< ヨエル書 2 >
1 あなたがたはシオンでラッパを吹け。わが聖なる山で警報を吹きならせ。国の民はみな、ふるいわななけ。主の日が来るからである。それは近い。
Ẹ fun ìpè ní Sioni, ẹ sì fún ìpè ìdágìrì ní òkè mímọ́ mi. Jẹ́ kí àwọn ará ilẹ̀ náà wárìrì, nítorí tí ọjọ́ Olúwa ń bọ̀ wá, nítorí ó kù sí dẹ̀dẹ̀.
2 これは暗く、薄暗い日、雲の群がるまっくらな日である。多くの強い民が暗やみのようにもろもろの山をおおう。このようなことは昔からあったことがなく、後の代々の年にも再び起ることがないであろう。
Ọjọ́ òkùnkùn àti ìrọ́kẹ̀kẹ̀, ọjọ́ ìkùùkuu àti òkùnkùn biribiri. Bí ọyẹ́ òwúrọ̀ ti í la bo orí àwọn òkè ńlá: àwọn ènìyàn ńlá àti alágbára; ya dé, ti kó ti ì sí irú rẹ̀ rí, bẹ́ẹ̀ ni irú rẹ̀ kì yóò sí mọ́ lẹ́yìn rẹ̀, títí dé ọdún ìran dé ìran.
3 火は彼らの前を焼き、炎は彼らの後に燃える。彼らのこない前には、地はエデンの園のようであるが、その去った後は荒れ果てた野のようになる。これをのがれうるものは一つもない。
Iná ń jó níwájú wọ́n; ọwọ́ iná sì ń jó lẹ́yìn wọn. Ilẹ̀ náà dàbí ọgbà Edeni níwájú wọn, àti lẹ́yìn wọn bí ahoro ijù; nítòótọ́, kò sì sí ohun tí yóò bọ́ lọ́wọ́ wọn.
4 そのかたちは馬のかたちのようであり、その走ることは軍馬のようである。
Ìrí wọn dàbí ìrí àwọn ẹṣin; wọ́n ń sáré lọ bí àwọn ẹlẹ́ṣin ogun.
5 山の頂でとびおどる音は、戦車のとどろくようである。また刈り株を焼く火の炎の音のようであり、戦いの備えをした強い軍隊のようである。
Bí ariwo kẹ̀kẹ́ ogun ni wọn ń fo ní orí òkè bí ariwo ọ̀wọ́-iná tí ń jó koríko gbígbẹ, bí akọni ènìyàn tí a kójọ fún ogun.
6 その前にもろもろの民はなやみ、すべての顔は色を失う。
Ní ojú wọn, àwọn ènìyàn yóò jẹ ìrora púpọ̀: gbogbo ojú ní yóò ṣú dudu.
7 彼らは勇士のように走り、兵士のように城壁によじ登る。彼らはおのおの自分の道を進んで行って、その道を踏みはずさない。
Wọn yóò sáré bi àwọn alágbára; wọn yóò gùn odi bí ọkùnrin ológun; olúkúlùkù wọn yóò sì rìn lọ ní ọ̀nà rẹ̀, wọn kì yóò sì yà kúrò ni ọ̀nà wọn.
8 彼らは互におしあわず、おのおのその道を進み行く。彼らは武器の中にとびこんでも、身をそこなわない。
Bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kì yóò kọlu ẹnìkejì rẹ̀; olúkúlùkù wọn yóò rìn ní ọ̀nà rẹ̀, nígbà tí wọn bá sì ṣubú lù idà wọn kì yóò gbọgbẹ́.
9 彼らは町にとび入り、城壁の上を走り、家々によじ登り、盗びとのように窓からはいる。
Wọn yóò sáré síwá sẹ́yìn ní ìlú; wọn yóò súré lórí odi, wọn yóò gùn orí ilé; wọn yóò gbà ojú fèrèsé wọ̀ inú ilé bí olè.
10 地は彼らの前におののき、天はふるい、日も月も暗くなり、星はその光を失う。
Ayé yóò mì níwájú wọn; àwọn ọ̀run yóò wárìrì; oòrùn àti òṣùpá yóò ṣókùnkùn, àwọn ìràwọ̀ yóò sì fà ìmọ́lẹ̀ wọn sẹ́yìn.
11 主はその軍勢の前で声をあげられる。その軍隊は非常に多いからである。そのみ言葉をなし遂げる者は強い。主の日は大いにして、はなはだ恐ろしいゆえ、だれがこれに耐えることができよう。
Olúwa yóò sì bú ramúramù jáde níwájú ogun rẹ̀: nítorí ibùdó rẹ̀ tóbi gidigidi; nítorí alágbára ní òun, tí n mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ; nítorí ọjọ́ Olúwa tóbi ó sì ní ẹ̀rù gidigidi; ara ta ni ó lè gbà á?
