< エゼキエル書 27 >

1 主の言葉がわたしに臨んだ、
Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé:
2 「人の子よ、ツロのために悲しみの歌をのべ、
“Ọmọ ènìyàn, pohùnréré ẹkún fún Tire.
3 海の入口に住んで、多くの海沿いの国々の民の商人であるツロに対して言え、主なる神はこう言われる、ツロよ、あなたは言った、『わたしの美は完全である』と。
Sọ fún Tire, tí a tẹ̀dó sí ẹnu-bodè Òkun, oníṣòwò àwọn orílẹ̀-èdè fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù. ‘Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: “‘Ìwọ Tire wí pé, “Ẹwà mi pé.”
4 あなたの境は海の中にあり、あなたの建設者はあなたの美を完全にした。
Ààlà rẹ wà ní àárín Òkun; àwọn ọ̀mọ̀lé rẹ ti mú ẹwà rẹ pé.
5 人々はセニルのもみの木であなたのために船板を造り、レバノンから香柏をとって、あなたのために帆柱を造り、
Wọn ṣe gbogbo pákó rẹ ní igi junifa láti Seniri; wọ́n ti mú igi kedari láti Lebanoni wá láti fi ṣe òpó ọkọ̀ fún ọ.
6 バシャンのかしの木で、あなたのためにかいを造り、クプロの島から来る松の木に象牙をはめて、あなたのために甲板を造った。
Nínú igi óákù ti Baṣani ní wọn ti fi gbẹ́ ìtukọ̀ ọ̀pá rẹ̀; ìjókòó rẹ ni wọn fi eyín erin ṣe pẹ̀lú igi bokisi láti erékùṣù Kittimu wá.
7 あなたの帆はエジプトから来るあや布であって、あなたの旗に用いられ、あなたのおおいはエリシャの海岸から来る青と紫の布である。
Ọ̀gbọ̀ dáradára aṣọ iṣẹ́ ọnà abẹ́rẹ́ láti Ejibiti wá ni èyí tí ìwọ ta láti fi ṣe àsíá ọkọ̀ rẹ; aṣọ aláró àti elése àlùkò láti erékùṣù ti Eliṣa ni èyí tí a fi bò ó.
8 あなたのこぎ手は、シドンとアルワデの住民、あなたのかじとりは、あなたのうちにいる熟練なゼメルの人々である。
Àwọn ará ìlú Sidoni àti Arfadi ni àwọn atukọ̀ rẹ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n ẹ̀rọ rẹ, ìwọ Tire, ni àwọn atukọ̀ rẹ.
9 ゲバルの老人たち、およびその熟練な人々は、あなたのうちにいて漏りを繕い、海のすべての船およびその船員らはあなたのうちにいて、あなたの商品を交易する。
Àwọn àgbàgbà Gebali, àti àwọn ọlọ́gbọ́n ibẹ̀, wà nínú ọkọ̀ bí òṣìṣẹ́ atukọ̀ rẹ, gbogbo ọkọ̀ ojú Òkun àti àwọn atukọ̀ Òkun wá pẹ̀lú rẹ láti dòwò pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.
10 ペルシャ人、ルデびと、プテびとはあなたの軍に加わって、あなたの戦士となる。彼らはあなたのうちに、盾とかぶとを掛け、あなたに輝きをそえた。
“‘Àwọn ènìyàn Persia, Ludi àti Puti wà nínú jagunjagun rẹ àwọn ẹgbẹ́ ọmọ-ogun rẹ. Wọ́n gbé asà àti àṣíborí wọn ró sára ògiri rẹ, wọn fi ẹwà rẹ hàn.
11 アルワデとヘレクの人々は、あなたの周囲の城壁の上にあり、ガマデの人々は、あなたのやぐらの中にあり、彼らは、あなたの周囲の城壁にその盾を掛けて、あなたの美観を全うした。
Àwọn ènìyàn Arfadi àti Heleki wà lórí odi rẹ yíká; àti àwọn akọni Gamadi, wà nínú ilé ìṣọ́ rẹ. Wọ́n fi àwọn asà wọn kọ ara odi rẹ; wọn ti mú ẹwà rẹ pé.
12 あなたはそのすべての貨物に富むゆえに、タルシシはあなたと交易をなし、銀、鉄、すず、鉛をあなたの商品と交換した。
“‘Tarṣiṣi ṣòwò pẹ̀lú rẹ torí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ tí ó ní; wọn ṣe ìpààrọ̀ fàdákà, irin idẹ àti òjé fún ọjà títà rẹ̀.
