< 詩篇 26 >
1 ヱホバよねがはくはわれを鞫きたまへわれわが完全によりてあゆみたり 然のみならず我たゆたはずヱホバに依賴めり
Ti Dafidi. Ṣe ìdájọ́ mi, Olúwa, nítorí tí mo ti ń rìn nínú ìwà òtítọ́ ọ̀ mi, mo sì ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa, ǹjẹ́ ẹsẹ̀ mi kì yóò yẹ̀.
2 ヱホバよわれを糺しまた試みたまへ わが腎とこころとを錬きよめたまへ
Wádìí mi wò, Ìwọ Olúwa, kí o sì dán mi wò, dán àyà àti ọkàn mi wò;
3 そは汝のいつくしみわが眼前にあり 我はなんぢの眞理によりてあゆめり
nítorí ìfẹ́ ẹ̀ rẹ tí ó dúró ṣinṣin ń bẹ níwájú mi, èmí sì ti rìn nínú òtítọ́ rẹ.
4 われは虚しき人とともに座らざりき 惡をいつはりかざる者とともにはゆかじ
Èmi kò jókòó pẹ̀lú aláìṣòótọ́, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò bá àwọn àgàbàgebè wọlé.
5 惡をなすものの會をにくみ惡者とともにすわることをせじ
Èmi ti kórìíra àwùjọ àwọn ènìyàn búburú èmi kì yóò sì bá àwọn ènìyàn ìkà jókòó.
6 われ手をあらひて罪なきをあらはす ヱホバよ斯てなんぢの祭壇をめぐり
Èmí ó wẹ ọwọ́ mi ní àìlẹ́ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò sì yí pẹpẹ rẹ ká Olúwa.
7 感謝のこゑを聞えしめ すべてなんぢの奇しき事をのべつたへん
Èmi yóò kọrin sókè àní orin ọpẹ́, èmi yóò sì máa sọ iṣẹ́ ìyanu rẹ̀.
8 ヱホバよ我なんぢのまします家となんぢが榮光のとどまる處とをいつくしむ
Háà Olúwa, èmí ń fẹ́ ilé rẹ níbi tí ìwọ ń gbé, àní níbi tí ògo rẹ̀ wà.
9 願くはわがたましひを罪人とともに わが生命を血をながす者とともに取收めたまふなかれ
Má ṣe gbá mi dànù pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, tàbí ẹ̀mí mi pẹ̀lú àwọn ọkùnrin tí òǹgbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ,
10 かかる人の手にはあしきくはだてあり その右の手は賄賂にてみつ
àwọn tí ọwọ́ wọn kún fún ìwà ibi, tí ọwọ́ ọ̀tún wọn kún fún àbẹ̀tẹ́lẹ̀.
11 されどわれはわが完全によりてあゆまん願くはわれをあがなひ我をあはれみたまへ
Ṣùgbọ́n èmi ó máa rìn nínú ìwà títọ́; rà mí padà, kí o sì ṣàánú fún mi.
12 わがあしは平坦なるところにたつ われもろもろの會のなかにてヱホバを讃まつらん
Ẹsẹ̀ mi dúró lórí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú; nínú ìjọ ńlá èmi yóò fi ìbùkún fún Olúwa.