Ahohi; Mikloti jẹ́ olórí ìpín tirẹ̀. Ọkùnrin ẹgbàá méjìlá ni ó wà ní ìpín tirẹ̀.
5 삼월 군대의 세째 장관은 대제사장 여호야다의 아들 브나야요 그 반열에 이만 사천명이라
Olórí àwọn ọmọ-ogun ẹlẹ́ẹ̀kẹta fún oṣù kẹta jẹ́ Benaiah ọmọ Jehoiada àlùfáà. Ó jẹ́ olóyè, àwọn ọkùnrin ẹgbàá méjìlá ní ó wà ní ìpín tirẹ̀.
6 이 브나야는 삼십인중에 용사요 삼십인 위에 있으며 그 반열 중에 그 아들 암미사밧이 있으며
Èyí ni Benaiah náà tí ó jẹ́ ọkùnrin ńlá láàrín àwọn ọgbọ̀n àti lórí àwọn ọgbọ̀n. Ọmọ rẹ̀ Amisabadi jẹ́ alákòóso lórí ìpín tirẹ̀.
7 사월 네째 장관은 요압의 아우 아사헬이요 그 다음은 그 아들 스바댜니 그 반열에 이만 사천명이요
Ẹlẹ́ẹ̀kẹrin fún oṣù kẹrin, jẹ́ Asaheli arákùnrin Joabu: ọmọ rẹ̀ Sebadiah jẹ́ arọ́pò rẹ̀. Ẹgbàá méjìlá ọkùnrin ni ó wà ní ìpín rẹ̀.
8 오월 다섯째 장관은 이스라 사람 삼훗이니 그 반열에 이만 사천명이요
Ẹ̀karùnún fún oṣù karùn-ún, jẹ́ olórí Ṣamhuti ará Israhi. Ẹgbàá méjìlá ọkùnrin ní ó wà ní ìpín tirẹ̀.
9 유월 여섯째 장관은 드고아 사람 익게스의 아들 이라니 그 반열에 이만 사천명이요
Ẹ̀kẹfà fún oṣù kẹfà jẹ́ Ira ọmọ Ikẹsi, ará Tekoi. Ọkùnrin ẹgbàá méjìlá ni ó wà ní ìpín rẹ̀.
10 칠월 일곱째 장관은 에브라임자손에 속한 발론 사람 헬레스니 그 반열에 이만 사천명이요
Èkeje fún oṣù keje jẹ́ Helesi ará Peloni, ará Efraimu. Ọkùnrin ẹgbàá méjìlá ni o wà ní ìpín rẹ̀.
11 팔월 여덟째 장관은 세라 족속 후사 사람 십브개니 그 반열에 이만 사천명이요
Ẹ̀kẹjọ fún oṣù kẹjọ jẹ́ Sibekai ará Huṣati, ará Sera ọkùnrin ẹgbàá méjìlá ni ó wà ní ìpín rẹ̀.
12 구월 아홉째 장관은 베냐민 자손 아나돗 사람 아비에셀이니 그 반열에 이만 사천명이요
Ẹ̀kẹsànán fún oṣù kẹsànán jẹ́. Abieseri ará Anatoti, ará Benjamini ọkùnrin ẹgbàá méjìlá ni ó wà ní ìpín rẹ̀.
13 시월 열째 장관은 세라 족속 느도바 사람 마하래니 그 반열에 이만 사천명이요
Ẹ̀kẹwàá fún oṣù kẹwàá jẹ́ Maharai ará Netofa, ará Sera ọkùnrin ẹgbàá méjìlá ni ó wà ní ìpín rẹ̀.
14 십일월 열 한째 장관은 에브라임 자손에 속한 비라돈 사람 브나 야니 그 반열에 이만 사천명이요
Ìkọkànlá fún oṣù kọkànlá jẹ́ Benaiah ará Piratoni ará Efraimu ọkùnrin ẹgbàá méjìlá ni ó wà ní ìpín tirẹ̀.
15 십이월 열 둘째 장관은 옷니엘 자손에 속한 느도바 사람 헬대니 그 반열에 이만 사천명이었더라
Èkejìlá fún oṣù kejìlá jẹ́ Heldai ará Netofa láti ìdílé Otnieli. Ẹgbàá méjìlá ọkùnrin ni ó wà ní ìpín tirẹ̀.
16 이스라엘 지파를 관할하는 자는 이러하니라 르우벤 사람의 관장은 시그리의 아들 엘리에셀이요 시므온 사람의 관장은 마아가의 아들 스바댜요
Àwọn ìjòyè lórí àwọn ẹ̀yà tí Israẹli: lórí àwọn ará Reubeni: Elieseri ọmọ Sikri; lórí àwọn ọmọ Simeoni: Ṣefatia ọmọ Maaka;
17 레위 사람의 관장은 그무엘의 아들 하사뱌요 아론 자손의 관장은 사독이요
lórí Lefi: Haṣabiah ọmọ Kemueli; lórí Aaroni: Sadoku;
18 유다의 관장은 다윗의 형 엘리후요 잇사갈의 관장은 미가엘의 아들 오므리요
lórí Juda: Elihu arákùnrin Dafidi; lórí Isakari: Omri ọmọ Mikaeli;
19 스불론의 관장은 오바댜의 아들 이스마야요 납달리의 관장은 아스리엘의 아들 여레못이요
lórí Sebuluni: Iṣmaiah ọmọ Obadiah; lórí Naftali: Jerimoti ọmọ Asrieli;
20 에브라임 자손의 관장은 아사시야의 아들 호세아요 므낫세 반 지파의 관장은 브다야의 아들 요엘이요
lórí àwọn ará Efraimu: Hosea ọmọ Asasiah; lórí ààbọ̀ ẹ̀yà Manase: Joẹli ọmọ Pedaiah;
21 길르앗에 있는 므낫세 반 지파의 관장은 스가랴의 아들 잇도요 베냐민의 관장은 아브넬의 아들 야아시엘이요
lórí ààbọ̀ ẹ̀yà Manase ní Gileadi: Iddo ọmọ Sekariah; lórí Benjamini: Jaasieli ọmọ Abneri;
22 단의 관장은 여로함의 아들 아사렐이니 이스라엘 지파의 관장이 이러하며
lórí Dani: Asareeli ọmọ Jerohamu. Wọ̀nyí ni àwọn ìjòyè lórí ẹ̀yà Israẹli.