13 ヤワン、トバル、およびメセクはあなたと取引し、彼らは人身と青銅の器とを、あなたの商品と交換した。
“‘Àwọn ará Giriki, Tubali, Jafani àti Meṣeki, ṣòwò pẹ̀lú rẹ, wọ́n fi ẹrù àti ohun èlò idẹ ṣe pàṣípàrọ̀ fún ọrọ̀ rẹ.
14 ベテ・トガルマは馬、軍馬、および騾馬をあなたの商品と交換した。
“‘Àwọn ti ilé Beti-Togarma ṣe ìpààrọ̀ ẹṣin-ìṣiṣẹ́, ẹṣin ogun àti ìbáaka ṣòwò ní ọjà rẹ.
15 ローヅ島の人々はあなたと取引し、多くの海沿いの国々は、あなたの市場となり、象牙と黒たんとを、みつぎとしてあなたに持ってきた。
“‘Àwọn ènìyàn Dedani ni àwọn oníṣòwò rẹ, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù ni wọ́n jẹ́ oníbàárà rẹ̀; wọ́n mú eyín erin àti igi eboni san owó rẹ.
16 あなたの製品が多いので、エドムはあなたと商売し、彼らは赤玉、紫、縫い取りの布、細布、さんご、めのうをもって、あなたの商品と交換した。
“‘Aramu ṣòwò pẹ̀lú nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ òwò rẹ̀; wọn ṣe ìpààrọ̀ òkúta iyebíye, òwú elése àlùkò, aṣọ iṣẹ́ ọnà abẹ́rẹ́, aṣọ ọ̀gbọ̀ dáradára, ìlẹ̀kẹ̀ iyùn pupa fún ọjà títà rẹ.
17 ユダとイスラエルの地は、あなたと取引し、麦、オリブ、いちじく、蜜、油、および乳香をもって、あなたの商品と交換した。
“‘Juda àti Israẹli, àwọn ni oníṣòwò rẹ; wọn ṣe ìpààrọ̀ ọkà, Minniti, àkàrà àdídùn; oyin, epo àti ìkunra olóòórùn dídùn ni wọ́n fi ná ọjà rẹ.
18 あなたの製品が多く、あなたの富が多いので、ダマスコはあなたと取引し、ヘルボンの酒と、さらした羊毛と、
“‘Damasku ni oníṣòwò rẹ, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ọjà tí ó ṣe àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀; ní ti ọtí wáìnì tí Helboni, àti irun àgùntàn funfun láti Sahari,
19 ウザルの酒をもって、あなたの商品と交換し、銑鉄、肉桂、菖蒲をもって、あなたの商品と交易した。
àti ìdẹ̀ ọtí wáìnì láti Isali, ohun wíwọ̀: irin dídán, kasia àti kálàmù ni àwọn ohun pàṣípàrọ̀ fún ọjà rẹ.
20 デダンは乗物の鞍敷をもって、あなたと取引した。
“‘Dedani ni oníṣòwò rẹ ní aṣọ ìjókòó-lẹ́sin fún ẹṣin-gígùn.
21 アラビヤびと、およびケダルのすべての君たちは小羊、雄羊、やぎをもって、あなたと取引し、これらの物をあなたと交易した。
“‘Àwọn ará Arabia àti gbogbo àwọn ọmọ-aládé ìlú Kedari àwọn ni àwọn oníbàárà rẹ; ní ti ọ̀dọ́-àgùntàn, àgbò àti ewúrẹ́, nínú ìwọ̀nyí ni wọ́n ti jẹ́ oníbàárà rẹ.
22 シバとラアマの商人は、あなたと取引し、もろもろの尊い香料と、もろもろの宝石と金とをもって、あなたの商品と交換した。
“‘Àwọn oníṣòwò ti Ṣeba àti Raama, àwọn ni oníṣòwò rẹ; wọ́n ta onírúurú tùràrí olóòórùn dídùn dáradára ní ọjà rẹ, àti àwọn òkúta iyebíye àti wúrà.
23 ハラン、カンネ、エデン、アッスリヤ、キルマデはあなたと取引した。
“‘Harani àti Kanneh àti Edeni, àwọn oníṣòwò Ṣeba, Asiria àti Kilmadi, ni àwọn oníṣòwò rẹ.
24 彼らは、はなやかな衣服と、青く縫い取りした布と、ひもで結んで、じょうぶにした敷物などをもって、あなたと取引した。
Wọ̀nyí ní oníbàárà rẹ ní onírúurú nǹkan: aṣọ aláró, àti oníṣẹ́-ọnà àti àpótí aṣọ olówó iyebíye, tí a fi okùn dì, tí a sì fi igi kedari ṣe, nínú àwọn ilé-ìtajà rẹ.
