< オバデヤ書 1 >
1 オバデヤの幻。主なる神はエドムについてこう言われる、われわれは主から出たおとずれを聞いた。ひとりの使者が諸国民のうちにつかわされて言う、「立てよ、われわれは立ってエドムと戦おう」。
Ìran ti Obadiah. Èyí ni Olúwa Olódùmarè wí nípa Edomu. Àwa ti gbọ́ ohùn kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá, a sì ti rán ikọ̀ kan sí gbogbo kèfèrí láti sọ pé, “Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a dìde ogun sí i.”
2 見よ、わたしはあなたを国々のうちで小さい者とする。あなたはひどく卑しめられる。
“Kíyèsi i, Èmi yóò sọ ọ́ di kékeré láàrín àwọn kèfèrí; ìwọ yóò sì di gígàn lọ́pọ̀lọ́pọ̀.
3 岩のはざまにおり、高い所に住む者よ、あなたの心の高ぶりは、あなたを欺いた。あなたは心のうちに言う、「だれがわたしを地に引き下らせる事ができるか」。
Ìgbéraga àyà rẹ ti tàn ọ́ jẹ, ìwọ tí ń gbé inú pálapàla àpáta, tí o sì kọ́ ibùgbé rẹ sí ibi gíga, ìwọ wí nínú ọkàn rẹ pé, ‘Ta ni yóò mú mi sọ̀kalẹ̀?’
4 たといあなたは、わしのように高くあがり、星の間に巣を設けても、わたしはそこからあなたを引きおろすと主は言われる。
Bí ìwọ tilẹ̀ gbé ara rẹ ga bí ẹyẹ idì, bí ìwọ tilẹ̀ tẹ́ ìtẹ́ rẹ sí àárín àwọn ìràwọ̀, láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti sọ̀ ọ kalẹ̀,” ni Olúwa wí.
5 もし盗びとがあなたの所に来、強盗が夜きても、彼らは、ほしいだけ盗むではないか。ああ、あなたは全く滅ぼされてしまう。もしぶどうを集める者があなたの所に来たなら、彼らはなお余りの実を残さないであろうか。
“Bí àwọn olè tọ̀ ọ́ wá, bí àwọn ọlọ́ṣà ní òru, Háà! Irú ìparun wo ló dúró dè ọ́, wọn kò ha jalè tó bí wọ́n ti fẹ́? Bí àwọn tí ń ká èso àjàrà tọ̀ ọ́ wá, wọn kò ha ni fi èso àjàrà díẹ̀ sílẹ̀?
6 ああ、エサウはかすめられ、その隠しておいた宝は探り出される。
Báwo ni a ṣe ṣe àwárí nǹkan Esau, tí a sì wá ohun ìní ìkọ̀kọ̀ rẹ̀ jáde.
7 あなたと契約を結んだ人々はみな、あなたを欺き、あなたを国境に追いやった。あなたと同盟を結んだ人々はあなたに勝った。あなたの信頼する友はあなたの下にわなを設けた、しかしその事を悟らない。
Gbogbo àwọn ẹni ìmùlẹ̀ rẹ ti mú ọ dé ìpẹ̀kun ilẹ̀ rẹ, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ti tàn ọ́ jẹ, wọ́n sì ti borí rẹ; àwọn tó jẹ oúnjẹ rẹ dẹ pàkúté dè ọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kò ní ní òye rẹ̀.”
8 主は言われる、その日には、わたしはエドムから知者を滅ぼし、エサウの山から悟りを断ち除かないだろうか。
Olúwa wí pé, “Ní ọjọ́ náà, Èmi kì yóò ha pa àwọn ọlọ́gbọ́n Edomu run, àti àwọn amòye run kúrò ní òkè Esau?
9 テマンよ、あなたの勇士は驚き恐れる。人はみな殺されてエサウの山から断ち除かれる。
A ó ṣe ẹ̀rù ba àwọn jagunjagun rẹ, ìwọ Temani, gbogbo àwọn tó wà ní orí òkè Esau ní a ó gé kúrò nínú ìpànìyàn náà.
10 あなたはその兄弟ヤコブに暴虐を行ったので、恥はあなたをおおい、あなたは永遠に断たれる。
Nítorí ìwà ipá sí Jakọbu arákùnrin rẹ, ìtìjú yóò bò ọ, a ó sì pa ọ run títí láé.
11 あなたが離れて立っていた日、すなわち異邦人がその財宝を持ち去り、外国人がその門におし入り、エルサレムをくじ引きにした日、あなたも彼らのひとりのようであった。
Ní ọjọ́ tí ìwọ dúró ní apá kan, ní ọjọ́ tí àlejò kó ogún rẹ lọ, tí àwọn àjèjì sì wọ ibodè rẹ, tí wọ́n sì sẹ́ kèké lórí Jerusalẹmu, ìwọ náà wà bí ọ̀kan nínú wọn.