12 主は言われる、「今からでも、あなたがたは心をつくし、断食と嘆きと、悲しみとをもってわたしに帰れ。
“Ǹjẹ́ nítorí náà nísinsin yìí,” ni Olúwa wí, “Ẹ fi gbogbo ọkàn yín yípadà sí mi, àti pẹ̀lú àwẹ̀, àti pẹ̀lú ẹkún, àti pẹ̀lú ọ̀fọ̀.”
13 あなたがたは衣服ではなく、心を裂け」。あなたがたの神、主に帰れ。主は恵みあり、あわれみあり、怒ることがおそく、いつくしみが豊かで、災を思いかえされるからである。
Ẹ sì fa ọkàn yín ya, kì í sì í ṣe aṣọ yín, ẹ sì yípadà sí Olúwa Ọlọ́run yín, nítorí tí o pọ̀ ní oore-ọ̀fẹ́, ó sì kún fun àánú, ó lọ́ra láti bínú, ó sì ṣeun púpọ̀, ó sì ronúpìwàdà láti ṣe búburú.
14 神があるいは立ち返り、思いかえして祝福をその後に残し、素祭と灌祭とをあなたがたの神、主にささげさせられる事はないとだれが知るだろうか。
Ta ni ó mọ̀ bí òun yóò yípadà, kí o sì ronúpìwàdà, kí ó sì fi ìbùkún sílẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀— àní ọrẹ-jíjẹ àti ọrẹ mímu fún Olúwa Ọlọ́run yín?
15 シオンでラッパを吹きならせ。断食を聖別し、聖会を召集し、
Ẹ fún ìpè ní Sioni, ẹ ya àwẹ̀ kan sí mímọ́, ẹ pe àjọ tí ó ni ìrònú.
16 民を集め、会衆を聖別し、老人たちを集め、幼な子、乳のみ子を集め、花婿をその家から呼びだし、花嫁をそのへやから呼びだせ。
Ẹ kó àwọn ènìyàn jọ, ẹ ya ìjọ sí mímọ́; ẹ pe àwọn àgbàgbà jọ, ẹ kó àwọn ọmọdé jọ, àti àwọn tí ń mú ọmú, jẹ kí ọkọ ìyàwó kúrò nínú ìyẹ̀wù rẹ̀. Kí ìyàwó sì kúrò nínú iyàrá rẹ̀.
17 主に仕える祭司たちは、廊と祭壇との間で泣いて言え、「主よ、あなたの民をゆるし、あなたの嗣業をもろもろの国民のうちに、そしりと笑い草にさせないでください。どうしてもろもろの国民に、『彼らの神はどこにいるのか』と言わせてよいでしょうか」。
Jẹ́ kí àwọn àlùfáà, àwọn ìránṣẹ́ Olúwa, sọkún láàrín ìloro àti pẹpẹ. Sí jẹ́ kí wọn wí pé, “Dá àwọn ènìyàn rẹ sí, Olúwa. Má sì ṣe fi ìní rẹ fun ẹ̀gàn, tí yóò sì di òwe ní àárín àwọn kèfèrí. Èéṣe tí wọn yóò fi wí láàrín àwọn ènìyàn pé, ‘Ọlọ́run wọn ha da?’”
18 その時主は自分の地のために、ねたみを起し、その民をあわれまれた。
Nígbà náà ní Olúwa yóò jowú fún ilẹ̀ rẹ̀, yóò sì káàánú fún ènìyàn rẹ̀.
19 主は答えて、その民に言われた、「見よ、わたしは穀物と新しい酒と油とをあなたがたに送る。あなたがたはこれを食べて飽きるであろう。わたしは重ねてあなたがたにもろもろの国民のうちでそしりを受けさせない。
Nítòótọ́, Olúwa yóò dá wọn lóhùn, yóò sì wí fun àwọn ènìyàn rẹ̀ pé: “Wò ó èmi yóò rán ọkà, àti ọtí wáìnì tuntun, àti òróró sí i yín, a ó sì fi wọn tẹ́ yín lọ́rùn; Èmi kì yóò sì fi yín ṣe ẹ̀gàn mọ́ láàrín àwọn aláìkọlà.
20 わたしは北から来る者をあなたがたから遠ざけ、これをかわいた荒れ地に追いやり、その前の者を東の海に、その後の者を西の海に追いやる。その臭いにおいは起り、その悪しきにおいは上る。これは大いなる事をしたからである。
“Ṣùgbọ́n èmi yóò lé ogun àríwá jìnnà réré kúrò lọ́dọ̀ yín, èmi yóò sì lé e lọ sí ilẹ̀ tí ó ṣá, tí ó sì di ahoro, pẹ̀lú ojú rẹ̀ sí Òkun ìlà-oòrùn, àti ẹ̀yìn rẹ̀ sí ìwọ̀-oòrùn Òkun. Òórùn rẹ̀ yóò sì gòkè, òórùn búburú rẹ̀ yóò sì gòkè.” Nítòótọ́ ó ti ṣe ohun ńlá.