25 タルシシの船はあなたの商品を運んでまわった。あなたは海の中にいて満ち足り、いたく栄えた。
“‘Àwọn ọkọ̀ Tarṣiṣi ní èrò ní ọjà rẹ a ti mú ọ gbilẹ̀ a sì ti ṣe ọ́ lógo ní àárín gbùngbùn Òkun.
26 あなたのこぎ手らはあなたを大海の中に進め、海の中で東風があなたの船を破った。
Àwọn atukọ̀ rẹ ti mú ọ wá sínú omi ńlá. Ṣùgbọ́n afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn yóò fọ́ ọ sí wẹ́wẹ́ ní àárín gbùngbùn Òkun.
27 あなたの財宝、あなたの貨物、あなたの商品、あなたの船員、あなたのかじ取り、あなたの漏りを繕う者、あなたの商品を商う者、あなたの中にいるすべての軍人、あなたの中にいるすべての仲間は皆、あなたの破滅の日に海の中に沈む。
Ọrọ̀ rẹ, ọjà rẹ àti àwọn ohun títà rẹ, àwọn ìṣúra rẹ, òṣìṣẹ́ ìtukọ̀ rẹ. Àwọn oníbàárà rẹ àti gbogbo àwọn jagunjagun rẹ, tí ó wà nínú rẹ, àti nínú gbogbo ẹgbẹ́ rẹ tí ó wà ní àárín rẹ yóò rì sínú àárín gbùngbùn Òkun ní ọjọ́ ìparun rẹ.
28 あなたのかじ取りの叫び声に、近郷は震い、
Ilẹ̀ etí Òkun yóò mì nítorí ìró igbe àwọn atukọ̀ rẹ.
29 すべてかいをとる者は船からくだる。船員および海のすべてのかじ取りは海べに立ち、
Gbogbo àwọn alájẹ̀, àwọn atukọ̀ Òkun àti àwọn atọ́kọ̀ ojú Òkun; yóò sọ̀ kálẹ̀ kúrò nínú ọkọ̀ wọn, wọn yóò dúró lórí ilẹ̀.
30 あなたのために声をあげて泣き、はげしく叫び、ちりをこうべにかぶり、灰の中にまろび、
Wọn yóò jẹ́ kí a gbọ́ ohùn wọn lòdì sí ọ wọn yóò sì sọkún kíkorò lé ọ lórí wọn yóò ku eruku lé orí ara wọn wọn yóò sì yí ara wọn nínú eérú.
31 あなたのために髪をそり、荒布をまとい、あなたのために心を痛めて泣き、はげしく嘆く。
Wọn yóò fá irun orí wọn nítorí rẹ wọn yóò wọ aṣọ yíya wọn yóò pohùnréré ẹkún pẹ̀lú ìkorò ọkàn nítorí rẹ pẹ̀lú ohùn réré ẹkún kíkorò.
32 彼らは悲しんで、あなたのために悲しみの歌をのべ、あなたを弔って言う、『だれかツロのように海の中で滅びたものがあるか。
Àti nínú arò wọn ni wọn yóò sì pohùnréré ẹkún fún ọ wọn yóò sì pohùnréré ẹkún sórí rẹ, wí pé: “Ta ni ó dàbí Tire èyí tí ó parun ní àárín Òkun?”
33 あなたの商品が海を越えてきた時、あなたは多くの民を飽かせ、あなたの多くの財宝と商品とをもって、地の王たちを富ませた。
Nígbà tí ọjà títà rẹ ti Òkun jáde wá ìwọ tẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè lọ́rùn ìwọ fi ọrọ̀ tí ó pọ̀ àti àwọn ọjà títà rẹ sọ àwọn ọba ayé di ọlọ́rọ̀.
34 今あなたは海で破船し、深い水に沈み、あなたの商品と、あなたのすべての船員とは、あなたと共に沈んだ。
Ní ìsinsin yìí tí Òkun fọ ọ túútúú nínú ibú omi; nítorí náà òwò rẹ àti gbogbo ẹgbẹ́ rẹ ní àárín rẹ, ni yóò ṣubú.
35 海沿いの国々に住む者は皆あなたについて驚き、その王たちは大いに恐れてその顔を震わす。
Ẹnu yóò ya gbogbo àwọn ti ń gbé ní erékùṣù náà sí ọ jìnnìjìnnì yóò bo àwọn ọba wọn, ìyọnu yóò sì han ní ojú wọn.
36 もろもろの民の中の商人らはあなたをあざける。あなたは恐るべき終りを遂げ、永遠にうせはてる』」。
Àwọn oníṣòwò láàrín àwọn orílẹ̀-èdè dún bí ejò sí ọ ìwọ yóò sì jẹ́ ẹ̀rù ìwọ kì yóò sì ṣí mọ́ láéláé.’”

< エゼキエル書 27 >