23 이스라엘 사람의 이십세 이하의 수효는 다윗이 조사하지 아니하였으니 이는 여호와께서 전에 말씀하시기를 이스라엘 사람을 하늘의 별같이 많게 하리라 하셨음이라
Dafidi kò kọ iye àwọn ọkùnrin náà ní ogún ọdún sẹ́yìn tàbí dín nítorí Olúwa ti ṣe ìlérí láti ṣe Israẹli gẹ́gẹ́ bí iye ìràwọ̀ ojú ọ̀run.
24 스루야의 아들 요압이 조사하기를 시작하고 끝내지 못하여서 그 일로 인하여 진노가 이스라엘에게 임한지라 그 수효를 다윗 왕의 역대지략에 기록하지 아니하였더라
Joabu ọmọ Seruiah bẹ̀rẹ̀ sí ní kà wọ́n, ṣùgbọ́n kò parí kíkà wọ́n nítorí, ìbínú dé sórí àwọn Israẹli nípasẹ̀ kíka iye àti iye náà, a kò kọ ọ́ sínú ìwé ìtàn ayé ti ọba Dafidi.
25 아디엘의 아들 아스마웹은 왕의 곳간을 맡았고 웃시야의 아들 요나단은 밭과 성읍과 촌과 산성의 곳간을 맡았고
Asmafeti ọmọ Adieli wà ní ìdí ilé ìṣúra ti ọba. Jonatani ọmọ Ussiah wà ní ìdí ilé ìṣúra ní iwájú agbègbè nínú àwọn ìlú, àwọn ìletò àti àwọn ilé ìṣọ́.
26 글룹의 아들 에스리는 밭 가는 농부를 거느렸고
Esri ọmọ Kelubu wà ní ìdí àwọn òṣìṣẹ́ lórí pápá, tí wọ́n ń ko ilẹ̀ náà.
27 라마 사람 시므이는 포도원을 맡았고 스밤 사람 삽디는 포도원의 소산 포도주 곳간을 맡았고
Ṣimei ará Ramoti wà ní ìdí àwọn ọgbà àjàrà. Sabdi ará Sifmi wà ní ìdí mímú jáde ti èso àjàrà fún ọpọ́n ńlá tí a ń fi ọ̀tún èso àjàrà sí.
28 게델 사람 바알하난은 평야의 감람나무와 뽕나무를 맡았고 요아스는 기름 곳간을 맡았고
Baali-Hanani ará Gederi wà ní ìdí olifi àti àwọn igi sikamore ní apá ìhà ìwọ̀-oòrùn àwọn ní ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀. Joaṣi wà ní ìdí fífún ni ní òróró olifi.
29 사론 사람 시드래는 사론에서 먹이는 소떼를 맡았고 아들래의 아들 사밧은 골짜기에 있는 소떼를 맡았고
Ṣitrai ará Ṣaroni wà ní ìdí fífi ọwọ́ ẹran jẹ oko ní Ṣaroni. Ṣafati ọmọ Adlai wà ní ìdí àwọn ọ̀wọ́ ẹran ní àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀.
30 이스마엘 사람 오빌은 약대를 맡았고 메로놋 사람 예드야는 나귀를 맡았고 하갈 사람 야시스는 양떼를 맡았으니
Obili ará Iṣmaeli wà ní ìdí àwọn ìbákasẹ. Jehdeiah ará Meronoti wà ní ìdí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.
31 다윗 왕의 재산을 맡은 자들이 이러하였더라
Jasisi ará Hagari wà ní ìdí àwọn agbo ẹran. Gbogbo wọ̀nyí ni àwọn oníṣẹ́ tí wọ́n wà ní ìdí ẹrù ọba Dafidi.
32 다윗의 아자비 요나단은 지혜가 있어서 모사가 되며 서기관도 되었고 학모니의 아들 여히엘은 왕의 아들들의 배종이 되었고
Jonatani, arákùnrin Dafidi jẹ́ olùdámọ̀ràn, ọkùnrin onímọ̀ àti akọ̀wé. Jehieli ọmọ Hakmoni bojútó àwọn ọmọ ọba.
33 아히도벨은 왕의 모사가 되었고 아렉 사람 후새는 왕의 벗이 되었고
Ahitofeli jẹ́ olùdámọ̀ràn ọba. Huṣai ará Arki jẹ́ ọ̀rẹ́ ọba.
34 브나야의 아들 여호야다와 아비아달은 아히도벨의 다음이 되었고 요압은 왕의 군대 장관이 되었더라
(Jehoiada ọmọ Benaiah àti nípasẹ̀ Abiatari jẹ ọba rọ́pò Ahitofeli.) Joabu jẹ́ olórí ọmọ-ogun ọba.