21 地よ恐るな、喜び楽しめ、主は大いなる事を行われたからである。
Má bẹ̀rù, ìwọ ilẹ̀; jẹ́ kí inú rẹ̀ dùn kí o sì yọ̀, nítorí Olúwa ti ṣe ohun ńlá.
22 野のもろもろの獣よ、恐るな。荒野の牧草はもえいで、木はその実を結び、いちじくの木とぶどうの木とは豊かに実る。
Ẹ má bẹ̀rù, ẹranko igbó, nítorí pápá oko aginjù ń rú. Nítorí igi ń so èso rẹ̀, igi ọ̀pọ̀tọ́ àti àjàrà ń so èso ọ̀rọ̀ wọn.
23 シオンの子らよ、あなたがたの神、主によって喜び楽しめ。主はあなたがたを義とするために秋の雨を賜い、またあなたがたのために豊かに雨を降らせ、前のように、秋の雨と春の雨とを降らせられる。
Ẹ jẹ́ kí inú yín dùn, ẹ̀yin ọmọ Sioni, ẹ sì yọ̀ nínú Olúwa Ọlọ́run yín, nítorí ó ti fi àkọ́rọ̀ òjò fún yín bí ó ti tọ́, Òun ti mú kí òjò rọ̀ sílẹ̀ fún un yín, àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò ní oṣù kìn-ín-ní.
24 打ち場は穀物で満ち、石がめは新しい酒と油とであふれる。
Àwọn ilẹ̀ ìpakà yóò kún fún ọkà; àti ọpọ́n wọn nì yóò sàn jáde pẹ̀lú ọtí wáìnì tuntun àti òróró.
25 わたしがあなたがたに送った大軍、すなわち群がるいなご、とびいなご、滅ぼすいなご、かみ食らういなごの食った年をわたしはあなたがたに償う。
“Èmi yóò sì mú ọdún wọ̀nyí ti eṣú jẹ run padà fún un yín. Èyí tí eṣú agénijẹ àti eṣú jewéjewé ọwọ́ eṣú agénijẹ àti kòkòrò ajẹnirun mìíràn ti fi jẹ àwọn ogun ńlá mi tí mo rán sí àárín yín.
26 あなたがたは、じゅうぶん食べて飽き、あなたがたに不思議なわざをなされたあなたがたの神、主のみ名をほめたたえる。わが民は永遠にはずかしめられることがない。
Ẹ̀yin yóò ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti jẹ, títí ẹ̀yin yóò fi yó ẹ ó sì yín orúkọ Olúwa Ọlọ́run yín, ẹni tí ó fi ìyanu bá yín lò; ojú kì yóò sì ti àwọn ènìyàn mi láéláé.
27 あなたがたはイスラエルのうちにわたしのいることを知り、主なるわたしがあなたがたの神であって、ほかにないことを知る。わが民は永遠にはずかしめられることがない。
Ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, èmi wà láàrín Israẹli, àti pé; Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, àti pé kò sí ẹlòmíràn, ojú kì yóò sì ti àwọn ènìyàn mí láéláé.
28 その後わたしはわが霊をすべての肉なる者に注ぐ。あなたがたのむすこ、娘は預言をし、あなたがたの老人たちは夢を見、あなたがたの若者たちは幻を見る。
“Yóò sì ṣe níkẹyìn ọjọ́, èmi yóò tú nínú Ẹ̀mí mí sí ara ènìyàn gbogbo; àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti àwọn ọmọ yín obìnrin yóò máa sọtẹ́lẹ̀, àwọn arúgbó yín yóò máa lá àlá, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yín yóò máa ríran.
29 その日わたしはまたわが霊をしもべ、はしために注ぐ。
Àti pẹ̀lú sí ara àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ ọkùnrin, àti sí ara àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ obìnrin, ní èmi yóò tú ẹ̀mí mí jáde ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì.
30 わたしはまた、天と地とにしるしを示す。すなわち血と、火と、煙の柱とがあるであろう。
Èmi yóò sì fi iṣẹ́ ìyanu hàn ní ọrun àti ní ayé, ẹ̀jẹ̀ àti iná, àti ọ̀wọ́n èéfín.
31 主の大いなる恐るべき日が来る前に、日は暗く、月は血に変る。
A á sọ oòrùn di òkùnkùn, àti òṣùpá di ẹ̀jẹ̀, kí ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ ẹ̀rù Olúwa tó dé.
32 すべて主の名を呼ぶ者は救われる。それは主が言われたように、シオンの山とエルサレムとに、のがれる者があるからである。その残った者のうちに、主のお召しになる者がある。
Yóò sí ṣe, ẹnikẹ́ni tí ó ba ké pè orúkọ Olúwa ní a ó gbàlà, nítorí ní òkè Sioni àti ní Jerusalẹmu ní ìgbàlà yóò gbé wà, bí Olúwa ti wí, àti nínú àwọn ìyókù tí Olúwa yóò pè.