12 しかしあなたは自分の兄弟の日、すなわちその災の日をながめていてはならなかった。あなたはユダの人々の滅びの日に、これを喜んではならず、その悩みの日に誇ってはならなかった。
Ìwọ kì bá tí fi ojú kéré arákùnrin rẹ, ní àkókò ìbànújẹ́ rẹ̀ ìwọ kì bá tí yọ̀ lórí àwọn ọmọ Juda, ní ọjọ́ ìparun wọn ìwọ kì bá tí gbéraga púpọ̀ ní ọjọ́ wàhálà wọn.
13 あなたはわが民の災の日に、その門にはいってはならず、その災の日にその苦しみをながめてはならなかった。またその災の日に、その財宝に手をかけてはならなかった。
Ìwọ kì bá tí wọ inú ibodè àwọn ènìyàn mi lọ, ní ọjọ́ àjálù wọn. Ìwọ kì bá tí fojú kó wọn mọ́lẹ̀ nínú ìdààmú wọn, ní ọjọ́ àjálù wọn. Ìwọ kì bá tí jí ẹrù wọn kó, ní ọjọ́ ìpọ́njú wọn.
14 あなたは分れ道に立って、そののがれる者を切ってはならなかった。あなたは悩みの日にその残った者を敵にわたしてはならなかった。
Ìwọ kì bá tí dúró ní ìkóríta ọ̀nà láti ké àwọn tirẹ̀ tó ti sálà kúrò. Ìwọ kì bá tí fa àwọn tó ṣẹ́kù nínú wọn lélẹ̀ ní ọjọ́ wàhálà wọn.
15 主の日が万国の民に臨むのは近い。あなたがしたようにあなたもされる。あなたの報いはあなたのこうべに帰する。
“Nítorí ọjọ́ Olúwa súnmọ́ etílé lórí gbogbo àwọn kèfèrí. Bí ìwọ ti ṣe, bẹ́ẹ̀ ni a ó ṣe sí ìwọ náà; ẹ̀san rẹ yóò sì yípadà sí orí ara rẹ.
16 あなたがたがわが聖なる山で飲んだように、周囲のもろもろの民も飲む。すなわち彼らは飲んでよろめき、かつてなかったようになる。
Gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀ ṣe mu lórí òkè mímọ́ mi, bẹ́ẹ̀ ni gbogbo kèfèrí yóò máa mu títí; wọn yóò mu ún ní àmutẹ́rùn wọn yóò sì wà bí ẹni pé wọn kò mu ún rí.
17 しかしシオンの山には、のがれる者がいて、聖なる所となる。またヤコブの家はその領地を獲る。
Ṣùgbọ́n ìgbàlà yóò wà lórí òkè Sioni, wọn yóò sì jẹ́ mímọ́, àti ilé Jakọbu yóò sì ní ìní wọn.
18 ヤコブの家は火となり、ヨセフの家は炎となり、エサウの家はわらとなる。彼らはその中に燃えて、これを焼く。エサウの家には残る者がないようになると主は言われた。
Ilé Jakọbu yóò sì jẹ́ iná àti ilé Josẹfu ọwọ́ iná ilé Esau yóò jẹ àgékù koríko wọn yóò fi iná sí i, wọn yóò jo run. Kì yóò sí ẹni tí yóò kù ní ilé Esau.” Nítorí Olúwa ti sọ̀rọ̀.
19 ネゲブの人々はエサウの山を獲、セフェラの人々はペリシテびとを獲る。また彼らはエフライムの地、およびサマリヤの地を獲、ベニヤミンはギレアデを獲る。
Àwọn ará gúúsù yóò ni òkè Esau, àwọn ará ẹsẹ̀ òkè yóò ni ilẹ̀ àwọn ará Filistini ní ìní. Wọn yóò sì ni oko Efraimu àti Samaria; Benjamini yóò ní Gileadi ní ìní.
20 ハラにいるイスラエルの人々の捕われ人は、フェニキヤをザレパテまで取り、セパラデにいるエルサレムの捕われ人は、ネゲブの町々を獲る。
Àwọn ìgbèkùn Israẹli tí ó wà ní Kenaani yóò ni ilẹ̀ títí dé Sarefati; àwọn ìgbèkùn láti Jerusalẹmu tí ó wà ní Sefaredi yóò ni àwọn ìlú gúúsù ní ìní.
21 こうして救う者はシオンの山に上って、エサウの山を治める。そして王国は主のものとなる。
Àwọn tó ń gba ni là yóò sì gòkè Sioni wá láti jẹ ọba lé orí àwọn òkè Esau. Ìjọba náà yóò sì jẹ́ ti Olúwa.